صفة الوضوء والصلاة (مرئي)
PROJ-187
Bawo ni maa ṣe ṣe aluwala?
M
Ohun
1
Ohun pipe irun
2
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì.
[Al-Ma'idah: 6]
3
"Ko si irun laiṣe aluwala, ko si tun si aluwala laida aniyan, ko si tun si aniyan lai ṣe e pẹlu imọkanga, aaye aniyan ni ọkan, kii ṣe ori ahọn lasan"
4
Pẹlu orukọ Ọlọhun
Wọn ṣe didarukọ Ọlọhun lofin nigba ti a ba fẹ bẹrẹ aluwala.. Oun ni a o fi bẹrẹ aluwala wa.. Lẹyin igba naa ni a o waa lo pákò lati fi run ẹnu wa lati le baa fi mọ ẹnu ti o ba rọrun bẹẹ.
5
A o fọ ọwọ mejeeji de ọrun ọwọ lẹẹmẹta, a o bẹrẹ pẹlu eteeti awọn ọmọnika débi ọrun ọwọ..
6
"A o fọ ọwọ mejeeji titi yoo fi debi ọrun ọwọ lẹẹmẹta ni tẹlentẹle."
7
A o maa bẹrẹ pẹlu ọwọ ọtun, a maa fọ ọ ni ẹẹmẹta, ọwọ osi o wa tẹle e lẹẹmẹta bakan naa.
8
Gẹgẹ bi fifọ ọwọ ọtun ṣe lẹtọọ, lẹyin naa ni o kan fifọ ọwọ osi, lẹyin naa ni o kan fifọ ọwọ ọtun, lẹyin naa ni o kan fifọ ọwọ osi.. Bayii ni yoo ṣe maa lọ bẹẹ.
9
Pẹlu rírí aridaju pe omi de aarin awọn ọmọnika wa.
10
"Lẹyin igba naa ni a o wa lọ sibi fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi simu "
11
Fifi omi yọ ẹnu o maa waye pẹlu fifi omi si ẹnu, ati gbigbo o jigijigi nnu rẹ, lẹyin naa ni o kan titu u jade.
12
Ṣugbọn fifin omi simu maa waye pẹlu fifa omi simu pẹ̀lú èémí, lẹyin naa ni o wa n kan fifa a jade pẹlu ọwọ osi pẹlu fifin in jade.
13
Ninu sunnah ni ki a ṣe méjèèjì daadaa lopin igba ti a o ba ti jẹ alaawẹ abi a n paya inira kan..
14
Fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi simu maa n gba ọna meji wa:
15
Dida a pọ: Yoo maa waye pẹlu bíbu ẹkunwọ omi kan, a o wàá fi idaji ninu rẹ yọ ẹnu wa, lẹyin naa ni a o fin idaji ti o ku simu wa.
A o gbo omi ti o wa lẹnu wa jigijigi, lẹyin naa ni a maa tu u jade, lẹyin naa ni a o wàá fin omi ti a fa simu wa jade pẹlu ọwọ osi wa.
A o ṣe eleyii ni ẹẹmẹta pẹlu ẹkunwọ omi mẹ́ta.
16
Ṣugbọn ṣiṣe e ni ọtọọtọ maa waye pẹlu ki a da ẹkunwọ omi kan yatọ lọtọ lati fi yọ ẹnu, bakan naa ki a si fa omi simu pẹlu ẹkunwọ omi mìíràn, a o wàá bu ẹkunwọ omi si ẹnu tan, lẹyin naa ni a maa wa gbo o jìgìjìgì, lẹyin naa ni a maa wa tu u jade, lẹyin naa ni a tun maa wa bu ẹkunwọ omi ẹlẹẹkeji, a o waa fi imu fa a, lẹyin naa ni a maa wa fin in jade pẹlu ọwọ osi.
17
Fifọ oju maa wa tẹle fifi omi yọ ẹnu ati fifa omi simu.
18
Aala oju ni òòró naa ni: Lati ibi ti irun ori ti maa n saaba hù, debi ti agbọn pari si, ibu rẹ si jẹ ohun ti nbẹ laarin eti mejeeji si ara wọn.
19
Pẹlu jijẹ dan lati fọ gbogbo irun ti o wa loju; gẹgẹ bii irun agbọn ti ko pọ, ati irun imu, ati irun ipenpeju, ati irun ojú, ati irun abẹ ètè isalẹ.
