الإسلام دين رسل الله
رسالة لطبفة توضح أن الإسلام هو الاستسلام لله خالق الكون والانقياد له محبة وتعظيماً، وهو دين جميع الأنبياء، يقوم على الإيمان بالله، ورسله، وملائكته، وكتبه، واليوم الآخر، والقدر خيره وشره. ويدعو إلى عبادة الله وحده، ويرى أن عيسى عبد الله ورسوله وليس ابن الله.
Islaamu ni ẹsin awọn ojiṣẹ Ọlọhun.
Islaamu ni ijuwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun, Oluṣẹda ati Oludari gbogbo agbaye, ati itẹriba fun Un ni ti ifẹ ati gbigbetobi, ipilẹ Islaamu ni níní igbagbọ si Ọlọhun, ati pe Oun ni Ọba Asẹ́dàá, bẹẹ si ni ẹda ni gbogbo ohun tó yatọ Sii, ati pé Òun nikan ṣoṣo ni o tọ láti jọsin fún, ko si orogun fun Un, bẹ ni ko si ẹnikan ti a gbọdọ jọsin fun lododo ayafi Oun nikan, ti Rẹ̀ ni awọn orukọ tó rẹwa julọ ati awọn iroyin tó ga julọ, Oun ni O ni pipe laisi abuku, kò bimọ, ẹnikan ò si bi, bẹẹni ko si iru tabi alafijọ fun Un, ko si ki n ko si ara nkankan ninu awọn ẹda Rẹ̀.
Ati pé Islaamu ni ẹsin Ọlọhun Ọba tó ga, ti ko ni gba ẹsin miran lọwọ awọn eniyan yatọ si i, oun na si ni ẹsin tí gbogbo awọn Anabi mú wá, ki alaafia o maa ba wọn.
Lara awọn ipilẹ Islaamu ni igbagbọ ninu gbogbo awọn ojiṣẹ, ati pe dajudaju Ọlọhun rán awọn ojiṣẹ lati jẹ isẹ awọn ofin Rẹ̀ fun awọn ẹru Rẹ̀, O sì sọ awọn tira kalẹ fun wọn, ti ẹni ti o kẹyin ninu wọn si jẹ Muhammad -ki alaafia Ọlọhun maa ba a-, Ọlọhun ran pẹlu ofin atọrunwa (sharia) tí o je ipari awọn ofin, tí o si tun rọpo gbgbo ofin ati ilana awọn ojiṣẹ tó ṣiwaju rẹ̀, Ọlọhun kun lọwọ pẹlu awọn àamì titobi, eyi tí ó tobi julọ ninu rẹ̀ ni Al-Qur’an Alapọnle, ọrọ Oluwa gbogbo agbaye, iwe ti o tobi julọ ti iran eniyan mọ ri, o jẹ iyanu ninu akóónú rẹ, ninu ọrọ rẹ̀ ati ninu eto rẹ̀, inu rẹ̀ ni itọsọna si ododo ti n samọna si orire aye ati ọrun, ati pe ó wà ninu iṣọ àti ààbò titi di ọjọ oni pẹlu ede Larubawa ti a fí sọ kalẹ, wọn kò yi pada, bẹẹni wọn kò paarọ dede ẹyọ lẹta kan ninu rẹ̀,
ninu awọn ipilẹ Islaamu ni igbagbọ ninu awọn Malaika, ati igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin, ninu ọjọ na ni Ọlọhun yoo ji awọn eniyan dide lati inu saare wọn -ọjọ igbedide- lati ṣe isiro fun wọn nipa awọn iṣẹ wọn, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ rere ti o si ni igbagbọ; idẹra gbere yoo maa jẹ tirẹ̀ ninu ile Al-jannah, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣaìgbàgbọ́ tí ó sì ṣe iṣẹ́ buburú, tirẹ̀ ni iya titobi nínú ina jahannama, ninu awọn ipilẹ Islaamu bakana ni igbagbọ ninu Kádàrá ti Ọlọhun kọ silẹ, yala o jẹ ohun rere ni tabi ohun aburu.
Awọn Musulumi gbagbọ wipe Isah ẹru Ọlọhun ni, ojiṣẹ Rẹ̀ sì ni pẹlu, ati wipe kii ṣe ọmọ Ọlọhun; nitoripe Ọlọhun tobi lọla, kò ni yẹ fun lati ní iyawo tabi ọmọ, sugbọn Ọlọhun sọ fun wa ninu Al-Qur’an wipe Isah jẹ Anabi kan ti Ọlọhun fun un ni ọpọlọpọ iṣẹ iyanu, ati pe Ọlọhun ran an lati pe awọn eniyan rẹ̀ sibi ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, Ó tun sọ fún wa pé Isah kò ní kí awọn eniyan jọ́sìn fún òun, kàkà bẹ́ẹ̀, oun funra rẹ̀ n jọsin fun Ọlọhun Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni.
Islaamu jẹ ẹsin tí ó ní ibamu pẹlu àdámọ́ ati ọpọlọ pipe, ti awọn ẹmi tí o wa ni deede sì n tẹwọgba a, Ọlọhun Ẹlẹdaa tó Tobi ló ṣe e lofin fun awọn ẹda Rẹ̀, oun ni ẹsin daada ati orire fun gbogbo eniyan lapapọ, kò ya ìran kan sọ́tọ̀ sí ìran mìíràn, bẹẹni kò ya àwọ̀ kan sọ́tọ̀ sí àwọ̀ mìíran, dọ́gbadọ́gba ni àwọn ènìyàn wà nínú rẹ̀, ẹnikẹni kò lè ni ọla ju ẹlòmíràn lọ nínú ẹsin Islaamu ayafi pẹlu bí iṣẹ́ rere rẹ̀ ba ṣe pọ̀ tó.
Ó jẹ́ ọ̀ranyàn fún gbogbo onilaakaye lati gba Olohun gbọ gẹ́gẹ́ bí Oluwa, ati ẹsin Islaamu gẹ́gẹ́ bi ẹsin rẹ̀, kó sì gba Muhammad gbọ ni Ojiṣẹ, kò sí ìṣẹ̀ṣà fun ọmọniyan ninu awọn nkan wọnyi, nitoripe Ọlọhun yoo beere lọwọ ni ọjọ Ajinde nipa ohun ti o fi da awọn ojiṣẹ lohun; Ti o bá jẹ́ onigbagbọ ododo, erenjẹ tó tobi n bẹ fun, sugbọn tí ó bá jẹ alaigbagbọ, tirẹ ni òfò tó han gbangba.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ wọ inú ẹ̀sìn Islaamu yoo sọ pé: (Ash-hadu an laa ilaaha illaa Allah wa ash-hadu anna Muhammada-n-rasulu-Llah) èyí tí o túmọ sí pé: (mo jẹri pé kòsí ẹni kankan tí o lẹtọ láti jọsin fun ayaafi Allah Ọlọhun, mo sí jẹri pe Muhammad òjíṣẹ Ọlọhun ni), pẹlu mimọ ìtumọ rẹ̀ ati níni igbagbọ nínú rẹ̀, nipa eyi ni yoo di musulumi; Lẹyin naa ni yoo maa kọ awọn eyi tókù ninu awọn ofin Islaamu diẹdiẹ; láti lè mu awọn nnkan tí Ọlọhun ṣe ni ọranyan fún un sẹ.
Fún àlékún ìmọ àti àlàyé: