Ìwádìí àti ise Àlàyé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn koko ọrọ nípa Hajj àti Umrah àti Ìṣàbẹ̀wò nibamu sí Al-Qur'an àti Sunnah.
Tírà náà nṣe àlàyé àwọn idajọ Hajj àti Umrah àti Iṣabẹwo ní ìbámu pẹ̀lú Tírà (Al-Qur'an) àti Sunnah, ó sì nṣe àlàyé àwọn ohun tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn nínú Hajj àti Umrah, àwọn ohun èèwọ̀ lásìkò Ihram, àti àwọn ẹkọ ṣíṣe àbẹ̀wò sí Mọsalasi Anọbi, tí ó sì nṣe ikìlọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àdadáalẹ nínú àwọn ìlànà ìjọsìn wọ̀nyí.
This PDF is generated automatically from the book's text; its layout may differ from the printed edition.
Ìwádìí àti Àlàyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ibeere Hajj àti Umrah àti Iṣabẹwo nibamu sí Tírà (Al-Qur'an àti Sunnah)
Ti alufaa àgbà Shaikh Ọlọpọlọpọ mimọ kọ
Abdul Azeez ọmọ Abdullah ọmọ Bāz
Ọrọ itisiwaju lati ọdọ olukọwe
Pẹlu orukọ Ọlọhun Ọba Ajọkẹ ayé Àṣàkẹ́ ọrun.
Gbogbo iyin ti Ọlọhun ni, Ọba gbogbo agbaye, igbẹyin daadaa n bẹ fun awọn olupaya Ọlọhun, ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ ki o maa ba ẹru Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ Muhammad, ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ lapapọ.
Lẹyìn naa
Eleyi ni àkójọ ọrọ ní ṣókí nípa iṣẹ́ ìjọsìn Hajj àti àlàyé ọlá tí nbẹ fún-un àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, àti ohun tí ó yẹ fún ẹni tí ó fẹ́ rin ìrìn-àjò láti lọ ṣe é, àti àlàyé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ pàtàkì nínú àwọn ọ̀rọ̀ Hajj, Umrah àti ṣíṣe àbẹ̀wò ní ọ̀nà ṣókí àti àlàyé tó hàn kedere, mo ti ṣèwádìí dáadáa nínú rẹ̀ lórí ohun tí Tira Ọlọ́hun àti Sunnah Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a - tọ́ka sí, mo ṣàá jọ gẹ́gẹ́ bí ìgbaniníyànjú fún àwọn Musulumi, àti láti fi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ọlá Rẹ ga jùlọ: Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. [Suuratudh Dhāriyāt: 55], ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe: (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn àwọn tí A fún ní tírà pé ẹ gbọ́dọ̀ ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn, ẹ ò sì gbọdọ̀ fi pamọ́... [Āli ‘Imrān: 187]. Aayah, àti Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: «Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu.» [Al-Maa'ida: 2].
Àti nítorí ohun tó wà nínú Hadiisi tí ó ní àlàáfíà lati ọdọ Anọbi - kí ikẹ àti ọlá Ọlọhun máa bá a - pé dájúdájú ó sọ pé: « Ikìlọ̀ àti sise mimọ ni ẹṣin jẹ, lẹ́ẹmẹ́ta, wọ́n sọ pé: fún ta ni, ìwọ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun? Ó sọ pé: Fún Ọlọ́hun, àti fún Tírà Rẹ̀, àti fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti fún àwọn aṣáájú àwọn Mùsùlùmí àti àpapọ̀ wọn» [1]. [1] Muslim lo gba wa pẹlu onka (55).
At-Tọbarọni gba ẹgbawa lati ọdọ Huzaifah pe dajudaju Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: «Ẹnikẹni tí ọ̀rọ̀ àwọn Musulumi kò jẹ lógún, kò sí nínú wọn, àti ẹni tí kò bá jẹ́ olùṣe-nàsíà mimọ ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ fún Ọlọhun, àti fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti fún Tírà Rẹ̀, àti fún adarí rẹ̀, àti fún gbogbo àwọn apapọ Musulumi, kò sí nínú wọn» [2]. [2] At-Tobaraani lo gba wa nínú tira Al-Aosat, pẹlu onka (7469).
Ọlọhun ni a n bẹ kí O fi ṣe èmi àti àwọn Musulumi ní àǹfààní, kí O sì jẹ́ kí àkìtìyan lórí rẹ̀ jẹ́ nítorí ojú rere Rẹ̀ Àpọ́nlé nìkan, àti okùnfà fún àṣeyọrí ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra. Dájúdájú Oun ni Olùgbọ́, Olùjẹ́-ìpè, Oun sì ni Ó tó wa, O sì dára jùlọ gẹ́gẹ́ bí Alafẹyin ti.
Ìpín ọrọ kan
Nípa awọn ẹri àti jíjẹ ọranyan láti ṣe ìjọsìn Hajj àti Umrah àti yíyára sí ṣíṣe wọn
Nígbàtí a bá ti mọ èyí, kí ẹ wá mọ̀ - kí Ọlọhun fi èmi àti ẹ̀yin se kongẹ àṣeyọrí mímọ láti mọ òdodo àti láti tẹ̀lé e - kí ẹ mọ pé dájúdájú Ọlọhun Ọba - tí O gbọnngbọn - ti ṣe hajj lilọ sí ilé Rẹ̀ abeewọ ni ọranyan lórí àwọn ẹrù Rẹ̀, Ó sì ṣe é ní ọ̀kan nínú àwọn orígun Islam, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, tó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá lagbaaye. [Āli ‘Imrān: 97].
Ninu Saheehu tira hadith mejeeji, lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọ́n mọ Islaam pa lórí nǹkan márùn-ún: ìjẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ìjọsìn ododo tọ́ sí àyàfi Allāhu, àti pé dájúdájú Muhammad òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, àti gbígbé irun dúró, àti yíyọ Zakah, àti gbígba ààwẹ̀ Ramadān, àti ṣíṣe Hajj ( lilọ sí) Ilé Ọlọ́run ile ọwọ» [3]. [3] Al-bukhari lo gbaa wa, pẹlu onka (8), àti Muslim pẹlu onka (16).
Sa'iid gba ẹgbawa nínu tira Súnanì rẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: ""Dájúdájú mo ti gbèrò láti rán àwọn arákùnrin kan lọ sí àwọn ìlú wọ̀nyí, kí wọ́n lọ yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ní agbára [4] tí kò sì ṣe Hajjì wò, kí wọ́n lọ gba owo orí lọwọ wọn , wọn kì í ṣe Musulumi, wọn kì í ṣe Musulumi rara [5]"." [4] Ìyẹn ni pé: igbaà laayè nínú dúkìá. [5] ọ ṣe afiti rẹ nínú tira Jāmi'ul-Ahādīth pẹ̀lú ońká (31221) pé ó wá láti inú tira Sunan Sa'īd bn Mansūr, ṣùgbọ́n èmi kò rí i nínú ẹ́dà tó wà nílẹ̀.
wọn gba ẹgbawa lati ọdọ Aliy - ki Ọlọhun yọnu si i - pe o sọ pe: "Ẹni tí ó bá ní ìkápá Hajj ṣíṣe, tí ó sì fi sílẹ̀, kò sí àléébù fún un láti kú gẹ́gẹ́ bí Yahudi ( ọmọ lẹyìn Anọbi Musa ) tàbí Nasara" ( ọmọ lẹyìn Anọbi Isa) [6]. [6] At-Tirmidhi lo gba wa, pẹlu onka (812).
Ó sì jẹ́ dandan fún ẹni tí kò ṣe Hajj tí ó sì ní ìkápá rẹ̀, kí ó yára ṣe é; nítorí ohun tí a gbàwá láti ọ̀dọ̀ ọmọ Abbas - kí Ọlọhun yọnu si i - pé Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a - sọ pé: «Ẹ yára lọ ṣe Hájì - èyí tó jẹ́ ọ̀ranyàn - nítorí pé ọ̀kankan nínú yín kò mọ ohun tí ó lè dì í lọ́wọ́ tàbí ṣẹlẹ sí » [7]. [7] Abu Daud lo gba a wa, pẹlu onka (1732).
Ati Nítorípé ṣíṣe Hajj jẹ́ ọ̀ranyàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ( ni kiakia ) fún ẹni tí ó lágbára ọ̀nà sí i; nítorí ohun tí ó hàn nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga pé: « Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, fún ẹni to lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá Lagbaye . [Āli 'Imrān: 97]. ati ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tí o sọ nibi khutuba rẹ pe: «Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Ọlọhun ti ṣe Hajj ní dandan fún yín, ẹ ṣe Hajj.» [8]. [8] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1337).
Àwọn Hadiisi ti wá tí ó ń tọ́ka sí ọranyan Umrah, nínú rẹ ni:
Ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - nígbà tí ó ń dá Jibril lóhùn nígbà tí o bi í nípa Islam, ó sọ pé: «Islaam ni kí o jẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ìjọsìn ododo tọ́ sí àyàfi Allāhu, àti pé dájúdájú Muhammad òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, kí o máa gbé irun dúró, kí o máa yọ Zakah, kí o ṣe Hajj sí Ilé Ọlọ́run kí o sì ṣe 'Umrah, kí o máa wẹ̀ janābah, kí o máa pé alùwàláà, kí o sì máa gba ààwẹ̀ Ramadān» [9] Ọmọ Khuzaima ati Ad-Daaraqutni lo muu jáde lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i-, Ad-Daaraqutni sọ pe: eleyii ni ẹgbawa to fẹsẹmulẹ, to lalaafia. [9] Ọmo Khuzaimah lo gbaa wa, pẹlu onka (1).
Lára rẹ̀ ni: hadith Aishah - ki Ọlọhun yọnu si i - tí ó sọ pé: «Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, Ṣe jijagun jẹ ọranyan fún àwọn obìnrin ni? O sọ pe: « Igbiyanju si ojú ọnà Ọlọhun wa fun wọn tí kò ní jijagun ninu rẹ: ogun naa ni Hajj ati Umrah» [10] Ahmad ati ọmọ Maajah lo gba a wa pẹlu afiti ti o ni alaafia. [10] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1520).
Hajj ati Umrah kò jẹ́ dandan ninu isẹmi ènìyàn ju ẹẹkan ṣoṣo lọ; nitori ọrọ ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ ninu Hadith tó lálàáfíà pé: «ẹẹkan ṣoṣo ni ko se iṣẹ Hajj, ẹni ti o ba lekun jù ẹyọkan lọ aṣegbọrẹ ni yoo jẹ » [11]. [11] An-Nasa'i lo gba wa, pẹlu onka (2620).
Ọ wá nínú súnà pe kí a ṣe Hajj àti Umrah ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní aṣegbọrẹ; nítorí ohun tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú àwọn ìwé Saheeh méjèèjì, láti ọ̀dọ̀ Abū Hurayrah - kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i - pé, Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "«Umrah sí Umrah máa n pa àwọn ẹṣẹ tí ó wà láàrin méjèèjì rẹ́ ni, Hajj tí ènìyàn bá sì ṣe dáadáa kò sí ẹ̀san kankan fún un àyàfi Alujannah (ọgbà ìdẹ̀ra)» [12]." [12] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1773), àti Muslim, pẹlu onka (1349).
Ori-iwe
Nípa pé títúúbá ( isẹri kúrò níbi ẹsẹ ) jẹ dandan àti jíjáde kúrò níbi àwọn ise abosi
Tí Musulumi bá pinnu láti rin ìrìnàjò lọ sí Hajj tàbí Umrah: a fẹ́ fún un kí ó sọ aṣọlẹ ìbẹrù Ọlọhun - tí Ọ gbangban - kalẹ fún àwọn ará ilé rẹ̀, àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èyí tí í ṣe mímú àwọn àṣẹ Ọlọhun ṣẹ, àti jíjìnnà sí àwọn eewọ Rẹ̀.
Ó yẹ kí ó kọ ohun tí ó ní sílẹ̀, àti ohun tí ó jẹ ní gbèsè, kí ó sì pe ẹlẹ́rìí sí i, ó sì jẹ dandan fún un láti yára ṣe ìrònúpìwàdà àtọkànwá níbi gbogbo ẹsẹ; nitori pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: «Kí gbogbo yín sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ẹ lè jèrè». [suratul Nuur: 31].
Bí ìrònú piwada se ri gẹlẹ nipe : Jijawọ kuro nibi awọn ẹṣẹ ati gbigbe wọn ju silẹ, ati kika abamọ lori ohun ti o ti kọja ninu wọn, ati ìpinnu lati ma pada si ibẹ mọ. Tí ó bá sì jẹ́ pé ó ní àwọn àbòsí kan fún àwọn èèyàn nípa ẹ̀mí, tàbí dúkìá, tàbí ọmọlúwàbí, kí ó dá wọn padà fún wọn, tàbí kí ó bọ́ kúrò lọ́wọ́ wọn lórí rẹ̀ kí ó tó rìn ìrìn-àjò rẹ̀; nítorí ohun tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a - pé ó sọ pé: «Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàbòsí sí ọmọ-ìyá rẹ̀ lórí ọrọ̀ tàbí ọlá, kí ó yáá wá ìtúsílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí, kí ó tó di ọjọ́ tí kò ní sí dínárì tàbí dírámì mọ́. Bí ó bá ní iṣẹ́ rere, a óò gba nínú rẹ̀ ní ìwọ̀n bí àbòsí rẹ̀ ṣe tó, bí kò bá sì ní iṣẹ́ rere kankan, a óò gba nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tí ó ṣàbòsí sí, a óò wá gbé e ka lórí» [13]. [13] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (2449).
O yẹ kí ó ṣẹṣa yan owó tí ó mọ́ láti inú owó halaali (tí o lẹtọ) fún Hajj àti Umrah rẹ̀; nítorí ohun tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a - pé: «Dajudaju Ọlọhun Ọba Aleke-Ọla Ọba tí o mọ ni, ko si ni gba nkankan ayafi nkan ti o mo.» [14]. [14] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1015).
At-Tabarani gba ẹgbẹwa lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa bá a - sọ pé: «Bí ọkùnrin kan bá jáde lọ sí irinajo Hajji pẹ̀lú ináwó tó mọ, tí ó sì gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú nnkan gun rẹ, tí ó wá ké pe: 'Mo jẹ́ pè Rẹ Ọlọhun, mo jẹ́ pè Rẹ', olùpè kan láti sánmọ̀ yóò ké sí i pé: 'A gbà pè rẹ, a sì wà pẹ̀lú rẹ fún oore, ipese rẹ jẹ́ ẹ̀tọ́, nkan ìgùn rẹ jẹ́ ẹ̀tọ́, Hajji rẹ sì jẹ́ atẹ́wọ́gbà láìní ẹ̀ṣẹ̀'. Bí ọkùnrin kan bá sì jáde pẹ̀lú ináwó tí o jẹ ti eewọ, tí ó sì gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú nnkan gun rẹ, tí ó wá ké pe: 'Mo jẹ́ pè Rẹ Ọlọhun, mo jẹ́ pè Rẹ', olùpè kan láti sánmọ̀ yóò ké sí i pé: 'A kò gbà ipè rẹ, a kò sì wà pẹ̀lú rẹ fún oore, ipese rẹ jẹ́ èèwọ̀, ináwó rẹ jẹ́ èèwọ̀, Hajji rẹ kò sì jẹ́ atẹ́wọ́gbà» [15]. [15] At-Tobaraani lo gba wa nínú tira Al-Kabir, pẹlu onka (2989).
Ó sì yẹ fún ẹni tí nṣe ìjọsìn Hajj kí ó rọrọ̀ kuro lọ́dọ̀ àwọn èèyàn àti kí ó jìnà sí bibeere lọ́wọ́ wọn; gẹ́gẹ́ bí Anọbi ṣe sọ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ko ra rẹ nijanu wá, Allāhu yóò fún un ní itẹlọrun, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá irọrọ , Allāhu yóò rọọ lọrọn” [16]. [16] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1427), àti Muslim, pẹlu onka (1035).
ati ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí o sọ pe: «Arakunrin kan ko nii yé maa tọrọ lọwọ awọn eniyan titi ti yoo fi wa ni ọjọ igbende tí kò níí sí ègé ẹran ara kan ni oju rẹ » [17]. [17] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1474), àti Muslim, pẹlu onka (4040).
O jẹ ọranyan fún Alálaàji kí o fi Hajj àti Umrah rẹ̀ gbèrò ojurere Ọlọhun àti Ilé ìkẹhìn, àti láti fi sunmọ Ọlọhun pẹ̀lú ohun tí ó bá yọ́nú sí nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti iṣẹ́ ní àwọn ibi ọlọ́lá wọ̀nyẹn, kí o si ṣọra pátápátá níbi pé kí o fi Hajj rẹ̀ gbèrò ayé àti igbadun aiye, tàbí sekarimi, okiki, àti iṣe iyanran pẹ̀lú rẹ̀, nítorípé èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èrò-inú tí ó burú jùlọ àti òkùnfà bibajẹ iṣẹ àti àìní gbà wọlé lọdọ Ọlọhun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun tí Ọlá Rẹ ga ṣe sọ pé: « Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san asanpe lórí iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé. «Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún wọn mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé ṣe yóò sì bàjẹ́. Asan sì ni ohun tí wọ́n ti ṣe níṣẹ́ síwájú». [Huud:15 - 16].
Ọlọhun tí Ọlá Rẹ ga tún sọ pé: «Ẹnikẹni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A o jẹ kí o wọ iná Jahanamọ ní ẹni èébú, ẹni ẹ̀kọ̀, eni itiju » «Ẹnìkẹni tí ó fẹ́ àkhirah (ọrun) tí ó sì sapá fún un (tí o ṣiṣẹ rẹ) pẹ̀lú ìgbàgbọ́, àwọn náà ni a ó se ọ ṣeun fún iṣẹ́ wọn». [Suuratul Is’raai: 18-19].
O si tún ni àlàáfíà lati ọdọ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wipe o sọ pe: «Ọlọhun ti Ọla Rẹ̀ ga sọ pé: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní awan orogún, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan tí ó sì mú ẹlòmíràn pọ̀ mọ́ Mi nínú rẹ̀, Èmi yóò fi òun àti iwa orogún rẹ̀ sílẹ̀» [18]. [18] Muslim lo gba wa pẹlu onka (2985).
Ó sì yẹ fún un bakannaa pé kí o ba awọn eniire rin papọ níbi ìrìn-àjò rẹ̀, lára àwọn tí wọn jẹ́ olutẹle aṣẹ Ọlọhun, àti àwọn oní ìbẹ̀rù-Ọlọ́hun, àti àwọn oní òye nínú ẹ̀sìn, kí o sì ṣọ́ra fún bíba àwọn aláìgbọ́n àti àwọn òbìlèjẹ́ rin papọ lórí Irinajo rẹ̀.
Ó yẹ fún un pé kí ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí o jẹ ìlànà ẹṣin fún un nípa ìdájọ Hajj àti Umrah rẹ̀, kí ó sì jinlẹ̀ nínú rẹ̀, kí ó sì máa bèèrè nípa ohun tí ó bá dojúrú fún un; kí ó lè wà lórí ìmọ̀ tó dájú. Nígbàtí o bá gùn nkan igùn rẹ tàbí ọkọ rẹ tàbí ọkọ ofurufu tàbí àwọn nkan rinṣẹ míran, a fẹ́ fún un pé kí o da orúkọ Ọlọhun, kí o sì yin Ín, lẹ́yìn náà kí o gbé Ọlọhun tóbi lẹ́ẹ̀mẹta, yóò wá sọ pé: Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó rọ èyí fún wa, kì í ṣe pé ani ágbára lórí rẹ̀. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí.” [Surah Az-Zukhruf: 13-14]
«Irẹ Ọlọhun, dajudaju emi nbeere lọwọ Rẹ nibi irin-ajo mi yi daada ati ìbẹrù Ọlọhun, ati ninu ise eyiti O yonu si, Ire Olohun se irin-ajo wa yi ni irorun fun wa, sun jijina rẹ mọ wa, Irẹ Olohun, Iwọ ni Aladuroti ninu irin-ajo, Iwọ si ni Arole lọdọ awon ara ile àti ẹbi, Irẹ Ọlọhun, dajudaju emi nfi Ọ wa ìsọ kuro nibi idaamudaabo irin-ajo, ati kuro nibi irisi ibanuje, ati apadabọ aburu nibi dukia ati ara ile» [19]؛ Fun lilalaafia ìyẹn lati ọdọ Anọbi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a), Muslim lo gbe e jade ninu hadiisi ọmọ Umar (ki Ọlọhun ba wa yọnu si awọn mejeeji). [19] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1342).
Kí o si pọ̀ ní ṣíṣe iranti Ọlọhun àti ìtọrọ àforíjìn àti ṣíṣe adua (kike pé Ọlọhun) mimọ Fún un àti ijirẹbẹ sí I, àti kíkà Al'qurani àti ṣíṣe irorí sí àwọn ìtumọ̀ rẹ̀ lórí irin-ajo rẹ̀, kí o si máa ki àwọn irun rẹ̀ deede ní jọmọọ, kí o si pa ahọn rẹ mọ́ nínú ọ̀rọ̀ isọkusọ pípọ̀, àti fífi ẹnu si ohun tí kò kan an, àti àpọ̀jù àwàdà ṣíṣe, kí o si tún pa ahọn rẹ mọ́ kúrò nínú irọ́ pípa àti sísọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn àti òfófó ṣíṣe àti fífi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti àwọn yòókù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ Mùsùlùmí ṣe yẹ̀yẹ́.
O dara fún un kí o máa ṣe oore fún awọn sahabe rẹ̀, kí o si dáwọ́ ìpalára rẹ̀ dúró sí wọn, kí o si máa pa wọ́n láṣẹ sí ṣíṣe daadaa, kí o si máa kọ̀ fún wọn nípa ibajẹ pẹ̀lú ọgbọ́n àti waasi rere ní bi o ba se ni agbára rẹ̀.
Ori-iwe
Nípa ohun tí ẹni tí ó ń ṣe Hajj yóò ṣe nígbàtí ó bá dé Miqaat. (Ibi tí a o tí bẹrẹ iṣẹ Hajj)
Nigbati o ba de adugbo Miqat, o yẹ ki o wẹ, ki o si lo lọfinda; nitori nnkan ti a gba wa pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - bọ aṣọ tí wọn tí ran kuro nigbati o fẹ wọ asọ ihram, o si wẹ, ati nitori nnkan ti o fi ẹsẹ rinlẹ ninu iwe Sohiihain, lati ọdọ Aisha - ki Ọlọhun yọnu si - o so pe: «Emi a maa fi lọfinda si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lara fun bibẹrẹ iṣẹ Hajj (ihram) ṣiwaju ki o to gbe harami, ati fun ipari harami rẹ siwaju ki o to tawaf (rọkirika) kaaba» [20], O si pa Aa'ishah laṣẹ nigba ti o ṣe nnkan oṣu, ti o si ti gbe arami fun Umrah pe ki o wẹ, ki o si gbe arami fun Hajj, O si pa -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - Asmau ọmọ Umays laṣẹ nigba ti o bímọ ni ààyè tí wọn npe ni Zhul Hulayfah pe ki o wẹ, ki o si de aṣọ kan mọ oju ara rẹ, ki o si gbe arami [21], eleyii fihan pe ti obinrin ba de aaye ti a ti ń gbe arami, ti o si n ṣe nnkan oṣu tabi ti ẹjẹ ìbímọ n da lara rẹ, yoo wẹ yoo si gbe arami pẹlu awọn eniyan, yoo si ṣe nnkan ti awọn alalaaji n ṣe yatọ si irọkirika ile Oluwa, gẹgẹ bi Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe pa Aisha ati Asmau laṣẹ bẹẹ. [20] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1539), àti Muslim, pẹlu onka (1189). [21] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1218).
Wọn fẹ fún ẹni ti o ba fẹ gbe harami( fún ibẹrẹ ìjọsìn ti Hajj tabi Umrah) lati bojuto irun imu rẹ, awọn èékánná rẹ, irun abẹ rẹ ati irun abiya rẹ, ki o si mu ohun ti o ba yẹ lati mu kuro, nitori ki o ma baa nilo lati mu iyẹn kuro lẹyin ti o ba ti gbe harami tan, ti o si jẹ pé eewọ ni fun un láti ṣe bẹẹ, ati nitoripe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – fi lelẹ fun awọn Musulumi lati maa bojuto awọn nnkan wọnyi ni gbogbo igba, gẹgẹ bi o ti fi ẹsẹ mulẹ ninu Sọhiihu mejeeji (tira hadith mejeeji tí oní alaafia), lati ọdọ Abu Hurayrah – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ wipe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a – sọ wipe: “Adamọ ẹsin maarun ni: dida abẹ, ati fifa irun abẹ, ati gige irun imu, ati gige eekanna, ati titu irun abiya” [22]. [22] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (5891), àti Muslim, pẹlu onka (257).
Nínú Sọhiihu Muslim, láti ọdọ Anas – kí Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: “Wọ́n fi àkókò lélẹ̀ fún wa ní ti gige tubọmu, àti gige àwọn èékánná, àti fifa irun abiya, àti fifa irun abẹ: pé kí a má ṣe fi sílẹ̀ laa Lai ge ju ogójì òru lọ” [23]. [23] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (258).
An-Nasaa'iy naa gbe e jade pẹlu gbólóhùn pé: «Òjíṣẹ́ Allāh - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a - fi àkókò lélẹ̀ fún wa» [24]، Ati Ahmad, Abu Dawood, àti Tirmidhi ni wọ́n gbé e jáde pẹ̀lú gbólóhùn ti An-Nasaa'i. Ṣùgbọ́n nípa ti orí, kò jẹ́ àṣẹ láti mú ohunkóhun kúrò lára rẹ̀ nígbà Ihrām, yálà fún àwọn ọkùnrin tàbí fún àwọn obìnrin. [24] An-Nasa'i lo gba wa, pẹlu onka (14).
Ṣùgbọ́n ní ti irungbọn, èèwọ̀ ni gige rẹ̀ tàbí mímú nkankan kúrò lára rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ dandan kí a jẹ́ kí ó pọ̀, kí a sì fi í sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú àwọn ìwé Sahiih méjèèjì, láti ọ̀dọ̀ ọmọ Umar -kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì- ó sọ pé: Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun -kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a- sọ pé: “Ẹ yapa àwọn ẹlẹbọ, ẹ dá irùngbọ̀n yín sí, kí ẹ sì ge túnbọ̀mu yín” [25]. Muslim gbe e jade ninu Sọhiihu rẹ, lati ọdọ Abu Huraiara - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa bá a - sọ pé: “Ẹ ge awọn tubọmu, ki ẹ si da awọn irungbọn si, ẹ yapa àwọn Májúùsì”. [26] [25] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (2892), àti Muslim, pẹlu onka (259). [26] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (260).
Àdánwò ti tobi ni asiko yii pẹlu yiyapa ọpọlọpọ ninu awọn eniyan kuro ninu itẹle ìlànà Anọbi yii ati gbigbe ogun ti dídá irùngbọ̀n sí , àti yiyọ́nú wọn sí fífi ara wé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn obìnrin, pàápàá jùlọ awọn ti wọn n fi ara wọn ti si imọ ati ikẹkọ, dajudaju ti Ọlọhun ni awa, ọdọ rẹ si ni a maa pada si, a si n bẹ Ọlọhun ki O fi wa mọna ati àwọn Musulumi yooku lati tẹle Sunna ati gbigbamu daada ati didirọ mọ ọn, ati ṣiṣe ipepe si i, koda kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa yàgò fún un, Ọlọhun to fun wa, Oun si ni mọndala ẹni tí a le gbarale ti o dara julọ, kò sí àgbára, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ète kan àyàfi pẹlú Ọlọhun, Ọba Giga, Atobi.
Lẹ́yìn náà, ọkùnrin yóò wọ ìró àti ìdàbora, a sì fẹ́ràn kí méjèjì jẹ́ funfun méjì tí ó mọ daada, a sì fẹ́ràn kí ó gbé harami pẹ̀lú sálúbàtà ( bata tí kò ni itilẹ ) méjì; nítorí ọ̀rọ̀ Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a - tí ọ sọ pe : «Kí ẹnikọọkan yin lo asọ iro àti idabora àti bàtà méjì fun Ibẹrẹ ìjọsìn Hajj; tí kò bá rí bàtà méjì, kí ó wọ bàtà aláwọ méjì, kí ó sì gé wọ́n títí wọn yio fi wà ní isalẹ kókósẹ méjèjì» [27] Imam Ahmad - ki Ọlọhun ba wa kẹ ẹ - ni o gbe e jade. [27] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1177).
Àmọ́ obinrin, ó tọ́ fun un kí ó gbé harami pẹ̀lú aṣọ tí ó bá wù ú, yálà dúdú ni, tàbí àwọ̀ ewéko tàbí àwọn mìíràn, pẹ̀lú ṣíṣọ́ra kúrò nínú fífi ara jọ àwọn ọkùnrin nínú aṣọ wọn, ṣùgbọ́n kò níí wọ niqab ( iboju ) àti ibọwọ méjèèjì nígbà harami rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò bo ojú rẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì pẹ̀lú nkan mìíràn yàtọ̀ sí niqab àti ibọwọ; nítorí pé Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ̀ fún obinrin tí ó wà nínú harami láti wọ niqab ( iboju ) àti ibọwọ méjèèjì. Àmọ́ dídá aṣọ alawọ ewe tabi dúdú ya sọtọ tí àwọn èèyàn kan ṣẹṣe rẹ̀ pé ohun ni aṣọ arami obinrin yàtọ sí awọ míràn kò sí ìpìlẹ kankan fún un.
Lẹ́yìn ìparí ìwẹ, mímọ́ra, àti wíwọ aṣọ Ihram, yóò daniyan ní ọkàn rẹ̀ láti wọ inú iṣẹ́ ìjọsìn tí ó fẹ́ nínú Hajj tàbí Umrah; nítorí ọ̀rọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a tí o sọ pe -: "Dajudaju gbogbo iṣẹ nbẹ pẹ̀lú àníyàn ni, o si nbẹ fun gbogbo eniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gbalero" [28]. [28] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (1), àti Muslim pẹlu onka (1907).
Ó jẹ́ ohun tí a fọwọ́ sí nínú ẹ̀sìn fún un láti fi ẹnu sọ ohun tí ó gbèrò nínú ọkàn rẹ̀ jáde, tí o ba se pé èrò rẹ̀ bá jẹ́ ti Umrah, yóò sọ pé: "Mojẹpe rẹ fún ìjọsìn Umrah" tàbí "Ọlọhun, mojẹpe rẹ fún ìjọsìn Umrah", tí ẹrọ rẹ̀ bá sì jẹ́ tí Hajj, yóò sọ pé: "Mojẹpe rẹ fún ìjọsìn Hajj" tàbí "Ọlọhun, mojẹpe rẹ fún ìjọsìn Hajj"; nítorí pé Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a- se bẹ́ẹ̀. Tí o bá sì da aniyan méjèèjì papọ̀, yóò sọ gbólóhùn ìjẹ́pe báyìí pé: "Ọlọhun, mojẹpe rẹ fún ìjọsìn Umrah àti Hajj". Ohun tí o dára jùlọ ni pé kí sísọ ọ̀rọ̀ yí wáyé lẹ́yìn tí ó ti gun ohun ìgùn rẹ̀ dáadáa, yálà ó jẹ́ ẹranko tàbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí nǹkan mìíràn; nítorí pé Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a- kò bẹ̀rẹ̀ síí sọ gbólóhùn ìjẹ́pe rẹ̀ àfi lẹ́yìn ìgbà tí ó gun Rakunmi tàbí nkán ìgùn rẹ̀ dáadáa, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò pẹ̀lú rẹ̀ láti ibi ààlà (Miqat) fún ìgbéra. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí o fẹsẹ̀ múlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn.