20
Fifọ oju ma n gba ọna meji wa:
21
Akọkọ: A o fi ọwọ wa mejeeji bu omi papọ, a o fi mejeeji fọ oju wa lati ibi ti irun ori ti maa n hù ti a ti ba saaba titi de ibi ti agbọn pari si, ati lati eti ọtun de eti osi, ti irun agbọn ba pọ daadaa, wọn ṣe e ni sunnah lati jẹ ki omi o de isalẹ rẹ, a o si ya irun agbọn naa.
A o mu eleyii wa lẹẹmẹta, oun ni o pe, tabi ẹẹmeji tabi ẹẹkan ṣoṣo, oun ni o jẹ dandan.
22
Ẹlẹẹkeji: A o bu omi si ọwọ ọtun wa, lẹyin naa ni a o wa fi si oju ti a o si fi ọwọ wa mejeeji fọ ọ nu papọ gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ọna ti o ti ṣaaju.. A o ṣe iyẹn ni ẹẹmẹta..
23
Títo àwọn oríkèé aluwala tẹle ara wọn jẹ dandan, ati yíyára ṣe e naa jẹ dandan bakan naa, láìní ti oríkèé kan ṣaaju oríkèé miiran, a o si nii pẹ́ láti kúrò ni oríkèé kan bọ́ sí oríkèé tí ó tẹle e
24
Ti a ba ti pari fifọ oju tan, a maa lọ sibi fifọ ọwọ mejeeji.
25
Ààlà ọwọ́ méjèèjì ti fifọ wọn jẹ́ dandan ni: Lati etí awọn ọmọnika debi igunwọ pẹlu fifọ awọn igunwọ mejeeji.
26
A o bẹrẹ pẹlu fifọ ọwọ ọtun lati ibi etí àwọn ọmọnika ọwọ, a o si ya awọn ọmọnika pẹlu titi ọwọ bọ inú ara wọn, lẹyin naa ni a o wàá jẹ ki omi de igunwọ.
27
Lẹyin igba naa ni a o lọ sibi ọwọ osi, a o fọ oun naa bakan naa lati ibi awọn ọmọnika pẹlu yiya a titi de igunwọ..
28
A o lọ sibi pipa ori.. A o bu omi miiran rin ọwọ méjèèjì, lẹyin igba naa ni a o wàá gbé ọwọ mejeeji ti a bu omi rin yii sibi ibẹrẹ ori, a o wàá mu mejeeji lọ sibi ipakọ, lẹyin igba naa ni a o da ọwọ mejeeji pada si aaye ibi ti a ti bẹrẹ pipa wọn.. Ko wa si iyatọ nibi ààlà orí laarin ẹniti o pari ati ẹniti irun wa lori rẹ.
29
Lẹyin naa ni a o waa pa eti wa mejeeji pẹlu omi ti o ṣẹku ninu omi eleyii ti a fi pa ori, a o ṣe ìyẹn ni ẹẹkan ṣoṣo.
30
Iroyin pipa eti naa ni ki a ti ọmọnika odunnlabẹ bọ inu eti mejeeji, a o wa fi pa wọn, a o wa fi ọmọnika atanpako pa ẹyin eti, yoo waa jẹ pe a ti pa eti tinu tẹyin..
31
A o waa lọ fọ ẹsẹ mejeeji, ààlà ẹsẹ ti fifọ rẹ jẹ dandan naa ni: Lati etí ọmọnika ẹsẹ titi de kokosẹ, fifọ gigisẹ si jẹ dandan
32
"A o bẹrẹ pẹlu ẹsẹ ọtun, a o si fi ọwọ ya awọn ọmọnika rẹ. A si máa ni akolekan lati fọ kokosẹ mejeeji ati òkè ẹsẹ mejeeji naa.. "
33
Lẹyin naa ni a o waa fọ ẹsẹ osi gẹgẹ bi a ṣe fọ ẹsẹ ọtun, a o si gbọdọ gbagbe lati ya awọn ọmọnika rẹ, ki a si ri aridaju pe a fọ gbogbo gigisẹ, ki omi si de kokosẹ méjèèjì naa.
34
Ash'hadu an laa ilaaha illal-Loohu, wah'dahuu laa sheriika lahuu, wa ash'hadu anna Muhammadan ab'duhuu wa rosuuluhuu.
35
Wọn ṣe e ni sunna lẹyin pipari aluwala lati ṣe iranti ati adua naa, wọn si tun ṣe e ni sunna lati tun fi kun un pe:
36
Allahummo ij'hal'nii minat-tawwaabiin, waj'hal'nii minal-mutatohhiriin
37
tabi
Sub'haanaka Allaahummo wa bi ham'dika, ash'hadu an laa ilaaha illaa an'ta, astagfiruka, wa atuubu ilaeka
Mim
Eleyii ti wọn kọ si oju agbàwòrán-tàn
1
Bawo ni maa ṣe ṣe aluwala?
2
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì.
[Al-Ma'idah: 6]
3
Fifọ ọwọ mejeeji
4
Yiyọ ẹnu ati fifa omi simu
5
Ṣiṣe e papọ
6
Ṣíṣe e lọtọọtọ
7
"Fifọ oju"
8
"Alakọkọ"
9
"Ẹlẹẹkeji"
10
Didaniyan ati sisọ gbólóhùn (Bismillaahir-Rahmaanir-Roheem)
11
Fifọ ọwọ mejeeji
12
"Fifi omi yọ ẹnu"
13
''Fifa omi simu"
14
"Fifọ oju"
15
Fifọ ọwọ méjèèjì pẹlu igunwọ méjèèjì
16
"Pipa ori ati eti méjèèjì "
17
Fifọ ẹsẹ mejeeji pẹ̀lú kókósẹ̀ mejeeji
18
"Fifọ ọwọ mejeeji"
19
"Pipa ori"
20
Ìbẹ̀rẹ̀ ori = Títẹ̀ iwájú orí ati ìbẹ̀rẹ̀ ibi ti irun ti maa n hù ti a ti ba saaba
21
Opin ori = Igbẹyin ibi tí irun ti maa n hù láti ipakọ
22
"Pipa eti mejeeji"
23
"Fifọ ẹsẹ mejeeji"
24
Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a- sọ pé
{Egbé fún àwọn gigisẹ ninu ina, ẹ máa ṣe aluwala yin dáadáa)
Abu Daud ni o gba a wa.
25
Ash''hadu an laa ilaaha illal Loohu, wah'dahuu laa ṣẹriika lahuu, wa ash"hadu anna Muhammadan abduhuu wa rọsuulu
Muslim ni o gba a wa.
26
Allahumma ij'hal'nii minat-tawwaabiin, waj'hal'nii minal-mutatohhiriin
Tirmidhiy ni o gba a wa
27
Sub’haanakal laahummọ wa bi’amdika, ash’adu an laa ilaaha illaa anta, astagfiruka wa atuubu ilaik
An-Nasaa'iy ni o gba a wa nínú "Amalul-yaomi wal-laylah".
Bawo ni maa ṣe kirun?
Irun bẹrẹ láti kabara titi de salamọ..
M
Ohun
1
Ohun gbigberun duro
2
Ohun gbigberun duro n tẹ siwaju
Mimu aniyan wa ni ohun akọkọ ti ẹniti o fẹ kirun maa ṣe, aaye rẹ si ni ọkan
3
A maa kọju si qib'lah, ti o ba jẹ imaamu tabi o n da irun ki, yaa fi gaga kan siwaju rẹ.
4
Allaahu Ak'bar
Kabara iwọ irun, oun ni a maa fi wọnú irun, a gbọ́dọ̀ pe e jade pẹ̀lú ahọ́n.
5
Nigba ti a ba kabara, a maa gbe ọwọ wa mejeeji soke titi de deedee ejika wa mejeeji, a maa waa jẹ ki inú awọn ọmọnika wa kọju si qib'lah.
tabi
Ki a gbe ọwọ mejeeji soke titi de deedee eti mejeeji ni irú ọna kan náà..
6
A maa wa gbe ọwọ mejeeji si aya lẹyin kabara, tabi si isalẹ aya ti o wa loke idodo, tabi isalẹ idodo, gbogbo iyẹn naa ni o ni alaafia.
Ọwọ ọtun wa, a maa gbe e lori ọwọ osi wa debi ọrun ọwọ
Tabi ki a fi ọwọ ọtun di ẹyin ọwọ osi debi ọrun ọwọ mú..
Tabi ki a fi ọwọ ọtun di apá osi mú.
