Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun. Àwọn asikiri ti a maa n sọ ni aarọ ati irọlẹ Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn…
Ní orúkọ Ọlọ́hun, Ẹni ti O ṣe pé, pẹ̀lu orúkọ Rẹ̀, kò si nkan kan ti o le kó ìnira báni, ní ilẹ ati sanmọ, Òun sì ni Olùgbọ́, Onímímọ̀.(A o sọ ọ ni ẹẹmẹta).
Mo yọ́nú sí Ọlọ́hun ní Olúwa mi, Mo yọ́nú sí Islam ní ẹ̀sìn mi, Mo sì yọ́nú sí Muhammad – kí ikẹ ati ọla Ọlọ́hun maa ba a – ní Anabi mi.(A o sọ ọ ni ẹẹmẹta).
A di òwúrọ̀, ti Ọlọhun si ni ijọba ní òwúrọ̀ naa, ọpẹ ni fún Ọlọhun, kò sí ọlọhun miran ayafi Ọlọhun (Allahu) nikan ṣoṣo, Ko si orogún fun Un, tiRẹ̀ ni ijọba, tiRẹ̀ sì ni ẹyìn, Oun ni Alagbara lori gbogbo nkan, Ìrẹ Ọlọhun mi, mo n beere lọwọ Rẹ oore nkan ti o wa ní ọjọ oni ati oore nkan ti o wa lẹyin ọjọ oni, mo si n wa iṣọ pẹlu Rẹ kuro nibi aburu nkan ti o wa ni ọjọ oni ati aburu nkan ti o wa lẹyin ọjọ oni, Irẹ Ọlọhun mi, mo n wa Ọ ni Olùṣọ́ kuro nibi òròjú, ogbó ati ìdàgbà burúkú, mo si n wa Ọ ni Olùṣọ́ kuro nibi iya ina ati iya inu saare.Ní àṣálẹ́, o maa sọ pe:A di aṣalẹ, ti Ọlọhun si ni ijọba ni aṣalẹ naa,O maa tún sọ pe:Irẹ Ọlọhun mi, mo n beere lọwọ Rẹ oore nkan ti o wa ni alẹ́ yii …A o sọ ọ títí dé ìparí, a o wí pé (A di aṣalẹ, ti Ọlọhun si ni ijọba ni aṣalẹ naa) dipo (A di òwúrọ̀, ti Ọlọhun si ni ijọba ní òwúrọ̀ naa), a o sì wipe: (alẹ́ yii) dipo (ọjọ yii).
Irẹ Ọlọ́hun, Ìwọ ni O mu wa di owurọ, Iwọ ni O mu wa di aṣalẹ, Iwọ ni O n mú wa yè, Iwọ ni O n mu wa kú, Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà.Ní àṣálẹ́, o maa sọ pe:Irẹ Ọlọhun, Iwọ ni O mu wa di aṣalẹ, Iwọ ni O mu wa di owurọ, Iwọ ni O n mu wa kú, Iwọ ni O n mu wa yè, ọdọ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá
Irẹ Ọlọhun, ìdẹ̀ra yòówù kó bá mi di owurọ tabi ọkan ninu awọn ẹda Rẹ, lati ọdọ Rẹ nikan ṣoṣo ni o ti wá, ko si orogun fun Ọ, nitori naa, tiRẹ ni ẹyin, tiRẹ sì ni ọpẹ.Ní àṣálẹ́, o maa sọ pe:Ìdẹ̀ra yòówù kó bá mi di aṣalẹ.
(A o sọ ọ ni ẹẹmẹta),
Irẹ Ọlọhun, dájúdájú mo n tọrọ alaafia lọwọ Rẹ ní aye ati ọrun, Irẹ Ọlọhun, dajudaju mo n tọrọ àmójúkúrò ati alaafia lọwọ Rẹ ninu ẹsin mi, ayé mi, ará ilé mi, ati dukia mi, Irẹ Ọlọhun, bo aṣiri àwọn ìhòhò mi, fi mí lọkan balẹ nibi gbogbo ohun tí n bami lẹru, Irẹ Ọlọhun, ṣọ mi lati iwaju mi, lati ẹyin mi, lati apa ọtun mi, lati apa osi mi, àti láti apa oke mi, mo sì n wá ìsọ́ pẹlu títóbi Rẹ kuro nibi kí wọ́n fi àdánwò kàn mí lati isalẹ mi.
Irẹ Ọlọ́hun, Ìwọ ni Oluwa mi, ko si Ọlọhun miran ayafi Ìwọ, Ìwọ ni O dá mi, ẹru rẹ sì ni mo jẹ́, mo duro pẹlu majẹmu ati adehun Rẹ bí mo ti lagbara mọ, mo n wa ìṣọ́ lọdọ Rẹ kuro nibi aburu ohun tí mo ṣe níṣẹ́, mo jẹwọ idẹra Rẹ lori mi fun Ọ, mo sì jẹwọ ẹṣẹ mi, nítorí náà fori jin mi, nitori pé dajudaju kò sí ẹniti ó le fori jin eniyan ayafi Ìwọ.
Irẹ Ọlọ́hun, Oluṣẹda àwọn sanmọ ati ilẹ, Olumọ kọ̀kọ̀ ati gbangba, Oluwa gbogbo nkan ati Olukapa rẹ, mo n jẹrii pe ko si ọlọhun miran ayafi Ìwọ, mo n wa ìṣọ lọdọ Rẹ kuro nibi aburu ẹmi mi ati aburu eṣu ati ẹbọ tó n pèpè si, ati pé ki n ṣe aburu sí ẹmi ara mi tabi pé ki n ṣé e sí musulumi kan.
