المنهج الوجيــز

المنهج الوجيــز

هذا الكتاب يعتبر مقدمة شاملة للمسلم الجديد حول أساسيات الدين الإسلامي، ويبين الأحكام الضرورية في العقيدة الإسلامية، وأركان الإسلام والإيمان، والعبادات الأساسية من الصلاة والصيام والزكاة والحج. كما يتضمن الكتاب إرشادات عملية حول كيفية أداءها بشكل صحيح، فهو يهدف إلى تزويد المسلم الجديد بالمعرفة الضرورية لفهم دينه وممارسة شعائره بطريقة مستنيرة.

Language: lang_yo
Prepared by:
Version: 1.0
Translations 8
Bosnian Spanish Fula French +4
Attachments 7
PDF
Audio
Video
+3

Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun.

Al-Wajiiz

Ìlànà ẹkọ ti yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ fun Musulumi tuntun

Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun.

Ọrọ isiwaju

Gbogbo ọpẹ jẹ ti Ọlọhun ti O fi ọna mọ wa fun Isilaamu, ti O tọ wa si awọn ọna ọla, ti O gbe ẹni ti o daa julọ ninu awọn eniyan dide ninu wa, - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. Lẹyin naa: O n dun mọ wa ninu lati ti eto ẹkọ yii si iwaju rẹ ti o maa sọ nipa ẹsin ododo (Ẹsin Isilaamu), ti o si maa ṣe alaye awọn nnkan ti o jẹ dandan lati mọ àti láti ṣe, lati le jẹ kọkọrọ fun ẹ lati da ẹsin rẹ mọ, ki o le jẹ olukunlọwọ fun ẹ lori gbigbe awọn ami ẹsin Isilaamu duro, eto ẹkọ yii n ti si iwaju rẹ:

"1. Àlàyé ṣókí kan nipa ẹsin Isilaamu, ati awọn ti o fi oju han julọ ninu awọn aaye rẹ ti o tobi

Oju-iwoye gbogbogboo nipa (Kuraani Alapọn-ọnle), ati alaye awọn itumọ apakan ninu awọn Surah ti Kuraani ti wọn kere

3. Àlàyé ṣókí kan fun idajọ awọn ijọsin ti wọn jẹ dandan

4. Àlàyé ṣókí kan fun eyi ti o han julọ ninu awọn idajọ ibaṣepọ ati àṣà ati awọn iwa ninu Isilaamu

Wọ́n ti pin awọn abala rẹ ni ibamu si eto ẹkọ ti wọn pin awọn ẹkọ abala kọọkan lori odiwọn ọjọ mẹfa sibẹ, pẹlu ṣíṣe odiwọn aala asiko ẹkọ kọọkan, gẹgẹ bi wọn ṣe gbe eto ẹkọ naa jade pẹlu ọna ẹkọ ti o ko ọpọlọpọ ninu awọn iṣẹ́ ati ìdánwò sinu, eyi ti yio ran Musulumi tuntun lọwọ lori iha imọ ati agboye rẹ, ni afikun si awọn ibeere ti igbelewọn ni ipari gbogbo abala ẹkọ kọọkan, ki o le rọrun fun akẹkọọ lati ṣe igbelewọn bi agbọye rẹ ṣe to fun eto ẹkọ naa. Eto ẹkọ naa si ti ko ọpọlọpọ ninu awọn ìrísí ti wọn gbero nibẹ lati kópa nibi imu ẹkọ dára si fun Musulumi tuntun, ati kikun un lọwọ nibi agbọye eto ẹkọ, gẹgẹ bi o ṣe n bọ yii:

Awọ yii n tọka si pataki imọ yii, ati si ṣee ṣe bibẹ ibeere kan ti o so pọ mọ ọn ni ipari ẹkọ naa

Iwe yii n tọka si ìmúnimọ̀ ati alaye gbólóhùn ti o wa ninu ọrọ naa.

Jíròrò

Ìpínrọ̀ yii n tọka si àkòrí ti ijiroro laaarin olukọ ati akẹkọọ, ti nnkan ti o da le lori maa jẹ ki ẹbun irori ati fífa-nnkan-yọ gbèrú lọdọ akẹkọọ

Idanwo

O ko iṣẹ́ idalẹkọọ sínú, eyi ti o duro lori ìròrí tabi fífa-nnkan-yọ tabi hiha.

Maa wolẹ maa rọra sinu irin-ajo imọ ti o dáa yìí

Ètò ẹkọ

Ìjókòó

Ìpínrọ̀

Àsìkò

Isẹju mẹ́wàá

Isẹju mẹẹẹdogun

Ogún ìṣẹ́jú

Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú

Isẹju marundinlaaadọta

Ọjọ́ àkọ́kọ́

Ìjókòó àkọ́kọ́

Ọrọ ìṣáájú

1. Idara-ẹni-mọ ati awọn àkíyèsí

2. Awọn ibeere ti o nii ṣe pẹlu bibẹ: (Ta ni wa? Ibo ni a n lọ? )

3. Idẹra imọna

Isilaamu

Ki ni Isilaamu?

Nitori ki ni maa ṣe gba Isilaamu?

3. Kikari-aye Isilaamu

4. Isilaamu maa n pa nnkan ti o ṣaaju rẹ ninu awọn ẹṣẹ rẹ

5. Isilaamu ẹsin ipari

6. Ijẹ anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-

7. Òṣùwọ̀n apemọra ìní-ọlá-ju-ẹlòmíì-lọ nínú Isilaamu

8. Kikọ awọn origun ẹsin Isilaamu

Bawo ni maa ṣe gba Isilaamu?

1. Ijẹrii mejeeji

2. Itumọ ijẹrii mejeeji

3. Awọn nǹkan ti ijẹrii mejeeji n bukaata si

Ìsinmi

Ìjókòó kejì

Bawo ni maa ṣe ṣe aluwala? (Ti afisiṣẹse)

Bawo ni maa ṣe kirun? (ti afisiṣẹse)

Iwe àkọsílẹ̀ pelebe ti ọjọ akọkọ

Ọjọ keji

Ìjókòó àkọ́kọ́

Ki ni igbagbọ?

Awọn origun igbagbọ:

1. Nini igbagbọ ninu Ọlọhun

2. Nini igbagbọ ninu awọn mọlaika

3. Nini igbagbọ ninu awọn iwe ti wọn sọ kalẹ

4. Nini igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ

5. Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin

6. Nini igbagbọ ninu kadara

Awọn eso nini igbagbọ

Kuraani Alapọn-ọnle:

1. Ki ni Kuraani ?

2. Kuraani jẹ ounjẹ ẹmi ati laakaye

3. Kuraani ni ilana igbesi aye

4. Awọn itan awọn Anọbi ninu Kuraani

Hiha Suratul Ikhlas ati agbọye itumọ rẹ

Ìjókòó kejì

Ijọsin:

Itumọ ijọsin.

Awọn majẹmu itẹwọgba awọn ijọsin

Awọn ìran ijọsin

Imọra

Awọn iran imọra:

1. Imọra ti a le ni ìmọ̀lára rẹ: Ipilẹ nibi awọn nnkan ni imọra, awọn nnkan ẹgbin, mimu ẹgbin kuro, bibiya bukaata

2. Imọra ti a ko le ni ìmọ̀lára rẹ: Gbigbe ẹgbin kuro, omi ti a n lo fun gbigbe ẹgbin kuro

Iwe àkọsílẹ̀ pelebe ti ọjọ keji

Ọjọ kẹta

Ìjókòó àkọ́kọ́

Bawo ni maa ṣe ṣe aluwala ? (ti àbá èrò orí lásán):

Itumọ aluwala

Bawo ni a ṣe n ṣe aluwala ?

Awọn nnkan ti o n ba aluwala jẹ

Awọn nǹkan ti n sọ aluwala di dandan

Pipa ibọsẹ mejeeji

Hiha Suratul Falaq ati agboye itumọ rẹ

Ìjókòó kejì

Bawo ni maa ṣe wẹ?

1. Itumọ iwẹ

2. Bawo ni a ṣe n wẹ?

3. Nigba wo ni iwẹ maa jẹ dandan?

4. Nnkan ti ṣiṣe rẹ jẹ eewọ fun onijanaba lara

5. Aluwala oni erupẹ

Ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ:

1. Awọn orisirisi ẹjẹ ti o n jade lati ara obinrin

2. Awọn idajọ ẹjẹ nǹkan oṣu ati ìbímọ

Hiha Suratun Nas ati agbọye itumọ rẹ

Iwe àkọsílẹ̀ pelebe ti ọjọ kẹta

Ọjọ kẹrin

Ìjókòó àkọ́kọ́

Hiha suuratul Kaafiruun ati gbigbọ itumọ rẹ ye

Bawo ni maa ṣe kirun? (Ti o nii ṣe pẹ̀lú àbá èrò orí lásán)

1. Ki ni irun?

2. Ki ni o de ti a fi n kirun?

3. Ipò irun

4. Àwọn májẹ̀mú irun

5. Àwọn irun wákàtí márùn-ún

6. Báwo ni a ṣe maa kirun?

Ìjókòó kejì

Irun

1. Pipari bi a ṣe n kirun

2. Irun jímọ̀

Ìwé àkọsílẹ̀ ojoojúmọ́ ti ọjọ́ kẹrin

Ọjọ́ karùn-ún

Ìjókòó àkọ́kọ́

Hiha Suuratul Kaothar ati gbigbọ itumọ rẹ ye

Sàká

1. Ki ni saka?

2. Ki ni o de ti a fi n yọ saka?

3. Bawo ni a ṣe maa yọ saka?

Aawẹ:

1. Ki ni aawẹ?

2. Ki ni o de ti a fi n gba aawẹ?

3. Awọn nǹkan ti n ba aawẹ jẹ

4. Àwọn ti a yọnda fun lati má gba Ramadan

Hajj

1. Ki ni hajj?

2. Ki ni o de ti a fi n ṣe hajj?

3. Ta ni hajj jẹ dandan fun?

Ìjókòó kejì

Hiha Suuratul Asr ati gbigbọ itumọ rẹ ye

Aṣọ:

Ìpìlẹ̀ nibi aṣọ

Àwọn aṣọ ti wọn ṣe ni eewọ.

Oúnjẹ ati nǹkan mímu:

Ìpìlẹ̀ nibi oúnjẹ ati nǹkan mimu.

Àwọn oúnjẹ ati nǹkan mimu ti wọn ṣe ni eewọ.

3. Ki ni àwọn májẹ̀mú didu nǹkan ti o ba sharia mu?

4. Àwọn ìdájọ́ àwọn nǹkan tí a n du ni àwọn ile oúnjẹ ati awọn ṣọọbu.

Iwe àkọsílẹ̀ ojoojumọ ti ọjọ́ karùn-ún

Ọjọ́ kẹfà

Ìjókòó àkọ́kọ́

Àwọn ibalopọ ti owó:

1. Ki ni àwọn ibalopọ ti owó?

2. Ìpìlẹ̀ nibi awọn ibalopọ ti owó

3. Awọn ibalopọ ti owó ti wọn ṣe ni eewọ.

Àwọn ìwà:

1. Àwọn ìwà nínú Isilaamu.

2. Ọla ti o n bẹ fun iwa rere

3. Awọn aaye iwa ninu Isilaamu

Ìjókòó kejì

Ṣiṣe atunyẹwo awọn Surah ti a há

Ṣiṣe atunyẹwo bi a ṣe n ṣe aluwala ati bi a ṣe n ki irun

Iwe àkọsílẹ̀ pelebe ti ọjọ kẹfa

Awọn àkòrí ìlànà igbesi aye naa

Abala Àkọ́kọ́

Ẹsin Isilaamu

Abala keji

Kuraani Alapọn-ọnle

Abala kẹtà

Awọn ijọsin

Abala kẹrin

Awọn idajọ ti Isilaamu

Abala Àkọ́kọ́

Ẹsin Isilaamu

Ẹkọ Alakọkọ

Isilaamu ati awọn ibeere nla

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Àwọn ìbéèrè kan maa n wa si ẹ̀dá ni ẹ̀mí nípa bibẹ ọmọniyan, wọn o wàá máa beere nípa paapaa alamọri wọn, ati nipa ipilẹ wiwa wọn, ati okunfa rẹ, ati nipa opin alamọri wọn. Ati pe Isilaamu ti dahun si awọn ibeere yii pẹlu awọn idahun kan ti wọn to:

Ibeere akọkọ

Tani wá?

Isilaamu ṣe àlàyé itumọ ọmọniyan pe ẹ̀dá kan ni ninu awọn ẹda Ọlọhun- ti Ọla Rẹ ga- ti o pọ, ti Ọba ti ọla Rẹ ga gbe ọla fun un ju ọpọlọpọ ninu awọn ẹda lọ, ti o rọ ọpọlọpọ fun un ninu wọn lati maa wa ikunlọwọ pẹlu wọn lori pipe ojuṣe rẹ ti wọn ni ki o ṣe fun gbogbo isẹmi aye rẹ. Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí A dá.} (Surah Al-Isrâ’: 70)

Ati pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi afijọ kan si ara eniyan ninu:

Awọn Mọlaika nibi imọra wọn ati ijọsin wọn

Ati awọn èṣù nibi àtakò wọn ati iyapa wọn

Ati awọn ẹranko nibi ṣíṣe ìfẹ́-ọkàn wọn ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn

Ati pe O fi ipalemọ fun ohun rere si i lara, ati ipalemọ fun aburu, O si fun un ni nnkan ti yio fi máa ṣe iyatọ laaarin ohun rere kuro nibi aburu; gẹgẹ bii adamọ ati laakaye

O si ṣe e ni olómìnira ti o le ṣe ẹsa, ti wọn si maa bi i léèrè nipa awọn iṣẹṣa rẹ ati awọn iṣẹ rẹ

Awọn Mọlaika: Ẹda kan ni wọn jẹ ninu ẹda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- da wọn lati ara imọlẹ, awọn ti a n tọju ti a rọ ni wọ́n, ẹrusin alapọn-ọnle ni wọ́n, wọn ko ki n yapa nnkan ti Ọlọhun ba pa wọn laṣẹ, ati pe wọn máa n ṣe nnkan ti wọn ba pa wọn laṣẹ rẹ, ko si ẹni ti o mọ onka wọn afi Ọlọhun

Ibeere keji

Ibo lati wa ati tori kini? Isilaamu n ṣe alaye pe dajudaju ipilẹ dida eniyan wa lati ara erupẹ, Ọlọhun da Adam lati ara rẹ, oun ni baba awọn ẹda patapata, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú erùpẹ̀ amọ̀} (Surah Al-Mu’minûn: 12) Ati pe erongba ninu dida eniyan yii ni ijọsin Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, pẹlu rirọrọ Rẹ- mimọ ni fun Un- kuro lọdọ ẹda Rẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi} (Surah Adh-Dhâriyât: 56)

Adam

Ọlọhun sọ fun wa ninu Kuraani itan dida rẹ ati bi èṣù ṣe bẹrẹ ibaṣe ọta rẹ, wo alaye Surah Al-baqorah fun awọn aayah (30-39)

Jíròrò

Wo si ara wọn laaarin iwoyesi rẹ fun itumọ bibẹ rẹ ṣiwaju ki o to wọnu Isilaamu ati lẹyin rẹ:

Ibeere kẹta

Ibo ni a n lọ? Kuraani Alapọn-ọnle ṣe alaye pe dajudaju gbogbo ẹda máa pada ku ni aye yii, ati pe ipele iṣẹ máa wa si opin pẹlu iku rẹ, ti ipele iṣiro ati ẹsan máa bẹrẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Dájúdájú ìwọ máa kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú – Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín} (Az-Zumar: 30-31)

Ti eniyan ba ti wa ku, o maa kọja si ipele kan ti wọn ti máa bi i nibẹ nipa ẹsin rẹ, ti wọn máa san an ni ẹsan lori awọn iṣẹ rẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A ó sì san yín ní ẹ̀san yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí A bá mú jìnnà tefé sí Iná, tí A sì mú wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó kúkú ti jèrè. Kí sì ni ìgbésí ayé bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn} Surah Âl-`Imrân: 185

Ti ọjọ igbedide ba de, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa gbe awọn oku dide lati inu saare wọn fun iṣiro ati ẹsan, ti yóò si fi alujanna ṣe ẹsan fun awọn onigbagbọ, ti yoo si fi ina ṣe ẹsan fun awọn alaigbagbọ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Báyẹn ni A ṣe fi al-Ƙur’ān ránṣẹ́ sí ọ ní èdè Lárúbáwá nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù), àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ nípa Ọjọ́ Àkójọ, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìjọ kan yóò wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìjọ kan yó sì wà nínú Iná t’ó ń jò} [Surah Ash-Shûrâ: 7]

Idẹra imọna: Ẹni ti o ba mọ ọgbọn ti o wa nibi dida rẹ, ati igbẹyin ti o ṣe pe o n reti awọn eniyan ni ọjọ igbedide, yoo si ni amọdaju pe dajudaju idẹra ti o tobi julọ ti Ọlọhun máa n fi ṣe idẹra fun awọn ẹru Rẹ ni idẹra imọna lọ si oju-ọna ẹsin ododo ati iṣẹ rere. Fun idi eyi ni Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- fi ṣe ni dandan le awọn ẹru Rẹ lori nibi irun lati máa beere imọna si oju-ọna taara lọwọ Rẹ, eyi ti o ṣe pe oun ni ẹsin Isilaamu, ti o maa muni de ibi iyọnu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-

Lilo ori ilẹ wa ninu awọn ipa ti eniyan maa ko nibi isẹmi aye rẹ, lati rọ ọ lọrun lati mu iṣẹ pataki ti o tobi yii ṣẹ, ati pe Ọlọhun ti ṣe adamọ rẹ ni irọrun lati le sa ipá yii… Ṣe alaye bi o ṣe le rọrun fun ẹda lati le lo ilẹ yii laisi awọn ẹda yoku?

Darukọ apakan ninu awọn oripa ti iṣẹ ti o to le jẹ jáde látàrí mimọ ibupadasi ẹda lẹyin iku?

Awọn ibeere ti igbelewọn

Bawo ni Isilaamu ṣe gbe ọla fun ọmọniyan ju gbogbo awọn ẹda yoku lọ?

Ki ni erongba ti a tori rẹ da ẹda?

Nitori kini Kuraani ṣe ṣe àlàyé itan ibẹrẹ ẹda?

Ti eniyan ba ku, o maa ṣi lọ si ipele kan ti wọn ti maa bi i leere nipa ẹsin rẹ, ti wọn si maa san an ni ẹsan nibẹ lori awọn iṣẹ rẹ

Opin erongba ninu dida eniyan ni lilo ori ilẹ aye ati ṣíṣe àtúnṣe rẹ lati le ṣẹmi nibẹ

O tọna

Àṣìṣe

Lẹyin ti o ti kọ agbọye ti Isilaamu nipa bibẹ eniyan:

Ròyìn bi ìmọ̀lára rẹ nipa ìbámu rẹ si adamọ ti inu rẹ ati ìmọ̀lára ti ọkan rẹ ṣe tó

Ẹkọ ẹlẹẹkeji :

Ki ni ẹsin Isilaamu?

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Isilaamu: Oun ni ẹsin ti o ṣe pe Ọlọhun gbe Anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dide pẹlu rẹ, itẹsiwaju ni o jẹ fun nnkan ti awọn Ojiṣẹ ti wọn ṣaaju mu wa, ati pe ipilẹ rẹ duro lori pe dajudaju Ọlọhun ti O ni ẹtọ si ijọsin jẹ ẹyọkan ti ko si orogun fun Un. Oun ni Allahu- Alagbara ti O ga-, ti ko si oluranlọwọ fun Un nibi ọla Rẹ, ti ko si alagata laaarin Rẹ ati awọn ẹru Rẹ, ṣugbọn nitori ki ni o ṣe jẹ dandan fun mi lati gba Isilaamu? Ati pe njẹ ẹsin awọn eniyan patapata ni tabi o jẹ ẹsa fun awọn larubawa nikan sọ? Ati pe ta ni Anọbi rẹ? Njẹ Anọbi miiran n bẹ ti o n bọ lẹyin rẹ?

Nitori ki ni màá fi gba Isilaamu?

Ati pe apakan awọn eniyan le maa beere pe: Nitori ki ni o ṣe jẹ dandan fun mi lati gba Isilaamu?

Idahun: O jẹ dandan fun mi lati gba Isilaamu nitori awọn àlámọrí kan, ninu rẹ:

Akọkọ: Dajudaju ẹsin Isilaamu ni ẹsin ti Ọlọhun yọnu si fun awọn ẹru Rẹ, ti ko si nii gba ẹsin miiran ti o yatọ si i lọwọ ẹnikẹni, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò} [Surah Âl-`Imrân: 85]

Ikeji: Dajudaju ẹsin Isilaamu ni ẹsin awọn Anọbi patapata, ti o si paṣẹ pẹlu nini igbagbọ ninu awọn Anọbi patapata, ti ko yọ ẹnikan sọtọ laaarin wọn, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un} [Surah Al-Baqarah: 136] Ati pe iyatọ to wa laaarin awọn Anọbi ni iyatọ nibi awọn idajọ ti ofin ti o so pọ mọ awọn iṣẹ ẹru, gẹgẹ bi Ọba- ti mimọ n bẹ fun Un- sọ pe: {Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún} [Surah Al-Mâ’idah: 48] Ìtumọ̀ rẹ ni pé: Ọlọhun ti ṣe ofin fun gbogbo ijọ kọọkan ninu awọn ijọ ki wọn maa fi ṣe idajọ, ati oju-ọna ki wọn maa fi ṣe asunmọ lọ si ọdọ Rẹ, awọn idajọ n bẹ fun olukuluku ìjọ ti wọn jẹ ẹsa fun wọn, ati awọn ofin ti o ṣe deedee wọn, sugbọn nibi adisọkan, adisọkan awọn Anọbi jẹ ẹyọkan Lẹyin naa Ọlọhun gbe ikẹyin awọn Anọbi Rẹ ati awọn Ojisẹ Rẹ Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ ga- dide, O si fi pari awọn Ojisẹ, O si fi ofin rẹ pari awọn ofin, ti wọn ko nii tẹwọ gba ẹsin ti o yatọ si Isilaamu lọwọ ẹnikẹni

Ikẹta: Dajudaju wiwọ inu Isilaamu ni oju-ọna oriire ni aye ati oju-ọna igbala ni ọrun, ẹnikẹni ti ipepe Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba de ọdọ rẹ ko nii la ni ọrun afi ẹni ti o ba gba a gbọ ti o si tẹle e, Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò} [Surah Âl-`Imrân: 85] Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: <> (Muslim lo gba a wa 153)

Ikẹrin: Dajudaju Isilaamu n fesi ni awọn idahun kan to to fun awọn ibeere mi ti o tobi: Nitori ki ni mo ṣe wa si aye? Ibo ni mo ti n bọ? Ibo ni maa lọ lẹyin iku?

