المختصر في صفة العمرة وأحكامها
Ọrọ ní ṣókí (aboode ọrọ) nípa bí aṣele ṣe iṣẹ Umrah àti awọn ìdájọ rẹ
Ọrọ ní ṣókí (aboode ọrọ) nípa bí aṣele ṣe iṣẹ Umrah àti awọn ìdájọ rẹ
Ọpẹ ni fun Ọlọhun Olúwa gbogbo àgbáyé, kí ikẹ àti ọla Ọlọhun máa ba Anọbi wa Muhammad àti awọn ara ilé rẹ àti awọn saabe rẹ lapapọ. Ọpẹ ni fun Ọlọhun Olúwa gbogbo àgbáyé, kí ikẹ àti igẹ Ọlọhun máa ba anọbi wa Muhammad ati awọn ara ilé rẹ àti awọn ọmọ lẹyìn rẹ lapapọ.
Lẹyin naa:
Eleyi ni idani lẹkọ ni ṣoki nipa bí aṣele ṣe ìjọsìn Umrah àti awọn idajọ àti ẹkọ rẹ, a gbiyanju láti ṣe àlàyé ọpọ nkán tí ẹni ti o nṣẹ Umrah ni bukaata sí nínú rẹ.
À ń bẹ Ọlọhun pé kí O ṣe ni ohun tí a fi wa ojuure Rẹ Alapọnle, kí O si jẹ kí o wúlò fún gbogbo apapọ awọn musulumi.
Ìgbìmọ̀ imọ ni ijọ ti n ṣe iṣẹ sin ohun tí wọn kojọ pọ (nipa ẹsin Ìslámù) pẹlú orisirisi ede:
ọ̀rọ̀ ìṣáájú
Alakọkọ: awọn mọjẹmu titẹwọ gba ìjọsìn wọle.
Ìjọsìn o ní di gbígba wọlé lọdọ Ọlọhun tí ọlá Rẹ ga jùlọ ayaafi pẹlu majẹmu méjì:
Iṣe ìjọsìn ní mimọ (fun Ọlọhun), iyẹn ni pé kí a fi (ìjọsìn na) wa ojurere Ọlọhun àti ile igbẹyin, Ọlọhun tí Ọlá Rẹ ga jùlọ sọ pé: (A kò sì pa wọ́n laṣẹ ju pé kí nwọ́n jọ́sìn fún Ọlọhun lọ, ki nwọ́n fọ ẹ̀sin mọ́ fun U, ki nwọ́n si dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn) [1], [Al-bayyinah: 5]. [1] Ìtumọ ni pé: wọn dajúkọ (Ọlọhun) wọn gbajumọ ìjọsìn fún Un, tí wọn si sẹri kúrò lọdọ nkan tó yatọ si I. Tira itúmọ Qur'an tí onimimọ As-sa'adi kọ (ojú ewé 538)
Anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba a sọ pé: "Dajudaju gbogbo iṣẹ pẹ̀lú àníyàn ni, gbogbo eniyan kọ̀ọ̀kan si ni yio gbẹsan aniyan ti o fi ṣiṣe" [2]. [2] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (1), àti Muslim pẹlu onka (1907).
Titẹle Anọbi níni (ìjọsìn) nipa ọrọ àti nipa iṣẹ, Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba- sọ pé: "Ẹnikẹni ti o ba da adadaalẹ kan sinu alamọri wa yii ninu nnkan ti ko si nibẹ, a o da pada ni" [3] Nínú ẹgbawa miran: "Ẹni ti o ba ṣe iṣẹ kan (ninu ẹsin) ti ko si àṣẹ wa lori rẹ, yio di adapada" [4]. [3] Al-bukhari lo gbaa wa, pẹlu onka (2697), àti Muslim, pẹlu onka (1718) [4] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1718).
***
Ẹlẹẹkeji: idajọ kíkọ́ bí a ti nṣe ìjọsìn Umrah àti awọn ìdájọ́ rẹ
O dara fún ẹni tí o ba fẹ ṣe iṣẹiṣẹ ìjọsìn kan fún Ọlọhun -tí ọlá Rẹ ga jùlọ- ki o kọ ilana Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti Ọla Rẹ maa baa- ninu ìjọsìn naa; kí iṣẹ rẹ le wa ni ìbámu sí ilana àti alaalẹ Anọbi, Anọbi fúnra rẹ -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa baa- a maa gba awọn ènìyàn níyànjú láti máa tẹ le, kí wọ́n si máa tẹlé imọna rẹ; ẹgbawa ọrọ wa láti ọdọ Maalik ọmọ Al-Huwairis -kí Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: òjíṣẹ Ọlọhun -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba- sọ pé: "Ẹ máa kirun gẹgẹ bí ẹ ṣe rí mi tí mo ṣe nkirun" [5]. [5] Al-bukhari lo gba wa, pẹlu onka (6008).