Irẹ Ọlọ́hun, mo jí ni owurọ ni ẹni tí n fi Ọ ṣe Ẹlẹ́rìí, mo sì n fi àwọn tó gbé aga alaaraṣi Rẹ dání ṣe ẹlẹ́rìí, ati àwọn Malaika Rẹ, ati àwọn Anabi Rẹ, ati gbogbo ẹda Rẹ, pé dajudaju Ìwọ ni Ọlọhun, ko si ọlọhun miran ayafi Ìwọ, àti pé dajudaju Muhammad ẹru Rẹ ni, ojiṣẹ Rẹ sì ni.Ní àṣálẹ́Irẹ Ọlọ́hun, mo di àṣálẹ́ ...A o sọ ọ títí dé ìparí (ni ẹẹmẹrin)
Ko si ọlọhun miran ti ìjọsìn tọ si pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ayafi Ọlọhun (Allah) nikan ṣoṣo, ko si orugun fun Un, tiRẹ ni ijọba, tiRẹ sì ni ẹyin, Ohun ni Alagbara lori gbogbo nkan.(A o sọ ọ nigba ọgọ́rùn-ún) ní òwúrọ̀ tabi àṣálẹ́.
Ọlọhun tó fún mi, ko si ọlọhun miran ti ìjọsìn tọ́ sí pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ayafi Oun, Oun ni mo gbarale, Oun sì ni Ọba ti O ni aga aliaraṣi ńlá.(A o sọ ọ ni ẹẹmeje).
Mímọ́ ni fún Ọlọhun pẹlu ẹyìn ni fun Un(A o sọ ọ nigba ọgọ́rùn-ún) ni owurọ tabi àṣálẹ́. Tabi ni igba mejeeji.
Mo n tọrọ aforijin lọdọ Ọlọhun, Mo sì n ronupiwada lọ sí ọdọ Rẹ̀.(A o sọ ọ nigba ọgọ́rùn-ún).
Eyi ni ohun tí ó rọrùn lati kọ, Mo n beere lọwọ Ọlọhun Ọba Aleke ọlá pé kí Ó fi ṣe anfaani fún àwọn eniyan.
Muhammad Al-Salih Al-Uthaimeen ni o kọ ọ ní ọjọ 20-1-1418 AH.
Bí Anabi - kí ikẹ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - ṣe n kirun.
75 èdè
Bí Anabi - kí ikẹ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - ṣe n kirun.
Ìwé 'Kayfiyyatu ṣalātin Nabiyy ﷺ ( Bí anọbi ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa bá ) ni Ọlọla wa Olumọ agba Abdul Azeez ọmọ Bāz - ki Ọlọhun kẹ ẹ - tí ko àsàyàn ọrọ ṣe lórí irun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, sínú rẹ, pẹ̀lú ọ̀nà ìgbékalẹ̀ tí ó rọrùn àti ìlànà tí ó péye, tí ó ní ìpìlẹ̀ nínú àwọn ìpìlẹ ọrọ tí ó jẹ́ ododo, láti jẹ́ amọ̀nà fún Musulumi nínú irun rẹ̀. Ó sì ti ṣàlàyé àwọn òpó irun kíkí, àwọn Sunna rẹ̀, àti àwọn ìrísí rẹ̀ nínú rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí alùwàlá títí dé orí Tasliim ( pipari irun pẹlu salaman , nígbàtí ó pa ẹ̀rí pọ̀ mọ́ àlàyé, tí ó n pèpè sí títẹ̀lé Anabi - ki ikẹ ati ọla…
Tira "al-Wasā'ilul Mufīdah lil-Hayātis Sa'īdah" ti Sheik Abdur-Rahman bin Nasir As-Sa'di ni nṣalaye àwọn okunfa oriire gidi lati oju-iwoye ìgbàgbọ́ tí ó jìn, ó sì n ṣe amọna onkawe sí ìfọkànbalẹ̀ nípasẹ̀ Ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ rere, àti ìrántí Ọlọhun, àti ìní tẹlọrun, àti ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ìdẹra, àti ṣíṣe rere, àti gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọhun, àti sùúrù, àti gbígbé ọ̀ràn yẹ̀wò lọ́nà tó bójú mu, pẹ̀lú ọ̀nà tí ó rẹwà, tí ó gbé àwòrán ìtọ́sọ́nà kalẹ̀ síwájú rẹ fún ìgbésí ayé onífọkànbalẹ̀, tí ó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti oníriire tounh tí àwọn ìyípadà ayé .
Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun. Al-Wajiiz Ìlànà ẹkọ ti yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ fun Musulumi tuntun Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun. Ọrọ isiwaju Gbogbo ọpẹ jẹ ti Ọlọhun ti O fi ọna mọ wa fun Isilaamu, ti O tọ wa si awọn ọna ọla, ti O gbe ẹni ti o daa julọ ninu awọn eniyan dide ninu wa, - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. Lẹyin naa: O n dun mọ wa ninu lati ti eto ẹkọ yii si iwaju rẹ ti o maa sọ nipa ẹsin ododo (Ẹsin Isilaamu), ti o si maa ṣe alaye awọn nnkan ti o jẹ dandan lati mọ àti láti ṣe, lati le jẹ kọkọrọ fun ẹ lati da ẹsin rẹ mọ, ki o le jẹ olukunlọwọ fun ẹ lori…