Ikarun-un: Dajudaju Isilaamu ni ẹsin ti o ṣe deedee pẹlu adamọ, bẹrẹ lati ìwà ti o tobi ti o wa nibẹ, oun ni imu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni ọkan ṣoṣo, ti o si pari pẹlu awọn ẹkọ rẹ ti o ṣe pe o maa n tọ ni sọna lọ si ibi iwa daadaa ti o tọ.

Jíròrò

Bawo ni Isilaamu ṣe maa jẹ ẹsin gbogbo awọn Anọbi?

Ninu awọn ìròyìn ti Isilaamu fi da yatọ:

Isilaamu da yatọ si awọn ẹsin yoku pẹlu awọn ìròyìn ẹsa ti o pọ, eyi ti o han julọ ninu wọn ni:

1. Isilaamu jẹ ẹsin ti agbaye

Ẹsin Isilaamu kii ṣe ti larubawa nikan, bi ko ṣe pe oun ni ẹsin ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- yọnu si fun awọn ẹda patapata, fun idi yẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ fun Ojiṣẹ Rẹ Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a- pe: {A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá} [Surah Al-Anbiyâ’: 107] Ati pe Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- fi Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a- ṣe ikẹ ti o kari gbogbo awọn eniyan patapata, ti O n tọ wọn si oju-ọna igbagbọ, ti O si ṣe ofin rẹ ni eyi ti o gbooro julọ ninu awọn ofin ni ikẹ fun awọn eniyan

Anfaani

Isilaamu bọwọ fun awọn aṣa awọn ijọ ati awọn iṣe wọn, ko si ṣe ayipada wọn ni dandan fun wọn afi ti wọn ba tako nǹkan kan ninu awọn ami ẹsin ati awọn ẹkọ rẹ

Isilaamu maa n pa nnkan ti o ba ṣaaju rẹ ninu awọn ẹṣẹ rẹ.

Ti eniyan ba gba Isilaamu ni gbigba ododo; dajudaju Ọba Ajọke-aye Aṣakẹ ọrun maa ṣe aforijin awọn ẹṣẹ rẹ ti o ti ṣáájú fun un, ati pe eleyii wa ninu awọn daadaa Isilaamu. Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ fun Anọbi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: {Sọ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), A máa ṣàforíjìn ohun t’ó ti ré kọjá fún wọn } [Surah Al-Anfâl: 38] Arakunrin kan ti o fẹ gba Isilaamu wá si ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sugbọn o ṣe majẹmu pe ki wọn o ṣe aforijin nnkan ti o ti re kọja fun oun, ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa fun un ni iro idunnu, o wa sọ fun un pe: Ṣe ìwọ ko mọ pe dajudaju Isilaamu maa n wo nnkan ti o ti ṣiwaju rẹ ni Muslim ni o gbe e jade (121)

Isilaamu ni ẹsin ikẹyin

Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe Isilaamu ni itẹsiwaju fun awọn ofin ti sanmọ ti wọn ṣaaju, ti O si yọnu si i ni ẹsin fun ẹda patapata titi di ọjọ igbedide, a ko ri ẹsin òdodo miiran yatọ si ẹsin Isilaamu ni ori-ilẹ, Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò} (Surah Âl-`Imrân: 85)

Jíròrò

Bawo ni a ṣe maa fesi fun ẹni ti o ba lero pe Isilaamu jẹ ẹsin larubawa nikan

Ta ni Anọbi Isilaamu?

Musulumi n di adisọkan pe dajudaju Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ipari awọn Anọbi ti Ọlọhun gbe wọn dide si awọn eniyan lati pe wọn sibi ijọsin Rẹ ni Oun nikan ṣoṣo, ati pe dajudaju ko si Anọbi miiran lẹyin rẹ, Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan} (Surah Al-Ahzâb: 40)

Kọ́ ẹsin

Nnkan ti o jẹ dandan fun musulumi ni ki o kọ ninu alamọri ẹsin rẹ nnkan ti o n bukaata rẹ, titi ti o fi máa jọsin fun Oluwa rẹ pẹlu imọ

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ni loju kokoro sibi agboye ẹsin ninu ẹsin, o wa sọ pe: Ẹni ti Ọlọhun ba fẹ oore fun yio fun un ni agboye ninu ẹsin Bukhari ni o gbe e jade (71)

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju wiwa imọ ti sharia jẹ oju-ọna kan fun wiwọ alujanna, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: Ẹni ti o ba tọ oju-ọna kan ti o n wa imọ nibẹ, Ọlọhun O ṣe oju-ọna kan ni irọrun fun un pẹlu rẹ lọ si alujanna Muslim ni o gbe e jade (2699)

Kíkà ti afikun

Ki o le mọ síi nipa itan igbesi aye Ojiṣẹ Ọlọhun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa bá a- lọ ka iwe Muhammad Rosuulullah, o wa ni ibutaja Usuul pẹ̀lú awọn ede agbaye

Ṣe ẹ̀dá àwòrán barcode naa lati fi ẹ̀dà ìwé naa ránṣẹ́

Tira pọ̀ ti musulumi le kọ awọn idajọ ẹsin rẹ ninu rẹ titi ti o fi máa sin Oluwa rẹ pẹlu amọdaju, ki o si maa wa iranlọwọ pẹlu awọn ti wọn ni imọ nipa awọn idajọ naa lati tọ́ ọ sọna lọ si ibi eyi ti o dára jùlọ nínú àwọn tira yìí.

Òṣùwọ̀n apemọra ìní-ọlá-ju-ẹlòmíì-lọ nínú Isilaamu

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe òṣùwọ̀n apemọra ìní-ọlá-ju-ẹlòmíì-lọ laaarin awọn ẹru Rẹ pẹlu igbagbọ ati ibẹru Ọlọhun; nitori naa, apemọra ìní-ọlá-ju-ẹlòmíì-lọ maa jẹ pẹlu ini agbara igbagbọ wọn, ko kii ṣe pẹlu awọn irisi wọn, tabi pẹlu awọn iran wọn, tabi pẹlu awọ wọn, ati pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti sọ pe: {Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tá} (Surah Al-Hujurât: 13)

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa bá a- sọ pe: Mo pe ẹyin eniyan, ẹ tẹti ẹ gbọ, dajudaju Oluwa yin ọkan ni, ati pe dajudaju baba yin ọkan ni, ẹ tẹti ẹ gbọ, ko si ọla fun larubawa lori eledekede, tabi fun eledekede lori larubawa, tabi fun alawọ pupa lori dudu, tabi fun dudu lori pupa, afi pẹlu ibẹru Ọlọhun Al-Bayhaqiy ni o gbe e jade ninu SHUHABUL IIMAAN (4774)

Awọn origun Isilaamu:

Wọn mọ Isilaamu pa lori origun marun-un:

Dandan ni fun gbogbo musulumi ki wọn dunni mọ awọn origun yii titi ti Isilaamu rẹ fi maa duro tọ́; nitori pe àṣeètó nibi ọkan ninu awọn origun yii a ko ipalara ba Isilaamu rẹ

Ijẹrii mejeeji

Jijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si afi Allohu ati pe dajudaju Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ni

Gbigbe irun duro

O jẹ dandan fun musulumi lati maa ki irun ni ẹẹmarun-un ni ojoojumọ, alaye rẹ n bọ

Gbigba àwẹ̀ Ramadan

Yiyọ sàká

Lílọ si ile Ọlọhun

Lẹyin ti o ti wo fídíò yii (igbesi aye musulumi tuntun) (Muslim’s new life), sọrọ nipa nnkan ti o jẹ ki Isilaamu o wù ọ́ jù.

Ṣe ẹ̀dà àwòrán barcode naa lati wo fídíò naa

Ki ni awọn nnkan ipilẹ ti kíkọ́ wọn jẹ dandan fun musulumi titi ti o fi maa jọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- gẹgẹ bi O ṣe pa a láṣẹ?

Ẹsin Isilaamu ko awọn ẹkọ kan si inu:

A) Ti ìwà

B) Ti ìmọ̀

D) Ti iṣẹ

E) Gbogbo nnkan ti o ṣaaju

Onka àwọn origun Isilaamu:

A) 6

B) 5 D) 4

E) 3

Lẹyin kongẹ Ọlọhun fun ẹru pẹlu wiwọ Isilaamu, dajudaju kíkọ́ awọn nnkan ipilẹ ẹsin jẹ dandan fun un, eyi ti o maa jẹ ki o le jọ́sìn fun Ọlọhun

O tọna

Àṣìṣe

Ẹkọ ẹlẹẹkẹta

Bawo ni màá ṣe gba Isilaamu

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Ninu àkókò ti Mùsùlùmí tuntun ko le gbagbe julọ ni àsìkò ti o kéde gbigba Isilaamu pẹ̀lú pipe gbólóhùn ijẹrii méjèèjì, pẹ̀lú ìkéde yii, o n kede fúnra rẹ pe ni ọla oun maa di nǹkan mìíràn yàtọ̀ si ohun ti o jẹ tẹ́lẹ̀, ati pe lati àkókò yii, o ti gbe àwọn igbesẹ àkọ́kọ́ lati mọ òdodo àti lati gba a mu. Ninu ẹkọ yii, a maa mọ gbólóhùn ijẹrii méjèèjì ati itumọ wọn ati awọn nǹkan ti o maa jẹ yọ latara rẹ fun Mùsùlùmí

Ijẹrii mejeeji

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe kọkọrọ iwọle sinu Isilaamu ni pipe ijẹrii mejeeji, awọn mejeeji ni: Ash-hadu an laa ilaaha illallohu wa ash-hadu anna Muhammadan rọsuulullah

Ki ni itumọ ijẹrii mejeeji?

Ni akọkọ: Itumọ Jijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si afi Allohu

Itumọ (Ash-hadu an laa ilaaha illallohu) ni: Mo n di si ọkan ni adisọkan kan ti o rinlẹ pe dajudaju ko si ẹni ti a n jọsin fun ti o ni ẹtọ si ijọsin afi Allohu nikan ṣoṣo

Dajudaju ijẹrii yii ti ko alamọri meji sinu

Akọkọ

Kikọ nini ẹtọ si ìjọsìn òdodo fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-

Ikeji

Fifi nini ẹtọ si ìjọsìn òdodo rinlẹ fun Allahu nikan ṣoṣo

Ati pe ipilẹ ẹsin Isilaamu eyi ti o jẹ pe oun ni ẹsin awọn Anọbi patapata ni: Ìjọsìn fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ati ṣíṣe aigbagbọ si gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si I. Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-sọ pe: {A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi} [Surah Al-Anbiyâ’: 25]

Nini adisọkan ìní ẹtọ si ìjọsìn òdodo fun nǹkan mii yatọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko tọ rara, isunmọ nnkan ti o yatọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko tọ pẹlu eyikeyii iran ninu awọn ijọsin

Ikeji: Itumọ Jijẹrii pe dajudaju Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ni

Itumọ (ash-hadu anna Muhammadan rọsuulullah) ni: Mo n di si ọkan ni adisọkan kan ti o rinlẹ pe dajudaju Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni Ojiṣẹ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ikẹyin awọn Anọbi, ko si Anọbi kankan lẹyin rẹ, ati pe iranṣẹ rẹ wa fun awọn eniyan patapata, Ọba- ti mimọ n bẹ fun Un ti ọla Rẹ si ga- sọ pe: {Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá} (Surah Al-Furqân: 1)

Idanwo

Lẹyin iṣẹri rẹ pada si iwe Muhammad Rosuulullah, ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìsọfúnni ti iṣe alaye ti o n bọ yii nipa Ojiṣẹ Ọlọhun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-:

Ṣe ẹ̀dá àwòrán barcode naa lati fi ẹ̀dà ìwé naa ránṣẹ́

Orúkọ rẹ:

Iran rẹ:

Aye ibi rẹ:

Idagbasoke rẹ:

Ijẹ Anọbi rẹ:

Hijira rẹ:

Iku rẹ:

Awọn nǹkan ti o maa jẹ yọ latara ijẹrii mejeeji:

Pipe ijẹrii mejeeji nikan ko to, bi ko ṣe pe a gbọdọ ni imọ nipa itumọ rẹ ati iṣẹ pẹlu nnkan ti o maa jẹ yọ lati ara mejeeji. Yio maa jẹ dandan lati ara Jijẹrii (pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si afi Allohu) iṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, àti ini igbagbọ ninu Allahu nikan ṣoṣo ni Oluwa ati Ọlọhun ti O ni ẹtọ si ijọsin, pẹlu imọkanga nibi ijọsin rẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí àwọn òrìṣà, tí ó sì ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ó kúkú ti dìmọ́ okùn t’ó fọkàn balẹ̀ jùlọ, tí kò níí já} [Surah Al-Baqarah: 256] Yio maa jẹ dandan lati ara jijẹrii pe (Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ni): Gbigba a lododo nibi nnkan ti o ba sọ, ati titẹle e níbi nnkan ti o pa láṣẹ tabi ti o ba kọ kuro nibẹ, ati pe ki a má jọsin fun Ọlọhun afi pẹlu nnkan ti o ba mu wa

Jíròrò

Nitori ki ni o ṣe jẹ dandan lati ara jijẹrii pe (ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si afi Allohu) iṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun?

Ba awọn akẹgbẹ rẹ kópa nibi ṣíṣe onka awọn okunfa ti o ṣe pe o maa n jẹ ki awọn ẹda máa ṣe ojukokoro lori ṣe àwárí orisirisi awọn ooṣa ati pipe awọn eniyan sibi ijọsin wọn

Ninu awọn ẹri ti laakaye ti Anọbi Ọlọhun Ibrahim- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- fi jiyàn pẹ̀lú awọn ijọ rẹ ni ibeere rẹ fun wọn pe: {Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?} [Surah As-Sâffât: 95]

Awọn ibeere ti igbelewọn

O tọna

Àṣìṣe

Ti o ba mọ pe dajudaju Allahu ni Ọlọhun aye, dajudaju èyí jẹ nnkan ti a maa ka si pe o to fun wiwọ Isilaamu:

Ó to nibi Jijẹrii pe dajudaju Muhammad-ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- Ojiṣẹ Ọlọhun ni lati jẹ ki n gba a lododo ki n si má tẹle e:

Lẹyin ti o ti wo fídíò yii (ta nj Muhammad?) sọrọ nipa abala titobi Anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ki o si ṣe alaye awọn oju-ọna ti awọn ọta Isilaamu n tọ fun biba aworan alapọn-ọnle rẹ jẹ

Laaarin igba ti o ṣi oju-iwe yii “Isa ninu Kuraani -jesusandquran.com” wò, sọrọ nipa asopọ Anọbi Muhammad pẹlu Anọbi Isa- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba awọn mejeeji

Ṣe ẹ̀dà àwòrán barcode naa lati ṣe abẹwo ikanni naa

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrin

Ìgbàgbọ́

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Ọpọ igba ni Mùsùlùmí maa n ni ìmọ̀lára ifọkanbalẹ ati ifayabalẹ nígbà tí ó bá n ka Kuraani, tabibti o ba n jọsin fun Ọlọhun pẹlu irun tabi nǹkan ti o yatọ si i ninu awọn ìjọsìn, ìmọ̀lára yii ti o maa n gbe ẹlòmíì ga ti wọn o fi de ìpele ti o tẹsiwaju ninu ìdùnnú, oun naa ni ọkan ninu awọn oripa ìgbàgbọ́ ti yoo ti Musulumi títí ti yoo fi fi gbogbo iṣẹmi rẹ fun Ọlọhun, yoo maa tẹle àṣẹ Rẹ ninu ẹ pẹ̀lú ìfẹ́, ti yoo si maa jìnnà si awọn nǹkan ti O kọ pẹ̀lú itẹle pátápátá. Ninu ẹkọ yii, a maa mọ agbọye ìgbàgbọ́ ati awọn origun rẹ ati awọn èso rẹ.

Ki ni igbagbọ?

Igbagbọ: Oun ni gbigba lododo ọkan ati ahọn pẹlu nnkan ti o wa lati ọdọ Ọlọhun, ati itẹle ọkan fun un ni ti ifẹ ati agbiyele ati ibẹru, ati iṣẹ awọn oríkèé ara pẹlu iyẹn, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà tefétefé} (Surah An-Nisâ': 136)

Jíròrò

Ki ni iyatọ laaarin agbiyele ati ibẹru?

Awọn origun igbagbọ:

Igbagbọ duro lori awọn origun mẹfa, awọn ni:

1. Nini igbagbọ ninu Ọlọhun: Musulumi maa ni igbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun- ti ọlá Rẹ̀ ga- ati ninu awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati pe dajudaju Oun ni Oluwa aye ti o gbaaye yii, Oun ni O da a, Oun si tun ni Olukapa fun gbogbo nnkan ti o wa nibẹ, ati Oludari fun awọn àlámọ̀rí wọn, ati Olùpèsè fun awọn ẹru Rẹ, yio tun ni igbagbọ pe dajudaju pe ko si ọlọ́hun miiran yatọ si I ti o ni ẹtọ ki a maa jọsin fun un, ati pe Oun ni a n royin pẹlu awọn iroyin pipe

2. Nini igbagbọ ninu awọn mọlaika: Musulumi maa ni igbagbọ pẹlu bibẹ awọn mọlaika alapọn-ọnle, ati pe dajudaju Ọlọhun ni O da wọn, ati pe dajudaju wọn n jọsin fun Ọlọhun, wọn ko kii yapa Rẹ nibi nnkan ti O n pa wọn laṣẹ, yio si ni igbagbọ pẹlu awọn iroyin wọn ati awọn iṣẹ wọn eyi ti o wa ninu Kuraani ati Sunnah

3. NIni igbagbọ ninu awọn iwe ti a sọ kalẹ: Musulumi maa ni igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun sọ awọn iwe kan kalẹ fun awọn ẹru Rẹ lati ọdọ Rẹ fún awọn Ojisẹ Rẹ, O sọ wọn kalẹ fun itọsọna awọn eniyan, ati kikọ wọn ni awọn alamọri ẹsin wọn, o wa ninu rẹ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ Taorat kalẹ fun Musa ọmọ Imran- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-, Zabur fun Daud- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-, Injil fun Isa ọmọ Maryam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-, Kuraani fun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati pe dajudaju Kuraani ni ikẹyin wọn ti o si jẹ olujẹrii le wọn lórí

4. Nini igbagbọ nínú àwọn Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun maa ba wọn-: Musulumi maa ni igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ran awọn Ojiṣẹ kan si awọn ijọ wọn ti O si kun wọn lọwọ pẹlu awọn iṣẹ iyanu ti wọn da lori ododo wọn, lati jẹ kí wọn fun awọn olugbagbọ ni ìró-ìdùnnú, ki wọn si maa kilọ fun awọn alaigbagbọ, ki wọn si kọ awọn ijọ wọn ni awọn alamọri ẹsin wọn, itẹle àṣẹ wọn ati itẹle wọn si jẹ dandan lori awọn ti a ran wọn si, ati pe dajudaju Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ikẹyin wọn ati opin wọn

5. Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin: Musulumi maa ni igbagbọ ninu ọjọ igbedide, ati pe dajudaju Ọlọhun maa gbe awọn oku dìde lati inu sàréè wọn ní ọjọ yẹn, ti yoo si ṣe ìṣirò wọn lórí awọn iṣẹ wọn, ti yoo si san wọn ni ẹsan le e lori, o n bẹ ninu wọn ẹni tí o maa wọ alujanna, o si n bẹ ninu wọn ẹni tí o ma wọ ina

6. Nini igbagbọ ninu kadara: Musulumi maa ni igbagbọ pe dajudaju gbogbo nnkan ti o maa ṣẹlẹ ni aye yii ni daadaa tabi aburu n bẹ lábẹ́ kadara Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti mọ ọn, O si ti kọ ọ sinu laohul mahfuuz, ati pe nnkankan o le sẹlẹ ni aye yii afi nnkan ti Ọba- ti ọla Rẹ ga- ba fẹ

Ṣíṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun:

Oun ni nini adisọkan ìní ẹtọ si ìjọsìn ẹnikan ti o yatọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, tabi asunmọ pẹlu rẹ pẹlu nǹkan kan ninu awọn ijọsin. Oun jẹ ẹṣẹ ti o tobi, ati iwa ọdaran nla, ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko lee ṣe aforijin rẹ, gẹgẹ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ pe: {Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá} [Surah An-Nisâ': 48]

Ohun ti a gbero pẹlu Kuraani ati Sunnah ni: Kuraani Alapọn-ọnle ati awọn hadisi Ojiṣẹ Ọlọhun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- torí pé wọn ka wọn si ipilẹ meji ti o pàtàkì fun ṣíṣe ofin ninu Isilaamu

Al-Laohul Mahfuuz: Oun ni iwe ti Ọlọhun kọ nnkan ti o kadara fun awọn ẹda sibẹ titi di ọjọ igbedide

Awọn eso igbagbọ:

