Ìwé
Ìwé
رسالة واحدة فقط!
Iṣẹ́-rírán kan ṣoṣo pere! Dokita Naaji ọmọ Ibrọ̄hīm Al-'Arfaj Ìyàsímímọ́ Fun gbogbo oluṣewadii nipa ododo pẹlu ootọ ati imọkanga Fun awọn oni laakaye oloye
Àwọn ọ̀nà tó ṣàǹfààní fún ìgbésí aye ìdùnnú
Tira "al-Wasā'ilul Mufīdah lil-Hayātis Sa'īdah" ti Sheik Abdur-Rahman bin Nasir As-Sa'di ni nṣalaye àwọn okunfa oriire gidi lati oju-iwoye ìgbàgbọ́ tí ó jìn, ó sì n ṣe amọna onkawe sí ìfọkànbalẹ̀ nípasẹ̀ Ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ rere, àti ìrántí Ọlọhun, àti ìní tẹlọrun, àti ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ìdẹra, àti ṣíṣe rere, àti gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọhun, àti sùúrù, àti gbígbé ọ̀ràn yẹ̀wò lọ́nà tó bójú mu, pẹ̀lú ọ̀nà tí ó rẹwà, tí ó gbé àwòrán ìtọ́sọ́nà kalẹ̀ síwájú rẹ fún ìgbésí ayé onífọkànbalẹ̀, tí ó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti oníriire tounh tí àwọn ìyípadà ayé .
Awọn ẹkọ ti o ṣe pataki fun gbogbo ali'ummah ( ìjọ musulumi)
Tira 'Ad-duruusul Muhimmah li 'aammatil Ummah' ( Awàn ẹkọ tí o pàtàkì fún apapọ ìjọ musulumi) ti alufaa agba Sheik Abdul Azeez ọmọ Bāz - ki Ọlọhun kẹ ẹ - jẹ́ ìwé tí o wa nisoki ṣùgbọ́n tí anfaani rẹ̀ pọ̀ yanturu, tí Imaamu ( asíwájú ẹṣin,) naa ṣe àkójọ rẹ láti jẹ́ ipese ìmọ̀ fún gbogbo Musulumi. Ó ṣe àlàyé àwọn ìpìlẹ̀ ẹsìn àti àwọn òpó rẹ̀ nínú rẹ , bẹ̀rẹ̀ láti orí ọrọ imọn Ọlọhun nikanṣoṣo Tawhiidi, Imaani, ìgbàgbọ àti Isilaamu, títí dé orí àwọn òfin imọra àti irun kíkí, àwọn ẹkọ rere ti Isilaamu kọ wa , àti àlàyé lórí ewu Ṣirik ( iṣẹ ẹbọ pẹlu Ọlọhun,) àti àwọn ìyapa Ọlọhun, pẹ̀lú ọ̀nà…
Adisọkan to ni alaafia ati ohun ti o takò ó, ati awọn nǹkan
Òǹkọ̀wé Pẹlu orukọ Ọlọhun Ọba Ajọkẹ ayé Àṣàkẹ́ ọrun. Ọrọ isiwaju Ọpẹ ni fun Ọlọhun nikan, ikẹ ati ọla ki o lọ maa ba ẹniti ko si Anọbi kankan mọ lẹyin rẹ, ati lori awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ.