Láti ọdọ Jaabir -kí Ọlọhun yọnu si-, o sọ pé: "Mori Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba- ní ọjọ igunran tí o nsọ òkúta (ni ibusọko ni Haji) láti orí rankumi rẹ, o si nsọ bayii pé: "ẹ gba (ẹ kọ imọ) bi ẹ ti ma ṣe iṣe Haji yin (lọ́wọ́ mi), nítorípé èmi ò mọ̀ọ, o le ṣee ṣe kí nma ṣe isẹ Haji mii mọ lẹyin eleyi i" [6]. [6] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1297).
***
Ẹlẹẹkẹta: Ọlá ti o wa fún Umrah
Umrah ni ọlá (orisi) méjì: (ọlá) ti gbogbogbò (alapapọ) àti eyi ti o dawa.
Eyi ti o jẹ ti gbogbogbò (Alapapọ):
Lati ọdọ Abu Hurayrah -ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa báa- sọ pé: "Umrah kan sí Umrah miran aa máa ṣe iparẹ àti ìtanràn awọn aṣiṣe tí o ba waye láàrin méjèjì, bẹẹni Hajji daada (eyii ti o pe) kò ní ẹsan kan tí o ju ọgbà idẹra (Alujanna) lọ) [7]. [7] Al-bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (1773), àti Muslim, pẹlu onka (1349).
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd –ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba- sọ pe: "Ẹ maa ṣe Hajj àti Umura tẹlera wọn, nitoripe dájúdájú awọn méjeejì a máa gban ìṣẹ (òṣì) ati awọn ẹsẹ danu, gẹgẹ bi ina (iderọ) ṣe máa n yọ idọti ara irin, àti wura, àti fàdákà danu, kò wa sí ẹsan miiran fún Hajji tí a gba (Al-maroor) bí ko ṣe Al-Jannah" [9]. [8] Ààyè inan Alagbẹdẹ àti ẹni tonrọ irin.Tira: At-Tamhid tí Ibnu Abdil-Barr ṣe (15/102) [9] At-Tirmidhi lo gba wa, pẹlu onka (810), àti An-Nasa'i, pẹlu onka (2631).
Èyí tí o da wà lọtọ ni ti inú Ramadan: láti ọdọ ọmọ Abbas -kí Ọlọhun yọnu si awọn méjeejì- o sọ pé dájúdájú Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba- sọ pé: "ṣíṣe Umrah kan nínú osù Ramadana se déédé ṣíṣe Hajji pẹlu mi" [10]. [10] Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1863), ati Muslim, pẹlu onka (1256).
***
Alaye bi a ti n ṣe Umura
Alakọkọ: awọn ìdájọ awọn àsìkò ati aaye igbaradi fún isẹ Hajji tàbí Umrah
Al-Mawaqit ni: awọn ààyè tí Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba a- ti se adayanri rẹ (ṣe àlàyé rẹ) kí ẹni tí o fẹ se ìsẹ Hajji tàbí Umrah le ti àti aaye na gbe aniyan ìjọsìn náà.
Ẹni kẹni tí o ba gba ọkan nínú awọn ààyè náà kọjá ti o si ní èrò láti ṣe HajjI tàbí Umrah: ọranyan ni o jẹ fun kí o daaàníyàn fun ìjọsìn náà níbi aaye náà, kò si tọ fun láti kọjá ààyè náà lai mú àníyàn wa (lai gbé asọ arami wọ).
Ẹni kẹni tí o ba sunmọ Makkah ju awọn ààyè yii lọ: dájúdájú ààyè tí naa ni yóò ti gbaradi, tí yóò si mú àníyàn Hajj àti Umrah wá láti ibẹ.