Kò sí nínú ilana ofin ẹsin fún un láti wi aníyàn jáde afi nígbà gbigbe Ihrọọmu fun ibẹrẹ ìjọsìn Hajj tabi Umrah nìkan, fún wíwá rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ànábì -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.
Sugbọn ní ti Irun àti Tawaaf àti àwọn iṣẹ́ ìjọsìn mìíràn, kò yẹ kí ó fi ẹnu sọ aniyan nínú ìkankan nínú wọn, kò gbọdọ sọ pé: mo da aniyan láti kirun báyìí báyìí, tàbí mo da aniyan láti ṣe tawaaf báyìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, fífẹnu sọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn adadaalẹ tí a dá sílẹ̀, sísọ ọ́ sókè sì burú jù, ó sì le ní ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ jùlọ. Tí ó bá jẹ́ pé fífẹnu sọ aniyan jẹ́ ohun tí a pa láṣẹ ni, Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ìbá ti ṣàlàyé rẹ̀, tí yóò sì fi yé ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn àṣíwájú rere ìbá sì ti ṣíwájú nínú rẹ̀.
sugbọn nígbà tí wọn kò gba iyẹn wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, tabi lati ọdọ awọn Sahabe rẹ - ki Ọlọhun yọnu si wọn -, a mọ̀ daju pé adadaalẹ ni, ati pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti sọ pe: "Eyí tí ó burú jù nínú àwọn àlámọ̀rí náà ni àwọn adadaalẹ rẹ, gbogbo adadaalẹ si nìyí anu ni" [29] Muslim ni o gbe e jade ninu sohiihu rẹ, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: «Ẹnikẹni ti o ba da adadaalẹ kan sinu alamọri wa yii ninu nnkan ti ko si nibẹ, a o da pada ni» [30] Ohun ti wọn fẹnu ko lori nini alaafia rẹ ni, Ninu gbolohun tabi ẹgbawa ti Muslim: "Ẹnikeni tí o ba ṣe iṣẹ kan ti ko si àṣẹ wa lori rẹ, yio di ohun idapada ." [31] [29] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (867). [30] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (2697), àti Muslim pẹlu onka (1718). [31] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (2550), àti Muslim, pẹlu onka (1718).
Àwọn ààyè fún ìgbé-áràmí àti adá yanrí wọn:
Àwọn ààyè ibẹrẹ ìjọsìn márùn-ún ni:
Èkíní: zul-hulayfah, òun ni ààyè igbe arami fún àwọn ará ìlú mẹdina, èyí tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí lónìí ni: abyaaru aliyy.
Èkejì: Al-juhfah, òun ni meeqaat àwọn ará ìlú Sham, òun sì ni abúlé ahoro kan tí ó tẹ̀lé robigu, àwọn ènìyàn lónìí sì máa ń gbé harami láti robigu, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé harami láti robigu, dájúdájú ó ti gbé harami láti ibi Meeqat tí o yẹ kí o ti gbe e; nítorí pé robigu wà ṣíwájú rẹ̀ díẹ̀.
Ẹkẹta: Qarnul-Manaazil, òun ni Meeqaat ààyè ibẹrẹ ìjọsìn Hajj tabi Umrah fún àwọn ará Najd, tí a sì ń pè lónìí ní: As-sayl.
Ẹlẹẹkẹrin: Yalamlam, òhun ni Ibùdó ìgbe arami àwọn ará ìlú Yemen.
Ẹlẹẹkarun: Zaatu ir'kin, òhun ni miqoti aaye ìgbé arami ti àwọn ará ìlú Iraq.
Àwọn Meeqat ( ààyè ìgbé arami) wọ̀nyí ni Anabi - kí ikẹ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - ti ṣe àdàyanrí rẹ̀ fún àwọn tí a ti mẹ́nu bà, àti fún ẹnikẹ́ni to yàtọ̀ sí wọn tí ó bá gba ibẹ kọjá, tí ó sì fẹ́ ṣe Hajj tàbí Umrah.
Ọranyan ni o jẹ́ fún ẹni tí ó bá gba awọn ààyè náà kọjá pé kí ó gbé harami láti ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò tọ́ fún un láti kọjá wọn láì gbé harami tí ó bá jẹ́ pé Makkah ni ó ń lọ láti ṣe Hajj tàbí Umrah, yálà lórí ilẹ̀ ni tàbí lójú òfuurufú; nítorí gbogbo-gbòò ọ̀rọ̀ Anabi (kí ikẹ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a) nígbàtí ó la àwọn ààyè harami wọ̀nyí kalẹ̀: "Awọn aaye yii wà fun wọn (iyẹn: awọn ara ilu), àti fún àwọn tí wọ́n bá lọ síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe ará ìlú náà, nínú àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe Hajj àti Umrah" [32]. [32] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (1524), àti Muslim pẹlu onka (1181).
Ohun tí ó tọna fún ẹni tí ó nlọ Mẹkka nípasẹ̀ ọkọ ofurufu pẹ̀lú èrò Hajj tàbí Umrah ni pé kí ó múra sílẹ̀ fún èyí nípa wíwẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ síwájú kí ó tó wọ ọkọ ofurufu, tí o bá ti súnmọ Meeqat, ( ààyè ìgbé arami) yóò wọ ìró rẹ̀ àti aṣọ ìbora rẹ̀, lẹ́yìn náà yóò ṣe Labaika fún Umrah tí àkókò bá wà fún un, ṣùgbọ́n tí àkókò bá há, yóò ṣe Labaika fún Hajj. Tí o bá sì wọ ìró rẹ̀ àti aṣọ ìbora rẹ̀ síwájú kí ó tó wọ ọkọ ofurufu tàbí kí o tó súnmọ Meeqat, kò burú, ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ daniyan láti wọ inú iṣẹ́ ìjọsìn náà, bẹ́ẹ̀ni kò gbọdọ̀ ṣe Labaika àfi tí o bá ti wà ní ògángán Meeqat ( ààyè ìgbé arami) tàbí tí ó súnmọ ọ; nítorí pé Ànábì - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kò gbé harami àyàfi láti Meeqat, ọranyan sì ni fún àwọn ìjọ mùsùlùmí láti fi anọbi ṣe àwòkọ́ṣe - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - níbi ìjọsìn yii bíi ti àwọn ọrọ ìjọsìn mìíràn; nitori ọ̀rọ̀ Ọlọhun Mímọ́: «Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere wà fún yín lára Òjíṣẹ́ Allāhu...» [Surah Al-Ahzâb: 21]. ati ọrọ Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - ni hajj idagbere ti o sọ pe: ""Ẹ kẹkọ awọn iṣẹ Hajj yin lati ọdọ mi"" [33]. [33] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1297).
Ṣùgbọ́n ẹní tí ó bá gba Makkah lọ tí kò sì ní èrò Hajj tàbí Umrah; gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò, agbẹ́gilódó, oníṣẹ́ ifi iwe-ránṣẹ́ àti irú wọn, kò jẹ́ ọranyan fún wọn láti gbé harami, àfi bí ó bá wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí ọ̀rọ̀ Ànábì - kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a - nínú hadith tí ó ṣáájú, nígbàtí ó mẹ́nu kan àwọn ààyè harami: ""Awọn aaye yii wà fun wọn (iyẹn: awọn ara ilu), àti fun àwọn tí wọ́n bá lọ síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe ara ìlú náà, nínú àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe Hajj àti Umrah" [34]," Ìtumọ̀ àti agbọye èyí ni pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àwọn ààyè harami kọjá tí kò sì ní èrò láti ṣe Hajj tàbí Umrah, kii se dandan kí o gbé arami. [34] Gbigbe jade rẹ̀ ti ṣíwájú.
Èyí sì jẹ́ ara ikẹ tí Ọlọhun ṣe fún àwọn ẹrú rẹ̀, àti ṣíṣe nǹkan ni ìrọ̀rùn fún wọn, ọpẹ́ àti ìdúpẹ́ sì jẹ́ tirẹ̀ lórí ìyẹn. Ohun tí ó sì fi ìdí èyí múlẹ̀ ni pé, Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nígbàtí ó dé Mẹkkah ní ọdún íwọ ilu Makkah padà , kò wọ aṣọ arami , ṣùgbọ́n ó wọ inú rẹ̀ tí akọtì sì wà lórí rẹ̀; nítorí pé kò gbèrò láti ṣe iṣẹ́ Hajj tàbí iṣẹ́ ‘Umrah nígbà náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ó gbèrò ni láti wọ ilu Makkah padà àti láti mú ìbọ̀rìṣà tí o wa nínú rẹ kuro.
Ní ti ẹni tí ibùgbé rẹ̀ kò de àwọn ààyè harami; gẹ́gẹ́ bí àwọn olùgbé Jeddah, àti Ummus-Salam, àti Bahrah, àti Ash-Sharaa'i, àti Badr, àti Mastoorah àti àwọn irú wọn, kò pọn dandan fún un láti lọ sí èyíkéyìí nínú àwọn ààyè harami máàrún tí a ti mẹ́nu bà ṣáájú, kàkà bẹ́ẹ̀, ibùgbé rẹ̀ ni ààyè gbígbé harami rẹ̀, yóò sì gbé harami láti ibẹ̀ fún èyíkéyìí tí ó bá fẹ́ nínú Hajj tàbí Umrah. Bí ó bá sì ní ibùgbé mìíràn ní ìta ààyè harami, ó ní ààyè láti yàn, bí ó bá fẹ́, ó lè gbé harami láti ààyè harami, bí ó sì tún fẹ́, ó lè gbé harami láti ibùgbé rẹ̀ tí ó súnmọ́ Makkah ju ààyè harami lọ; nítorí gbogbo-gbòò ọ̀rọ̀ Anọbi - kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọla Rẹ̀ máa bá a - nínú hadith ọmọ 'Abbas - kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i - nígbà tí ó mẹ́nu ba àwọn ààyè harami, ó sọ pé: "«Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà níbi tí kò de àwọn ààyè wọ̀nyí, ibùgbé rẹ̀ ni yóò ti gbé harami, bákan náà ni títí dé àwọn ara Mẹka, wọ́n yóò gbé harami láti Mẹka» [36]" Bukhari lo mu jáde, àti Muslim. [35] Ibẹ̀rẹ̀ jíjẹ pé rẹ̀ : Itumọ rẹ ni pé : wiwi gbólóhùn Talbiyah rẹ̀ láti ibi ìgbé arami rẹ̀. [36] Apá kan nínú Hadith ti o ṣáájú.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe Umrah tí ó si wà nínú Makkah, ó di dandan fún un kí ó jáde lọ sí ìta Makkah, kí ó sì gbé harami fún Umrah níbẹ̀; nítorípé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nígbà tí Aisha - ki Ọlọhun yọnu si i - beere Umrah lọ́wọ́ rẹ̀, ó pàṣẹ fún arakunrin rẹ̀, Abdur-Rahman, kí ó mú un jáde lọ sí ìta Makkah kí ó lè gbé harami láti ibẹ̀, èyí sì fihàn wípé ẹni tí ó fẹ́ ṣe Umrah kìí gbé harami fún Umrah láti Makkah, ṣùgbọ́n láti ìta Makkah ni ó ti gbọ́dọ̀ gbé harami rẹ̀.