الإسلام - نبذة موجزة عن الإسلام (مشتملة على الأدلة)
Ẹsin Isilaamu Eleyii ni akọsilẹ soki kan nipa ẹsin Isilaamu gẹgẹ bi o ṣe wa ninu Alikuraani alapọnle pẹlu Sunnah Anọbi Tira pataki to ko alaye nipa ẹsin Isilaamu sinu, to nṣalaye eyi ti o pataki ju ninu awọn ìpìlẹ, ẹkọ ati awọn ẹwa rẹ lati inu awọn iwe-ẹri ipile; eyi tii ṣẹ Alikuraani alapọnle ati Sunnah Anọbi. Tira yii eyi ti a fi nba gbogbo ẹniti o ti balaga sọrọ, yala o jẹ musulumi tabi kii tiẹṣe musulumi, to si wa ni ede onikaluku wọn, ko le baa wulo ni gbogbo asiko, aaye ati oniruuru iṣesi tabi ipo ti wọn ba wa. Ẹda kan niyi ti o ko awọn ẹri lati inu Alikurani ati Sunnah Anọbi sinu 1.…
المختصر المفيد للمسلم الجديد
Ọrọ ṣókí ti yoo ṣe anfaani fún Musulumi titun Ìgbéjáde Muhammad Ash-Shihriy 1441 - 2020 Pẹlu orukọ Ọlọhun Ajọkẹ ayé Àṣàkẹ́ ọ̀run Ọrọ itisiwaju
المنهج الوجيــز
Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun. Al-Wajiiz Ìlànà ẹkọ ti yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ fun Musulumi tuntun Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun. Ọrọ isiwaju Gbogbo ọpẹ jẹ ti Ọlọhun ti O fi ọna mọ wa fun Isilaamu, ti O tọ wa si awọn ọna ọla, ti O gbe ẹni ti o daa julọ ninu awọn eniyan dide ninu wa, - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. Lẹyin naa: O n dun mọ wa ninu lati ti eto ẹkọ yii si iwaju rẹ ti o maa sọ nipa ẹsin ododo (Ẹsin Isilaamu), ti o si maa ṣe alaye awọn nnkan ti o jẹ dandan lati mọ àti láti ṣe, lati le jẹ kọkọrọ fun ẹ lati da ẹsin rẹ mọ, ki o le jẹ olukunlọwọ fun ẹ lori…
الأذكار التي تقال صباحًا ومساءً
Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun. Àwọn asikiri ti a maa n sọ ni aarọ ati irọlẹ Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn…
الإسلام دين رسل الله
Islaamu ni ẹsin awọn ojiṣẹ Ọlọhun. Islaamu ni ijuwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun, Oluṣẹda ati Oludari gbogbo agbaye, ati itẹriba fun Un ni ti ifẹ ati gbigbetobi, ipilẹ Islaamu ni níní igbagbọ si Ọlọhun, ati pe Oun ni Ọba Asẹ́dàá, bẹẹ si ni ẹda ni gbogbo ohun tó yatọ Sii, ati pé Òun nikan ṣoṣo ni o tọ láti jọsin fún, ko si orogun fun Un, bẹ ni ko si ẹnikan ti a gbọdọ jọsin fun lododo ayafi Oun nikan, ti Rẹ̀ ni awọn orukọ tó rẹwa julọ ati awọn iroyin tó ga julọ, Oun ni O ni pipe laisi abuku, kò bimọ, ẹnikan ò si bi, bẹẹni ko si iru tabi alafijọ fun Un, ko si ki n ko si ara nkankan ninu awọn ẹda Rẹ̀.…
الإسلام دين رب العالمين
Ní orúkọ Ọlọ́hun, Ọba Àjọkẹ́ ayé, Ọba Àṣàkẹ́ ọ̀run Islaamu ni ẹsin Oluwa gbogbo agbaye Tani Oluwa rẹ? Eyi ni ibeere tí ó tobi julọ ni aye; o sì jẹ ibeere pataki ti eniyan gbọdọ mọ idahun rẹ̀. Oluwa wa, Oun ni Ẹniti O ṣẹda sanma ati ilẹ, O sì nsọ omi ojo kalẹ lati sanma, O sì n fi mú awọn eso ati awọn igi jade kó lè jẹ́ ounjẹ fun wa ati fun awọn ẹranko ti a n jẹ, Oun naa ni O ṣẹda wa, O ṣẹda awọn baba wa, O ṣẹda gbogbo nkan, Oun sì ni O dá oru ati ọsan, àti pé Oun ni O ṣe oru ni asiko oorun ati ìsinmi, O sì ṣe ọ̀sán ní asiko wiwa ounjẹ ati àsìkò fún wíwá ìjẹ-ìmu Oun ni O tẹ…
مقدمة وغلاف المنتقى من موسوعة الأحاديث النبوية
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. Ọrọ itisiwaju Ọpẹ ni fun Ọlọhun Ọba gbogbo agbaye, ikẹ ati ọla Ọlọhun kó maa bá Anabi wa Muhammad, ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ lapapọ, ati gbogbo awọn ti wọ́n tẹle wọn pẹlu dáadáa titi di ọjọ ẹsan, lẹ́yìn náà: Dájúdájú ohun tí ó tóbi julọ ninu awọn nkan ti o jẹ dandan ki mùsùlùmí ó ṣe akolekan rẹ; ni kika ati ironujinlẹ, pẹlu imọ ati iṣẹ - lẹyin Tira Ọlọhun - naa ni sunna ojiṣẹ Ọlọhun ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Mo fi silẹ fun yin, ẹyin eniyan, ohun tí ó ṣe pe ti ẹ ba di…
الشهادتين
Ti o ba fẹ wọ inu Islam, o gbọdọ sọ ijẹri ti o nbọ yii pẹlu ohùn tí eeyan ma gbọ, waa si gbọ itumọ rẹ ye, waa si ni igbagbọ si i: Mo gba lododo wipe kosi ẹniti ijọsin ododo tọsi ayaafi Allah (awọn gbolohun yii tumọ si pe kosi enikankan ti o lẹtọ si ijọsin ayaafi Allah), Mo si gba lododo wipe dajudaju anabi Muhammad ojiṣẹ Allah ni, ati pe dajudaju anabi Isa ọmọ Maryam ẹrusin Allah ati ojiṣẹ Rẹ ni. Mo gba lododo wipe kosi ẹniti ijọsin ododo tọsi ayaafi Allah, mo si gba lododo wipe dajudaju anabi Muhammad ojiṣẹ Allah ni.
Bí Anabi - kí ikẹ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - ṣe n kirun.
Ìwé 'Kayfiyyatu ṣalātin Nabiyy ﷺ ( Bí anọbi ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa bá ) ni Ọlọla wa Olumọ agba Abdul Azeez ọmọ Bāz - ki Ọlọhun kẹ ẹ - tí ko àsàyàn ọrọ ṣe lórí irun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, sínú rẹ, pẹ̀lú ọ̀nà ìgbékalẹ̀ tí ó rọrùn àti ìlànà tí ó péye, tí ó ní ìpìlẹ̀ nínú àwọn ìpìlẹ ọrọ tí ó jẹ́ ododo, láti jẹ́ amọ̀nà fún Musulumi nínú irun rẹ̀. Ó sì ti ṣàlàyé àwọn òpó irun kíkí, àwọn Sunna rẹ̀, àti àwọn ìrísí rẹ̀ nínú rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí alùwàlá títí dé orí Tasliim ( pipari irun pẹlu salaman , nígbàtí ó pa ẹ̀rí pọ̀ mọ́ àlàyé, tí ó n pèpè sí títẹ̀lé Anabi - ki ikẹ ati ọla…
Awọn ẹkọ Irinajo àti awọn ìdájọ rẹ
Ọpẹ ni fún Ọlọhun Olúwa gbogbo agbanlaaye, kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba Anọbi wa Muhammad àti awọn ará ilé rẹ àti awọn saabe rẹ lapapọ. Lẹyin naa: Eleyii ní àkójọ ọrọ ní ṣókí nipa awọn ẹkọ Irinajo àti awọn ìdájọ rẹ, a ṣe igbiyanju lati ṣalaye ọpọlọpọ nkan ti arinrin-ajo ni bukaata si. Ọlọhun (Allah) ni a nbẹ kí o ṣé ni nkan tí a ṣe nítorí Rẹ nìkan tí a si fi wa ojurere Rẹ, kí o si jẹ kí o wúlò fún apapọ gbogbo Musulumi. Alakọkọ: awọn ẹkọ Irinajo
Ọrọ ní ṣókí (aboode ọrọ) nípa bí aṣele ṣe iṣẹ Umrah àti awọn ìdájọ rẹ
Ọpẹ ni fun Ọlọhun Olúwa gbogbo àgbáyé, kí ikẹ àti ọla Ọlọhun máa ba Anọbi wa Muhammad àti awọn ara ilé rẹ àti awọn saabe rẹ lapapọ. Ọpẹ ni fun Ọlọhun Olúwa gbogbo àgbáyé, kí ikẹ àti igẹ Ọlọhun máa ba anọbi wa Muhammad ati awọn ara ilé rẹ àti awọn ọmọ lẹyìn rẹ lapapọ. Lẹyin naa: Eleyi ni idani lẹkọ ni ṣoki nipa bí aṣele ṣe ìjọsìn Umrah àti awọn idajọ àti ẹkọ rẹ, a gbiyanju láti ṣe àlàyé ọpọ nkán tí ẹni ti o nṣẹ Umrah ni bukaata sí nínú rẹ. À ń bẹ Ọlọhun pé kí O ṣe ni ohun tí a fi wa ojuure Rẹ Alapọnle, kí O si jẹ kí o wúlò fún gbogbo apapọ awọn musulumi.