Ẹẹ rí awọn ará ìlú Makkah ati ẹni tí o ba ni ero bibẹrẹ iṣẹ [Hajji tabi Umura] lati inu ilu Makkah: wọn yóò daaniyan Hajj láti Makkah, ṣugbọn ìjọsìn ti umrah: wọn ní láti jáde lọsí ẹyin ilu Makkah gẹgẹ bí At-Tan'iim àti ibi to fara jọ ọ kí wọn lè daniyan iṣẹ ìjọsìn náà lati ibẹ.
Ẹni tí o ba wà nínú ọkọ òfurufú: yóò daniyan nigbati ọkọ òfurufú náà ba ti wa ni ògángán ààyè idaniyan iṣẹ Hajj àti Umrah, yóò sí mura, bẹẹ ni yóò wọ aṣọ (Ihromu) re siwaju ki o to de ògángán ààyè idaniyan, ki o si daniyan lẹsẹ kẹṣẹ ti o ba ti wa ni ògángán ààyè na, kò si tọ fun láti lọọ lára di igba tí yóò sọkalẹ ní ibùdó kọ ofurufu, o si ṣe se fun kí o ko akoyawọ fún kí o tí daniyan síwájú ki o to dé ògán gán ààyè idaniyan nítorí ìbẹrù kí o mọ kọ ja ààyè na; nítorí yiyara ọkọ ofurufu.
Ẹlẹẹkeji: Alaye bí a se n daaniyan (Hajji tàbí Umrah) ati awọn idajọ re:
A se l'òfin (ẹṣin) fún ẹni to ba fẹ gbe arami (Hajji tàbí Umrah) lati ṣe awọn nnkan wọn yii ni:
1- Iwẹ (Ghuslu), eyi si jẹ ìlànà Anọbi tí o kan pa lori ọkunrin àti obìnrin titi o fi de orí obìnrin tí nṣe nkan oṣù àti obinrin tí se ẹjẹ ibimọ lọwọ.
2- Lilo lọfinda olòórùn dídùn tó dára jù lọ tí eiyàn bá rí; yálà lọfinda (Oud) ni tàbí omìíràn si orí rẹ àti irungbọn rẹ, Ko sì sí aburú kankan bí òórùn náà bá ṣì kù lẹ́yìn tí ó bá ti wọ asọ Ihram. Ṣugbọn fun obinrin, kò lẹtọ fun un láti lo nnkan olòórùn dídùn; kí awọn ọkunrin ajoji ma baa gboorun náà lara rẹ.
3- Wíwọ aṣọ arami (Ihrọmu), òun ni aṣọ ilọdi àti asọ ikọrun, ìlànà Anọbi ni ki o jẹ aṣọ funfun méjì tí o mọn tóní tàbí tuntun. Obìnrin le wọ aṣọ ti o ba wù láti ṣẹ Hajji tabi Umura ni eyi tí kò ní fi ihoho ati ọsọ ara rẹ silẹ, sugbọn yóò jina sí wíwọ ìbojú (Nikobu) àti ibọwọ méjèjì, o si le bo ojú rẹ àti ọwọ rẹ méjèjì pẹlu nkan míràn yatọ sí eyiun (Nikobu ati ibọwọ).
4- Sunnah si ni ki a gbe arami (aniyan iṣẹ Hajji tabi Umura) lẹyìn ti a ba kiirun, yala irun ọranyan ni tàbí irun Naafilah).
Tí yóò si máa sọ pé: (mo wa jẹ'pe Rẹ Irẹ Ọlọhun fún ìjọsìn Umurah) tí o ba se pé o fẹ se Umurah náà dipo ẹlòmíràn ni yóò sọ pé: (mo jẹ'pe Rẹ fún Umurah ni orúkọ Lagbaja).
Tí o ba se pé ẹnì tí o fẹ bẹrẹ iṣẹ Hajji tàbí Umrah ba nbẹrù idiwọ kan tí o le dii lọwọ láti má lee pari ìjọsìn rẹ, o dara fun kí o sẹ majẹmu kalẹ nígbàtí o ba fẹ daaniyan tí yóò sọpe: (mọ jẹ ipe Rẹ fun Umurah, tí nnkan kan ba dii mi lọwọ ààyè tí o ba ti mumi mọlẹ náà ni iṣẹ ìjọsìn mi ti pari) gbogbo igba ti o ba ti fi majẹmu yí le'lẹ tí nkankan ba wa dii lọwọ láti má parí ìjọsìn náà yóò bọ aṣọ arami rẹ silẹ bẹẹ kò sí ni si ìtanràn kankan lori rẹ.