Hadiithi yii ya Hadiithi Ọmọ Abbaas tí ó ṣíwájú sọ́tọ̀, ó sì ń tọ́ka sí pé èrò Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pẹlu ọrọ tí o sọpe : «Títí dé àwọn ara Mẹka, wọ́n yóò gbé harami láti Makkah» [37], Òun ni gbigbe arami fún Hajj nikan, kii ṣe fún Umurah, torí pé tí ó bá jẹ́ pé gbigbe arami fún Umurah lẹtọọ láti inú Makkah ni, Anọbi ìbá yọnda fún Aisha -kí Ọlọ́hun yọnu si i- nípa ìyẹn, kò sì ní fi ṣe dandan fún un láti jáde lọ sí ilẹ̀ ita Makkah, Èyí sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó yanjú, òun sì ni ọ̀rọ̀ ogunlọ́gọ̀ àwọn onímọ̀ - kí ìkẹ́ Ọlọ́hun máa bá wọn-, òun ló sì fúnni ní akoyawọ jùlọ fún Mumini ( olugbagbọ ); torí pé nínú rẹ̀ ni ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn hadiisi méjèèjì papọ̀ wà. Ọlọ́hun ni Olù fini se kongẹ daada . [37] Ìwádìí rẹ̀ ti ṣáájú.
Ní ti ohun tí àwọn ènìyàn kan ń ṣe nípa ṣíṣe Umrah lọ́pọ̀lọpọ̀ lẹ́yìn Hajj láti Tanheem (ààyè tí ọ wa ni ita aala ibi ti ilẹ ọwọ ile Ọlọhun pari sí) tàbí Ji'raanah (ààyè tí ọ wa ni ita aala ibi ti ilẹ ọwọ ile Ọlọhun pari sí) tàbí àwọn ibòmíràn, nígbà tí ó jẹ́ pé wọ́n ti ṣe Umrah ṣáájú Hajj, kò sí ẹ̀rí kankan lórí pé ilana ofin Islam fẹ́ ẹ bẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀rí fi hàn pé ohun tí ó lọlá jù ni kí á fi í sílẹ̀; nítorí pé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - àti àwọn saabe rẹ̀ - ki Ọlọhun yọnu si wọn - wọn kò ṣe Umrah lẹ́yìn tí wọ́n parí Hajj, Ṣùgbọ́n Aisha ṣe Umrah láti Tanheem; nítorí pé kò ṣe Umrah pẹ̀lú àwọn ènìyàn nígbà tí wọ́n wọ Makkah nítorí nǹkan oṣù rẹ, ó wá tọrọ lọ́wọ́ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pé kí óun ṣe Umrah kan ní ààrọ̀pò Umrah tí ó ti gbé harami fún láti Miqat, Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sì gbà fún un. Ó sì ti ní Umrah méjì nígbà náà: Umrah tí ó wà pẹ̀lú Hajj rẹ̀, àti Umrah ẹlẹ́yọ kan yìí. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ipò bíi ti Aisha, kò sí aburu níbẹ̀ pé kí ó ṣe Umrah lẹ́yìn tí ó bá ti parí Hajj; láti fi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀rí, àti láti fún àwọn Musulumi ní ìgbà lààyè.
Kò sí iyèméjì pé kí àwọn alalaaji (Hajj) máa ṣe Umrah mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí iṣẹ́ Hajj, yàtọ̀ sí Umrah tí wọ́n fi wọ Makkah yóò jẹ inira fún gbogbo ènìyàn, ó sì le fa ìdífunfunfun púpọ̀ àti ìjàǹbá, pẹ̀lú bí ó ṣe tun lòdì sí ilana Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - àti sunnah rẹ̀, Ọlọ́hun ni Olù fini se kongẹ daada.
Ori-Akori Ọrọ
Ìdájọ́ nípa ẹni tí ó dé Miqaat ( Ààyè ibẹrẹ iṣẹ Hajj ) ní akoko tí kìí se àwọn oṣù Hajj.
Mọ̀ dájú pé ẹni tí ó bá dé Mīqāt, ìsesí méjì ni ó wà fún un:
Kí ó jẹ́ pé ó dé ibẹ̀ ní àsìkò tii kii se àwọn oṣù Hajj, gẹ́gẹ́ bí oṣù Ramadan àti Sha'ban, ohun tí ó jẹ́ Sunnah fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni pé kí ó gbé arami fún Umrah, yóò si da aniyan rẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀, tí yóò sì fi ahọ́n rẹ̀ sọ ọ́, tí yóò máa wí pé: "Mojẹpe Rẹ fún ìjọsìn Umrah" tàbí "Ọlọ́hun, mojẹpe Rẹ fún ìjọsìn Umrah", lẹ́yìn náà yóò máa wi gbólóhùn ijẹpe ti Ànábì - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a - èyí tíí ọ lọ bayi pé : Labbaikal laahummo labbaik, labbaika laa sheriika laka labbaik, innal amda, wan ni'imata, laka wal mul'k, laa sheriika lak. ( Mọ jẹ ìpe rẹ Irẹ Ọlọhun, mọ jẹ ìpe rẹ lajẹ tún jẹ, kò sí orogún fún irẹ Ọlọhun, dájú dájú gbogbo ọpẹ tirẹ ni ati idẹra àti ọlá tirẹ Ọlọhun nii se , kòsí orogún tàbí ẹnìkejì fún Ọ) [38] Yio máa sọ Talbiyah ( gbólóhùn ijẹpe) yìí púpọ̀, yio sì máa rántí Ọlọhun títí yio fi dé ilé Ọlọhun, nígbà tí ó bá sì ti dé ilé Ọlọhun yio dá Talbiyah dúró, yio yí ilé náà po ní ẹẹmeje, yio sì kí ìrun raka méjì lẹ́yìn Maqaamu. Lẹ́yìn náà, yio jáde lọ sí Safa yio sì pọṣẹṣẹ láàrin Safa àti Mariwa ní ẹẹmeje, lẹ́yìn náà yio fá irun orí rẹ tàbí kí o gẹẹ́ kúrú, pẹ̀lú èyí, umura rẹ ti parí, gbogbo nkan tí ó sì jẹ́ èèwọ̀ fún un pẹ̀lú latara gbigbe harami ti di ẹ̀tọ́ fún un. [38] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1549), àti Muslim pẹlu onka (1184).
Èkejì: ni kí ó dé ibi Meeqat nínu àwọn oṣù Hajj, àwọn osu náà ni: Shawwaal, Dhul-Qa'dah, àti ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ oṣù Dhul-Hijjah.
Iru ẹni yii ni a fun ni aṣayan laarin nkan mẹta, eyíinì ni Hajj nìkan, Umrah nìkan, àti pípa méjèèjì pọ̀; nítorí pé Anabi -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nígbàtí ó dé ibi Miiqaati ní oṣù Dhu al-Qa'dah nígbà Hajj ìdágbére, ó fún àwọn sàhábà rẹ̀ ní àṣàyàn láàrin àwọn iṣẹ́ ìjọsìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ohun tí ó jẹ́ Sunnah fún irú ẹni báyìí pẹ̀lú, tí kò bá ní ẹran ìtọrẹ pẹ̀lú rẹ̀ ni pé kí ó gbé harami fún Umrah, kí ó sì ṣe ohun tí a ti mẹ́nu kàn nípa ẹni tí ó dé Miiqaati ní àwọn oṣù tí kìí ṣe oṣù Hajj; nítorí pé Anabi -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pàṣẹ fún àwọn sàhábà rẹ̀ nígbà tí wọ́n súnmọ́ Makkah pé kí wọ́n yí harami wọn padà sí Umrah, ó sì tẹnu mọ́ ọ fún wọn ní Makkah, wọ́n sì ṣe irọkirika, wọ́n ṣe ipọsẹsẹ, wọ́n gé irun wọn kúrú, wọ́n sì tú harami wọn láti fi tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, àfi ẹni tí ó bá ní ẹran ìtọrẹ pẹ̀lú rẹ̀, nítorí Anabi -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pàṣẹ fún un pé kí ó wà nínú harami rẹ̀ títí di ìgbà tí yóò fi tú harami ní ọjọ́ Nahri ( ọjọ igun ẹran lẹyìn gigun Aráfah), Ìlànà anọbi fún ẹni tí ó fa ẹran ìjọsìn lọ́wọ́ ni kí ó gbé harami fún Hajj àti Umrah papọ̀; nítorí pé anọbi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì jẹ́ pé ó ti fa ẹran ìjọsìn lọ́wọ́, o sì paṣẹ fún àwọn tí wọ́n fa ẹran ìjọsìn lọ́wọ́ nínú àwọn saabe rẹ̀ tí wọ́n ti gbé harami fún Umrah pé kí wọ́n ṣe labbaika ( mu àníyàn wa ) fún Hajj pẹ̀lú Umrah wọn, àti pé wọn kò gbọdọ̀ bọra silẹ títí wọn yóò fi bọra silẹ kúrò nínú méjèèjì papọ̀ ní ọjọ́ ìgunran. Tí o bá sì jẹ́ pé ẹni tí ó fa ẹran ìjọsìn lọ́wọ́ ti gbé harami fún Hajj nìkan ṣoṣo, yóò máa bẹ nínú harami rẹ̀ bẹ́ẹ̀ títí yóò fi bọra silẹ ní ọjọ́ ìgunran, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣe Qiran ( Qiran ni kí a pa ìjọsìn Umrah papọ mọn Hajj lẹẹkan ṣoṣo) .