Àwọn eso igbagbọ pọ, ninu wọn ni:

Ifayabalẹ ẹmi: Igbagbọ maa ṣe ẹmi olugbagbọ ni eyi ti o maa balẹ, ti o maa yọnu si Ọlọhun ati kádàrá Rẹ, ko nii bẹru nǹkan kan afi Ọlọhun

Dida Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- mọ: Musulumi maa da Oluwa rẹ mọ ni mimọ kan ti o maa ṣe alekun asopọ rẹ mọ Oluwa rẹ, yio si mọ awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ

Igbe Ọlọhun tobi: Olugbagbọ, gbogbo igba ti o ba ti n da Oluwa rẹ mọ ni yio maa ṣe alekun fun Un ni ti igbetobi ati gbigbọnngbọn, yoo si lekun fun Un ní ti ifẹ ati agbiyele, yoo si tun lekun ni ibẹru ati ipaya Rẹ

Ìní ìmọ̀lára ọla Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ: Ati pe Ọlọhun ti ran awọn Ojiṣẹ si wọn, O si sọ awọn tira kalẹ fun wọn; ki wọn le mọna lọ sibi ẹsin ododo

Níní ifẹ awọn mọlaika: Fún ijọsin wọn fun Ọlọhun, ati itẹle wọn fun Un

Ìní ifẹ awọn Ojiṣẹ: Ati pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti sa wọn lẹsa fun imu de ogongo iṣẹ Rẹ fun awọn eniyan

Igbiyanju níbi ijọsin: Gbogbo igba ti igbagbọ bá ti n lágbára ni ijọsin eniyan o maa lekun

Ìgbésí aye ti o mọ: Musulumi o maa yọnu si nnkan ti Ọlọhun ba pin fun un, yoo si mọ pe nnkan ti o ba n ṣẹlẹ si i ni aye ninu awọn adanwo jẹ igbega fun awọn ipo rẹ, ati ipa ẹṣẹ rẹ rẹ, gẹgẹ bi o ṣe maa ṣe agbiyele nnkan ti Ọlọhun pa lese silẹ fun un ninu idẹra fun awọn olugbagbọ ni ọrun

Àìgba ẹtanjẹ pẹlu aye: Igbesi aye jẹ nnkan ti o ni asiko, oun ni oju-ọna si igbesi aye gbere ni ọrun

Titu àṣírí àwọn ìgbàgbọ́ asán: Igbagbọ maa n tu àṣírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu awọn igbagbọ asán yẹn, o si maa n ba a jẹ

Wiwọ alujanna: Oun ni ọgba idẹra gbere eyi ti o jẹ pe ko nii tan, ati pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣa a ni ẹsa fun awọn olugbagbọ ninu awọn ẹru Rẹ

Kadara: Oun ni kadara Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fún àwọn nǹkan kan láti igba lailai, ti Ọba- ti mimọ n bẹ fun Un- ni imọ nipa rẹ pe dajudaju yio ṣẹlẹ ni awọn akoko kan ti O mọ ni ọdọ Rẹ, lori awọn iroyin kan pato

Ìwé àkọsílẹ̀ mi

Kọ apakan ninu awọn eso igbagbọ ti o mọ lara lẹyin wiwọ inu Isilaamu rẹ

Itumọ nini igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ ni ki o ni igbagbọ ninu Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nikan:

O tọna

Àṣìṣe

Lẹyin ti o ti wo fídíò yii (tani Allahu) sọrọ nipa titobi Aṣẹ̀dá

Wo fidio yii (Awọn nnkan ipilẹ igbagbọ mẹfa) ki o wa darukọ awọn oripa ti o maa rí lati ara igbagbọ rẹ pẹlu origun kọ̀ọ̀kan ninu awọn origun igbagbọ mẹfẹẹfa

Igbelewọn ti ara ẹni

Erongba ti ẹkọ kikọ

Ipo igbelewọn

Ko ri bẹẹ

O lẹ

O dáa

O tayọ

1. Njẹ o mọ awọn idahun awọn ibeere ti wọn so pọ mọ bibẹ eniyan?

2. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye itumọ Isilaamu ni ọna ti o rọrun?

3. Njẹ o mọ oju-ọna wiwọ inu Isilaamu?

4. Njẹ o gbọ agbọye itumọ ijẹrii mejeeji

5. Njẹ o ni ikapa ṣíṣe alaye awọn ko-ṣeé-ma-ṣe ijẹrii méjèèjì?

6. Njẹ o mọ awọn origun igbagbọ?

7. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye itumọ nini igbagbọ ninu Ọlọhun?

8. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye itumọ nini igbagbọ ninu awọn mọlaika?

9. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye itumọ nini igbagbọ ninu awọn iwe ti A sọ kalẹ?

10. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye itumọ nini igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ?

11. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye itumọ nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin?

12. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye itumọ nini igbagbọ ninu kadara?

13. Njẹ o mọ bi waa ṣe pe ijẹrii mejeeji ni pipe ti o ni alaafia?

14. Njẹ o mọ bi Musulumi tuntun ṣe le fun igbagbọ rẹ ni agbara?

15. Njẹ o n ni ìmọ̀lára ifẹ ẹsin Isilaamu ninu ọkan rẹ?

Abala keji

Kuraani Alapọn-ọnle

Awọn ẹkọ abala naa:

Ẹkọ Alakọkọ

Ni imọ nipa Kuraani Alapọn-ọnle

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Nígbà tí Ọlọhun gbe àwọn Anọbi dide lati pe àwọn ìjọ wọn, O fun wọn ni awọn iṣẹ iyanu kan ti wọn fi maa ṣe ẹri fun òdodo ijẹ anọbi wọn fun awọn ijọ wọn, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìyanu àwọn Anọbi maa n tan pẹ̀lú ikú wọn, ṣugbọn Ojiṣẹ Isilaamu- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- Ọlọhun ti fun un ni iṣẹ ìyanu kan ti o han jù lori awọn ijọ rẹ ati fun awọn eniyan patapata ni (iwe Rẹ Abiyi) ti o ṣe pe Ọlọhun ṣe àdéhùn ṣiṣọ rẹ lẹyin iku Anọbi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- Ninu ẹkọ yii, a maa pada mọ nǹkan kan ninu awọn ọla Kuraani ati awọn ẹkọ rẹ

Ki ni Kuraani?

Kuraani Alapọn-ọnle ni ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti O sọ ọ kalẹ fun Ojiṣẹ Rẹ Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- oun ni ikẹyin awọn iwe ti A sọ kalẹ, ti ko si iwe miiran lẹyin rẹ

Ọla ti o wa fun kika Kuraani:

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹnikẹni ti o ba ka arafi kan ninu iwe Ọlọhun, yio gba dáadáa kan pẹlu rẹ, dáadáa kan si niyi pẹ̀lú ìlọ́po mẹ́wàá irú rẹ̀ ni, mi o sọ pe: (ALIF LAAM MIIM) arafi kan ni o, ṣùgbọ́n ALIF arafi kan ni, LAAM arafi kan ni, MIIM arafi kan ni” Tirmidhi ni o mu u jade ninu Sunanu rẹ (nọmba 2910) pẹlu isnaadu ti o ni alaafia Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa bá a- sọ pe: “Ẹ máa ka Kuraani, nitori pe dajudaju o maa wa ni ọjọ igbedide ni oluṣipẹ fun awọn ti wọn n ka a” Muslim ni o mu u jade ninu Sohiihu rẹ (nọmba 804)

Awọn tira ti A sọ kalẹ: Awọn ni awọn iwe ti Ọlọhun- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga- sọ wọn kalẹ fun awọn Anọbi Rẹ

Musulumi maa ni igbagbọ ninu awọn iwe yii, ati pe dajudaju wọn sọ wọn kalẹ lati ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati pe dajudaju Ọlọhun ni O sọ nǹkan ti o wa nibẹ pẹlu nnkan ti o ba A mu- mimọ ni fun Un-, ninu awọn awọn iwe yii ni: Zabur ti o ṣe pe o sọ kalẹ fun Daud- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-, ati Taorat ti o sọ kalẹ fun Musa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-, ati Injil ti A sọ ọ kalẹ fun Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-, ṣugbọn ayipada ati ijirọ ti ṣẹlẹ si awọn iwe yii bi ọjọ́ ṣe n gorí ọjọ́

Kuraani ni ounjẹ ẹmi ati laakaye:

Kuraani Alapọn-ọnle ba awọn laakaye ẹda sọrọ ati awọn ẹmi wọn bákan náà, o n ba laakaye sọrọ lati ipasẹ:

Imu ẹri ti laakaye wa lori wọn alamọri, Ọba- ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)} [Suuratul Al-Anbiyâ’: 22] Ipepe lọ si ibi lilo laakaye ati irori nibi awọn ẹri ati awọn awijare, Ọba- ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fun yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀} [Suuratul Baqarah: 219]

Bibu awọn ti ko lo awọn laakaye wọn, ti ko si ronu jinlẹ pẹlu rẹ, Ọba- ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Tàbí ìwọ ń rò pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ń gbọ́ràn tàbí pé wọ́n ń ṣe làákàyè? Kí ni wọ́n ná, bí kò ṣe bí àgùtàn. Wọ́n wulẹ̀ ṣìnà jùlọ} [Surah Al-Furqân: 44]

O n ba awọn ẹmi wọn ati ìmọ̀lára wọn sọ̀rọ̀ lati ipasẹ:

Sisọ nǹkan ti èèyàn n ni ìmọ̀lára rẹ jáde, ati ṣíṣe àfihàn rẹ, ati iṣe aworan rẹ ni awọn isẹsi ti o pọ, Ọba- ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ (tó yẹ kí wọ́n ní sí) Allāhu. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì le jùlọ nínú ìfẹ́ sí Allāhu} [Surah Al-Baqarah: 165]

Ìránnilétí ìmọ̀lára ti ọmọniyan, ati ṣíṣe alaye awọn oripa rẹ ti o daa ati eyi ti ko dáa, Ọba- ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Dájúdájú o máa rí i pé àwọn ènìyàn tí ọ̀tá wọn le jùlọ sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ni àwọn yẹhudi àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Dájúdájú o sì máa rí i pé àwọn ènìyàn t’ó súnmọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo jùlọ ní ìfẹ́ ni àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú nasara ni àwa.” Ìyẹn nítorí pé àwọn àlùfáà àti olùfọkànsìn ń bẹ láààrin wọn. Àti pé dájúdáju wọn kò níí ṣègbéraga (sí òdodo)} [Surah Al-Mâ'idah: 82]

Pipa àṣẹ pẹlu pẹlẹpẹlẹ ati lílẹ̀ nibi ipepe, Ọba- ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì s.a.w.) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí t’ó dára jùlọ} [Surah An-Nahl: 125]

Fífi àwọn ìtumọ̀ ìgbàgbọ́ sínú àwọn aaya ìdájọ́, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Báyẹn ni ẹ̀yin náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, Allāhu sì ṣe ìdẹ̀ra (ẹ̀sìn) fun yín} [Surah An-Nisâ': 94]

Lilo awọn gbolohun ti wọn ni ilapa ninu ẹmi, ati eyi ti o maa n ru ìmọ̀lára òdodo sókè, Ọba ti ọlá Rẹ ga sọ pe: {Ṣé ẹ ò fẹ́ kí Allāhu foríjìn yín ni?} [Surah An-Nûr: 22]

O le ko ibanisọrọ mejeeji papọ: Ti laakaye ati ti ẹmi sinu aayah kan ṣoṣo, ti o maa ba làákàyè fi ọrọ wérọ̀ ti o si maa mu u yi èrò rẹ padà, ti o si maa ru ìmọ̀lára sókè bákan náà. Ọba ti ọlá Rẹ̀ ga sọ pé: {Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?} [Surah Fâtir: 3]

Jíròrò

Ki ni awọn aayah ti o ka siwaju gbigba Isilaamu rẹ? Bawo ni ilapa rẹ lori rẹ?

Kuraani ìlànà igbesi aye ni

Kuraani Alapọn-ọnle ni ọrọ Oluwa gbogbo ẹda, Ẹni ti O da awọn eniyan patapata, Oun ni O ni imọ julọ nipa wọn ju ara wọn lọ, O si ni imọ julọ pẹlu nnkan ti o le ṣe wọn ni anfaani ati pẹlu nnkan ti o le ko inira ba wọn, nitori ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi ṣe Kuraani- ni opin gbogbo awọn iwe Rẹ ti wọn sọ kalẹ- ni iwe kan ti o jẹ ti ìlànà ìgbésí aye, ti o n ya fun awọn èèyàn ìlànà igbesi aye wọn

Ati pe ìyẹn maa fi oju han lati ipasẹ awọn koko ti wọn n bọ̀ yii:

Gbigbooro ìwá ojútùú si nǹkan rẹ: Oun ni nnkan ti o maa n wa ojútùú si aye eniyan pẹlu awọn agbo rẹ mẹtẹẹta: Eyi ti o jẹ ti ènìyàn gangan, ati ti mọlẹbi, ati ti awujọ

Kikari àwọn àkòrí rẹ: O ko àwọn nǹkan wọ̀nyí sínú: Àwọn adisọkan, ati awọn ijọsin, awọn àṣà, awọn ibaṣepọ ti awujọ ati ti owo, ati awọn abala ti laakaye ati ti ìmọ̀lára ati ti ara, ati awọn ibaṣepọ ti ilu si ìlú, ati ipò alaafia ati ogun, ati nnkan ti o yatọ si wọn

Deedee: Oun ni iwe kan ti o n pàṣẹ déédéé ni gbogbo igba, ko da pẹlu awọn ọta, o si n kọ kuro nibi abosi pẹlu gbogbo aworan rẹ

Kuraani Alapọn-ọnle n ya ìlànà igbesi aye àwọn ènìyàn fun wọn, o si n ṣe alaye awọn ẹtọ wọn fun wọn ati awọn ojúṣe wọn, ti o n ṣe odiwon nnkan ti o jẹ ti wọn ati nnkan ti o jẹ dandan lórí wọn, pẹlu rírọ̀ ti o tayọ ti o maa jẹ ki ìṣe ofin rẹ dára fun gbogbo igba ati asiko

O jẹ dandan fun Musulumi lati ṣe ojukokoro lori titọ Kuraani Alapọn-ọnle ati kikọ awọn idajọ rẹ

Awọn itan awọn Anọbi ninu Kuraani:

Kuraani Alapọn-ọnle kun fun itan awọn Anọbi iṣaaju ati awọn ijọ wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí Anọbi Adam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- títí dórí Anọbi Nuh ati Hud ati Solih ati Ṣu'aib ati Ibrahim ati Ismaheel ati Ishaq ati Ya'kub ati Musa ati Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba wọn- ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn Anọbi ati awọn Ojiṣẹ, ati pe Kuraani Alapọn-ọnle sọ awọn itan wọn fun awọn ọgbọn kan, ninu wọn:

Ṣíṣe alaye pe dajudaju ẹsin awọn Anọbi patapata jẹ ẹsin kan ṣoṣo, ti ipilẹ rẹ jẹ mimu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni ọkan ṣoṣo.

Pípa ẹ̀tù si Anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lọkan, ati mimu u dúró ṣinṣin, nnkan ti o ba ṣẹlẹ pẹlu rẹ ti ṣẹlẹ si awọn Anọbi ṣiwaju rẹ

Bíbu tútù si ọkan awọn mumini pe dajudaju nnkan ti o ti ṣẹlẹ si wọn ninu ilekoko ati adanwo ti ṣẹlẹ si awọn alapọn-ọnle ninu awọn ẹru Ọlọhun ṣiwaju wọn

Mímú waasi ati ariwoye ninu rẹ, o jẹ awọn itan ododo ti o ṣẹlẹ

Idanwo

Fi gbogbo agbekalẹ ọrọ ninu awọn agbekalẹ ọrọ ti wọn n bọ yii si aaye ti o ba mu ni ibamu si asopọ wọn pẹlu rẹ.

Ọ̀rọ̀ Ọlọhun

Yio ṣipẹ fun awọn ti wọn n ka a

O n pàṣẹ pẹlu pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ ati ini aanu nibi ipepe

O n pepe si lilo laakaye

O n lo awọn gbolohun ti wọn maa n lapa ninu ẹmi

Ikẹyin awọn iwe ti A sọ kalẹ

Wọn sọ ọ kalẹ fun Anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-

Ninu awọn iroyin Kuraani:

Ninu awọn ọla ti o n bẹ fun Kuraani:

Kuraani Alapọn-ọnle

Iṣẹ iyanu rẹ

Awọn alaigbagbọ larubawa tako Kuraani; nitori naa, Ọlọhun pe wọn nija pẹlu mimu iru rẹ wa tabi Surah kan ninu rẹ tabi aayah mẹwaa, wọn ba kagara lati mu u wa

Awọn onka Surah rẹ

Surah 114

Ipilẹ rẹ

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ ọ kalẹ fun Ojiṣẹ Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati ipasẹ Jubril- ki alaafia maa ba a-

Sisọkalẹ rẹ

Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ọ kalẹ ni ẹyọ ẹyọ fun ọdun mẹtalelogun, ni Mekka ati Medina

Ede rẹ

Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ọ kalẹ pẹlu ede larubawa

Awọn onka aayah rẹ

Aayah 6236

Awọn orukọ rẹ

Ọlọhun sọ ọ ni Kuraani ati Al-Kitaab ati Al-Fur'qaan, ati Adh-Dhikr. O si tun ni àwọn orúkọ mìíràn tó pọ̀

Awọn àkòrí rẹ ti o tóbi jù

Ninu awọn àkòrí ti o ṣe pataki julọ ti Kuraani Alapọn-ọnle sọ̀rọ̀ nípa wọn ni:

Ọrọ nipa imu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni ọkan ṣoṣo ati dídá mimu orogun pẹlu Rẹ padà

Ọrọ nipa aye ti o n tọka pẹ̀lú dida a dáadáa lori Ẹni ti O da a- Ọba ti O gbọnngbọn ti O ga-

Àwọn itan Kuraani ti wọn kun fun awọn ariwoye ati awọn waasi

Ọrọ nipa ibẹrẹ ẹda ati igbe awọn ẹru dide lẹyin iku ati sisan wọn ni ẹsan pẹlu awọn iṣẹ wọn

Rire ati ṣíṣe ofin fun awọn olugbagbọ

Kuraani n ba laakaye sọrọ lati ipasẹ mímú ẹri ti laakaye wa lori awọn àlámọ̀rí

O tọna

Àṣìṣe

Nitori ki ni Ọlọhun ṣe sọ Kuraani kalẹ?

Wo ìkànnì yii lọ <> lẹyin naa ki o wa dárúkọ apakan awọn ẹri ti wọn n tọka si ìjẹ́ ododo Kuraani ati ifẹsẹrinlẹ rẹ, ni ẹni ti o n mu ẹri wa pẹ̀lú apakan awọn ojupọnna idanilagara ti o wa nibẹ

Ọlọhun sọ Kuraani kalẹ fun:

A) Gbogbo awọn Anọbi

B) Anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- .

Ẹkọ ẹlẹẹkeji :

Ṣíṣe alaye itumọ awọn suurah kéékèèké

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Wọn ka Surah Fatihah si eyi ti o tobi julọ ninu awọn Surah Kuraani, dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kanpa mọ ọla ti o n bẹ fun un ati titobi rẹ ninu awọn hadisi ti wọn pọ, oun ni Surah ti o jẹ dandan fun gbogbo Musulumi lati ha a sori; nitori pe o jẹ Surah kan ṣoṣo ti kika rẹ jẹ dandan lati máa ka a ni ori gbogbo irun. Ninu ẹkọ yii, a ma mọ Surah yii ti a si maa ha awọn aayah rẹ, a si maa mọ itumọ rẹ ti a tun maa mọ awọn onka awọn Surah ti wọn kuru ati eyi ti o ṣe pe o ko awọn itumọ ti o tobi sinu

Surah Al-Fatihah:

Itumọ Surah naa:

(Bismillahir Rahmonir Roheem) Mo n bẹrẹ kika Kuraani pẹlu orúkọ Ọlọhun ni ẹni ti o n wa iranlọwọ pẹlu Rẹ, (Allahu) Ẹni ti a n jọsin fun ni ododo, ti a n royin pẹlu aanu ti o kárí ti o gbooro ju gbogbo ẹda lọ, Oun ni Ẹni ti O maa n kẹ awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ni ikẹ kan ti o da yatọ

(Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen ) Ki ẹyin maa jẹ ti Ọlọhun pẹlu awọn iroyin Rẹ ti wọn pe, ati pẹlu awọn idẹra Rẹ lori gbogbo ẹda Rẹ, Oun nikan ṣoṣo ni O ni ẹtọ si gbogbo awọn aworan ọpẹ ati ìrísí rẹ, Oun ni Oluwa gbogbo awọn ẹda patapata, Ẹni ti O da wọn lẹyin aisi, ti O n mojuto awọn alamọri wọn, ti O n tun awọn iṣesi wọn ṣe.

(Ar-Rahmaanir-Raheem) Ar-Rahmaan: Ẹni ti a n royin pẹlu aanu ti o kari gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Ar-Raheem: Ẹni ti O ni iroyin aanu ti o wa fun awọn mumini nìkan nínú wọn

(Maaliki Yawmid-Deen) Olukapa ọjọ igbedide, ọjọ ìṣirò lori awọn iṣẹ ati sísan ẹsan lori wọn

(Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een) A maa jọsin fun Ẹ nikan ṣoṣo Irẹ Oluwa wa, a si maa wa iranlọwọ lọ si ọdọ Rẹ nikan ṣoṣo nibi gbogbo awọn alamọri wa; nítorí pe gbogbo àlámọ̀rí patapata ọwọ Rẹ lo wa

(Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem) Tọ wa si oju ọna taara, ki O si fi wa rinlẹ lori rẹ titi ti a fi maa pade Rẹ, oun ni Isilaamu, oju ọna ti o han ti a le tọ lọ si ibi iyọnu Ọlọhun ati lọ si awọn alujanna Rẹ

(Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) Oun ni oju ọna awọn ti O ti ṣe idẹra le wọn lori pẹlu imọna ninu awọn Anọbi ati awọn olukunlọwọ wọn, ati ẹni ti o rin lori oju ọna wọn, awọn ni awọn ti wọn mọna ti wọn si dúró deede.