Leyin naa yóò ma wi gbólóhùn ijẹpe Ọlọhun ní ọpọlọpọ: (Mo jẹpe Rẹ Irẹ Ọlọhun ipe rẹ ni mo jẹ, mo jẹpe Rẹ kò sí orogun fun Ọ, mo jẹpe Rẹ, dájúdájú ọpẹ (ẹyìn) ati idẹra àti ọlá/akoso ti Rẹ Ọlọhun nii se, kò sí orogun fún Ọ) [11], okunrin yóò ma gbé òun rẹ sókè lati ma wi, bẹẹ ni obìnrin náà; lópin ìgbàtí ko ba sí nibi tí awọn ọkunrin araata wa, o yẹ fún ẹni tí o nṣe iṣẹ (Umrah tabi Hajji) kí o máa wi gbólóhùn ijẹpe yii ni ọpọlọpọ, pàtàkì jù lọ nígbàtí ìsesí àti àsìkò rẹ ba ti nyi padà, gẹgẹ bí kí o gun ààyè tí o ga, tàbí kí o sọ kalẹ sí ilẹ tí o tẹju, tàbí nigbat ti òru tàbi ni osan ba wọle. [11] Ìtumọ kí ènìyàn sọ pe (Labbaika) nipe: Mo jẹpe Irẹ Ọlọhun Olúwa mi léraléra, ìtumọ rẹ si nipe: jíjẹpe ènìyàn fún Ọlọhun Olúwa rẹ àti ìdúró sinsin lórí titẹ le aṣẹ Rẹ. (Innal-hamda wan-Ni''imata laka wa-l-Mulk" Alhamdu: oun ni riroyin ẹni tí a nnyin pẹlu pípé pẹlu ifẹ àti gbigbee ga, tí a ba wa paara rẹ yóò di ìyìn. (wa-n-Ni'imata): oun ni ohun ti Ọlọhun fi n ṣe ọlá atí ibukun fún awọn ẹrú Rẹ nipa fifun wọn ní ohun tí wọn wa ati nipa gbigbe aburu jina si wọn. Gbólóhùn rẹ tí o sọ pe (Al-Mulk) tumọ si pe: Tirẹ ni akoso àti ọlá, Ọlọhun Mimọ tí ọlá Rẹ si ga ni Ẹni tí o ni gbogbo nkan ni ohun nikan soso. Gbólóhùn rẹ: (Laa shareeka lak) iyẹn nipe; kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè bá Ọlọ́hun -Ti o ga julọ- pin ninu awọn Iroyin Rẹ̀ tí ó péye, nínú rẹ naa si ni ijẹ ọkan ṣoṣo Re níbi ìkápá ọlá àti idẹda àti ìdarí gbogbo eto awọn ẹdá àti ijẹ Olúwa tí o yẹ kí a máa fi ìjọsìn fún. Láti inú tírà Majmu'u Fataawa àti Rọsailul Uthaemin (96/22) ni ṣoki.
Wiwi gbolohun ijẹpe Ọlọhun (Talbiya) jẹ ohun ti a fẹ ninu umrah láti ìgbà tí a ba ti bẹrẹ pẹlu gbígbé arami titi di akoko ti a o bẹrẹ tawafu (iyipo ile Ọlọhun -Ka'abah-).
O pan dandan fún ẹni tí nṣe Umrah lọwọ kí ọ ṣọra láti má kósí ọkan nínú awọn nkan tí a ṣe leewọ fún ẹni tí nṣẹ Umrah lọwọ kí o má ba ba iṣẹ ìjọsìn náà jẹ́ fun titi yoo fi pari rẹ.
Ẹlẹẹkẹta: Alaye bí a ti ṣe iyipo ile Ọlọhun (Tawafu)
Tí ẹni tí o fe ṣe Umrah ba ti wọ inu ile Ọlọhun tii se ìlé ọwọ (Masjid Al-Haram) sunnah ni fun pé kí o wọle pẹlu ẹsẹ ọtun rẹ kí o si wi adua wíwọ mosalasi, nínú èyí tí o dáajù ti o wayé nínú adua wíwọ mosalasi ni kí o sọ pé: "Irẹ Ọlọhun ṣilẹkun ikẹ Rẹ fún mi", Adua yii ni yóò sọ nigbati o ba fẹ wọ èyíkéyìí mọsalasi, kii se fún Masalasi Al-Haram nikan.