Ọrọ ní ṣókí nipa bí a ṣe nṣe iṣẹ ìjọsìn Hajj
Ọpẹ ni fún Ọlọrun Olúwa gbogbo agbanlaaye, kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba Anọbi wa Muhammad àti awọn ará ilé rẹ àti awọn ọmọ lẹyìn rẹ lapapọ. Lẹyin naa: Eleyi ni àkànṣe ẹkọ ní ṣókí nipa síse isẹ ìjọsìn Hajj, o wuwa lati ṣe àlàyé ọpọ awọn nkan tí ẹniti o fẹ ṣẹ Hajj ni bukata sí nínú rẹ. Ọlọhun Allah ni a nbẹ kí o ṣeé ni nkan tí a se nítorí Rẹ nìkan tí a si fi wa ojurere Rẹ, kí o si jẹ kí o wúlò fún apapọ gbogbo Musulumi. ọ̀rọ̀ ìṣáájú
Àwọn ìwé méjì nisoki nípa zakah àti aawẹ.
Tira naa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọranyan meji tii ṣe zakah ati aawẹ, ó sì n ṣàlàyé àwọn ìdájọ́ wọn àti àwọn ànfàní wọn, pẹ̀lú ìránnilétí nípa àwọn ẹ̀tọ́ Ọlọhun lórí àwọn ẹrú Rẹ̀, ó sì ní àlàyé àwọn ìdájọ́ zakah àti àwọn onírúurú dúkìá tí à n yọ zakah nínú wọn, àti awọn ọlá tí n bẹ fún Ramadan àti àwọn ìdájọ́ aawẹ àti àwọn ẹkọ rẹ̀, pẹ̀lú ọ̀nà ìgbékalẹ̀ onímọ̀ tí ó kó papọ̀ láàrin fífẹsẹ̀ ìpìlẹ̀ ìsìn múlẹ̀ àti ìtọ́sọ́nà ìkọ́ni àti ireni.
Àwọn ọla àti àwọn ẹkọ Masalasi Anọbi, àti àwọn ìdájọ ṣíṣe àbẹ̀wò sí saare Anabi (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) àti saare àwọn ọrẹ rẹ mejeeji (kí Ọlọhun yọnu si wọn).
Tírà náà ṣe àlàyé àwọn ọlá àti pàtàkì Mọsalasi Anọbi àti àwọn ẹkọ ṣíṣe àbẹ̀wò sí i, bákan náà ó ṣe àfihàn àwọn ẹkọ ṣíṣe àbẹ̀wò sí saare Anọbi (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) àti saare àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjèèjì (kí Ọlọ́hun yọ́nú sí wọn), ó sì tẹnu mọ́ pàtàkì ìfarabale àti imọra àti jíjìnnà sí àwọn iṣẹ́ àdádáalẹ lásìkò ṣíṣe àbẹ̀wò.
Awọn iṣẹ ijọsin Hajj
Ìwé pélébé tó ṣe àlàyé ní ṣókí lórí àwọn iṣẹ́ ìjọsìn Hajj, bẹ̀rẹ̀ láti gbígbé harami ní ọjọ́ kẹjọ, títí kan àwọn iṣẹ́ ọjọ́ Arafa, ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìjọsìn ọjọ́ ọdún, àti jijú òkúta Jamarat, títí dé tawaafu ( irọkirika ile Ọlọhun) Ifaada àti tawaafu Wadaa (Irọkirika ilé Ọlọhun ti idagbere).