Gbe wa jinna kuro nibi oju ọna àwọn tí O binu si; nitori pe wọn mọ ododo wọn ko si ṣiṣẹ tọ ọ, ati oju ọna awọn ti wọn sọnu awọn ti wọn ṣe pe wọn ko mọ ọna lọ si oju ọna taara latara aimọkan wọn

Ar-Rahmaan: Fun gbogbo ẹda Rẹ

Ar-Raheem: Nikan fun awọn olugbagbọ

Jíròrò

Ki ni awọn atẹgun ti o le ṣe iranlọwọ lati ha Suuratul Faatihah?

Surah Al-Ikhlas

Itumọ Surah naa:

{Qul huwal laahu ahad} Sọ- irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun- fun ẹni ti o bi ẹ nipa iroyin Oluwa rẹ: Oun ni Ọlọhun ti o da nikan ni ẹtọ si ìjọsìn òdodo ati ijẹ Oluwa, ko si ẹlomiran ti o ni ẹtọ si ìjọsìn lododo ayafi Oun.

Allahus-Somad Oun ni Allahu Ọba ti O pe nibi awọn iroyin Rẹ, Ẹni ti O ṣe pe awọn ẹda maa n gbero Rẹ nibi wiwa awọn bukaata wọn pẹlu rirọrọ Rẹ kuro ni ọdọ wọn

(Lam yalid wa lam yoolad) Oun ni Allahu ti O ṣe pe ko si ọmọ fun Un, ko ni ọmọkunrin tabi ọmọbinrin, ko si obi fun Un, baba ni tabi iya.

(Wa lam yakul-lahoo kufuwan ahad Ẹni ti o jọ Ọ ko si fun Un ninu ẹda Rẹ, tabi nibi paapaa Rẹ, tabi nibi awọn orukọ Rẹ tabi nibi awọn iroyin Rẹ, tabi nibi awọn iṣẹ Rẹ

Surah Al-falaq

Itumọ Surah naa:

{Qul a’oozu bi rabbil-falaq} Sọ- irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun- mo n sa di, mo si n wa aabo pẹlu Ọlọhun Oluwa òwúrọ̀ kùtùkùtù, oun ni yiyọ òwúrò.

{Min sharri maa khalaq} Ninu aburu nnkan ti O da ninu awọn ẹda, eyi ti a n ri ati eyi ti a kìí ri.

{Wa min sharri ghaasiqin izaa waqab} Ati ninu aburu oru ti o ba dé pẹ̀lú okunkun rẹ, ati nnkan ti o wa nibẹ ninu awọn aburu ati nnkan ti o le ṣe eniyan ni suta

{Wa min sharrin-naffaa-saati fil ‘uqad} Ninu aburu awọn onidan ti wọn n fẹ atẹgun sibi nnkan ti wọn ta ni koko ninu awọn iṣẹ idan

{Wa min sharri haasidin izaa hasad} Ati nibi aburu oni keita ti o n rankan yiyẹ idẹra kuro lọdọ ẹni ti wọn ṣe keita rẹ, ati ṣiṣẹlẹ suta fun un

Al-Falaq: Yíyọ òwúrọ

Al-Gọsaq: Ki òru ṣókùnkùn gan

Surah An-Nas

Itumọ Surah naa:

{Qul a’oozu birabbin naas } Sọ- irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun- pé: Mo n sa di, mo si n wa aabo pẹlu Oluwa awọn eniyan, Ọba Olukapa nikan ṣoṣo lori gbogbo nnkan

{Malikin naas} Ọba awọn eniyan patapata, Ọba Oluṣe nnkan ti o wu U nibi gbogbo alamọri wọn

{Ilaahin naas} Ọlọhun awọn eniyan patapata, ko si ẹni ti a maa jọsin fun fun wọn lododo yatọ si I

{Min sharril waswaasil khannaas} Nibi suta èṣù ti o ṣe pe o maa n kó royiroyi ba wọn nigba igbagbera wọn, ti yio si maa jawọ nibi ìyẹn nigba ti wọn ba n ṣe iranti Ọlọhun

{Allazee yuwaswisu fee sudoorin naas} Ẹni ti o ṣe pe o maa n fọn awọn irori buburu si awọn igba-aya àwọn ènìyàn ká, ti o si máa n fi ìmọ̀lára wọn ati ìròrí wọn ṣeré.

{Minal jinnati wannaas} Ninu awọn Eṣu ninu alujannu ati eniyan

Surah Al-Kafirun

Itumọ Surah naa:

{Qul yaaa-ayyuhal kaafiroon} Sọ- irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun- fun awọn ti wọn ṣe aigbagbọ si Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ pe: Mo pe ẹyin alaigbagbọ si Ọlọhun

{Laaa a’budu maa t’abudoon} Mi ko nii jọsin fun nnkan ti ẹ n jọsin fun ninu awọn ọlọhun irọ́; gẹgẹ bii awọn ooṣa ati nnkan ti o yatọ si wọn

{Wa laa antum ‘aabidoona maa a’bud} Ẹyin naa ko nii jọsin fun Ọlọhun ododo ti mo n jọsin fun Un, Oun nikan ṣoṣo ni O lẹ́tọ̀ọ́ si ijọsin

{Wa laa ana ‘abidum maa ‘abattum} Mi ko si nii jẹ olùjọsìn fun ọlọhun irọ ti ẹ n jọsin fun

{Wa laa antum ‘aabidoona maa a’bud} Ẹyin naa ko nii jọsin fun Ọlọhun ododo ti mo n jọsin fun Un, Oun nikan ṣoṣo ni O lẹ́tọ̀ọ́ si ijọsin

{Lakum deenukum wa liya deen} Ẹsin yin ko maa jẹ tiyin eyi ti o ṣe pe ẹ n dirọ mọ, ẹsin ti emi naa maa jẹ temi eyi ti o ṣe pe mo n dirọ mọ ọ

Al-kaafir: Oun ni ẹni ti o ṣe pe ko jẹrii pẹlu ijẹrii imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo pẹlu igbagbọ, ti ko si tẹle iṣẹ Ojiṣẹ Ọlọhun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-

Jíròrò

Ki ni akọle eyi ti o ṣe pe awọn Surah mejeeji Al-Ikhlas ati Al-Kafirun kanpa mọ?

Surah Al-Kaothar

Itumọ Surah naa:

{Innaaa a’tainaa kal kauthar} Dajudaju Awa ni A fun ẹ, irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ni oore ti o pọ ti ko ni onka ti ko ni iye ni aye ati ọrun, ninu ìyẹn ni abata Kaothar ninu alujanna

{Fasalli li rabbika wanhar} Mọ́ irun rẹ ati iduran rẹ kanga fun Oluwa Rẹ, ki o jọsin fun Un nikan ṣoṣo, ko si orogun fun Un, du ẹran pẹlu orúkọ Rẹ, ko si orogun fun Un, ni ti idupẹ fun Un lori nnkan ti O fun ẹ ninu apọnle ati oore

{Inna shaani-aka huwal abtar} Dajudaju ẹni ti o korira rẹ, ti o korira nnkan ti o mu wa ninu ẹsin ododo, oun ni ẹni ti o kere julọ ẹni yẹpẹrẹ julọ, ẹni ìgbàgbé, ẹni ti wọn pa ni àdánù oore.

Shaani-aka: Ìtumọ̀ rẹ ni ẹni ti o korira rẹ ẹni ti o ṣe pe ko ni ifẹ rẹ ti o ko rira nnkan ti o mu wa ninu ẹsin ododo

Surah Al-Asr

Itumọ Surah naa:

{Wal ‘asr} Ọlọhun bura pẹlu igba ati asiko eleyii ti o ṣe pe awọn lilọ bibọ awọn ọmọ Anọbi Adam n sẹlẹ nibẹ, ninu daadaa ati aburu

{Innal insaana lafee khusr} Dajudaju awọn ẹda wa ninu ofo ati iparun

{Illal lazeena aamanoo wa ‘amilus saalihaati wa tawaasaw bilhaqqi wa tawaasaw bissabr} Afi awọn ti wọn ṣe pe wọn ni igbagbọ ninu Ọlọhun ti wọn si n ṣe awọn iṣẹ oloore, ti apakan ninu wọn si n sọ asọtẹlẹ fun apakan pẹlu didirọ mọ ododo ati diduro ṣinṣin lori rẹ, ati pẹlu suuru lori ìyẹn

Igbelewọn ti ara ẹni

1. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye nnkan ti a n pe ni Kuraani?

2. Njẹ o ni ikapa lati ṣe aworan asopọ laaarin Kuraani ati igbesi aye?

3. Njẹ o mọ idi ti Ọlọhun ṣe sọ itan awọn Anọbi ninu Kuraani?

4. Njẹ o ni agbọye itumọ gbogbogboo fun Surah Al-Fatiha?

5. Njẹ o ni agbọye itumọ gbogbogboo fun Surah Al-Ikhlas?

6. Njẹ o ni agbọye itumọ gbogbogboo fun Surah Al-Falaq?

7. Njẹ o ni agbọye itumọ gbogbogboo fun Surah An-Nas?

8. Njẹ o ni agbọye itumọ gbogbogboo fun Surah Al-Kafirun?

9. Njẹ o ni agbọye itumọ gbogbogboo fun Surah Al-Kaothar?

10. Njẹ o ni agbọye itumọ gbogbogboo fun Surah Al-Asr?

11. Njẹ o ni ikapa lati ka Surah Al-Fatiha ni kika ti o ni alaafia?

12. Njẹ o ti ha Surah Al-Fatiha?

13. Njẹ o ni ikapa lati ka Surah Al-Ikhlas ni kika ti o ni alaafia?

14. Njẹ o ti ha Surah Al-Ikhlas?

15. Njẹ o ni ikapa lati ka Surah Al-Falaq ni kika ti o ni alaafia?

16. Njẹ o ti ha Surah Al-Falaq?

17. Njẹ o ni ikapa lati ka Surah An-Nas ni kika ti o ni alaafia?

18. Njẹ o ti ha Surah Al-Nas?

19. Njẹ o ni ikapa lati ka Surah Al-Kafirun ni kika ti o ni alaafia?

20. Njẹ o ti ha Surah Al-Kafirun?

21. Njẹ o ni ikapa lati ka Surah Al-Kaothar ni kika ti o ni alaafia?

22. Njẹ o ti ha Surah Al-Kaothar?

23. Njẹ o ni ikapa lati ka Surah Al-Asr ni kika ti o ni alaafia?

24. Njẹ o ti ha Surah Al-Asr?

25. Njẹ o ti n ni ìmọ̀lára awọn itumọ awọn Surah ti o kọ?

Abala kẹtà

Awọn ijọsin

Awọn ẹkọ abala naa:

Ẹkọ Alakọkọ

Ijọsin

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Muslim maa n ṣe ijọsin ti o pọ ninu iṣẹmi rẹ ti o ṣe pe o n fi wọn sunmọ Aṣẹ̀dá rẹ- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga-, ati pe gbogbo awọn ijọsin yii wa fun igbe Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- tobi ati titẹriba fun Un yatọ si elomii, gbogbo igba ti ọkan Musulumi ba ti n gbe Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- tobi, ni oripa rẹ maa han nibi ìjọsìn rẹ, ati pe Musulumi ododo oun ni ẹni ti o maa n fi gbogbo aye rẹ pẹlu ohun ti o wa nibẹ bii iṣẹ ati oorun ati ere fun Ọlọhun- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga-, ni ẹni ti o n mu ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣẹ: {Sọ pé: "Dájúdájú ìrun mi, ẹran (pípa) mi, ìṣẹ̀mí ayé mi àti ikú mi ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un. Ìyẹn ni Wọ́n pa láṣẹ fún mi. Èmi sì ni ẹni-àkọ́kọ́ àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi)} (Surah Al-An`âm: 162 - 163) Ninu ẹkọ yii a maa mọ itumọ ijọsin, ati awọn iran rẹ, ati awọn majẹmu itẹwọgba rẹ, ati awọn ipo rẹ

Itumọ ijọsin:

Ìjọsìn: Oun ni àwọn iṣẹ́ ti Ọlọhun ṣe ni òfin ki Mùsùlùmí le fi sunmọ Ọlọhun. O si ko gbogbo ìṣe ati gbólóhùn ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ sí sínú: Boya o jẹ èyí ti o han ni; bii ìjọsìn ti ara, gẹgẹ bii irun ati hajj, tabi o jẹ eyi ti ko han; bii àwọn ìjọsìn ti ọkàn, gẹgẹ bii: Inifẹẹ Ọlọhun, ati ìpayà Rẹ, ati agbiyele Rẹ, ati ohun ti o yatọ si I nínú àwọn ìjọsìn ti ọkàn. O rọrùn fun ẹrú lati yí àwọn àṣà rẹ padà si ìjọsìn pẹ̀lú dida àníyàn rere mọ ọn; ti o ba da àníyàn lati ni agbára lórí itẹle àṣẹ Ọlọhun pẹlu oúnjẹ rẹ ati ohun mímu rẹ ati oorun rẹ, wọn maa san an ni ẹsan lori ìyẹn.

Awọn iran ijọsin

Awọn ijọsin pin si oríṣiríṣi:

Awọn ìjọsìn ti ọkan

Musulumi maa ṣe e pẹlu ọkan rẹ; gẹgẹ bii ini ifẹ ati ibẹru ati agbiyele ati ipaya

Awọn ijọsin ti ara

Musulumi maa n ṣe e pẹlu ara rẹ; gẹgẹ bii irun ati zakat ati hajj.

Awọn ijọsin ti gbigbe-ju-silẹ

Musulumi maa sunmọ Oluwa rẹ pẹlu gbigbe nnkan ti O ṣe ni eewọ fun un ju silẹ; gẹgẹ bii gbigbe ọti ju silẹ ati ṣìná, tabi gbigbe apakan awọn nnkan ti a ṣe ni ẹtọ ju silẹ ni awọn asiko kan pato; gẹgẹ bii gbigbe jijẹ ati mimu ju silẹ ni àsìkò àwẹ̀.

Agbiyele: Oun ni didunnu pẹlu ọla Ọlọhun, ati irankan daadaa Rẹ ati ọrẹ Rẹ, pẹlu ṣíṣe igbiyanju ati dídára igbarale Ọlọhun

Irẹlẹ: Iṣesi kan ni ti ẹmi maa wa nibẹ nibi ifayabalẹ ati ki ọpọlọ má kúrò nibi ìjọsìn ni àsìkò ti a ba n ṣe e lọwọ, gẹgẹ bii irun fun àpẹrẹ, oripa rẹ o maa han nibi ifarabalẹ awọn orikee ara

Awọn majẹmu itẹwọgba awọn ijọsin:

Wọn ṣe majẹmu meji fun itẹwọgba awọn ijọsin: Akọkọ: Imọkanga fun Ọlọhun, Musulumi o maa ṣe ijọsin láti sunmọ Ọlọhun nikan ṣoṣo, laini ẹbọ ninu tabi ṣekarimi Ikeji: Biba ofin Ọlọhun mu, Musulumi o maa ṣe ijọsin gẹgẹ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe ṣe e ni ofin ati gẹgẹ bi Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ṣe e

Ṣekarimi: Ki Musulumi gbero ṣíṣe ijọsin lati le jẹ ki awọn eniyan ri i nigba ti o ba n ṣe e, ti wọn si maa yin in lori ṣíṣe rẹ

Jíròrò

Ki ni nnkan ti oniṣekarimi maa pàdánù rẹ pẹlu gbigbe imọkanga fun Ọlọhun ju silẹ?

Awọn ipo awọn ijọsin:

Ipò ìjọsìn ju ara wọn lọ: O n bẹ ninu ẹ ohun ti o jẹ dandan fun gbogbo Musulumi; bii irun ni àpẹrẹ. Ninu ẹ ni ohun ti o jẹ dandan fun awọn kan nínú àwọn Musulumi;

Idanwo

Fi gbogbo ijọsin kọ̀ọ̀kan ninu awọn ijọsin ti wọn n bọ yii sínú òpó rẹ ti o yẹ ẹ́ ni ibamu si ipo rẹ ninu Isilaamu:

Irun Asr

Awọn iranti aarọ

Ṣíṣe dáadáa si awọn obi méjèèjì

Hajj

Awẹ

Awẹ Ramadan

Sàká

O jẹ dandan fun gbogbo Musulumi:

O jẹ dandan fun apakan awọn Musulumi:

Nnkan ti a fẹ ti ko kii ṣe dandan:

Latara wíwo fidio yii: (Nitori ki ni mo ṣe gba fun Ọlọhun?) sọrọ nipa eso ti o ṣe pe Musulumi maa ri latara àfiyèsí rẹ sí erongba Ọlọhun nikan ṣoṣo ati imọkanga rẹ fun Un ni Òun nikan ṣoṣo nibi gbogbo awọn iṣẹ rẹ

Dandan ni fun itẹwọgba iṣẹ oloore ki o jẹ tori ti Ọlọhun, ki o si ba ofin Ọlọhun mu.

O tọna

Àṣìṣe

Ẹkọ ẹlẹẹkeji :

Imọra

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Isilaamu pepe si imọra ati wiwa ni mimọ, o si kan an nipa fun Musulumi lati ko akolekan imọtoto ara rẹ, o si ṣe àlámọ̀rí yii ninu awọn àmì ẹsin, o si so ini àlàáfíà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọsìn mọ ki Mùsùlùmí mu imọra wa si imuṣẹ, o si wa ninu awọn iroyin ti Musulumi fi maa da yàtọ̀ si ẹlomiran, nínú ẹ̀kọ́ yìí, a maa mọ itumọ imọra, ati ìran rẹ, ati awọn idajọ kan ti o rọ mọ ọn.

Itumọ imọra:

Imọra

Ijọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-

Oun ni gbigbero iṣẹ ni ti itẹle ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati ni ti isunmọ Ọn

Pẹlu mimu ẹgbin kuro

Ẹgbin ni iroyin ti Sharia fun gbogbo nǹkan ti o n bọ si awọn orikee ara ti imọra si maa n kuro pẹ̀lú okùnfà rẹ.

Mímú awọn ẹgbin kúrò

Oun ni awọn ẹgbin ti ofin pàṣẹ pẹlu mimọra kuro nibẹ ati mimu u kuro; gẹgẹ bii itọ ati igbẹ

Kíkà ti afikun

Ki o le mọ si i nipa awọn idajọ imọra, ka iwe imọra ninu Isilaamu, eyi ti o wa ni ibutaja Usuul, pẹlu oriṣiriṣi ede agbaye

Ṣe ẹ̀dá àwòrán barcode naa lati fi ẹ̀dà ìwé naa ránṣẹ́

Awọn iran imọra:

Imọra pin si iran meji:

1- Imọra ti a lè ni ìmọ̀lára rẹ̀.

Oun naa ni: Mimu ẹgbin kúrò, ati mímọ́ ààyè rẹ, ati mimu àwọn okùnfà ti o le kọ̀ fúnni lati ma ki ìrun kúrò, ìyẹn maa wáyé pẹ̀lú fífọ àwọn ẹ̀yà ara kan, tabi fifọ gbogbo ara.

2. Imọra ti a kò lè mọ̀ lára

Oun ni: Mimọ ọkàn kúrò nibi ẹbọ ati inúnibíni ati ìkórìíra fun awọn ẹru Ọlọhun ti wọn jẹ onigbagbọ òdodo, ati ohun ti o yàtọ̀ si i ninu awọn àrùn ọkàn. O si pàtàkì gẹgẹ bii imọra ti ara, kódà kò rọrùn kí imọra ti ara ti o ba òfin mu ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú bibẹ ẹgbin ẹbọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: "Dájúdájú ẹ̀gbin ni àwọn ọ̀sẹbọ" [At-Taobah: 28]

Imọra ti a le mọ lára maa jẹ pẹlu aluwala tabi iwẹ

Nnkan ti a gba lero pẹlu aluwala ni: Fifọ apakan awọn ẹya ara pẹlu omi

Nnkan ti a gba lero pẹlu iwẹ ni: Fifọ gbogbo ara pẹlu omi

A maa n lo omi ti o mọ níbi imọra; gẹgẹ bii omi okun tabi akeremọdo tabi kannga, tabi eyi ti o yatọ si ìyẹn ninu awọn omi ti ẹgbin ko ro pọ mọ wọn

Awọn idajọ ti wọn so pọ mọ imọra:

Ipilẹ nibi gbogbo nnkan ni imọra, a ko nii dajọ pe nǹkan kan ni ẹgbin afi nnkan ti ofin ba sọ pe ẹgbin ni.

O to níbi mimọ ara tabi aṣọ kúrò níbi ẹgbin pẹlu mimu u kúrò pẹlu omi tabi eyikeyi nnkan ti o le mọ nnkan

Ti eniyan ba wọ ile ẹgbin fun bibiya bukaata, eyi ti o daa julọ ni ki o mọ aye itọ ati igbẹ pẹlu omi, o tọ lati mọ ọn pẹlu awọn inuju tabi nnkan ti o yatọ si ìyẹn ninu nnkan ti o le mu ẹgbin kuro

Jíròrò

Orí ki ni kikanpa mọ ijẹ dandan imọra Mùsùlùmí ati ṣiṣọ imọtoto ara rẹ n tọka si?