7
Allahummo baa'id bay'nii wa bayna khatooyaaya, kamaa baa'had'ta bay'nal mash'riki wal magrib. Allahumo nakkinii min khatooyaaya kamaa yunakkos-saobul ab'yadu minad-danas. Allahummo ig'sil'nii min khatooyaaya bis-sal'ji wal maa'hi wal barod.
A maa ṣe adua ibẹrẹ irun lẹyin kabara wiwọ irun ati ṣíwájú kika Faatiha, awọn adura miiran ti wa fun ìbẹ̀rẹ̀ irun, ninu sunna si ni ṣíṣe gbogbo e wọnu ara wọn ki o ma jẹ pe oríṣi kan pere ni a ma maa ṣe lọ.
8
Auuzu bil-Laahi minash-shaytoonir-rojiim
Ohun ti yoo tẹle adua ibẹrẹ irun ni: Ṣíṣe auuzu, lẹyin rẹ ni o maa wa kan kika Faatiha..
9
Pẹlu ìpayà ati ifarabalẹ ni a o maa fi ka aaya kan si aaya miiran.
10
Amin
Sísọ ọ́ jẹ sunna fun ẹniti o n kirun, boya imaamu ni o jẹ ni abi ẹniti o n kirun lẹyin imaamu, abi o n da irun ki ni, kii ṣe aaya nínú suratul Faatiha, ṣùgbọ́n adua ni ti o n túmọ̀ si: Ọlọhun mo pe Ọ, gba a.
11
A maa ka ohun ti o ba rọ wa lọrun ninu Alukurani lẹyin faatiha, o le jẹ odindi suura kan tabi ipin kan ninu rẹ, lẹyin ti a ba pari kike e rẹ tan, a o wa dakẹ diẹ ṣiwaju ki a to lọ si rukuu.
12
Ọlọhun ni O tobi julọ
A maa ṣe kabara lati kuro ni aaye iduro lọ si rukuu..
Eleyii ni aaye ẹlẹẹkeji nibi irun, eleyii ti Anọbi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ti maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji soke nibẹ; wọn wa ṣe e ni sunna pe ki a gbe ọwọ wa mejeeji soke ti yoo fi ṣe deedee ejika tabi eti wa mejeeji..
13
A maa gbe ọwọ wa mejeeji lori orokun wa mejeeji, a si maa ya awọn ọmọnika wa, a si maa jẹ ki wọn da bii pe a di orokun méjèèjì mu
A maa farabalẹ nibi rukuu wa, a si maa gbe ọwọ wa mejeeji jina si ẹgbẹ wa mejeeji, a o si nii jẹ ki ẹkẹ wa o hàn pẹ̀lú fífì si ọkan ninu awọn ẹgbẹ wa méjèèjì.
14
Ẹyin maa wa ni dọgba-n-dọgba lai tẹ, ori si maa ṣe deedee ẹyin, a o slni gbe soke, a o si ni tẹ ẹ walẹ.
15
"Subhaana Robbiyal Aziim"
A maa wi gbolohun ṣiṣe afọmọ yii ni ẹẹmẹta, oun ni pípé tí ó kéré jù, ṣùgbọ́n ṣiṣe e lẹẹkan ṣoṣo naa to. A si le fi kun un ti o ba wu wa, a si ma maa ṣe àwọn gbólóhùn afọmọ orisirisi tí wọ́n gba wa wọnú ara wọn ki o ma jẹ pe oríṣi kan péré ni a ma maa ṣe ni gbogbo ìgbà.
16
Awọn azkaar ti wọn maa n sọ ni rukuu pe orisirisi.
17
Samihal-Loohu liman hamidah
A maa sọ ọ nígbà tí a bá n dide lati rukuu ti a ba n dá kirun tabi ti ọkan ninu wa bá jẹ Ìmáàmù
18
A maa gbé ọwọ wa méjèèjì sí deede èjìká tabi deede etí, eleyii ni ààyè kẹta ti a ti máa gbé ọwọ wa méjèèjì soke
19
Leyin naa a maa wáá nàró lẹni tí yóò máa sọ pe:
Robbanaa wa lakal-ham'd
20
Ó tọ́ fún wa láti da ọwọ wa silẹ tabi lati ká a mọ́ àyà nígbà tí a ba ti gbori soke lati rùkúù
21
Wọn ṣe é ni sunna lati pẹ ni iduro lẹyin rùkúù, ati fifarabalẹ níbẹ̀.