A sì ti mọn bayi pẹ̀lú pé: ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé harami fún Hajj nìkan, tàbí fún Hajj àti Umrah, tí kò sì ní ẹran ìtọrẹ, kò yẹ fún un pé kí ó máa bẹ pẹlu harami rẹ̀, ṣùgbọ́n ìlànà Anabi nípa rẹ̀ ni pé kí ó sọ harami rẹ̀ di ti Umrah, kí ó si rọkirika ile Ọlọhun, kí ó ṣe ipọsẹsẹ, kí ó sì gẹ́ irun rẹ̀, kí ó sì bọra sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe pàṣẹ fún àwọn tí kò ní ẹran ìtọrẹ nínú àwọn Saabe rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, Àfi bí ẹni náà bá bẹ̀rù pé Hajj yóò bọ́ lọ́wọ́ òun; nítorí pé ó pẹ́ se e, nígbà náà kò sí aburu kí ó máa bẹ pẹlu harami rẹ̀, Ọlọ́hun ni Onímọ̀ jùlọ.
Tí ẹni tí ó gbé harami bá n bẹ̀rù pé òun kò ní lè parí iṣẹ́ ìjọsìn rẹ̀ nítorí pé ó nṣe àìsàn tàbí ó nbẹ̀rù ọ̀tá tabi irú bẹẹ, ó dára fún un kí ó sọ nígbàtí ó bá gbé harami rẹ̀ pé: "tí nkankan bá dími lọ́wọ́, níbi tí mo bá ti ṣe é dé náà ni màá ti bọ́ra sílẹ̀"; nítorí hadith Duba’ah ọmọ Al-zubair - kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i -, pé ó sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo fẹ ṣe Hajj, mo si n kérora, Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sì sọ fún un pé: ""ṣe Hajj pẹlu aniyan rẹ, kí o sì ṣe majẹmu pé aaye ipari Hajj mi ni ibi ti wọ́n bá ti mumi mọlẹ."" [39] Wọn fi ẹnu ko le e lori. [39] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (5089), àti Muslim, pẹlu onka (1207).
Àǹfààní dída majẹmu yíì nipé: tí nkan bá ṣẹlẹ̀ sí ẹnití o gbe harami, èyí tí yóò dí i lọ́wọ́ láti parí iṣẹ́ ìjọsìn rẹ̀, bíi àìsàn tàbí ìdínà lọ́wọ́ ọ̀tá, o lẹtọ fún un láti bọ́ra sílẹ̀, kò sì sí ìtánrán kankan lórí rẹ̀.
Ori- Ọrọ
Nípa ìdájọ Hajj ọmọkùnrin kékeré, ṣé a máa kà á sí Hajj ọranyan nínú Islam ?
Hajj ọmọkunrin kékeré àti ọmọbinrin kékeré lálàáfíà; gẹgẹ bi ohun ti o wa ninu ìwé Sahih Muslim, láti ọdọ ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - pé obinrin kan gbé ọmọkunrin kekere kan sókè sí Anabi, o si sọ pe: irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ṣé Hajj wà fún eléyìí? Anabi si sọ pe: «Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀san sì wà fún ọ» [40]. [40] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1336).
O wa ninu Saheeh Bukhari, lati ọdọ As-Saa'ib ọmọ Yazeed – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: «Ó mú mi ṣe Hajj pẹ̀lú ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún méje» [41]. Ṣùgbọ́n Hajj yii kò tó fún àwọn méjèèjì lati duro nipo Hajj ọranyan Islam. [41] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1858).
Bẹẹ naa ni ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣíṣe Hajj tọ́ lọ́wọ́ wọn, kò sì ní gbà wọ́n ní ipò Hajj ẹ̀sìn Islam; nítorí ohun tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú hadith ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -, pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a - sọ pé: «Ọmọkunrin kekere èyíkéyìí tí ó bá ṣe Hajj, lẹ́yìn náà tí ó sì balaga, ó di ọ̀ranyàn fún un láti ṣe Hajj mìíràn, àti ẹrú èyíkéyìí tí ó bá ṣe Hajj, lẹ́yìn náà tí wọ́n sì sọ ọ́ di òmìnira, Hajj mìíràn di ọ̀ranyàn lé e lórí» [42] Ọmọ bàbá Shaybah ati Al-Bayhaqiy gba a wa pẹlu afiti ti o dara. [42] Ọmọ bàbá Shaybah lo gba wa (apá 4/444).
Lẹyin naa, ti ọmọkunrin kekere kò bá tíì da nnkan mọ, alabojuto rẹ ni yoo gbe erongba harami fun un, yoo si bọ aṣọ riran kuro lara rẹ, yoo si ba a pe Talbiyyah, ọmọkunrin naa yoo si tipa bẹẹ di ẹni to wa ninu harami, a o si ka ohun ti o jẹ eewọ fun agbalagba ti o wa ninu harami ni eewọ fun un. Gẹgẹ bẹẹ naa ni ọmọbinrin kekere ti kò tii da nnkan mọ, alabojuto rẹ ni yoo gbe erongba harami fun un, yoo si ba a pe Talbiyyah, yoo si tipa bẹẹ di ẹni to wa ninu harami, a o si ka ohun ti o jẹ eewọ fun agbalagba obinrin ti o wa ninu harami ni eewọ fun un. O si yẹ ki awọn mejeeji mọ ni ti aṣọ ati ti ara ni asiko Tawaaf; nitori pe Tawaaf dabi irun, imọra si jẹ mọnjẹmu fun lilalaafia rẹ.
Tí ọmọkunrin àti ọmọbinrin kekere naa bá jẹ́ àwọn tí wọ́n ti ń dá ǹkan mọ̀, wọn yóò gbé harami pẹ̀lú ìyọ̀ǹda alábòójútó wọn, wọn yóò sì ṣe ní àsìkò gbígbé harami ohun tí àgbàlagbà ń ṣe nínú ìwẹ̀, fífi lọfinda òloórùn dídùn sí ara àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Alábòójútó wọn ni ẹni tí yoo ṣe ìtọ́jú ọ̀rọ̀ wọn, tí yoo sì rí sí àǹfààní wọn, yálà ó jẹ́ bàbá wọn, ìyá wọn, tàbí ẹlòmíràn; òun ni yóò ba wọ́n ṣe ohun tí agbára wọn kò ba ká, gẹ́gẹ́ bí sísọ òkò fún sétánì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ó sì jẹ́ dandan fún wọn láti ṣe àwọn iṣẹ́ Hajj yòókù, bíi dídúró ní Arafah, sísùn ní Mina àti Muzdalifah, irọkirika, àti ipọnsẹsẹ, Tí wọ́n bá kágara láti ṣe Tawaafu ( irọkirika ilé Ọlọhun ) àti Safa àti Mariwa, a óò gbé wọn ṣe Tawaafu ( irọkirika ), a óò sì gbé wọn sá Safa àti Mariwa. Ohun tó ṣàfàájù fún ẹni tí ó gbé wọn ni pé kí ó má ṣe dá Tawaafu ( irọkirika ) àti Safa àti Mariwa náà pọ̀ láàrin òun àti àwọn méjèèjì, ṣùgbọ́n kí ó gbà níyàn Tawaafu àti Safa àti Mariwa náà fún wọn, kí ó sì ṣe Tawaafu ọ̀tọ̀ fún ara rẹ̀, kí ó sì sá Safa àti Mariwa ọ̀tọ̀ fún ara rẹ̀; fún ìṣọ́ra lórí ìjọsìn, àti láti fi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Hadith ọlọ́lá náà: «Gbe ohun ti nse ọ ni iyemeji jusilẹ, ki o lọ sibi ohun ti ko se ẹ ni iyemeji» [43]. Ti ẹni ti o gbe eniyan ba pinu irọkirika fun ara rẹ ati fun ẹni ti o gbe, eyi naa to fun un ni ìbámu sí èyí tí o ni alaafia ninu ọrọ mejeeji; nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko paṣẹ fun obinrin ti o beere lọwọ rẹ nipa Hajj ọmọde pe ki o ṣe irọkirika fun oun nikan, ti o ba si jẹ pe eyi jẹ dandan, iba ti ṣalaye rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, Ọlọhun ni Oluranlọwọ. [43] At-Tirmidhi lo gba wa, pẹlu onka (2518).
A óò pa ọmọkùnrin kekere tí ó ti dá nǹkan mọ́ àti ọmọbìnrin kekere tí ó ti dá nǹkan mọ́ láṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìmọ́ra kúrò níbi ẹgbin àti èérí kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ Tawaaf, gẹ́gẹ́ bí ẹni àgbàlagbà tó gbé harami. Gbigbe harami fún ọmọkùnrin kékeré àti ọmọbìnrin kékeré kò sì jẹ́ ọ̀ranyàn lórí alábòójútó wọn, ṣùgbọ́n iṣẹ́ àfiléje ni, tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, èsán ń bẹ fún un, tí ó bá sì fi sílẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un, Ọlọhun ló ni mọ jùlọ.
Ori-akori ọrọ
Àlàyé nípa àwọn eewọ àti àwọn ohun tí ó lẹtọ láti ṣe fún ẹni tí ó gbé harami.
Ẹni tí ó ti gbé harami lẹ́yìn aniyan Ihram ( ibẹrẹ ìjọsìn náà ) - yálà ọkùnrin ni tàbí obìnrin - kò lẹtọ fún un láti mú ohunkóhun kúrò nínú irun ará rẹ̀ tàbí àwọn eekanna rẹ̀, tàbí kí ó lo lọfinda.
Kò tọ́ fún ọkùnrin ní pàtàkì láti wọ aṣọ rírán mọ́ gbogbo ara rẹ̀, ìyẹn ni pé: gẹ́gẹ́ bí ìrísí tí wọ́n gé tí wọ́n sì rán an sí, gẹ́gẹ́ bíi ẹwu, tàbí apá kan lára rẹ̀; gẹ́gẹ́ bíi ṣòkòtò, khuff ( bàtà alaaini itilẹ́ méjèèjì, àti ìbọ̀sẹ̀ méjèèjì, àyàfi tí kò bá rí aṣọ ìgbànú (izaar) ó tọ́ fún un láti wọ ṣòkòtò. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹni tí kò bá rí bàtà- pẹlẹbẹ méjì, ó tọ́ fún un láti wọ khuff méjèèjì láì gé e; látàrí hadith ọmọ ‘Abbaas - kí Ọlọhun yọnu sí àwọn méjèèjì - tí ó fẹsẹ̀ mulẹ nínú ìwé hadith to lalaafia méjèèjì, pé dájúdájú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - sọ pé: «Ẹni tí kò bá rí bàtà méjì, kí ó wọ bàtà aláwọ méjì, àti ẹni tí kò bá rí aṣọ ìgbànú, kí ó wọ ṣòkòtò» [44]. [44] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1841), àti Muslim, pẹlu onka (1179).