Ti o ba fẹ bẹrẹ láti máa yipo ile Ọlọhun (Tawafu) yóò da gbólóhùn ijẹpe Ọlọhun dúró, bẹẹ ni yóò si pakaja, bí a se má npakaja nipe: kí a fi àárín aṣọ iro wa sínú abiya ọwọ ọtun kí a si fi eteeti méjèjì sí orí ejika wa ti òsì, tí o ba ti parí Tawafu ile Ọlọhun yóò da aṣọ iro rẹ pada sí ààyè rẹ tí o wa síwájú kí o to se Tawafu; nítorípé ipakaja wa fun akoko ti a ba n Tawafu ile Ọlọhun nìkan ni.
Lẹyìn náà ni yóò bosi ibi tí òkúta dudu náàn (Hajarul Aswad), yóò si fi ọwọ ọtun rẹ kan òkúta dúdú náà, yóò wa fi kii ẹnu rẹ, ti kò ba rọrun láti fi ẹnu ko o, yóò fi ọwọ kan yóò wa fi ẹnu koo ọwọ naa, tí kò ba rọrun fun láti fi ọwọ kan rárá, yóò fi nkankan bí pọpa tí o wa lọwọ rẹ kan tàbí nkan mii bẹẹ ni yóò fi ẹnu kòó, ti ko ba rọrun fun láti ṣe bẹẹ, yóò kọjú sí òkúta dúdú náà yóò si nọ ọwọ si lẹẹkan ṣoṣo lai ni fi ẹnu kò ọwọ náà, èyí tí o si daraju nipe kí o má se wọduwọdu àti idifunfun pẹlu awọn ènìyàn nítorí ki o ni wọn lara ki oun na si má rí ìnira kan láti ọdọ wọn.
Yóò sọ pé: ALLAHU AKBAR (Ọlọhun ni o tóbi julọ) nigbati o ba fẹ fọwọ kan òkúta dúdú náà tàbí tí o ba fẹ tọka si i.
Lẹyìn bẹẹ ni yóò gba apá ọtun yóò fi kaaba sí apá òsì rẹ, tí o ba de ibi origun ti Al-yamaani yóò fọwọ kan lai ni fi ẹnu kòó, tí kò ba rọọ lọrun láti ṣe bẹ kí o má se se idifunfun láti de bẹ, bẹẹ koni tọkasi.
yóò ti máa sọ bayii láàrin orígun Al-Yamaani àti òkúta dúdú: (Olúwa wa fún wa ni rere ni ile-aiye, si fun wa ni rere ni ọrun, wa sọ wa nibi iya ina).
Gbogbo ìgbà tí o ba tí re kọ já lẹgbẹ okuta dudu yoó máa tọ́ka sí i pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, yoó sì máa sọ pé: (Allahu Akbar) (Ọlọhun lo tóbi julọ).
Yóò si máa wi eyi tí o ba wu u nínú iranti Ọlọhun àti adua àti kíkà Al-kuraani ni bi Tawafu rẹ̀ tí o sẹku.
Nínú ìlànà anọbi ni kí o pọ ṣẹṣẹ níbi ipoyi mẹta alakọkọ nìkan, ipọ ṣẹṣẹ ni: iyara rìn pẹlu kí igbesẹ sunmọra wọn, ṣugbọn ipori mẹrin tí o sẹku kòní sí ipọsẹsẹ níbẹ, yóò kan máa rìn gẹgẹ bí ìṣe rẹ ni.