22
Allaahu Ak'bar
Lẹyìn náà, a maa wáá lọ ilẹ̀ lẹniti yóò máa kabara láti kúrò ní ìnàró lọ sí ìforíkanlẹ̀.
A maa fi ọwọ wa kan ilẹ ṣíwájú orúnkún tabi ki a ti orúnkún ṣíwájú ọwọ, èyíkéyìí tó bá ti rọ̀ wá lọrun ni.
23
O waa pọndandan ki a foribalẹ pẹlu awọn oríkèé ara méje gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọhun- kí ikẹ àti ọlà Ọlọhun máa bá a- ti ṣe fi mọ wa.
Iwaju orí pẹlu imú, ati atẹlẹwọ méjèèjì, àti ẹsẹ mejeeji, ati orúnkún méjèèjì.
24
A maa jẹ kí àwọn etí awọn ọmọnika ẹsẹ mejeeji kọjú sí kiblah, a si maa gbe ẹsẹ mejeeji sókè.
A maa fi ààyè sílẹ láàrín itan méjèèjì, a si maa gbé ikùn jìnà sí wọn
A maa gbé apa méjèèjì soke kuro ni ilẹ, ti wọn yóò sì jìnà sí ẹ̀gbẹ́, lopin igba ti a ko ba ti kirun ni janmọọn, ti a ko sì paya ìnira fún àwọn tí wọn wà ní ẹgbẹ wa
A maa gbé ọwọ méjèèjì sí deede ejika tabi deede etí mejeeji
25
Subhaana Robbiyal A'laa
A maa wi gbolohun ṣiṣe afọmọ yii ni ẹẹmẹta, oun ni pípé tí ó kéré jù, ṣùgbọ́n ṣiṣe e lẹẹkan ṣoṣo naa to. A si le fi kun un ti o ba wu wa, a si ma maa ṣe àwọn gbólóhùn afọmọ orisirisi tí wọ́n gba wa wọnú ara wọn ki o ma jẹ pe oríṣi kan péré ni a ma maa ṣe ni gbogbo ìgbà, a sì maa tọrọ ohun ti a ba fẹ ninu oore ayé àti ìkẹhìn.
26
Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Igba ti ẹrú máa n sunmọ Olúwa rẹ jùlọ ní ìgbà tí o bá wa ni ìforíkanlẹ̀, ki ẹ pọ ni adua níbẹ̀.
M
Allaahu Ak'bar
A maa gbé ori wa soke lati iforikanlẹ lẹniti n gbe Ọlọhun tóbi
A maa tẹ ẹsẹ alaafia silẹ, a si maa jókòó le e lórí pèlú ifọkanbalẹ, a sì maa gbé ẹsẹ ọtun sókè, a maa waa dojú awọn ọmọnika ẹsẹ kọ kiblah
tabi
A maa gbé ẹsẹ mejeeji sókè, a sì maa jókòó lori gìgísẹ̀ méjèèjì
A maa tẹ apá wa méjèèjì; ọtun lórí itan ọtun, àlàáfíà lórí itan àlàáfíà, níbi orunkun tabi lori orunkun.
28
Robbig-fir'lii
A maa ṣe adua yìí laarin ìforíkanlẹ̀ méjèèjì, laaye ibi ti a ba ti jókòó lẹniti o fi ara balẹ..
29
Allaahu Ak'bar
A maa lọ si ilẹ láti fi orí kanlẹ lẹẹkeji lẹnití yóò máa sọ gbólóhùn "Allahu akbar", ṣíṣe rẹ dà gẹgẹ bí ti ìforíkanlẹ̀ akọkọ ni ọ̀nà ti a maa gbà ṣe e ati níbi nǹkan tí a maa sọ nibẹ.
30
Allaahu Ak'bar
A maa mú rakaa ẹlẹẹkeji wa gẹgẹ bí a ṣe mu alakọkọọ wa
Gbigbe ọwọ méjèèjì lori ara wọn, kika Suuratul-Faatiha, ati aaya kan tabi awọn aaya ninu Kuraani.
Lẹ́yìn náà, a maa rùkúù
Allaahu Ak'bar
A sì maa dide
Samihal-Loohu liman hamidah
"Lẹyin naa a maa lọ si iforikanlẹ. "
Allaahu Ak'bar
A maa forikanlẹ lẹẹmeji, leyin naa a maa jókòó fun ataaya ... "
Allaahu Ak'bar
Allaahu Ak'bar
Allaahu Ak'bar
31
Lẹyin igba ti a ti pari rakaa ẹlẹẹkeji ti ijoko naa a jẹ ti ataaya, a maa jókòó ni ìjókòó iftirọọṣ (jíjókòó lori ẹsẹ osi pẹlu ninaro ẹsẹ otun)..