Mu idahun ti o tọna

Imọra n tumọ si:

A) Gbígbé ẹgbin kuro

B) Mímú awọn ẹgbin kúrò

D) Gbogbo nnkan ti o ti ṣaaju

Wọn n pe fifọ gbogbo ara pẹlu omi ni:

A) Aluwala

B) Iwẹ

C) Aluwala oni erùpẹ̀

Ni apapọ, iran meji ni o n bẹ fun imọra, awọn mejeeji ni:

A) Imọra ti a lè mọ lára ati imọra ti a ko le mọ lára.

B) Aluwala ati Aluwala oni erùpẹ̀

D) Aluwala ati iwẹ

Ẹkọ ẹlẹẹkẹta

Aluwala

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Aluwala pàtàkì nínú Isilaamu torí asopọ rẹ ti o nipọn pẹlu irun ti o jẹ àmì ẹsin Isilaamu ti o tobi ju; tori ẹ ni o ṣe jẹ́ dandan fun Musulumi lati ṣe ojúkòkòrò lati kọ́ ọ Ati lati ṣe e dáadáa, nínú ẹ̀kọ́ yii, a maa mọ itumọ aluwala, ati awọn okunfa ti o maa sọ ọ di dandan, ati awọn nǹkan ti o n ba a jẹ, ati ọ̀nà ti a le gba ṣe e dáadáa

Itumọ aluwala:

Aluwala: Fifọ oju ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji ati pípa ori ni ọ̀nà kan pato

Awọn nnkan ti yoo sọ aluwala di dandan:

Awon nnkan ti yoo sọ aluwala di dandan ni awọn alamọri ti o ṣe pe wọn ṣe aluwala ni májẹ̀mú fun wọn, ti o si maa jẹ dandan nitori wọn, ti ẹnikan ba ni ẹgbin lara o ti di eewọ fun un, awọn ni:

A) Irun

Rirọkirika Ka'ba

Gbigba Kuraani mu

Al-Hadath: Ìròyìn kan ni ti a ko le fi ojú ri ni ara eniyan ti yoo maa kọdi rẹ nibi kiki irun ṣiwaju ki o to mọra, ko kii ṣe nnkan ti a le mọ lára, gẹgẹ bii An-Najaasah, oun pin si iran meji, akọkọ ninu mejeeji o maa sọ aluwala di dandan fun Musulumi lati gbe e kuro, ti ikeji ko si nii kuro afi pẹlu iwẹ

Bawo ni a ṣe n ṣe aluwala

Ti Musulumi ba fẹ ṣe aluwala, o jẹ dandan fun un lati gbe awọn igbesẹ ti o n bọ yii:

1. Yio daniy pẹlu ọkan rẹ, o maa sọ pe: “Bismillah”

2. Yio fọ ọwọ rẹ mejeeji pẹlu omi ti yio bẹrẹ pẹlu ọtun

3. Yio mọ ẹnu rẹ pẹlu mimu omi wọle sibẹ, lẹyin naa yio gbo o jigijigi, oun ni a n pe ni Al-Madmọdọ

4. Yio mọ imu rẹ pẹlu mimu omi wọle sibẹ pẹlu fífa omi si imu, lẹyin naa yio mu u jade pẹlu fifẹ atẹgun lati imu rẹ

5. Yio fọ gbogbo ojú rẹ, awọn aala rẹ ni ti ooro bẹrẹ lati ibi ti irun ti n hù nibi oke iwaju ori titi de isalẹ agbọn, pẹlu irun agbọn fun ẹni tí ó bá ni i, aala rẹ ni ti ìbú ni lati eti si eti

6. Yio fọ ọwọ rẹ mejeeji lati awọn eti ọmọnika titi de igunpa, bẹrẹ lati ọwọ rẹ ọtun

7. Yio fi omi tutu ọwọ rẹ mejeeji, lẹyin naa yio fi mejeeji pa ori rẹ, bẹrẹ lati iwaju ori titi de ipakọ, lẹyin naa yio da ọwọ rẹ pada si iwaju

8. Yio pa eti rẹ mejeeji pẹlu ìka ìlábẹ̀ rẹ mejeeji ninu eti mejeeji, yio si fi atanpako rẹ mejeeji pa ẹyin eti mejeeji

9. Yio fọ ẹsẹ rẹ mejeeji titi de kokosẹ mejeeji, awọn mejeeji ni eegun meji ti wọn han nibi ti eegun méjì ti pàdé pọ̀ ni ẹsẹ, bẹrẹ lati ẹsẹ ọtun

Onka iye igba ti a maa fọ awọn ẹya ara aluwala:

Sunna nibi aluwala ni fifọ gbogbo ẹya kọ̀ọ̀kan ni ẹẹmẹta afi pipa ori ati eti mejeeji, ìyẹn maa jẹ ẹẹkan pere, gbigba tito pẹlu fifọ ni ẹẹkan tọ́ fun ẹya ti a maa n fọ pẹlu majẹmu fifọ gbogbo rẹ

Awọn nnkan ti wọn n ba aluwala jẹ:

Aluwala o maa bajẹ pẹlu ọkan ninu awọn alamọri mẹrin kan:

Jijade nǹkan kan ninu ọkan ninu awọn ọ̀nà mejeeji; gẹgẹ bii iso tabi itọ tabi igbẹ tabi atọ tabi itutu ti o ṣe pe o maa n wa pẹlu adun

Yíyẹ̀ laakaye pẹlu oorun tabi ìmutíyó

Fifi ọwọ kan oju ara pẹlu adun laisi gàgá

Jíjẹ ẹran rakunmi

Kíkà ti afikun

Wo fíìmù bi a ṣe maa n ṣe aluwala yii, o jẹ agbejade ilé iṣẹ Markazu Usuul

Ṣe ẹda aworan barcode naa lati wo fidio naa

Jíròrò

Onka awọn atẹgun ti o maa ṣe iranlọwọ lori kíkọ́ bi a ṣe n ṣe aluwala ati lilo o ni ọna ti o ni alaafia

Igba wo ni o maa jẹ dandan fun mi lati da aluwala pada?

Ti Musulumi ba ṣe aluwala, ipilẹ ni ki o si ni aluwala titi ti nnkan ti yoo sọ aluwala di dandan fi maa ṣẹlẹ si i nínú nnkan ti a dárúkọ ṣiwaju

Idanwo

Fi gbogbo agbekalẹ ọrọ ninu awọn agbekalẹ ọrọ ti wọn n bọ yii si aaye ti o ba mu ni ibamu si asopọ wọn pẹlu rẹ.

Jijade itọ

Gbigba Kuraani mu

Oorun

Irun

Rirọkirika Ka'bah

Gbigba oju ara mu pẹlu adun

Jíjẹ ẹran ràkúnmí

Wọn ṣe aluwala ni majẹmu fun un:

Awọn nnkan ti wọn n ba aluwala jẹ:

Pípa ibọsẹ méjèèjì:

Ti ẹni ti o ba n ṣe aluwala ba jẹ ẹni ti o wọ ibọsẹ si ẹsẹ méjèèjì, o tọ fun un ki o pa ori méjèèjì nikan pẹ̀lú ọwọ rẹ tútù méjèèjì lori ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, ko bùkátà si ki o bọ́ ọ lati fọ ẹsẹ̀ méjèèjì. Ìyẹn si ni májẹ̀mú mẹta:

Akọkọ: Ki wiwọ ibọsẹ mejeeji jẹ lori imọra

Ikeji: Ki ibọsẹ naa bo ẹsẹ̀ pẹlu koko ẹsẹ mejeeji

Ikẹta: Ki asiko pipa mejeeji ma tayọ (wakati mẹrinlelogun) fun ara ile, tabi (wakati mejilelaadọrin) fun arinrin-ajo

Asiko pipa awọn ibọsẹ o maa bẹrẹ lati igba akọkọ ti a ba pa wọn

To awọn iṣẹ aluwala ti wọn n bọ yii bẹrẹ pẹlu akọkọ ninu rẹ:

A) Pipa ori

B) Fifi omi yọ ẹnu

D) Fifọ oju

E) Pipa eti mejeeji

F) Fifọ ẹsẹ̀ méjèèjì

F) Fifọ ọwọ méjèèjì

Ṣe adayanri awọn ijọsin ti wọn ṣe aluwala ni majẹmu fun wọn ninu awọn nnkan ti wọn n bọ yii:

A) Irun

B) Awẹ

D) Gbigba Kuraani mu

E) Pipe irun

Ẹ) Rirọkirika Ka'bah

Mu idahun ti o tọna

Onka awọn nnkan ti wọn n ba aluwala jẹ ni apapọ:

A) 2

B) 3

D) 4

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrin

Iwẹ

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Awọn iṣesi kan n bẹ ti aluwala ko nii to nibẹ fun ṣíṣe ijọsin, bi ko ṣe pe iwẹ ni yoo jẹ dandan, ninu ẹkọ yii a maa mọ itumọ iwẹ, ati awọn okunfa ti yio maa sọ ọ di dandan, ati bi a ṣe n ṣe e

Itumọ iwẹ:

Al-Ghuslu: Fifọ gbogbo ara pẹlu omi pẹlu aniyan gbigbe ẹgbin nla kuro

Bawo ni a ṣe maa wẹ?

Ko si ibuyẹ nibi wiwẹ ti omi ko fi nii kari gbogbo ara pẹlu fifi omi yọ ẹnu ati fífa omi si imu, ti Musulumi ba ti ṣe ìyẹn o ti mọ́ra kuro nibi ẹgbin nla

Ẹgbin nla: Nnkan ti iwẹ o maa jẹ dandan fun gbigbe e kuro ti aluwala ko nii to, oríṣiríṣi ni:

1. Janaba: Iroyin kan ni fun ọkunrin ati obinrin ti ibalopọ ba sẹlẹ lati ọwọ awọn mejeeji, tabi ki atọ jade pẹlu adun ko da ki o ma si ibalopọ

2. Ẹjẹ nnkan oṣu: Ẹjẹ oṣooṣu ti o ṣe pe o maa n jáde lara obinrin

3. Ẹjẹ ìbímọ: Ẹjẹ ti o maa n jade lara obinrin lẹyin ti ọmọ ba jade ninu apo ibi rẹ

Iroyin iwẹ ti o pe:

Ti Musulumi ba fẹ wẹ iwẹ ti o pe, o jẹ dandan fun un lati gbe awon igbesẹ ti wọn n bọ yii:

Yoo da aniyan iwẹ pẹlu ọkan rẹ, yio si bu omi rin oju ara rẹ

Yio ṣe aluwala gẹgẹ bii ti aluwala irun

Yio fi omi fọ gbogbo ara rẹ

Ìgbà wo ni iwẹ o maa jẹ dandan?

Iwẹ o maa jẹ dandan fun Musulumi ni awọn iṣesi mẹta kan:

Akọkọ: Jijade atọ pẹlu adun, boya o jade ni oju aye ni tabi ni oju orun

Ikeji: Ibalopọ, boya jijade atọ sẹlẹ ni o tabi ko sẹlẹ

Ikẹta: Jijade ẹjẹ nnkan oṣu tabi ẹjẹ ìbímọ lọdọ obinrin, ti ẹjẹ ba ti da iwẹ jẹ dandan fun un

Jíròrò

Lori ki ni itọsọna lati wẹ̀ fun gbígbé ẹgbin ńlá kúrò n tọka si?

Nnkan ti ṣíṣe rẹ jẹ eewọ fun oni janaba:.

Wọn n pe iṣesi ẹni ti o ṣe pe iwẹ jẹ dandan fun pẹlu okunfa ibalopọ tabi jijade atọ ni (Janaba), ti wọn si n pe ẹni ti o wa lara rẹ ni (Junub). Yio maa jẹ eewọ fun un nibi iṣesi yii:

A) Irun

B) Rirọkirika Ka'bah

D) Fifi ọwọ kan Kuraani tabi gbigbe e

E) Wiwa ni mọsalasi

Ẹ) Kika Kuraani Alapọn-ọnle

Aluwala oni erùpẹ̀

Ti ẹni ti o fẹ́ ṣe aluwala tabi wẹ ba kagara lati ṣe ìyẹn tori aisi omi, tabi àìní ikapa lati lo omi tori àìsàn tabi nǹkan mìíràn, a ṣe aluwala oni erùpẹ̀ ni ofin fun un rọpo méjèèjì Bi a ṣe n ṣe tayammum: Dida aniyan aluwala oni erùpẹ̀ pẹlu ọkan rẹ, yio si fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan ṣoṣo, lẹyin naa yio fi nnkan ti o ṣẹku ninu oripa iyẹpẹ pa oju rẹ lẹyin naa ọwọ rẹ mejeeji

Ki ni maa ṣe ti mo ba ri omi lẹyin ti mo ti ṣe tayammum?

Ti Musulumi ba ri omi tabi ni ikapa lati lo omi, imọra rẹ ti bajẹ nìyẹn, aluwala si jẹ dandan fun un tabi iwẹ lẹyin igba yẹn

Ko si ibuyẹ ti omi ko fi nii kari gbogbo ara ki iwẹ to le ni alaafia ti o le gbe janaba kuro

Iwẹ ko nii jẹ dandan nigba ti atọ ba jade ni oju orun, yio si maa jẹ dandan nigba ti o ba jade ni oju aye

Ko tọ fun oni janaba lara lati jokoo si inu mọsalasi

O tọna

Àṣìṣe

Wọn ṣe aluwala oni erùpẹ̀ ni ofin fun Musulumi nigba :

A) Ikagara kuro nibi lilo omi

B) Nigba ti ko ba si omi

D) Gbogbo nnkan ti o ti ṣaaju

Ẹkọ ẹlẹẹkarun

Awọn idajọ kan ti a da ṣẹṣa fun obinrin Musulumi

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sa obinrin ni ẹsa pẹlu awọn iroyin kan ti wọn ṣe pe yio maa jẹ ki o yatọ si ọkunrin, gẹgẹ bi o ṣe ṣe awọn ijọsin kan ni dandan fun un yatọ si ọkunrin. Nínú ẹkọ yii, a maa mọ awọn idajọ kan ti o jẹ mọ́ obìnrin Musulumi nìkan.

Ipo obinrin ninu Isilaamu:

Ninu awọn àpẹrẹ awọn idajọ ti wọn so pọ mọ ṣíṣe apọn-ọnle obinrin ninu Isilaamu:

Isilaamu fun obinrin ni iwọ rẹ ninu ogun nibi ipin ti o ṣe deedee ti o jẹ ti apọnle, ti o n fi ọkùnrin ṣe deedee obinrin ni awọn aaye kan, ti ipin rẹ o si maa yatọ si i ni awọn aaye kan, ni ibamu si asunmọ rẹ ati awọn ojúṣe inawo rẹ.

O fi ọkùnrin dọ́gba pẹ̀lú obinrin nibi awọn alamọri ti o pọ ti o ṣe ọtọọtọ, ninu ìyẹn ni gbogbo awọn ibasepọ ti owo

O fun obinrin ni òmìnira yiyan ọkọ

O ṣẹ orúkọ rẹ ku fun un ati iyi ìṣe afiti rẹ si ara baba rẹ, ti afiti rẹ o nii maa yi pada lẹyin igbeyawo, bi ko ṣe pe afiti rẹ si ara baba rẹ ati mọlẹbi rẹ o maa ṣeku

O ṣe àmójútó rẹ ni dandan fun ọkùnrin ati ninawo le e lori laisi iregun, ti o ba wa ninu awọn ti ninawo rẹ fun jẹ dandan fun un, gẹgẹ bii iyawo ati iya ati ọmọbinrin

O kanpa mọ iyi ati ọla ikunlọwọ obinrin ti o lẹ ti o ṣe pe ko si ẹni kankan fun un, ko da ki o ma jẹ ọkan nínú awọn ẹbi rẹ, o si ṣeni ni ojukokoro sibi igbiyanju fun ikunlọwọ rẹ, o si ṣe ìyẹn ninu awọn eyi ti o ni ọla julọ ninu awọn iṣẹ lọdọ Ọlọhun

Kíkà ti afikun

Wo fidio yii, ti o n ṣe àfihàn ìfiwéra láàrin ipò obìnrin nínú Isilaamu ati awọn ẹsin mìíràn

Ṣe ẹda aworan barcode naa lati wo fidio naa

Irẹpọ obinrin pẹlu ọkùnrin:

Irẹpọ obinrin pẹlu ọkùnrin pin si ipin mẹta:

1. Ki o ṣe pe obinrin naa ni iyawo rẹ:

O jẹ ẹtọ fun awọn mejeeji nnkan ti ko ni ẹtọ fun awọn ti wọn yatọ si wọn bii wiwo ati igbadun ara ẹni, dajudaju Ọlọhun pe ọkọ ni aṣọ fun iyawo O si pe iyawo ni aṣọ fun ọkọ, gẹgẹ bii aworan kan ti o jọju ninu asopọ ti ẹmi ati ti imọlara ati ti ara laaarin awọn mejeeji

Ki o wa ninu awọn eleewọ rẹ:

Nnkan ti a gba lero pẹlu eleewọ ni gbogbo ẹni ti a ṣe fifẹ wọn ni eewọ fun ọkùnrin ni eewọ gbere gẹgẹ bii: Iya ati ọmọ iya lobinrin ati ọmọbinrin ọmọ iya lobinrin ati ọmọbinrin ọmọ iya lọkunrin ati ọmọ iya baba ati ọmọ iya iya ati iya iyawo. Àwọn wọnyi, o tọ fun wọn lati jade ni iwaju awọn eleewọ wọn pẹlu ẹṣọ ti o maa gbe igunpa rẹ mejeeji jade ati ọrun ati irun ati nnkan ti o jọ ìyẹn, laini kọja aala

Ki obinrin naa jẹ ajoji si i:

Obinrin ajoji ni gbogbo obinrin ti ko kii ṣe eleewọ rẹ, yala o jẹ ninu awọn mọlẹbi rẹ ni gẹgẹ bii ọmọbinrin ẹgbon tabi aburo baba rẹ lọkunrin, ati ọmọbinrin ẹgbon tabi aburo baba rẹ lobinrin, ati iyawo ọmọ iya rẹ lọkunrin ati awọn alasunmọ mọlẹbi, tabi o jẹ ẹni ti ko kii ṣe mọlẹbi rẹ ti ko si irẹpọ ti ẹbi kankan ti o so o pọ mọ ọn, dajudaju Isilaamu ti gbe awọn ofin kan kalẹ fun ibasepọ laaarin iran mejeeji gẹgẹ bii ijẹ dandan lilo hijab ati ki wọn ma jọ dá wà papọ̀.

Hijab obinrin Musulumi:

Ọlọhun ṣe hijab ni dandan lori obinrin yatọ si ọkùnrin; nitori nnkan ti o fi si i lara ninu awọn irinisi ẹwa ati awọn okùnfà ifani-loju-mọra, ninu nnkan ti o le ṣe e ni wahala fun ọkùnrin ju ki ọkùnrin jẹ wahala fun un lọ, ati pe aala hijab yii ni ki o bo gbogbo ara rẹ fun awọn ọkùnrin ti wọn jẹ ajoji si i, o ni anfaani lati wọ nnkan ti o ba fẹ ninu oríṣiríṣi ìrísí ati àwọ̀ aṣọ pẹlu ṣíṣe amojuto awọn alamọri mẹrin kan:

Akọkọ: Ki hijab naa jẹ nnkan ti yoo bo nnkan ti bibo rẹ jẹ dandan

Ikeji: Ki o jẹ aṣọ gbagẹrẹ ti o fẹ ti ko kii ṣe nnkan ti o fun ti o maa sọ bi awọn ẹya ara ṣe ri.

Ikẹta: Ki o ma jẹ eyi ti o n fi odi keji han ti o n fi awọn ẹya ara ti wọn wa ni abẹ rẹ han

Ikẹrin: Ki o ma jẹ ọ̀ṣọ́ fun ara rẹ

Awọn iran ẹjẹ ti wọn n jade lati ara obinrin:

Iran meji ninu awọn ẹjẹ ni wọn maa n jade lara obinrin:

1. Ẹjẹ nnkan oṣu: Oun ni ẹjẹ ti adamọ ti o maa n jade lati inu apo ibi obinrin ni gbogbo oṣu ni ọpọlọpọ igba, ti o si maa n tẹsiwaju fun awọn ọjọ kan, wọn si maa n pe e ni (Àṣà oṣooṣu)

2.Ẹjẹ ìbímọ: Oun ni ẹjẹ ti adamọ ti o n jade lati inu apo ibi obinrin lẹyin jijade ọmọ, ti o si maa n tẹsiwaju fun awọn ọjọ kan ti o le to ogoji ọjọ

Awọn idajọ ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ:

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe awọn idajọ kan ni ofin fun ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ati ẹni ti ẹjẹ ibi n jade ni ara rẹ, ninu wọn ni:

Bibọ irun fun awọn mejeeji, ti irun ko nii jẹ dandan fun awọn mejeeji ni asiko ẹjẹ nnkan oṣu ati ẹjẹ ìbímọ, ti dida pada irun ko nii maa jẹ dandan fun awọn mejeeji lẹyin pipari ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ.