Ti o ba parí Tawafu ile Ọlọhun tan yóò bọ síbi ààyè ìdúró anọbi Ibrahim tí yóò si ka: (...Ẹ mú ibuduro Ibrahima gẹgẹbi ibukirun...), [Al-baqarah: 125] Lẹyìn náà yóò kirun raka méjì lẹyìn ibuduro Anọbi Ibrahim tí o ba rọrun bẹ, tí kò ba rọrun kí o kí raka méjèjì ni èyíkeyi ààyè nínú mọsalasi, nínu raka (ọpa) alakọkọ ni yóò ti ka: (Qul yaa ayyuha-l-kaafirun) (sọ pé: mo pe ẹyin alaìgbàgbọ) lẹyìn ti o ba ka Fatiah [Al-kaafirun: 1] Yóò si ka lẹyìn ti o ba ke Fatiah níbi raka ẹlẹẹkeji: (Qul Huwa-l-Laahu Ahad) (Sọ pé: Òun ni Ọlọhun Ọkan ṣoṣo). [Al-ikhlas: 1]
Ẹlẹẹkẹrin: Alaye bí a se má nṣe ìrìn ipọsẹsẹ (As-Sa'ayu)
Ti o ba ti pari Tawafu ile Ọlọhun àti kiki irun raka méjì lẹyìn rẹ yoo jáde lọ sí ibi tí yóò tí se ipọsẹsẹ (larin Safa ati Marwa) tí o ba ti sunmọ oke safa yóò ka: (Dájúdaju Safa àti Marwa nínú awọn aye ami Ọlọhun lo wa) [Al-baqarah: 158]. Lẹyìn náà ni yóò tún sọ pe: "N o bẹrẹ pẹlu ohun tí Ọlọhun fi bẹrẹ" [12]. [12] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1218).
Lẹyìn bẹẹ ni yóò wa gun oke safa titi yóò fi máa rí kaaba tàbí ni ọgangan rẹ tí yóò sí da ojú kọ Kaaba, yóò si se Ọlọhun ní ọkan ṣoṣo, yóò si gbé títóbi fun Un, yóò si sọ bayi pé: "LAA ILAAHA ILLAL-LAHU WAHADAHU LAA SHAREEKA LAH, LAHU -L-MULKU WA LAHU -L-HAMD, WA HUWA ALAA KULLI SHAI-IN QADEER, LAA ILAAHA ILLA-L-LAHU WAHADAH, ANJAZA WA’ADAH, WA NASARA ABDAH, WA HAZAMA-L-AHZAABA WAHDAH" "kò sí ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun nikan ṣoṣo, kò sí orogun fun Un, Oun l’O ni gbgbo akoso ati ọpẹ, Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan, ko si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun nikan ṣoṣo, O pé adehun Rẹ, O si se atilẹyin fun ẹrú Rẹ, O si ṣẹgun awọn ijọ alaigbagbọ l'Oun nikan ṣoṣo", lẹyìn náà ni yoo se adua láàrin eléyìun. Yoo sọ iru bayii lẹmẹta [13]. [13] Muslim lo gba wa, pẹlu onka: (1218).
Lẹyìn náà ni yóò Sọkalẹ láti oke Safa láti lọsí oke Marwah ni ẹni tí nrìn, tí o ba wa dé ibi ami alawọ ewe yóò sare kánkán, tí o ba de ibi ami alawọ ewe keji, yóò rìn gẹgẹ bí ṣe maa n rin tẹlẹ, Sísáré kánkán yìí kò si fún àwọn obìnrin.
Ti o ba ti wa de oke Marwah a ṣe ní ìlànà ẹṣin fun pé kí o ṣe iru ohun tí o ṣe ni ori oke Safa (ِAbala keji -2-).
Lẹyìn náà ni yóò Sọkalẹ láti orí òkè Marwah ni ẹni tí nrin, t'oba de ibi ami alawọ ewe yóò sare kánkán, tí o ba de ibi ami alawọ ewé keji yóò tún rìn gẹgẹ bí ṣe maa n rin tẹlẹ.
Bẹẹ ni yóò ṣe titi yóò fi pari ipele meje, láti ori oke Safa lọsí Marwah jẹ ipele kan, bẹẹ ni ipada rẹ láti oke Marwah losi oke Safa jẹ ipele míiran.
Yóò máa wi èyí tí o ba wu u ninu awọn ọrọ ìrántí Ọlọhun (Zikr) àti adua àti kíkà Al-Qur'an bi ṣe rin larin safa ati marwah.
Ẹlẹẹkarun: Alaye bí a ṣe ma n fa Irun tàbí gẹ Irun lọọlẹ:
Ti ẹni tí nṣe Umura ba ti pari Tawafu àti irin larin oke safa ati marwa re, o je oranyan fun un láti fa irun orí rẹ tàbí kí o gẹ tí o ba jẹ pé ọkùnrin ni, sunna si ni pe ki fifari tàbí gigẹ irun naa kárí gbogbo orí.
fifarisi ni ola ju gigẹ ẹ lọ, àyàfi tí o ba je'pe àsìkò Hajji tí sunmọ ti ko sí ni si áàyè kí irun orí náà hu padà; èyí tí o dara ju tí o si lọla jù ni kí a da a ma lórí gigẹ irun náà.