32
Ìjókòó iftirọọṣ maa waye nibi ataaya irun oni òpó meji; gẹgẹ bii irun asunbaa, ati jimọọn, ati ti yidi mejeeji, gẹgẹ bi o se maa waye nibi ataaya alakọkọọ nibi irun olopoo mẹta ati mẹrin, ati nibi ìjókòó laarin iforikanlẹ mejeeji... "
33
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun ẹniti ko ba ni ikapa lati jokoo iftirọọṣ látàrí titobi ara rẹ, tabi látàrí ìnira nibi ẹsẹ rẹ mejeeji, tabi nkan to yatọ si iyẹn, ko burú lati jókòó pẹlu eyikeyi ọna ti o ba ni ikapa rẹ.."
34
Nibi ataaya, a maa gbe ọwọ ọtun lori itan ọtun pẹlu kika gbogbo ọmọnika patapata kò, ayafi ika ilabẹ, a maa wa na ika naa.. "
35
Tabi ki a ṣe atanpako ati ika aarin ni róbótó, a maa waa na ìka ilabẹ.
36
Ṣugbọn ọwọ osi, ninu ki a tẹ ẹ lori itan osi, tabi ki a ka a lori orunkun. "
A fẹ ki a maa wo ìka ilabẹ ọwọ ọtun nibi ataaya
37
"At-Tahiyyātu lillāh was-sọlawātu wat-tọyyibātu, as salāmu ‘alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmọtullāh wa barakaatuhu, as salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis sọọlihīna, ’ashadu ’an lā ilāha illallāh, wa ’ashadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu".
A maa ka ataaya alakọkọọ nìkan ti o ba ṣe pe irun olopoo mẹta tabi olopoo mẹrin ni a n ki. "
Sugbọn ti o ba se pe irun olopo meji ni gẹgẹ bi irun asunba, tabi irun ọjọ jimọh tabi irun yidi mejeeji, a maa ka ataaya naa ni pipe, pẹlu kika asalaatu ti anọbi Ibrọheem.. "
Allaahummọ sọlli alaa Muhammadin wa alaa aali Muhammadin, kamaa sọllaeta alaa Ibrọọhiima wa alaa aali Ibrọọhiima innaka Hamiidun Majiid. Allaahummọ baarik alaa Muhammadin wa alaa aali Muhammadin, kamaa baarọk'ta alaa Ibrọọhiima wa alaa aali Ibrọọhiima, innaka Hamiidun Majiid.
38
As-salaamu alaykum warahmatullọọh
As-salaamu alaykum warahmatullọọh
Salamọ maa wa lẹyin ti a ba pari ataaya ati lẹyin kika awọn adua ti o wa ninu sunna ti ojiṣẹ Allahu.. ṣùgbọ́n eleyii a ri bẹẹ nibi irun olopoo meji.. "
39
A maa gbọ gbolohun "Allahu Akbar" fẹẹrẹfẹ"
Ṣùgbọ́n ti o ba ṣe pe irun olopoo mẹta ni gẹgẹ bii irun Magrib, tabi o jẹ irun olopoo mẹ́rin gẹgẹ bii irun Aila tabi Alaasari tabi Ishai. "
40
Ati pe a maa dide lẹyin ataaya alakọkọọ lati ki rakaa kan sii ti o ba ṣe pe irun Magrib ni a n ki, tabi lati ki rakaa meji sii ti o ba ṣe pe irun Aila tabi Alaasari, tabi Ishai ni a n ki, a maa ka faatiha nibẹ, pẹlu ṣíṣe gbogbo alaye ti a sọ ṣíwájú nibi rukuu, ati iforikanlẹ, ati dídìde ati ìjókòó..