Gbigbe awẹ ju silẹ, awẹ ko nii tọ́ fun awọn mejeeji ni asiko ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ, ṣugbọn dida awẹ awọn ọjọ ti wọn fi já awẹ ninu Ramadan padà maa jẹ dandan fun awọn mejeeji

Ṣíṣe ibalopọ ni eewọ, ko tọ fun ọkọ lati sunmọ iyawo rẹ ti o n ṣe nnkan oṣu tabi ti ẹjẹ ìbímọ n da ni ara rẹ titi ti yio fi wẹ lẹyin pipari ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ, biba a ṣere tọ́ fun ọkọ laini ba a lopọ ni oju ara

Wiwẹ lẹyin dida ẹjẹ, ti jijade ẹjẹ ba ti da lara ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu tabi ẹjẹ ìbímọ, iwẹ jẹ dandan fun un bi o ti ṣe ṣaaju

Kíkà ti afikun

Ki o tun le mọ̀ si nipa bi Isilaamu ṣe pọn obìnrin lé, ka iwe “OBÌNRIN NÍNÚ ISILAAMU”, eyi ti o wa kaakiri ni ibutaja “Usuul” pẹlu oriṣiriṣi awọn ede agbaye

Ṣe ẹ̀dá àwòrán barcode naa lati fi ẹ̀dà ìwé naa ránṣẹ́

Jíròrò

Sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àwọn ọgbọ́n ti o wa nibi bibọ apakan awọn alabọrun ti Sharia kuro fun obinrin

Awọn ibeere ti igbelewọn

O tọna

Àṣìṣe

Isilaamu ṣe ni dandan lori ọkùnrin amojuto obinrin ati nina owo le e lori laiṣe iregun

Wọn ko ṣe majẹmu nibi hijab pe ki o jẹ nnkan ti o maa ṣe gbagẹrẹ ti o fẹ

Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ba ti mọra, o jẹ dandan le e lori lati wẹ ṣiwaju ki o to ki irun

Ẹjẹ nnkan oṣu ni ẹjẹ kan ti o jẹ ti adamọ ti o maa n jade lati inu apo ibi obinrin lẹyin ibimọ

O jẹ dandan fun obinrin Musulumi lati pa gbogbo ara rẹ mọ kuro fun:

A) Awọn obinrin miiran

B) Awọn ọkunrin ajoji

D) Baba ọkọ

O jẹ dandan fun ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ati ìbímọ ti o ba ti mọra lati da awọn nnkan yii pada:

A) Irun

B) Awẹ

D) Gbogbo nnkan ti o ti ṣaaju

Ẹkọ ẹlẹẹkẹfa

Irun

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

A ka irun si eyi ti o tobi julọ ninu awọn ami ẹsin ti o ṣe pe kikọ ati ṣíṣe e rẹ jẹ dandan fun Musulumi, dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ wa bi a ṣe maa ṣe e pẹlu ọna ti o ṣe pe Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- yio maa yọnu si i fun wa, Ninu ẹkọ yii, a maa mọ awọn irun ọranyan, ati ipo wọn, ati awọn majẹmu wọn ati bi aa ṣe maa ki i pẹlu ọna ti o ni alaafia

Ki ni irun?

Irun: Ìjọsìn ojoojumọ ni, ti o ko akojọpọ kan ninu awọn ọrọ ati awọn iṣẹ ti Musulumi o maa fi sunmọ Oluwa rẹ sínú, ti o si maa ki i ni ẹẹmarun-un ni ọsan ati oru

Ati pe irun ni origun keji ninu awọn origun Isilaamu

Ipo irun:

Irun da yatọ pẹlu awọn akojọpọ awọn nnkan ẹsa, ninu wọn ni:

Oun ni origun keji ninu awọn origun ẹsin lẹyin ijẹrii mejeeji

Ijọsin ti o ṣe pe o jẹ dandan ki a ṣe e ni gbogbo ipo yòówù ki èèyàn wà, ni ipò alaafia ati aisan, ati ifọkanbalẹ ati ipaya

Ijọsin ti Musulumi fi maa n yatọ si alaigbagbọ.

Ki lo de ti a fi n ki irun?

A maa n kirun nitori pe irun jẹ ijọsin ti Ọlọhun ṣe e ni dandan fun awọn Musulumi

Ninu awọn ọgbọn irun ati awọn anfaani rẹ:

Asopọ kan ni o jẹ laaarin Musulumi ati Oluwa rẹ

O maa jẹ ki agbara gbigbero ati ìpinnu lágbára síi ni ọdọ Musulumi

O maa fun ẹmi ni ìsinmi nibi ifooro ayé

O maa tun awọn iwa ṣe, o si maa n gbe ẹni ti o ba n ki i jìnnà si awọn iwa buruku

Awọn majẹmu irun:

Wọn ṣe awọn majẹmu kan ni majẹmu fun kiki irun, awọn ni:

Imọra: O ko mimọ ara ati aaye kuro nibi awọn ẹgbin sínú, ati imọra kuro nibi ẹgbin pẹlu aluwala tabi iwẹ

Bibo ihoho: Ihoho: Ni nǹkan ti bibo rẹ jẹ dandan ninu ara ni iwaju awọn eniyan. Ati pe ihoho ọkùnrin eyi ti o ṣe pe bibo rẹ jẹ dandan nibi irun ni lati idodo titi de orunkun, ihoho obinrin eyi ti o ṣe pe bibo rẹ jẹ dandan nibi irun ni gbogbo ara rẹ afi oju ati ọwọ rẹ mejeeji

Dida oju kọ kiblah: Oun ni agbegbe Ka'bah abiyi ti o wa ni Mẹka alapọn-ọnle, o jẹ dandan fun ẹni ti o fẹ kirun lati dojukọ agbegbe rẹ nibi irun rẹ

Wiwọle asiko irun: Irun ko nii ni alaafia ṣiwaju wiwọlẹ asiko rẹ, lilọ ọ lara tayọ asiko rẹ ko tọ, eyi ti o daa julọ ni kiki rẹ ni akọkọ asiko rẹ

Awọn irun ọranyan marun-un:

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe ni dandan lori awọn ẹru Rẹ lati maa ki irun marun-un ni ọsan ati oru, awọn ni:

Irun asunba:

Akọkọ asiko rẹ: Yiyọ alufajari

Ipari asiko rẹ: Yiyọ oòrùn

Onka rakah rẹ: 2

Irun Zuhr:

Akọkọ asiko rẹ: Yiyẹ oòrùn (Oun ni yiyẹ rẹ si agbegbe iwọ oòrùn ni idaji ọsan)

Ipari asiko rẹ: Ṣíṣe deedee òjìji nǹkan pẹlu òró rẹ

Onka raka rẹ: 4

Irun Asr:

Akọkọ asiko rẹ: Ṣíṣe deedee òjìji nnkan pẹlu oro rẹ

Ipari asiko rẹ: Wiwọ oòrùn

Onka raka rẹ: 4

Irun Magrib:

Akọkọ asiko rẹ: Wiwọ oòrùn

Ipari asiko rẹ: Wíwọlé àwòǹpapa pupa

Onka raka rẹ: 3

Irun Ishai

Akọkọ asiko rẹ: Wíwọlé àwòǹpapa pupa.

Ipari asiko rẹ: Idaji oru

Onka raka rẹ: 4

Kíkà ti afikun

Wo fiimu yii fun bi a ṣe n ki irun ti o jáde lati Ile-iṣẹ “Usuul”.

Ṣe ẹda aworan barcode naa lati wo fidio naa

Bawo ni a ṣe n ki irun?

Ti Musulumi ba fẹ ki irun, o jẹ dandan fun un lati gbe awọn igbesẹ ti o n bọ yii:

1. Yio mu aniyan irun wa pẹlu ọkan rẹ

2. Yio duro ni ẹni ti yoo da oju kọ kiblah, yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si ẹgbẹ ejika rẹ mejeeji tabi eti rẹ mejeeji, yio si sọ pe: “Allahu Akbar”

3. Yio gbe ọwọ rẹ ọtun lori ọwọ rẹ osi. Lẹyin naa yio ka adura kan ninu awọn adura ṣiṣi irun, gẹgẹ bii: SubhaanaKa Allahumo wa bihamdiKa, wa tabaaraka ismuKa, wa tah'aala jadduKa, wa laa ilaaha goiruKa” Lẹyin naa yio sọ pe: A'uudhu billahi minaa -sh- Shaitoonir Rajeem, Bismillahir Rahmonir Raheem Lẹyin naa yoo ka Surah Al-Fatiha, lẹyin naa yio sọ pe: “Aamin” lẹyin ti o ba ka a tan, itumọ Aamin ni pe: Irẹ Ọlọhun, gba adua wa Lẹyin naa yio ka lẹyin Fatiha nnkan ti o ba rọrun fun un ninu nnkan ti o ha ninu Kuraani Alapọn-ọnle, ko da ki o ṣe aayah kan ṣoṣo

Yio gbe ọwọ rẹ mejeeji si ẹgbẹ ejika rẹ mejeeji tabi eti rẹ mejeeji, yio sọ pe: “Allahu Akbar”, yio waa tẹ ẹyin rẹ ni ẹni ti o rukuu, yoo wa gbe ọwọ rẹ mejeeji lori orunkun rẹ mejeeji, yio si ṣe ẹyin rẹ ati ori rẹ ni bákannáà, yio waa sọ ni rukuu rẹ pe: “Subhaana Robbiyal Azeem”.

Yio gbe ori rẹ dide lati pada si ìdúró pẹlu gbigbe ọwọ rẹ mejeeji si ẹgbẹ ejika rẹ mejeeji, ti o maa sọ pe: “ Samiha llahu liman hamidaHu”. Lẹyin naa yio sọ ni ìdúró pe: “Robanna wa laKal hamdu”.

Yio gbe ori rẹ dide lati pada si ìdúró pẹlu gbigbe ọwọ rẹ mejeeji si ẹgbẹ ejika rẹ mejeeji, ti o maa sọ pe: “ Samiha llahu liman hamidaHu”. Lẹyin naa yio sọ ni ìdúró pe: “Robanna wa laKal hamdu”.

7.Yio gbe ori rẹ sókè ni ẹni ti o maa sọ pe: “Allahu Akbar”, yóò waa jokoo lori ẹsẹ rẹ osi, pẹlu ki ẹsẹ rẹ ọtun wa ni inaro, yio gbe ọwọ rẹ mejeeji lori itan rẹ mejeeji, yio maa sọ lori ijokoo rẹ pe: “Robbi igfir lii”.

8. Yio fi ori kanlẹ ni ẹẹkan si gẹgẹ bii iforikanlẹ akọkọ, yio maa sọ nigba ti o ba n tẹ̀ lọ fun iforikanlẹ pe: “Allahu Akbar”. Yio ṣe nnkan ti o ṣe ni iforikanlẹ rẹ akọkọ ni iforikanlẹ rẹ ikeji

9.Yio gbe ori rẹ sókè, yio si dide fun raka keji, ni ẹni tí o maa sọ pe: “Allahu Akbar”. Yio ki raka keji gẹgẹ bi o ṣe ki raka akọkọ gẹ́lẹ́.

10. Lẹyin iforikanlẹ keji nibi raka keji, yio jokoo gẹgẹ bii ijokoo rẹ laaarin iforikanlẹ mejeeji, yio sọ pe: <> A n pe e ni “ATAAYA ÀKỌ́KỌ́” Lẹyin naa yio sọ lẹyin rẹ pe: Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, kamoo sollaiTa 'alaa Ibrahim wa 'alaa aali Ibrahim innaKa Hameedun Majeedun, wa baarik alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, kamoo baarakTa alaa Ibrahim wa 'alaa aali Ibrahim innaKa Hameedun Majeedun A n pe e ni solatul Ibrahiimiyyah

11. Yio wo ẹgbẹ ọtun rẹ yio sọ pe: “As salaamu alaykum wa rahmotullah”, lẹyin naa yio wo ẹgbẹ osi yio si sọ iru ìyẹn, pẹlu ìyẹn irun rẹ maa pari

Iroyin yii nigba ti irun rẹ ba jẹ raka meji ni; gẹgẹ bii irun Alufajari ati Jimọh, ṣugbọn ti o ba jẹ raka mẹta; gẹgẹ bii Magrib, tabi raka mẹrin; gẹgẹ bii Zuhr ati Asr ati 'Ishai, dajudaju lẹyin pipari ataya akọkọ, yio pe nnkan ti o ba ṣẹku ninu awọn raka gẹgẹ bii raka akọkọ, ṣùgbọ́n ko nii ka nnkan kan lẹyin Fatiha, lẹyin naa yio jokoo gẹgẹ bi o ṣe jokoo lẹyin raka keji, yio si ka ataya akọkọ, lẹyin naa yio ka solatul Ibraahiimiyyah, lẹyin naa yio salamọ

Irun Jimọ:

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe ni dandan lori awọn Musulumi kiki irun kan ti a sa ni ẹsa fun ọjọ jimọh ti a n pe ni (Irun Jimọh), ti o ni iroyin kan pato ati awọn majẹmu kan pato, ti o n jẹ ijirọ fun irun Zuhr fun ọjọ yẹn

Awọn Musulumi o maa kojọ nitori rẹ si mọsalasi, ti olubanisọrọ mọsalasi naa yio ṣe khutubah meji, lẹyin naa yio ki raka meji fun wọn, ti yio gbe ohun soke pẹlu kika Kuraani nibi mejeeji

Wọn ṣe iwẹ ni ofin fun wiwa si jimọh, ati yíyára de ibẹ̀ láti ki i, aiki i ko tọ́ afi pẹlu idi, ẹni ti ko ba ki i dajudaju yio ki Zuhr ni raka mẹrin, ko si nii gbe ohun soke pẹlu kika Kuraani

Irun jimọh ko jẹ dandan fun obinrin tabi arinrin-ajo

Jíròrò

Ṣe ìwádìí pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ nipa awọn ipenija kan ti Musulumi n dojú kọ ti ko jẹ ki o le kirun ni àsìkò rẹ, ati bi a ṣe le kọjá ipenija naa.

{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀} [Surah Al-Jumu`ah: 9]

O tọna

Àṣìṣe

O tọ fun Musulumi lati ki irun ọranyan koda ṣiwaju ki asiko rẹ to wọle

Asiko irun alufajari o maa tan nigba yiyọ oòrùn

Darukọ ijọsin meji kan ninu awọn ijọsin ti o wa fun ọjọ jimọh nikan

Ki ni oripa awọn irun maraarun lori igbesi aye Musulumi ti ojoojumọ?

Laaarin abẹwo rẹ si ikanni yii: islamicfiqh.net/en, sọrọ nipa idajọ ẹni ti o n gbe irun ju silẹ ninu Isilaamu

Ihoho ti o ṣe pe o jẹ dandan fun ọkùnrin lati bo o nibi irun:

A) Gbogbo ara yatọ si oju ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji

B) Lati idodo titi de orunkun

D) Lati ejika titi de orunkun

Agbegbe ti o ṣe pe o jẹ dandan fun olukirun lati doju kọ ni:

A) Agbegbe àríwá

B) Agbegbe ibuwọ oòrùn

Agbegbe Ka'bah

Ẹni ti o n ki irun yio sọ nibi iforikanlẹ rẹ pe:

A) Subhaana Robbiyal 'Azeem

B) Subhaana Robbiyal A'alaa

D) Robbi igfir liy

Ẹkọ ẹlẹẹkeje

Sàká

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Lati igba lailai ati igba ti ẹda ti n bẹ lori ilẹ yii ni wọn ti n ṣẹmi pẹlu ipò ti o ṣe ọtọọtọ; o n bẹ ninu wọn olowo ti o ṣe pe o ni ọpọlọpọ ninu awọn dukia, o si n bẹ ninu wọn olosi ti o ṣe pe ko ri oúnjẹ jẹ, oun jẹ ìlànà kan ninu awọn ìlànà Ọlọhun ninu aye yii, Isilaamu si ti ṣe ìpín kan ni ọranyan nínú dúkìá àwọn olówó ti wọn maa fun awọn tálákà lati le kun wọn lọwọ ati lati le ṣe oripa osi ni fifuyẹ fun wọn. O tun ṣe Musulumi ni ojúkòkòrò láti maa na ninu awọn dukia rẹ nǹkan ti o ju ohun tí ó jẹ́ dandan fún un lọ, o ṣe ẹsan fun ìyẹn ni awọn ẹsan kan ti wọn tobi ti ọwọ Musulumi maa tẹ wọn ni igbesi aye rẹ ati lẹyin iku rẹ, gẹgẹ bi o ṣe ṣeni ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe dáadáa si awọn talaka ni gbogbo igba ati gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀. O ṣeni ni ojúkòkòrò lórí fifun awọn ti ebi n pa ni oúnjẹ, ati fífún awọn arin-hoho ni aṣọ wọ̀, gbogbo èyí nitori ki awujọ le so papọ ni ti wọn si maa wa gẹgẹ bi Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe fẹ, ninu ẹkọ yii a maa mọ idajọ Zakah, ati bi a ṣe maa yọ ọ, ati awọn dukia ti wọn ṣe pe o jẹ dandan nibẹ ẹ

Ki ni sàká?

Sàká: Yíyọ ipin kan ti o ni odiwọn jade ninu dukia awọn olowo ti wọn jẹ Musulumi ti a maa fun awọn olosi wọn. Oun si ni origun kẹta ninu awọn origun ẹsin

Kíkà ti afikun

Wo fídíò ti o n sọ̀rọ̀ nipa zakat ati oripa rẹ ni àwùjọ yii, ilé-iṣẹ́ “Usuul” ni wọn gbe e jáde.

Ṣe ẹda aworan barcode naa lati wo fidio naa

Ki ni o de ti a fi n yọ Zakah?

A n yọ zakat lati mu aṣẹ Ọlọhun ṣẹ Ọba ti O ṣe pe O ṣe Zakat ni ọranyan le wa lori

Ninu awọn ọgbọn yíyọ Zakah ati awọn anfaani rẹ ni:

Akọkọ: Fifọ ẹmi mọ kuro nibi asopọ mọ dukia ati ṣíṣe ahun pẹlu rẹ

Ikeji: Ṣíṣe alekun owo, dajudaju ko lee dinku bi ko ṣe pe yio ṣe alekun rẹ yio si fi alubarika si i.

Ikẹta: Ikunlọwọ awọn ti wọn ni bukaata ninu awọn olosi ati awọn mẹkunnu ati awọn ti wọn yatọ si wọn

Ki ni awọn dukia ti wọn ṣe pe Zakah yiyọ jẹ dandan nibẹ?

Wura ati Fadaka

Owo

Awọn irugbin ati awọn eso

Awọn nǹkan ọ̀sìn

Awọn nnkan ti a fi n ṣe òwò

Awọn nnkan ti a fi n ṣe òwò: Gbogbo nnkan ti a pese kalẹ pẹlu erongba ṣíṣe òwò; bii ile tabi ṣọọbu, tabi ọkọ tabi ẹranko, tabi nnkan ti o yatọ si ìyẹn

Awọn ẹran-ọ̀sìn ni: Rakunmi, ati màálù ati àgùntàn.

Ba wo ni a ṣe n yọ zakat owo?

Musulumi o maa yọ Zakah ninu awọn dukia owo rẹ ti wọn ṣe pe Zakah yíyọ jẹ dandan nibẹ ni ẹẹkan ni gbogbo ọdun hijira, odiwọn rẹ ni 2.5%, wọn maa fun awọn talaka ati awọn ti wọn ni bukaata

Idanwo

Fi gbogbo agbekalẹ ọrọ ninu awọn agbekalẹ ọrọ ti wọn n bọ yii si aaye ti o ba mu ni ibamu si asopọ wọn pẹlu rẹ.

Wura ati Fadaka

Ago ọwọ

Iye owo kan

Ohun ọ̀ṣọ́ ilé

Adiẹ

Awọn ẹran

Oko èso ápù

O jẹ dandan fun Musulumi lati yọ Zakah nibẹ:

Ko si Zakah nibẹ

Jíròrò

Ki ni awọn oripa ti o maa jẹ yọ latara yíyọ Zakah gbogbo awọn olowo ninu dukia wọn?

Wo fidio yii “Why do Muslims pay zakat”, lẹyin naa ki o sọrọ nipa awọn itumọ ti o ga ti o wa fun jijẹ dandan yíyọ Zakah

O jẹ dandan fun Musulumi lati yọ Zakah awọn dukia ti owo rẹ:

A) Ni ẹẹkan ni ìgbésí ayé

B) Ni ẹẹkan ni ọdun

D) Ni ẹẹkan ni oṣu

Odiwọn Zakah awọn dukia ti owo

A) 25%

B) 10%

D) 2.5%

Ẹkọ ẹlẹẹkẹjọ

Awẹ

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

A ka awẹ sinu awọn ijọsin ti wọn ṣe pe Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe wọn ni ọranyan lori gbogbo awọn ijọ, ninu Isilaamu, Musulumi maa pe ọranyan yii ni ti itẹle ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ninu ẹkọ yii a maa mọ nnkan ti a gba lero pẹlu awẹ, ati awọn nnkan ti wọn n ba a jẹ, ati apakan awọn ti o ṣe pataki julọ ninu awọn idajọ rẹ

Ki ni awẹ?

Àwẹ̀: Ijọsin kan ni ti Musulumi ko nii jẹun ninu ẹ, ko si nii mu, ko si nii ni ìbálòpọ̀ tọkọtaya, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun fi maa wọ̀.

Awẹ oṣu Ramadan ni origun kẹrin ninu awọn origun Isilaamu

Ki ni o de ti a fi n gba awẹ?

Musulumi maa n gba awẹ ni ti itẹle ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati idahun si aṣẹ Rẹ

Ninu awọn ọgbọn awẹ ati awọn anfaani rẹ:

Mimu ibẹru ṣẹ pẹlu pipọ ni ijọsin ati didin awọn ẹṣẹ kù.

Lati mọ irora ebi lara, eyi ti o ṣe pe o maa n sẹlẹ si awọn olosi ati awọn ti wọn ni bukaata

Lati la ẹ̀mí ara rẹ kuro nibi ifẹkufẹẹ rẹ, ati láti da ara rẹ ni ẹkọ lori ṣíṣe àkóso rẹ.