Ni ti ohun ti o wa ninu hadiith ọmọ Umar – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – nipa aṣẹ gige khuffi mejeeji nigbati o ba ni bukaata si wiwọ wọn latari aisi bata, dajudaju wọn ti pa ofin naa rẹ; toripe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – paṣẹ bẹẹ ni ilu Mọdiina, nigbati wọn beere lọwọ rẹ nipa iru aṣọ ti ẹni to gbe harami le wọ. Lẹyin naa nigbati o wa se idani lẹkọ fun awọn eniyan ni Arafah, o yọnda wiwọ khuffi nigbati a ko ba ri bata, kò si paṣẹ pe ki wọn ge e. Atipe awọn ti ko gbọ idahun rẹ ni ilu Mọdiina wa nibi idani lẹkọ yii, atipe iṣun alaye ọrọ siwaju kuro nigba ti a ni bukata rẹ ko tọna, gẹgẹ bi o ti jẹ ohun ti a mọ ninu imọ Usuulul Hadiith,( ìpìlẹ hadith ) ati ìmọ ìpìlẹ agbọye ẹṣin (Fiqhu). Eyi wa fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti pa aṣẹ gige rẹ rẹ. Ati wipe ti o ba jẹ pe ọranyan ni, Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iba ti ṣe alaye rẹ, Ọlọhun lo mọ ju.
Ó lẹtọọ fun ẹniti ó wà ninu harami láti wọ bàtà aláwọ̀ tí kò bo kokòsè ẹsẹ̀ méjèèjì mọ́lẹ̀; nítorí pé wọ́n jẹ́ irú kan náà pẹ̀lú sálúbàtà.
Ó sì tọ́ fún un láti di aṣọ ipele rẹ̀ àti láti so ó pẹ̀lú òwú àti irú rẹ̀; nítorí àìsí ẹ̀rí tó sọ ọ́ di eewọ̀.
Ó lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹni tí ó wà nínú harami kí ó wẹ̀, kí ó sì fọ orí rẹ̀, kí ó sì yáá pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ tí ó bá nílò rẹ̀. Tí nkankan bá wá jábọ́ láti orí rẹ̀ nítorí ìyẹn, kò sí àléébù lórí rẹ̀.
Wọn ṣe e ni eewọ fun obinrin ti o wa ninu harami ki o wọ nkan ti a rán si oju rẹ, gẹgẹbi iboju ati niqab, tabi si ọwọ rẹ mejeeji, gẹgẹbi ibọwọ; nítorí ọ̀rọ̀ Ànábì- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -: «Obinrin tí nṣe ìjọsìn Umrah tàbí Hajj kò gbọdọ wọ ìbòjú, bẹẹni kò gbọdọ wọ ìbọ́wọ́» [45] Bukhaari ni o gba a wa. Ìbọwọ́: ni ohun tí a rán tàbí tí a hun latara irun àgùntàn tàbí òwú tàbí àwọn nǹkan mìíràn, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọwọ́ mejeeji. [45] Al-Bukhari lo gba a wa pẹlu onka (1838).
Wọn sì ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn ní ẹtọ́ fún un nínú àwọn nǹkan tí a rán; gẹ́gẹ́ bíi ẹwu àwọ̀tẹ́lẹ̀, ṣòkòtò, Khuffu mejeeji, Ibọsẹ, àti ohun tó jọ bẹ́ẹ̀.
Bakan naa, o tọ fun un ki o da iborùn rẹ̀ bo ojú rẹ̀ nígbàtí ó bá nílò ìyẹn láì fi nǹkan dè é, tí iborùn náà bá sì kan ojú rẹ̀, kò sí nkankan lórí rẹ̀; nítorí hadith Aishah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ wipe: «Àwọn arìnrìn-àjò lórí ẹṣin maa nkọja lẹba wa, ti awa si wa ninu aso arami pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun – Ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tí wọn ba tí fẹ kọja níbi tí a wa ni ọkankan ninu wa yo ba sọ jilbaabu rẹ kalẹ lati ori rẹ bo oju rẹ, ti wọn ba si ti rekọja wa, a o si ṣi i.» [46] Bàbá Da'ud ni o gbe e jade, ati ọmọ Maajah, Ad-Daraqutni si gbe iru rẹ jade lati ọdọ iya Salamah. [46] Baba Daud l'o gba wa, pẹlu onka (1833).
Bákan náà, kò sí aburu kí ó bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tàbí nǹkan mìíràn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó pan dandan fún un láti bo ojú rẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì nígbàtí ó bá wà níbi tí àwọn ọkùnrin ajoji bá wà; nítorí pé ihoho ni; nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun - mimọ ni Fún Ọba tí ọlá Rẹ ga jùlọ -: (...wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi fún àwọn ọkọ wọn...) {suratul Nuur: 31.} Ko si iyemeji pe ojú ati atẹlẹwọ méjèèjì wa ninu awọn ọṣọ ti o tobi julọ.
Ojú si ni o lagbara jù, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pé: « ...Nígbà tí ẹ bá sì fẹ́ bèèrè n̄ǹkan ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó rẹ̀, ẹ bèèrè rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn ní ẹ̀yìn gàgá. Ìyẹn jẹ́ àfọ̀mọ́ jùlọ fún ọkàn yín àti ọkàn wọn» [Al-Ahzāb: 53].
Ṣugbọn niti ohun ti ọpọlọpọ awọn obinrin ti sọ di aṣa, nipa gbigbe nǹkan si abẹ ibori bí bandeji lati gbe e soke kuro loju wọn, kò ní ipilẹ nínú òfin ẹ̀sìn gẹgẹ bi a ṣe mọ. Tí ó bá sì jẹ́ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ nínú ẹ̀sìn, Anabi - kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - ìbá ti ṣàlàyé rẹ̀ fún ìjọ rẹ̀, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún un láti dákẹ́ nípa rẹ̀.
Ó lẹtọ fun awọn ọkunrin ati awọn obinrin tí wọ́n wà ninu harami lati fọ aṣọ harami wọn kúrò nínú èérí tàbí irú rẹ̀, ó sì lẹtọ fun wọn lati paarọ̀ rẹ sí omiran.
Kò si lẹtọ fun un lati wọ aṣọ kankan ti Zaafurani tabi Oorisi ba kan; nitori pe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ nipa eyi ninu ẹgbawa Ọmọ Umar – ki Ọlọhun ba wa yọnu si awọn mejeeji –.
Ó sì di dandan fún ẹni tó wà ní ipò Ihrām kí ó jìnnà sí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, ìwà ìbàjẹ́, àti àríyànjiyàn; nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- tí ọ sọ pé: «Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí a mọ̀ nínú ẹṣin. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí orun ìfẹ́, ( Ibalopọ láàrin ọkọ àti aya), rírú òfin àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj...» [Al-Baqara: 197].
O sí ni àlàáfíà lati ọdọ Anọbi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe o sọ pe: «Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì dá ẹ̀ṣẹ̀, yoo pada gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bí i saye ni » [47]. Ar-Rafath: Wọn a máa lo láti túmọ sí ìbálòpọ̀ laarin okunrin àti Obìnrin àti ọ̀rọ̀ àti iṣẹ́ ìbàjẹ́, Al-Fusūq sì ni: àwọn ẹṣẹ àti ìyapa Ọlọhun, Al-Jidāl sì ni: ijiyàn nínú ọ̀rọ̀ èké, tàbí nínú ohun tí kò ní ànfàní nínú, ṣùgbọ́n ní ti ijiyàn lọ́nà tí ó dára jùlọ láti fi òtítọ́ hàn àti láti tako èké, kò sí aburú nínú rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí A pa láṣẹ ni; nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun - tí ọlá Rẹ ga jùlọ-: «Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí tó dára jùlọ...» [Surah An-Nahl: 125] [47] Al-Bukhari lo gba a wa láti ọwọ́ Abu Hurayrah, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (1521), àti Muslim pẹlu onka (1350).
Ó sì jẹ́ eewọ̀ fún ọkùnrin tí ó gbé arami láti fi nǹkan bo orí rẹ̀ èyí tí yóò lẹ̀mọ́ ọ; gẹ́gẹ́ bí i: fìlà, lawani tàbí irúu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú rẹ̀; nítorí ọ̀rọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - nípa ẹni tí ó jábọ́ lat'ori nkán tí o gun ní ọjọ́ Arafah tí ó sì kú: Ẹ wẹ ẹ pẹlu omi ati ewe Sidiru, bakannaa ki ẹ si we e nibi aṣọ rẹ mejeeji, bakannaa ẹ kò gbọdọ da nkan bo ori rẹ, tabi oju rẹ; tori wipe wọn o gbe e dide ni ọjọ igbende Al-kiyaamọ ni ẹni ti yoo maa ṣe Labbaeka ( ijẹpe fún Ọlọhun níbi ìjọsìn). [48] Wọn panu pọ le e lori, atipe gbolohun yi ti Muslim ni. [48] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1521), àti Muslim, pẹlu onka (1350).
Ṣugbọn Nípa ti wíwà lábẹ́ òjìji òrùlé mọ́tò tàbí agbòòrùn tàbí irú wọn, kò sí aburú níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wíwà lábẹ́ àtíbàbà àti igi; nítorí ohun tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Sọhíh pé wọ́n fi aṣọ ṣe òjìji bo Anabi - kí ìkẹ́ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - nígbàtí ó sọ Jamratul-Aqabah, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - pé wọ́n kọ́ ipagọ fún un ní Namrah, ó sì sọkalẹ sí abẹ́ rẹ̀ títí oòrùn fi yẹ kúrò ní àtàrí ní ọjọ Harafah.
O si jẹ eewọ fun ẹnití o gbe harami nínú àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin pípa ẹran ìgbẹ́, àti ṣíṣe ìkúnlọ́wọ́ lórí pípa rẹ̀, àti lílé e jáde kúrò ní ipò rẹ̀, àti títa kókó ìgbéyàwó, àti ìbálòpọ̀, àti kíkọnu sí àwọn obìnrin àti fífọwọ́kàn wọ́n pẹ̀lú adùn; nítorí Hadīth Uthmān - kí Allāhu yọ́nú sí i-, pé dájúdájú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a- sọ pé: « Ẹni tí nse ìjọsìn Hajj tabi Umrah kò gbọdọ bani ṣe ìgbéyàwó, bẹẹni kò gbọdọ fúnni nígbèyawó, bẹẹni kò gbọdọ tọrọ ìyàwó» [49] Muslim ni o gba a wa. [49] Muslim lo gba a wa, pẹlu onka (1409).