41
Allaahu Ak'bar
42
Ojiṣẹ Allahu (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) maa n jókòó ni eniti o maa fi ìbàdí rẹ jókòó nibi ataaya ikẹyin nibi gbogbo irun ti o ni ataaya meji.. "
43
Fifi ibadi jókòó maa n waye nibi ataaya ikẹyin nikan nibi gbogbo irun olopoo mẹta tabi mẹrin, ọ̀nà ti a si maa n gba jó irú ìjókòó yìí ju ẹyọkan lọ.. "
44
ki okunrin tẹ ẹsẹ osi kalẹ ki o de ka otun soke,ki o si yọ mejeeji jade si ẹgbẹ otun, ki o si fi idi rẹ mẹjeeji le ilẹ.. "
tabi
Titẹ ẹsẹ mejeeji silẹ papọ, ki o si yọ mejeeji jade si ẹgbẹ otun. "
tabi
ki okunrin tẹ ẹsẹ otun sile , ki o wa ti ẹsẹ osi bọ inu itan ati orokun ọtun. "
45
A maa ka ataaya nibi ìjókòó ataaya ikẹyin, lẹyin naa a maa fi asalaatu fun Anọ̀bi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) tẹle e..
46
ki a to salamọ ati lẹyin pipari ataaya, a maa wa iṣọra lọdọ Allāhu kuro nibi nnkan mẹrin kan: Kuro nibi iya jahannamọ, ati kuro nibi iya inu sàréè, ati kuro nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati kuro nibi aburu fitina Maseehu Dajjaal.. "
A maa bèrè nnkan ti a ba fẹ ninu oore aye ati ọjọ ikẹyin.."
47
As-salaamu alaykum warahmatullooh
As-salaamu alaykum warahmatullooh
Pipari irun ko le waye ati ibọra kuro ninu rẹ àyàfi pẹlu salamọ.."
48
Pẹlu salamọ ni a fi maa di ẹni tí o ti pari irun.."
Astagfirullooh.. Astagfirullooh.. Astagfirullooh
49
"Ninu sunna fun eniti o n kirun ni ki o wa aforijin lọdọ Allahu lẹẹmẹta ti o ba ti salamọ, lẹyin naa yoo ṣe iranti Allahu ti mimọ n bẹ fun ti ọla Rẹ si ga, pẹlu nkan ti o wa ninu iranti lati ọdọ ojiṣẹ Allahu (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)...
M
Nkan ti a kọ si oju agbaworantan.."
1
Imaamu ni o jẹ ni tabi eniti o n da irun ki.. "
2
kabara ti iwọ inu irun..."
3
A maa gbe ọwọ mejeeji si deede ejika mejeeji.."
4
Tabi ki a gbe e si deede eti mejeeji pẹlu ọna yẹn gangan.."
5
A maa gbe ọwọ mejeeji le ori àyà... "
6
Tabi ki a gbe e soke idodo.."
7
Tabi ki a gbe e si abẹ idodo.."
8
Ọwọ ọtun wa, a maa gbe e lori ẹyin atẹlẹwọ ọwọ osi..."
9
Tabi ki a fi ọwọ ọtun di apa osi mú.."
10
Adura ìṣírun.."
11
Allaahummọ baa'id baynii wa bayna khatọọyaaya kamaa baa'had'ta baynal mash'riki wal magrib, Allaahummọ nakkinii min khatọọyaaya kamaa yunakkọs-saobul ab'yadu minad-danas, Allaahummọ ig'sil'nii min khatọọyaaya bis-sal'ji wal maa'hi wal barọdi. Muslim ni o gba a wa.
12
Ati pe o wa ninu sunna lati maa ṣe e wọnú ará wọn, ki o ma jẹ pe oríṣi kan péré ni èèyàn ma maa ṣe ni gbogbo ìgbà.
13
Iwaṣọra lọdọ Ọlọhun kuro lọwọ eṣu
14
Auuzu bil-Laahi mina Shaetọọnir-rọjiim
15
"Al-Faatihah"
16
( Alhamdulillahi Rabbil ‘aalameen, Ar-Rahmaanir-Raheem, Maaliki Yawmi-Deen, Iyyaaka na’budu wa iyyaka nastaeenu, Ihdinas Siraatal Mustaqeema, Siraatal lazeena an’amta ‘alaihim ghayril maghduubi ‘alaihim wa lad daaalleena ) "
17
Aamiin
18
Adua ni ti itumọ rẹ jẹ: Iwọ Ọlọhun, gba a .."