Ọlọhun ṣe ijọsin awẹ gbigba ni ọranyan lori awọn Musulumi ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu ìjọ ti wọn ṣaaju, gẹgẹ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ pé: {Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu)} [Surah Al-Baqarah: 183]

Awọn nnkan ti wọn n ba awẹ jẹ:

O jẹ dandan fun ẹni ti o n gba awẹ lati ko ara ro kuro nibi apapọ awọn nǹkan kan, ti o ba ti ṣe wọn awẹ rẹ maa bajẹ, awọn ni:

Jíjẹ ati mimu, ti gbigba abẹrẹ ni ipasẹ iṣan naa wọ inu idajọ mejeeji

Ki èèyàn mọọmọ mu àtọ̀ jade, boya pẹlu ibalopọ ni tabi laiṣe pẹlu ibalopọ, ati pe ibalopọ ni ọsan Ramadan jẹ ẹṣẹ nla

Mimọọmọ mu eebi jade

Ṣugbon obinrin, awẹ rẹ o maa bajẹ bákannáà nigba:

Jijade ẹjẹ nnkan oṣu tabi ẹjẹ ìbímọ

Oṣu Ramadan alalubarika:

Oun ni oṣu kẹsan-an ninu ọdun hijra, oun si ni oṣu alalubarika, Ọlọhun sọ Kuraani kalẹ fun Ojiṣẹ Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe awẹ ni ọsan rẹ, ati irun ni alẹ rẹ ni okunfa aforijin awọn ẹṣẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- da a yatọ pẹlu oru kan ti o ni ọla ju ẹgbẹrun oru lọ, wọn n pe e ni (Oru Abiyi), ẹni ti o ba ta a ji pẹlu iranti ati irun wọn maa fi nnkan ti o ti ṣiwaju ninu ẹṣẹ rẹ jin in.

Awọn Musulumi maa n ki irun aasamu ninu oṣu Ramadan, o wa ninu sunnah ti o so pọ mọ ọn, ti wọn si maa n ki i lẹyin irun 'Ishai

Awọn wo ni wọn yonda fun lati ma gba awẹ ninu Ramadan?

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- yonda fun awọn iran kan nínú àwọn èèyàn lati ma gba awẹ ni ọsan Ramadan, àwọn ni:

1. Alaisan ti o ṣe pe yio ri inira lati ara awẹ

2. Agbalagba ti ko le gba awẹ.

3. Arinrin-ajo ni asiko irin-ajo rẹ

4. Ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ati ẹni ti n ri ẹ̀jẹ̀ ìbímọ.

5.Oloyun ati ẹni ti o n fun ọmọ ni ọyan ti awọn mejeeji ba n bẹru lori ẹmi ara wọn tabi lori ẹmi ọmọ awọn mejeeji

Awọn akiyesi kan ti wọn so pọ mọ awẹ:

Ẹni ti o ba ja awẹ ninu Ramadan fun idi kan, dajudaju yio gba awẹ ọjọ miiran rọ́pò rẹ lẹ́yìn Ramadan.

Ti alaisan ba ja awẹ pẹlu okunfa aisan ti wọn lero pe ko le san, dajudaju gbigba awẹ Ramadan maa bọ fun un, yio si maa bọ alaini fun gbogbo ọjọ́ ti ko ba ti gba awẹ.

Ti Musulumi ti o jẹ agbalagba ko ba le gba awẹ, dajudaju gbigba awẹ Ramadan maa bọ fun un, yio si maa bọ alaini fun gbogbo ojo ti ko ba ti gba awẹ.

Awọn Musulumi o maa jẹ oúnjẹ ìṣínu pẹlu pípe irun Magrib, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn Musulumi ṣì máa ṣe ojúkòkòrò láti ṣínu pẹ̀lú àwọn ọmọ ìyá wọn.

Laaarin wiwo ti o wo fidio yii: Why do Muslims fast Ramadan? Sọrọ nipa awọn oripa ti Musulumi maa ri kojọ ninu awẹ

Ọlọhun yonda jija aawẹ fun awọn iran kan ninu awọn eniyan, darukọ apakan ninu wọn ki o si sọrọ nipa ọgbọn ti o wa nibẹ.

O jẹ dandan fun Musulumi ti o ba n gba awẹ lọ́wọ́ lati ko ara ro kuro nibi:

A) Jíjẹ ati mimu

B) Ibalopọ

D) Gbogbo nnkan ti o ti ṣaaju

Onka awọn nnkan ti wọn n ba awẹ jẹ:

A) 6

B) 5

D) 4

Ẹkọ ẹlẹẹkẹsan

Hajj

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Hajj jẹ ọkan ninu awọn origun Isilaamu, o wa ninu awọn eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ ti wọn ṣe pe Musulumi maa n fi sunmọ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, dajudaju ọla ti o n bẹ fun un wa ninu awọn hadisi pupọ lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu ẹkọ yii a maa mọ diẹ nipa ami ti o tobi yii

Ki ni hajj?

Hajj: Ijọsin kan ni ti Musulumi ti o ni ikapa yio lọ si Mẹka Alapọn-ọnle nitori rẹ lati ṣe awọn ijọsin kan pato ninu oṣu Dhul-Hijjah, oun ni oṣu ikẹyin ninu ọdun hijra

Hajj ni origun karun-un ninu awọn origun Isilaamu

Ọdun ti hijra: Oun ni itọka kan si hijra ti Anọbi ti o ni alubarika lati Mẹka Alapọn-ọnle lọ si Madina. Khalifa Umar ọmọ Khottob- Ki Ọlọhun yọnu si i- ṣe ẹsa hijra Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati jẹ ibẹrẹ fun kika déètì ti Isilaamu ti hijra.. Oṣu mejila ni o n bẹ fun ọdun ti hijra, bẹrẹ lati oṣu (Muharram) ti o si pari pẹlu oṣu (Dhul-Hijjah), awọn Musulumi fara mọ kíkọ déètì fun awọn ìṣẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú ọdún hijra.

Nitori ki ni a ṣe n ṣe hajj?

Musulumi n ṣe hajj lọ si Mẹka Alapọn-ọnle lati jẹ ipe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu ṣíṣe hajj lọ si ile ọwọ

Ninu awọn ọgbọn hajj ati awọn anfaani rẹ:

Ikọṣe awọn Anọbi Alapọn-ọnle ti wọn ṣe hajj lọ si ile ọwọ

Kiko airoju pẹlu ijọsin, alalaaji maa lo àwọn ọjọ́ kan lati wa aaye fun ìjọsìn, o maa kuro nibi ìjọsìn kan bọ si òmíràn.

Ipade pọ pẹlu awọn Musulumi ti wọn kojọ pọ si awọn aye ti o mọ, ati dida wọn mọ, ati mimọ afárá asopọ mọ wọn

Jíròrò

Fi ọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn ti ṣe ọranyan hajj, ki o si mọ lati ọdọ wọn awọn ìmọ̀lára wọn nigba ti wọn ṣe e

Ta ni hajj jẹ dandan fun?

Hajj jẹ dandan ni ẹẹkan ninu ọjọ ori lori ẹni ti o ba ni ikapa rẹ ninu awọn Musulumi lọkunrin ati lobinrin, gbogbo ẹni ti o ba ni ikapa lori hajj ni ti ara ati ati owo dajudaju hajj jẹ dandan fun wọn

Awọn akiyesi kan ti wọn so pọ mọ hajj

Ṣíṣe hajj o le rọrun fun Musulumi afi ni aaye kan pato oun ni (Mẹka Alapọn-ọnle) ati ni asiko kan pato ninu ọdun

Hajj ko ọpọlọpọ ninu awọn ijọsin ti wọn ṣe pe kikọ wọn tọ fun Musulumi ṣiwaju lílọ rẹ fun ṣíṣe hajj

Awọn kan ninu àwọn Musulumi ni wọn maa n ṣe hajj ni gbogbo ọdun lati awọn ilu ọtọọtọ, ti wọn maa wọ aṣọ kan náà, ti ko si nii si iyat laaarin olowo ati olosi ninu wọn

Laaarin wiwo ti o wo fidio yii: (Why Do Muslims Perform Pilgrimage (Hajj)?), sọrọ nipa awọn ojupanna ipanupọ ijọsin hajj ati adamọ ti ọmọniyan

Awọn Musulumi maa ṣe ọranyan hajj ni:

A) Oṣu Ramadan

B) Oṣu Dhul-Hijjah

D) Oṣù December

Hajj jẹ dandan fun Musulumi:

A) Ni ẹẹkan ni ìgbésí ayé

B) Ẹẹmeji ni ọjọ ori

D) Gbogbo igba ti o ba ni ikapa lati ṣe hajj

Igbelewọn ti ara ẹni

1. Njẹ o gbọ itumọ ijọsin ye?

2. Njẹ o le dárúkọ awọn majẹmu ijọsin?

3. Ǹjẹ́ o le dárúkọ awọn iran ijọsin?

4. Njẹ o gbọ itumọ imọra ye?

5. Njẹ o mọ awọn iran imọra?

6. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye bi a ṣe n ṣe aluwala?

7. Njẹ o mọ awọn nnkan ti wọn n ba aluwala jẹ?

8. Njẹ o mọ awọn idajọ pipa ibọsẹ mejeeji?

9. Njẹ o mọ bi a ṣe n wẹ?

10. Njẹ o mọ awọn nnkan ti wọn maa n sọ iwẹ di dandan?

11. Njẹ o mọ nnkan ti ṣíṣe rẹ jẹ eewọ fun oni janaba lara?

12. Njẹ o mọ awọn iran awọn ẹjẹ ti wọn n jade lati ara obinrin?

13. Njẹ o mọ awọn idajọ awọn ẹjẹ ti wọn n jade lati ara obìnrin ti o ṣe koko?

14. Njẹ o gbọ itumọ irun ye?

15. Njẹ o gbọ idi ti a fi n ki irun ye?

16. Njẹ o mọ awọn majẹmu irun?

17. Njẹ o mọ awọn irun ọranyan maraarun?

18. Njẹ o mọ bi a ṣe n ki irun?

19. Njẹ o mọ awọn idajọ irun jimọh?

20. Njẹ o ni ikapa agbọye itumọ Zakah?

21. Njẹ o gbọ idi ti a fi n yọ Zakah ye?

22. Njẹ o ni ikapa mimọ awọn dukia ti o ṣe pe Zakah yíyọ jẹ dandan nibẹ?

23. Njẹ o ni ikapa mimọ awọn majẹmu Zakah yíyọ?

24. Njẹ o ni ikapa mimọ awọn iran awọn ti wọn ni ẹtọ si Zakah?

25. Njẹ o gbọ itumọ awẹ yẹ?

26. Njẹ o ni ikapa agbọye idi ti a fi n gba awẹ?

27. Njẹ o ni ikapa mimọ awẹ ọranyan?

28. Njẹ o ni ikapa mimọ awọn nnkan ti wọn n ba awẹ jẹ?

29. Njẹ o ni ikapa mimọ ẹni ti wọn ṣe jija awẹ ninu Ramadan ni ẹtọ fun?

30. Njẹ o gbọ itumọ hajj ye?

31. Njẹ o gbọ idi ti a fi n ṣe hajj yẹ?

32. Njẹ o mọ ẹni ti hajj jẹ dandan fún?

33. Njẹ o ni ikapa lati ṣe aluwala ni aluwala kan ti o ni alaafia?

34. Njẹ o ni ikapa lati wẹ ni iwẹ kan ti o ni alaafia?

35. Njẹ o ni ikapa lati ki irun ni kiki kan ti o ni alaafia?

36. Njẹ o n ni ìmọ̀lára irọrun ẹsin Isilaamu ati rírọ̀ rẹ?

Abala kẹrin

Awọn idajọ ti Isilaamu

Awọn ẹkọ abala naa:

Ẹkọ Alakọkọ

Aṣọ wiwọ

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Aṣọ ti eniyan maa n wọ jẹ idẹra kan ninu awọn idẹra Ọlọhun lori ẹ, gẹgẹ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ pe: "{Ọmọ (Ànábì) Ādam, dájúdájú A ti sọ aṣọ kalẹ̀ fun yín, tí ó máa bo ìhòhò yín àti ohun àmúṣọrọ̀. Aṣọ ìbẹ̀rù Allāhu, ìyẹn l’ó sì lóore jùlọ. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí} Al A'raaf 26 Ninu ẹkọ yii, a maa mọ apakan ninu awọn idajọ ti wọn so pọ̀ mọ aṣọ.

Ìpìlẹ̀ nibi aṣọ

Ipilẹ nibi aṣọ wiwọ jẹ ẹtọ, nǹkan kan ninu rẹ ko nii jẹ eewọ afi nnkan ti ṣíṣe ni eewọ rẹ ba wa ninu Kuraani Alapọn-ọnle, tabi inu Sunnah ti Anọbi

Ipilẹ nibi ibara-ẹni-lopọ ti aṣọ wiwọ wa ninu rẹ ni ẹtọ, ko si ṣíṣe ni eewọ afi pẹlu ẹri, gbogbo awọn aṣọ ti a ṣe ni eewọ ti a dárúkọ nibi ni ṣíṣe ni eewọ rẹ ti wa lati inu Kuraani Alapọn-ọnle tabi Sunnah.

Jíròrò

Ki ni awọn bukaata ti a fẹ muṣẹ lati ara aṣọ wiwọ?

Àwọn aṣọ ti wọn ṣe ni eewọ.

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe awọn iran kan ni eewọ ninu awọn aṣọ, ninu wọn ni:

Nnkan ti o maa n tu ihoho si ita ti ko nii bo o

Nnkan ti jíjọra pẹ̀lú ìran mìíràn ba n bẹ nibẹ; gẹgẹ bii ki awọn ọkunrin wọ aṣọ awọn obinrin, tabi ki awọn obinrin wọ aṣọ awọn ọkunrin

Nnkan ti o maa n múni ni ìmọ̀lára igberaga ati motomoto

Nnkan ti ina apa n bẹ nibẹ

Wọn ṣe ni eewọ fun awọn ọkunrin wiwọ aṣọ ariiri, ati ṣíṣe ẹṣọ pẹlu wura ati fadaka

Wọn ṣe wiwọ nnkan ti afijọ pẹlu awọn aṣọ ti o wa fun awọn alaigbagbọ nikan n bẹ nibẹ ni eewọ, gẹgẹ bii aṣọ awọn pasitọ ati awọn àlùfáà ni apẹẹrẹ

Awọn aala ihoho ọkùnrin bẹrẹ lati idodo titi de orunkun, ṣugbọn obinrin ihoho ni ni iwaju ọkunrin ajoji, ṣugbọn awọn eleewọ rẹ gẹgẹ bii baba ati ọmọ iya ni ọkùnrin, yio maa fi han fun un nnkan ti o n fi han ni iwaju awọn obinrin, bíi oju ati irun ati ọrun ati apa mejeeji ati ojugun ẹsẹ mejeeji

kópa pẹ̀lú awọn akẹgbẹ rẹ nibi mimọ apakan ninu awọn okunfa ṣíṣe ni eewọ awọn iran kan ninu awọn aṣọ.

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ki ọkùnrin maa ṣe bii obìnrin ati obìnrin máa ṣe bii ọkùnrin, kikọ yii ko iran aṣọ wiwọ sinu ati ọ̀nà ti a n gba sọ̀rọ̀, wọn si ka ifarawe yii kun ara àwọn ẹṣẹ ńlá ti o maa sọ ìyà Ọlọhun di dandan fun ẹni tí ko ba tuuba kuro nibẹ. Isilaamu fẹ ki adamọ ọkùnrin ati irisi rẹ jẹ nnkan ti o maa yatọ si ti adamọ obinrin, gẹgẹ bẹẹ naa ni o ṣe fẹ fun obinrin; ìyẹn ni ẹri adamọ ti o ni alaafia ati làákàyè ti o ni alaafia.

Idanwo

Sọ awọn aṣọ ti a ṣe ni eewọ fun ọkùnrin nikan ati eyi ti ṣíṣe ni eewọ wọn ko ọkùnrin ati obinrin sinu:

Nnkan ti o maa n tu ihoho si ita ti ko nii bo o

Nnkan ti jijọra n bẹ nibẹ laaarin iran mejeeji

Nnkan ti ina apa n bẹ nibẹ

Nnkan ti o maa n múni ni ìmọ̀lára igberaga ati motomoto

Wiwọ ariiri ati wura

Afijọ pẹlu aṣọ awọn alaigbagbọ

Jíròrò

Njẹ o rọrùn ki irú aṣọ tabi àṣà ati isẹṣe tabi ètò jẹ nnkan ti a maa ṣẹri si lati mọ aṣọ ti o daa fun ọkùnrin tabi obinrin?

Ronu nipa awọn aṣọ ti a ṣe ni eewọ, lẹyin naa ki o wa ronu si awọn ọgbọn ti o fa ṣíṣe wọn ni eewọ wa

Mu idahun ti o tọna: Wíwọ wura jẹ eewọ fun:

A) Àwọn ọkùnrin

B) Àwọn obìnrin

D) Awon ọmọ kéékèèké

O jẹ eewọ fun awọn ọkunrin:

A) Wiwọ irun ẹran

B) Wiwọ alaari

D) Gbogbo nnkan ti o ti ṣaaju

Ẹkọ ẹlẹẹkeji :

Oúnjẹ ati nǹkan mímu:

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Musulumi maa ri oúnjẹ ati nǹkan mímu si pe àwọn mejeeji wa ninu awọn idẹra Ọlọhun ti o sọ ọpẹ ti dandan, ninu ọpẹ mejeeji ni níní agbára pẹlu wọn lori ṣíṣe ijọsin. Nínú ẹkọ yii, a maa mọ akojọpọ awọn idajọ ati awọn ẹkọ ti wọn so pọ̀ mọ oúnjẹ ati nǹkan mimu, gẹgẹ bi a ṣe maa da awọn oúnjẹ ti a ṣe ni eewọ mọ ti jijinna si wọn jẹ dandan fun Musulumi

Ìpìlẹ̀ nibi oúnjẹ ati nǹkan mimu ni

Ipilẹ nibi awọn oúnjẹ ati awọn nǹkan mimu ni ẹtọ, nǹkan kan ko nii jẹ eewọ nínú ẹ afi ohun ti ṣíṣe ni eewọ rẹ ba wa ninu Kuraani Alapọn-ọnle, tabi Sunnah ti Anọbi, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: "{Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jẹ nínú ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ (t’ó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti n̄ǹkan) dáadáa } (Al-Baqarah: 168.

Oúnjẹ ati nǹkan mimu ti o jẹ eewọ

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe awọn iran kan ni eewọ ninu awọn oúnjẹ ati nǹkan mimu, ninu wọn ni:

Ọti, o maa n mu laakaye lọ, ati pe ṣiṣọ laakaye jẹ erongba kan ninu awọn erongba ofin ti Isilaamu

Awọn egbogi oloro, wọn maa n ko iparun ba laakaye ati ara

Nnkan ti o ba ku ninu awọn ẹranko láì dú u, tabi wọn ko da orukọ Ọlọhun si i nigba ti wọn du u.

Ẹran ẹlẹdẹ, dajudaju o jẹ ẹgbin ti jíjẹ rẹ ko ni ẹtọ.

Awọn ẹranko abija; gẹgẹ bii awọn kìnìún ati awọn amọtẹkun ati awọn àṣá ati awọn ẹyẹ igún.

Nnkan ti wọn du lati sunmọ àwọn nnkan ti wọn jọsin fun awọn ti ko tọ; gẹgẹ bii awọn òrìṣà.

Makọọsidu Sharee'ah: Imọ kan ni ninu awọn imọ ti Isilaamu, ti a maa n da idajọ sharia mọ ninu rẹ, ati awọn aṣiri sharia gẹgẹ bii: Nitori ki ni Ọlọhun ṣe ṣe awọn idajọ yìí ni òfin? Nitori ki ni ni idajọ yii fi n bẹ?

Ki ni àwọn májẹ̀mú didu nǹkan ti o ba sharia mu?

Didu nǹkan ti o ba sharia mu ni didu tabi gigun ti awọn majẹmu ti o n bọ yii ba pe si i lara:

Ki ẹni ti o fẹ dunbu jẹ Musulumi tabi Júù tabi Nasara ti o le ṣe ìyàtọ̀ ti yoo si gbèrò didu.

2. Kí irin-iṣẹ́ naa jẹ nnkan ti o daa fun didunbu ati nnkan ti o le mu ẹjẹ san ti o maa ge nnkan pẹlu mímú rẹ gẹgẹ bii ọbẹ, wọn ṣe lilo nnkan ti yio pa a pẹlu wiwuwo rẹ ati gbigba orí ẹranko, tabi sisun un nina gẹgẹ bii fífi ina mọnamọna gbe nnkan.

3. Kí o dá orúkọ Ọlọhun, yio sọ pe: (Bismillah) nigba ti o ba ti fẹ gbe ọwọ rẹ lati du u.

4. Gígé nnkan ti gige rẹ jẹ dandan nibi didunbu, oun naa ni: Ihò ọ̀fun, ati ọ̀nà ọ̀fun, ati al-wadajaan, awọn naa ni iṣan mejeeji ti wọn tobi nibi ọrun, tabi gige mẹta ninu mẹrẹẹrin yii

Ki ni idajọ jíjẹ awọn ẹranko inu odo?

Awọn ẹranko inu odo ti wọn ko ki n ṣẹmi afi ninu omi, jíjẹ oku wọn ni ẹtọ, gẹgẹ bii awọn ẹja tabi edé ati nnkan ti o yatọ si wọn, yala o n ṣẹmi ninu awọn okun ni tabi awọn akeremọdo tabi awọn odo kekere

Dídọdẹ awọn ẹranko inu odo ni ẹtọ yatọ si abija ninu wọn, jíjẹ wọn naa si ni ẹtọ, pẹlu majẹmu dida orúkọ Ọlọhun si i nigba dídọdẹ wọn, ati didunbu wọn ti o ba ri wọn ni aye

Awọn idajọ awọn nǹkan ti a n dú ni awọn ile oúnjẹ ati awọn ile-itaja:

"1. Nnkan ti ẹni ti o yatọ si Musulumi ati Ahlul-Kitaab (Júù tabi Nasara); gẹgẹ bii awọn ẹlẹsin Búdà ati awọn Hindu, ati awọn ti wọn ni adisọkan pe ko si ẹsin, eyi jẹ eewọ, o tun wọ inu nǹkan ti a sọ yẹn àwọn ti o wa ni àwọn ilé oúnjẹ ati awọn ile-itaja ti o wa ni ìlú ti ọpọlọpọ awọn ti wọn n gbe nibẹ jẹ ẹni ti wọn kìí ṣe Musulumi ati awọn Ahlul-Kitaab

2. Nǹkan ti Musulumi tabi Ahlul-Kitaab ba du pẹlu oju-ọna ti sharia, eleyii lẹtọọ pẹlu ọ̀rọ̀ Kuraani

3. Nǹkan ti Musulumi tabi Ahlul-Kitaab ba pa pẹlu oju-ọna ti o yatọ si ti sharia gẹgẹ bii fifi ina gbe nnkan ati titẹ ẹ ri sinu omi, eleyii jẹ eewọ

4. Ipilẹ ni titọọ nnkan ti Ahlul-Kitaab ba du, ati àwọn nǹkan tí wọ́n du ti wọn wa ni ile oúnjẹ wọn ati awọn ile-itaja wọn, pẹlu ṣíṣe ojukokoro dida orúkọ Ọlọhun nigba ti a ba fẹ jẹ ẹ. Nǹkan ti o daa julọ fun Musulumi ni ki o ma jẹ ẹ afi pẹlu nini aridaju pe o wa ninu awọn ẹran ti a ṣe jíjẹ rẹ ni ẹtọ.