Ṣugbọn obìnrin ni tiẹ; òun yóò ge irun rẹ ní eteeti (ẹgbẹgbẹ) niwọnba orí ọmọ ika ọwọ.
Awọn nnkan tí kò tọ́ fún ẹni tí ó wà nínú Ihramu.
Awọn nnkan tí kò tọ́ fún ẹni tí ó wà nínú Ihramu ni:
1- Fifà irun tàbí gige rẹ tàbí fifa tu (fifà a yọ), lati èyí keyi ààyè nínú ara rẹ.
2- Gige gbogbo eekanna tàbí apa kan nínú rẹ, yala ti ẹsẹ tàbí ti ọwọ.
3- Bíbo orí pẹ̀lú nǹkan tó lẹ̀mọ́ ọ, gẹgẹ bi: fìlà, lawani, àti fífi asọ ilerun sí orí rẹ, tàbí gbígbé asọ inura (tawẹli) le, tàbí asọ ibora, tabi páálí, tàbí nnkan miiran ti a lè fi bo orí. Eyi jẹ òfin fun awọn ọkunrin nìkan lai sí awọn obìnrin.
4- Wiwọ aṣọ tí a ti ba saaba tí a ti gé ni dede ìwọn ara, pẹlu irisi rẹ tí a ti ba saaba, gẹgẹbi: aṣọ ti a rán, àti sokoto àti buba, àti ibọsẹ, àti ibọwọ. Eyi jẹ fún awọn okunrin nikan, ki i se fun awọn obìnrin; nitoripe awọn ohun ti a ṣe leewọ fún (obinrin) ni:
a- Wiwọ Niqab (ìbojú), tàbí Burqa, tàbí ohun tí ó jọ mọ́ wọn tí a fi ń bo ojú; ṣugbọn o pan dandan fún obìnrin lati bo oju rẹ niwaju awọn ọkùnrin ajoji pẹlu gèlè tàbí aṣọ ìboju rẹ tí a mọ pelu re. Kò sí aburu ti aṣọ náà ba kan ojú rẹ. Kò sì lẹtọọ fún un láti gbé nǹkan bí (igi) -tàbí ohun ti o jọ- sí orí rẹ pẹlu erongba kí aṣọ naa má baà kan ojú rẹ; nítorí ko sí ẹrí kankan nínú òfin ẹ̀sìn to fìdí rẹ mulẹ.
b- wíwọ ibọwọ si ọwọ re méjèjì, bẹẹ si ni o pan dandan fún un láti bo ọwọ rẹ méjèjì níbi tí awọn ọkunrin ajoji ba wà nipa pé kí o ti ọwọ rẹ sinu aṣọ rẹ.
5- Lílo lofinda sí ara, tàbí fifi sí ara aṣọ ihramu.
6- Pipa ẹranko igbo, tàbí didẹ ẹ ọdẹ rẹ, koda bí o pa a.
7- biba obìnrin sọrọ ifẹ (itọrọ iyawo), yala fún ara rẹ tabi fún ẹlòmíràn.
8- Ṣíso yigi (tita kókó yigi).
9- Fífara nu obìnrin (ti o jẹ ẹlẹtọ eniyan) lai si ibalopọ; gẹgẹ bi ífẹnukonu, tàbí fífọwọ kanra pẹlu ero iwa igbadun.
Ibalopọ láàrin ọkọ àti àyà, oun na si ni ki ọkunrin ba obinrin lopọ lati abẹ rẹ.
Ṣoki ọrọ nipa awọn iṣẹ Umura:
1- Wíwẹ̀.
2- Lílo lọfinda.
3- Wíwọ aṣọ Ihramu (aṣọ Arami) .
4- Al-Ihraam, oun ni didaniyan láti bẹrẹ Umura tàbí Hajji.
5- Gbólóhùn ijẹpe Ọlọhun.
6- Yiyi ká ile Ọlọhun (Tawafu).
7- Kiki irun raka méjì lẹyìn ààyè ibuduro Anọbi Ibrahim (Maqaamu Ibrahim)
8- Lilọ ati bibọ láàrin oke Safa ati Marwah.
9- Fifa irun orí tàbí kí a gẹ ẹ. Ọlọhun (Allah) nì O ní mimọ julọ, kí Ọlọhun ba wa ṣe ikẹ ati igẹ fún Anọbi wa Muhammad.