19
A maa ka eyi ti o ba rọrun ninu Kuraani.. "
20
Rukuu
21
Allahu akbar "
22
Ẹyin maa tẹ́ pẹrẹsẹ laini tẹ̀. "
23
Subhaana Rọbbiyal Aziim
24
Ninu awọn azkaar ti a maa n ka ni rukuu ti ẹri wa fun .. "
25
Subbuuhun kudduusun, Rọbbul malaaikati war-ruuh.. "
26
Subhaanaka Rọbbanaa wa bihamdika, Allaahummọ igfir lii.. "
M
Samihal-Lọọhu liman hamidah"
28
Rọbbanaa wa lakal hamdu, hamdan kasiirọn toyyiban mubaarọkan fiihi "
29
A maa da ọwọ wa silẹ "
30
tabi ki a ka a mọ àyà .. "
31
Iforikanlẹ
32
Iwaju ori pẹlu imu
33
Atẹlẹwọ mejeeji
34
Orunkun mejeeji
35
ati ẹsẹ mejeeji
36
Subhaana Rọbbiyal Ah'laa... "
37
Asiko ti ẹru o maa sunmọ Olúwa rẹ julọ ni igba to ba wa ni iforikanlẹ, nítorí náà ẹ pọ ni adua nibẹ… Muslim ni o gba a wa "
38
Ìjókòó if'tirọọṣ... "
39
Ìjókòó ik'haa'u.. "
40
Rọbbi igfir lii (lẹẹmẹta ) "
41
Allaahummọ igfir lii, war'ham'nii, waj'bur'nii, wah'dinii, warzuknii... "
42
Asunbaa
43
"Irun jimọọn
44
Irun yidi mejeeji
45
Àílà
46
Alaasari
47
Magribi
48
Ishai
49
"At-Tahiyyātu lillāh was-sọlawātu wat-tọyyibātu, as salāmu ‘alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmọtullāh wa barakaatuhu, as salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis sọọlihīna, ’ashadu ’an lā ilāha illallāh, wa ’ashadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu".
50
Allaahummọ sọlli alaa Muhammadin wa alaa aali Muhammadin, kamaa sọllaeta alaa Ibrọọhiima wa alaa aali Ibrọọhiima innaka Hamiidun Majiid. Allaahummọ baarik alaa Muhammadin wa alaa aali Muhammadin, kamaa baarọk'ta alaa Ibrọọhiima wa alaa aali Ibrọọhiima, innaka Hamiidun Majiid.
51
Dhu'r - Asr' - Maghreb- Isha'
52
Subh' - Jum'uah - Eid mejeeji..
53
Allaahummọ sọlli alaa Muhammadin wa alaa aali Muhammadin, kamaa sọllaeta alaa Ibrọọhiima wa alaa aali Ibrọọhiima innaka Hamiidun Majiid. Allaahummọ baarik alaa Muhammadin wa alaa aali Muhammadin, kamaa baarọk'ta alaa Ibrọọhiima wa alaa aali Ibrọọhiima, innaka Hamiidun Majiid.
54
As-salaamu alaykum warahmatullooh
55
Ti o ba jokoo ni rakaa igbẹyin, yoo ti ẹsẹ osi rẹ ṣíwájú, yoo waa gbe ikeji rẹ sókè, yoo waa fi ìdí rẹ jokoo. Bukhaari ni o gba a wa.
56
Ìjókòó tawarruk
57
Allaahummọ innii auuzu bika min azaabi jahannam, wa min azaabil kọbri, wa min fitnatil mah'yaa wal mamaat, wa min sharri fitnatil masiihid-dajjaal. Muslim ni o gba a wa.
58
Allaahummọ innii zọlam'tu nafsii zulman kasiiran, walaa yagfiruz-zunuuba illaa anta, fagfir lii magfiratan min in'dika war'ham'nii, innaka antal-Gọfuurur-Rọhiim. Bukhari ni o gba a wa.
59
Astagfirullọọh (lẹẹmẹta)
60
Hadiisi yii wa lati ọdọ Abu Hurayrah (Ki Ọlọhun ba wa yọnu si i) o sọ pe: Mo gbọ ojiṣẹ Ọlọhun (Ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ti o n sọ pe: Ohun àkọ́kọ́ ti wọn o kọkọ ṣe iṣiro iṣẹ ẹru le lori ni ọjọ igbende ninu iṣẹ rẹ naa ni irun rẹ; ti o ba dara, o ti jere o si ti la, ti ko ba si dara, o ti pòfo, o si ti ṣòfò. Abu Dăwud, Tirmidhi ati Nasaa'i lo gba a wa.