Jíròrò

Ṣe atunyẹwo pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ apakan ninu awọn ikanni lori Intanẹẹti, eyi ti o maa ran ẹ lọ́wọ́ lati ri awọn oúnjẹ ti wọn ni ẹtọ ni ilu rẹ

Awọn nnkan ti wọn n du ti wọn n ta ni awọn ile-itaja ati awọn ile oúnjẹ yàtọ̀ si ara wọn ni ibamu si ẹsin ẹni ti o dú wọn

Woye si awọn oúnjẹ ati awọn nǹkan mímu ti a ṣe ni eewọ, lẹyin naa ki o ronú si awọn ọgbọn ti o fa ṣíṣe ni eewọ wọn wa

O tọna

Àṣìṣe

Ti Yahudi tabi Nasọrọ ba du nnkan, dajudaju jíjẹ rẹ ni ẹtọ, koda ki o ma da orúkọ Ọlọhun si i.

Jíjẹ nnkan ti a n du ti o ku pẹlu ina gbigbe ko ni ẹtọ.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹta

Àwọn ibalopọ ti owó:

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Ninu titobi ẹsin Isilaamu ni pe o ko gbogbo awọn agbegbe igbesi aye ẹda sinu, ninu ìyẹn ni àkóso awọn ibaṣepọ awọn eniyan laaarin ara wọn, ati sisọ awọn ẹtọ wọn, ati kíkọ ṣíṣe abosi si ẹnikẹ́ni nínú wọn. Nínú awọn nǹkan ti o jẹ yọ latara akolekan yii ni: Ṣíṣe awọn ofin ati awọn ilana ti wọn fi n dari awọn ibaṣepọ ti owó laaarin wọn, ninu ẹkọ yii a maa mọ akojọpọ kan ninu awọn idajọ awọn ibaṣepọ ti owó.

1. Ki ni àwọn ibalopọ ti owó?

Awọn ibaṣepọ ti owó: Awọn ni awọn ibaṣepọ ti ijirọ awọn dukia maa n ṣẹlẹ nibẹ, boya o jẹ pẹlu ijirọ dukia miiran; gẹgẹ bii katakara, tabi ijirọ anfaani kan; gẹgẹ bii fífi nǹkan rẹ́ǹtì, tabi laini ijirọ; gẹgẹ bii ẹbun

Ìpìlẹ̀ nibi ìbálòpọ̀ ti owó:

Ipilẹ níbi awọn ibaṣepọ ti owó ni ẹtọ, nǹkan kan ko nii jẹ eewọ nínú ẹ, àyàfi ohun ti ṣíṣe ni eewọ rẹ ba wa lati inu Kuraani Alapọn-ọnle tabi Hadiisi.

Ipilẹ nibi awọn ibaṣepọ ti awọn ibaṣepọ ti owó naa wa nibẹ ni ẹtọ, ko si ṣíṣe ni eewọ afi pẹlu ẹri, yato si awọn ijọsin, ipilẹ nibẹ ni pe wọn gbọdọ ni ẹri, ijọsin o nii maa lẹtọọ afi pẹlu ẹri.

Awọn ibaṣepọ ti owó ti a ṣe ni eewọ:

Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe apakan ninu awọn ibaṣepọ ti owó ni eewọ, ninu wọn ni:

Gbigba awọn dukia awọn eniyan ni ọ̀nà ti ko tọ; gẹgẹ bii ki o gba a pẹlu ete tabi ipá.

Imu ẹnì kan ninu awọn ti wọn jọ n ṣe papọ ni tipátipá lori ibaṣepọ ti ko fẹẹ ṣe.

Imaa ṣe owo nibi awọn nnkan ti wọn le ko ipalara ba alaafia eniyan; gẹgẹ bii ọti ati awọn egbogi oloro ati tábà, ati eyi ti o yatọ si ìyẹn

Owo ele, oun ni yiya owo pẹlu majẹmu dida a pada pẹlu alekun odiwọn kan lori owo ti wọn ya gẹgẹ bii ṣíṣe alekun 5% fun apẹẹrẹ

Títa nnkan ti a kò mọ̀; gẹgẹ bii títa apoti ti a ko mọ nnkan ti o wa ninu rẹ.

Tẹtẹ ti ẹni ti o ba borí maa gba dukia ẹni ti o ba pofo ni ọna ti ko tọ.

Awọn okunfa ṣíṣe awọn ibaṣepọ ti owó ni eewọ:

Awọn okunfa ìpìlẹ̀ ti o maa n beere fun ṣíṣe ni eewọ awọn ibaṣepọ ti owo, awọn ni:

1. Abosi

2. Owó èlé

3. Ẹtanjẹ

Jíròrò

Ni abẹ ọpọlọpọ awọn ibaṣepọ ti owó ti Musulumi maa n ṣe ni igbesi aye rẹ, bawo ni yio ṣe maa ṣe akiyesi nnkan ti o tọ́ fun un ninu ẹ, ati nnkan ti o jẹ eewọ fun un?

Idanwo

Fi gbogbo agbekalẹ ọrọ ninu awọn agbekalẹ ọrọ ti wọn n bọ yii si aaye ti o ba mu ni ibamu si asopọ wọn pẹlu rẹ.

Tita ọtí

Abẹtẹlẹ

Rira aṣọ lori Intanẹẹti

Ṣíṣe owo nibi awọn nnkan ti o le ko inira báni

Yiya ẹnikan ni iye kan lori pe ki o da a pada pẹlu alekun 10%

Tita omi mímu

Awọn idije ti awọn olukopa nibẹ maa san owo kan, ti olubori si maa gba a

Ìbálòpọ̀ ti owó ti o ni ẹtọ

Ìbálòpọ̀ ti owó ti o jẹ eewọ

Owo ele jẹ ọkan ninu awọn ibaṣepọ ti owó ti o buru julọ ti Isilaamu ṣe ni eewọ fun nnkan ti o wa nibẹ ninu ifi ara ni ẹni, a si ka a si ọkan ninu awọn ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ ti Ọlọhun ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba n ṣe e pẹlu ijiya ti o le koko.

Ronú jinlẹ si awọn ibaṣepọ ti owó ti a ṣe wọn ni eewọ, lẹyin naa ki o ronu si awọn ọgbọn ti o n beere fun ṣíṣe e ni eewọ.

O tọna

Àṣìṣe

Tẹtẹ tita tọ́ pẹlu majẹmu iyọnu igun mejeeji

O lẹtọọ fun Musulumi lati ya owo pẹlu owo ele ti o ba ni bukaata si ìyẹn

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrin

Àwọn ìwà:

ọ̀rọ̀ ìṣáájú

Isilaamu ṣe awọn Musulumi ni ojukokoro lori fifi awọn iwa daadaa ṣe ẹṣọ, dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tọ wa si ọna lọ si iṣe pataki awọn iwa ninu ọpọlọpọ ninu awọn hadisi ti Anọbi, o si ko ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọsìn ti Musulumi maa n ṣe papọ mọ́ ìwà daadaa, Musulumi ti o ni awọn iwa daadaa jẹ ẹni ti a ṣe adehun awọn ẹsan ńlá fún ni aye ati ọrun, ninu ẹkọ yii a maa mọ pataki awọn iwa ninu Isilaamu, pẹlu alaye apakan ninu awọn ọla ti n bẹ fun wọn.

Àwọn ìwà nínú Isilaamu.

Awọn iwa daadaa ni ipo ti o tobi ninu Isilaamu, o jẹ erongba kan ti o ṣe koko ninu awọn erongba sharia ti Isilaamu, ati erongba ninu awọn erongba igbedide Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. Awọn iwa ni asopọ kan ti o nípọn pẹlu igbagbọ, ẹni ti o fi n pe julọ ninu awọn olugbagbọ ni ti igbagbọ ni ẹni ti o daa julọ ninu wọn ni ti iwa. Wọn maa san Musulumi ni ẹsan lori didara iwa rẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe n san an ni ẹsan lori irun ati awẹ

Jíròrò

Bawo ni o ṣe tọ ki awọn iwa Musulumi ṣe ri pẹlu awọn ẹlomiran? Njẹ oripa n bẹ fun awọn iwa yii nibi ṣíṣe idajọ wọn lori Isilaamu?

Ọla ti o n bẹ fun iwa daadaa:

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe ọpọlọpọ nnkan ti o maa mu awọn eniyan wọ alujanna ni: Ibẹru Ọlọhun ati iwa daadaa

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe nnkan ti o wuwo julọ ninu nnkan ti wọn maa fi sibi oṣuwọn iṣẹ eniyan ni ọjọ igbedide ninu awọn iṣẹ daadaa ni: Ìwà daadaa

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe ẹni ti o maa sunmọ oun julọ ninu awọn olugbagbọ ni ipo ni ọjọ igbedide ni: Ẹni ti o daa julọ ninu wọn ni iwa

Oṣuwọn eniyan: Ìyẹn maa waye ni ọjọ igbedide nigba ti wiwọn awọn iṣẹ daadaa eniyan ati awọn iṣẹ aburu rẹ maa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú oṣuwọn kan ti wọn yà sọ́tọ̀, ti ẹni kankan o mọ bi o ṣe ri tabi odiwọn rẹ, ẹni ti oṣuwọn awọn daadaa rẹ ba tẹsuwọn yio wọ alujanna, ẹni ti oṣuwọn awọn aburu rẹ ba tẹsuwọn yio wọ ina

Idanwo

Fi gbogbo agbekalẹ ọrọ ninu awọn agbekalẹ ọrọ ti wọn n bọ yii si aaye ti o ba mu ni ibamu si asopọ wọn pẹlu rẹ.

Ìpayà

Rírẹ́rìn-ín músẹ́ si Musulumi

Mimu suta kuro ni oju ọna

Ododo

Agbiyele

Riran ẹlòmíì lọ́wọ́

Iran ara ẹni lọwọ lori daadaa

Nínú àwọn iwa ti o dara

Ninu ìjọsìn ti ọkàn

Àwọn aaye iwa ninu Isilaamu

Ko si aye kan pere fun awọn iwa ninu Isilaamu, bi ko ṣe pe awọn aye ti o pọ ni wọn n bẹ fun wọn, awọn ni:

Awọn iwa pẹlu Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- gẹgẹ bii ibẹru Ọlọhun ati imọkanga fun Un

Awọn iwa pẹlu Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-; gẹgẹ bii nini ifẹ rẹ ati ṣíṣe apọnle rẹ ati ìwà ẹlẹkọọ nigba ti a ba n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ati titọrọ ikẹ fun un nigba ti wọn ba dárúkọ rẹ.

Awọn iwa pẹlu Sharia; gẹgẹ bii gbígbà fun awọn idajọ sharia ati ṣíṣe apọnle wọn

Awọn iwa pẹlu ẹmi; gẹgẹ bii ṣíṣe pẹlẹpẹlẹ lati le jẹ ki o maa tẹle ti Ọlọhun, ati nini ipinnu lati kọ̀ fun un kuro nibi ìmẹ́lẹ́

Awọn iwa pẹlu awọn ẹlomiran; gẹgẹ bii ododo ati ifọkantan

Awọn iwa pẹlu awọn ẹranko; gẹgẹ bii àmójútó wọn ati ki wọn ma na wọn, ki wọn si má fi ìyà jẹ wọn.

Awọn iwa pẹlu ayika; gẹgẹ bii sísọ ọ kuro nibi ibajẹ, ati gbingbin awọn igi, ati ki wọn ma na ina apa nibi awọn oore rẹ

Kíkà ti afikun

Ki o le da ọpọlọpọ mọ ninu awọn iwa Isilaamu ati awọn ọla ti n bẹ fun un, ati oripa wọn lori ìjẹ ọmọniyan, ka iwe “Isilaamu ni ẹsin ọla”, ti o wa kaakiri ni ilé-itaja Usuul, pẹlu awọn ede agbaye ti o pọ

Ṣe ẹ̀dá àwòrán barcode naa lati fi ẹ̀dà ìwé naa ránṣẹ́

Ìwà ninu Isilaamu ko mọ lori ibaṣepọ pẹ̀lú ẹda nikan, bi ko ṣe pe o ko ibaṣepọ pẹ̀lú ẹranko ati ayika sinu

Laaarin igba ti o wo fidio yii: The beauties of Islam, ṣe iroyin bi Isilaamu ṣe dahun fun bukaata ti ẹmi ati ti awọn iwa lọdọ awọn ẹda tó.

Sọ hadisi anọbi kan ti o da lori ọla ti o n bẹ fun iwa daadaa

O tọna

Àṣìṣe

Iwa ninu Isilaamu mọ lori ibaṣepọ pẹ̀lú awọn ẹda nikan

Igbelewọn ti ara ẹni

1. Njẹ o ni ikapa lati ṣe alaye ki ni ipilẹ nibi aṣọ wiwọ

" 2. Njẹ o da awọn aṣọ ti a ṣe ni eewọ mọ?

3. Njẹ o da ipilẹ nibi awọn oúnjẹ ati awọn nǹkan mimu mọ?

4. Njẹ o da awọn oúnjẹ ti a ṣe ni eewọ mọ?

5. Njẹ o da awọn nnkan mimu ti a ṣe ni eewọ mọ?

6. Njẹ o kọ ki ni ipilẹ nibi awọn ibaṣepọ ti owó?

Njẹ o da awọn ibaṣepọ ti owó ti a ṣe ni eewọ mọ?

"8. Njẹ o n ni ìmọ̀lára irọrun ẹsin Isilaamu ati rirọ rẹ?

Ipari

Ni ipari, a n gba Musulumi tuntun ni àwọn ìmọ̀ràn ti o bọ yii:

Iṣe ojukokoro lori kikọ nnkan ti o ni bukaata si ninu awọn alamọri ẹsin rẹ, ki o si wádìí nipa ìyẹn ninu awọn ipilẹ ti a le gbara le, boya o jẹ awọn onimimọ ni, ati awọn olupepe, tabi awọn tira, tabi awọn nǹkan ti a n gbọ tabi ti a n ri.

Ṣíṣe iṣẹ pẹlu imọ, o jẹ dandan fun Musulumi lati ṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o kọ ninu imọ ti o ṣe anfaani

Wíwá ìmọ̀ àti ṣíṣe iṣẹ ni sisẹ-n-tẹle, nini imọ, ati nini iwa dáadáa, ati ṣíṣe ìjọsìn, ọmọniyan ko lee ni i ni ẹẹkan náà, ṣùgbọ́n o maa ṣe wọn ni ẹyọ kọ̀ọ̀kan.

Jíjìnnà si nnkan ti yio lapa nibi igbagbọ ni ọna aida, boya o jẹ awọn iruju tabi awọn ifẹkufẹẹ

Didunni mọ wiwa imọna lọ si ibi ododo lati ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati dida ododo yatọ si ibajẹ

Awọn idajọ ẹsin so pọ̀ mọ ini ikapa, Musulumi o maa ṣe ninu rẹ nnkan ti o ba ni ikapa, láìní la nnkan ti apa rẹ o ka bọ ara rẹ lọrun

Iṣe ojukokoro lori imu awọn Musulumi rere ni ọrẹ, àwọn ti wọn maa mu u lekun ni igbagbọ ati daadaa, ati jíjìnnà si ìjókòó pẹ̀lú awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn oni ifẹkufẹẹ ati iruju

Idanwo ti ipari

Orúkọ

Maaki ipari: Ogójì maaki

A. Mu idahun ti o tọna ninu nnkan ti o n bọ yii:

Maaki 15

1. Ọlọhun fi afijọ si ara eniyan ninu:

Àwọn Malaika

Àwọn èṣù

Àwọn ẹranko

Gbogbo ohun ti o ṣáájú

2. Ipilẹ nnkan ti wọn fi da eniyan wa lati ara:

Omi

Amọ

Ina

Okuta

3. Isilaamu n fi rinlẹ pe dajudaju ẹda abara sẹ̀ wá lati iran baba wọn:

Ibrahim

Isa

Adam

Muhammad

4. Ti eniyan ba ku yio ṣi lọ si ipele:

Iṣẹ ati ìdánwò

Ẹsan ati ìṣirò

Aisi ati titan

Gbogbo ohun ti o ṣáájú

"5. Ọlọhun ko nii tẹwọ gba lọwọ eniyan lẹyin igbedide Anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- afi ẹsin kan ṣoṣo, oun naa ni:

Ẹsin Júù

Ẹsin Kristẹni

Isilaamu

Ẹsin Hindu

6- Onka awọn origun Islam:

.3

.4

.5

6

7. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ ninu Kuraani pe Oun yio ṣe aforijin gbogbo awọn ẹṣẹ ti Oun ba fẹ yatọ si:

Pípa

Jijale

Ẹbọ

Irọ

8. Gbogbo arafi ti Musulumi ba n ka ninu iwe Ọlọhun, dajudaju yio maa bẹ fun un lati ara rẹ̀:

Dáadáa ẹyọkan

Dáadáa meji

Dáadáa méje

Dáadáa mẹ́wàá

9. Ninu awọn orúkọ Kuraani Alapọn-ọnle

Ìrántí

Al-Furqaan

Al-Kitaab

Gbogbo ohun ti o ṣáájú

10. Itumọ (Kufuwan) ninu ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe: (Wa lam yakun laHu kufuwan ahad) tumọ si:

Ti O pe

Ti a n jọ́sìn fun

Ẹni ti o jọ Ọ

Ẹyọkan

11. Itumọ (Al-Falaq) ninu ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe:(Qul 'ahuudhu birobbil falaq), o n tumọ si:

Òkùnkùn alẹ́

Yiyọ òṣùpá

Hihan owurọ

Yíyẹ àtàrí oòrùn

12. Itumọ ('ahuudhu) ninu ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-: (Qul 'ahuudhu birobbin naas) n tumọ si:

Mo n sá di, mo ṣi n dìrọ̀ mọ́

Mo n jọsin, mo ṣi n sunmọ

Mo n yin, mo ṣi n ranti

Mo n gba fun, mo ṣi n jupa-jusẹ silẹ fun

13. Itumọ (Al-Waswaasil Khonnaas) ninu ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-: (Min sharril waswaasil khonnaas) n tumọ si:

Opidan

Onilara

Èṣù

Kèfèrí

14. Itumọ (Shaani-aka) ninu ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-: (Inna shaani-aka huwal abtar) n tumọ si:

Olukorira rẹ

Olunifẹẹ rẹ

Olugbagbọ ninu rẹ

Ẹni ti o n ṣẹri kúrò lọ́dọ̀ rẹ

15. Ninu ìjọsìn ti ara

Ìfẹ́

Agbiyele

Irun

Gbogbo ohun ti o ṣáájú

B. Pin awọn ọrọ ti wọn n bọ yii ni ibamu si awọn ijọ wọn ti o tọna:

Maaki 8

Rirọkirika ile Ọlọhun

Irun

Jijẹ

Dida oju kọ qibla

Jijade itọ

Bibo ihoho

Mimu

Oorun

Awọn nnkan ti wọn n sọ aluwala di dandan:

Awọn majẹmu irun kiki

Àwọn nǹkan ti n tu imọra

Àwọn nǹkan ti n ba aawẹ jẹ

D. To awọn iṣẹ aluwala ti wọn n bọ yii tẹle ara wọn bẹrẹ pẹlu akọkọ ninu wọn:

Maaki 6

Pipa ori

Fifọ ọwọ mejeeji titi de igunpa mejeeji

Fifọ ojú

Fifọ ẹsẹ mejeeji

Pipa eti

Fifi omi yọ ẹnu ati fifa omi si imu

E. To awọn iṣẹ ori irun ti wọn n bọ yii tẹle ara wọn bẹrẹ pẹlu akọkọ ninu wọn:

Maaki 6

Kike Faatiha

Rukuu

Kabara ìmúra

Salamọ

Kika ataaya

Fifi ori kanlẹ

Ẹ. Fi ami (O tọna) siwaju agbekalẹ ọrọ ti o tọna, ati ami (Àṣìṣe) siwaju agbekalẹ ọrọ ti ko tọna ninu awọn nnkan ti o n bọ yii:

Maaki 5

1. Musulumi maa n ṣe ijọsin Hajj ninu oṣu Ramadan alalubarika

2. Wọn ṣe wiwọ wura ni eewọ fun awọn ọkunrin ninu awọn Musulumi

"3. O tọ fun awọn Musulumi lati jẹ ẹran ẹlẹdẹ

4. Ipilẹ nibi awọn ibaṣepọ ti owó ni ẹtọ

5. Ẹni ti yoo sunmọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ipo julọ ninu awọn olugbagbọ ni ọjọ igbedide ni ẹni ti o daa julọ ninu wọn ni iwa

Atẹjade àkọ́kọ́

Atẹjade keji

Atẹjade kẹta

Atẹjade kẹrin

Atẹjade karùn-ún