Tí ẹni ti o gbe arami bá wọ aṣọ tí wọ́n ti rán, tàbí ó bo orí rẹ̀, tàbí ó lo lọfinda òórùn dídùn, ni ẹni ti o gbagbe tabi ni ti aimọkan, kò sí fidya (pípa ẹran itanran) kankan fún un, yóò sì yọ nnkan náà kúrò ní gbogbo ìgbà tí ó bá ti rántí tàbí tí ó bá ti mọ̀. Bákan náà ni ẹni tí ó bá fá orí rẹ̀, tàbí ó gé díẹ̀ nínú irun rẹ̀, tàbí ó gé èékánná rẹ̀ ni ẹni ti o gbagbe tabi ni ti aimọkan, kò sí ẹṣẹ̀ kankan fún un gẹ́gẹ́ bí ọ se ní àlàáfíà.
O si jẹ eewọ fun Musulumi - yálà ó jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, yálà ó wà nínú aṣọ harami tàbí kò sí níbẹ̀ - láti pa ẹran-ìgbẹ́ Ilẹ̀ Harami, àti láti ṣe ìkúnlọ́wọ́ lórí pípa rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò, tàbí ìfọwọ́júwe tàbí irú bẹ́ẹ̀.
O si jẹ eewọ lati lé e kúrò ní àyè rẹ̀, o si jẹ eewọ lati ge igi Haram àti ewéko rẹ̀ tútù, àti lati gbé ohun arihe rẹ̀ àfi fún ẹni tí yóò polongo rẹ̀; nitori ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – to sọ pe: «Dájúdájú ìlú yìí - ìyẹn Makkah - ó jẹ́ àbéèwò pẹ̀lú èèwọ̀ Ọlọ́hun títí di ọjọ́ Alqiyaamah, a kò gbọdọ̀ gé igi rẹ̀, a kò sì gbọdọ̀ lé ẹranko igbó rẹ̀, a kò sì gbọdọ̀ mú ohun ìhẹ́ rẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá fẹ́ fi wẹ́lọ, a kò sì gbọdọ̀ wo ewé rẹ̀» Wọn fi ẹnu ko le e lori. [50] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (1834), àti Muslim pẹlu onka (1353).
Al-Munshid: òun ni amọ̀ní, Al-Khala: òun ni koríko tútù, Mina àti Muzdalifah nínú Haram ni wọ́n wà, ṣùgbọ́n ní ti Arafah nínú ita Haram ni ó wà.
Orí-ọrọ
Nípa ohun tí aláàájì yóò ṣe nígbàtí o bá wọ Makkah àti àlàyé ohun tí yóò ṣe lẹ́yìn tí o bá wọ Masalaasi Harami bíi irọkirika àti àpèjúwe bí yóò se se .
Tí ẹni tí ó fẹ́ ṣe Umrah tàbí Hajj bá dé sí Mekkah, wọ́n fẹ́ kí ó wẹ̀ kí ó tó wọ inú rẹ̀; nítorí pé Ànábì- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe bẹ́ẹ̀. Tí o bá dé inú Masjid Al-Haram (mọsalasi ọwọ), sunnah ni fún un pé kí o gbé ẹsẹ ọ̀tún wọlé, kí o sì wí pé: "Pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́hun, kí ìkẹ́ àti ọla máa bá ojisẹ́ Ọlọ́hun, mo sádi Ọlọ́hun Atóbilọ́lá, àti ojú Rẹ̀ ọlọ́lá àti agbára Rẹ̀ ayérayé kúrò lọ́wọ́ Èṣù ẹni-ẹ̀kọ ẹni egbe . Irẹ Ọlọhun, ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ìkẹ́ Rẹ fún mi", Adura yìí kan náà ni yóò wí nígbàtí ó bá fẹ́ wọ àwọn mọ́sálásí yòókù, kò sì sí àdúà kan pàtó fún wíwọ Masjid Al-Haram tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nínú ohun tí èmi mọ̀.
Tí ó bá ti dé Kaaba (ile Ọlọhun tí o wa ni Makkah), yóò dá Talbiyah (gbólóhùn ijẹpe fún Ọlọhun) dúró kí ó tó bẹ̀rẹ̀ Tọwwaf (irọkirika ilé Ọlọhun), tí ó bá jẹ́ oní-Tamattu (ṣíṣe Umrah pẹlu Hajj nigbakannaa pẹlu bibọ asọ arami silẹ) tàbí oní-'Umrah. Lẹ́yìn náà, yóò kọrí sí Òkúta Dúdú yóò sì kọjú sí i, lẹ́yìn náà yóò fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kàn án, yóò sì fi ẹnu kò ó tí ó bá rọrùn, kò sì ní fi ìdífunfun pa àwọn ènìyàn lára. Yóò sọ nígbàtí ó bá fọwọ́ kàn án pé: “Bismillāhi wallāhu akbar”, ( ní orúkọ Ọlọhun, àti pé Ọlọhun ìn ọ Tobi jùlọ) tàbí kí ó sọ pé: “Allāhu akbar”. Tí kò bá rọrùn láti fi ẹnu kòó, yóò fi ọwọ́ rẹ̀ tàbí ọpa tàbí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kàn án, yóò sì fi ẹnu ko ohun tí ó fi kàn án náà, tí kò bá sì rọrùn láti fi ọwọ́ kàn án, yóò nà ọwọ́ sí i, yóò sì sọ pé: “Allahu Akbar”, láì fi ẹnu ko ọwọ́ rẹ̀. Ó jẹ́ Majẹmu fún àlááfíà Tawaafu pé: kí ẹni tí ó ń ṣe Tawaafu wà lórí imọ́ra kúrò nínú ẹgbin kékeré àti ẹgbin ńlá; nítorípé Tawaafu dàbí ìrun ni, àfi pé wọ́n yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ sísọ nínú rẹ̀. Kí ó sì fi Ilé náà sí apá òsì rẹ̀ ní àsìkò Tawaafu. Tí ó bá sì sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ Tawaafu rẹ pé: "Ọlọ́hun, fún ìgbàgbọ́ nínú Rẹ, àti fún gbígba Tírà Rẹ gbọ́, àti fún mímú àdéhùn Rẹ ṣẹ, àti fún títẹ̀lé ìlànà Ànábì Rẹ Muhammad – kí ìkẹ́ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a –" ó dára; nítorípé wọ́n ti gba èyí wa láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a –. Yóò yípo ní ẹẹmeje, yóò sì máa pọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ nínú gbogbo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àkọ́kọ́ nínú Tawaafu àkọ́kọ́, èyí sì ni Tawaafu tí yóò ṣe nígbàtí ó kọ́kọ́ dé Makkah, yálà ó jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe Umrah ni, tàbí ẹni tí ó ń ṣe Tamattuhu, tàbí ẹni tí ó gbé harami fún Hajj nìkan, tàbí ẹni tí ó pa Hajj pọ̀ mọ́ Umrah. Yóò sì rìn nínú mẹ́rin tí ó kù, yóò bẹ̀rẹ̀ olúkúlùkù ìyípo láti ibi òkúta dúdú, yóò sì parí rẹ̀ síbẹ̀.
Ipọṣẹṣẹ ni: iyara rìn pẹlu kí igbesẹ sunmọra wọn, ó sì jẹ́ ìlànà fún un kí ó ti aṣọ rẹ̀ bọ abẹ́ abiya ní gbogbo ipoyi yìí, láì ṣe ní ibòmíràn, Ipakaja: oun ni kí ó fi àárín aṣọ rẹ sábẹ́ abiya ọ̀tún rẹ, kí ó sì gbé etí aṣọ rẹ méjèèjì lé ejika òsì rẹ.
Ati ti o ba ṣe iyemeji nipa onka awọn ipoyi yóò fi lé orí amọdaju, oun naa ni eyi ti o kere ju, nitori naa ti o ba ṣe iyemeji boya o ṣe ipoyi mẹta ni tabi mẹrin, yóò ka à sí mẹta, báyìí gẹ́lẹ́ ni yóò ṣe níbi Sa'i.( Ipọsẹsẹ náà )
Lẹ́yìn tí o bá ti parí irọkirika yìí, yóò da aṣọ iro rẹ̀ padà sí orí ejika rẹ̀ méjèèjì, tí etí rẹ̀ méjèèjì yóò wà lórí àyà rẹ̀, síwájú kí ó tó kirun raka méjì ti irọkirika.
Ninu ohun ti o yẹ ki a kọ fun awọn obinrin, ti aa si ṣe ikilọ fun wọn nipa rẹ ni ṣíṣe Ṭawāf wọn pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ àti lọ́fíńdà, àti àìbo ara daada nígbà tí wọ́n jẹ́ ihoho. Ó sì jẹ́ dandan fún wọn kí wọ́n bo ara wọn, kí wọ́n si fi ọ̀ṣọ́ sílẹ̀ ní àsìkò Ṭawāf àti àwọn ipò mìíràn tí àwọn obìnrin ti máa n darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin; nítorí pé wọ́n jẹ́ ihoho àti fitina. Ojú obìnrin sì ni ọ̀ṣọ́ rẹ̀ tí ó hàn jùlọ, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún un láti ṣàfihàn rẹ̀ àfi fún àwọn ẹni-eèwọ̀ rẹ̀; nítorí ọ̀rọ̀ Allāhu tí Ọlá Rẹ ga jùlọ: ...wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfihàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi fún àwọn ọkọ wọn... {suratul Nuur: 31}, Kò lẹtọ fun wọn lati ṣii oju wọn lasiko fifi ẹnu kan okuta hajar aswad (dúdú) ti ọkunrin kankan bá n rí wọn. Tí kò bá sì rọrun fun wọn lati rí ààyè lati fọwọ́ kan okuta naa kí wọ́n sì fi ẹnu kò ó, kò lẹtọ fun wọn lati bá àwọn ọkùnrin dífunfunfun, kàkà bẹ́ẹ̀, ki wọ́n maa ṣe tawaf ni ẹyin wọn, èyí sì loore ju fun wọn, o si ni ẹsan nla ju tawaf ( irọkirika ilé Ọlọhun) ni itosi Kaaba lọ lasiko idifunfunfun pẹlu àwọn ọkùnrin. Kò sí nínú òfin ẹṣin lati ṣe iyàrá rin ati ipakaja asọ ni tawaf miiran yatọ si eyi, bẹẹni kò sí ninu sisare laarin Safa ati Marwa, kò sì si fún àwọn obìnrin; nitoripe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kò ṣe Raml ati Idtiba' ayafi ninu tawaf rẹ akọkọ ti o ṣe nigbati o de Makkah, ati pe nigba tawaf, ẹni ti n ṣe é gbọdọ jẹ́ ẹni tó mọ́ kúrò nínú ẹgbin àti idọti, ó gbọdọ jẹ́ onítẹríba àti onírẹ̀lẹ̀ fún Olúwa rẹ̀.
Ó sì jẹ́ nkán tí a fẹ fún un kí ó máa ṣe ìrántí Ọlọhun àti adura ní ọpọlọpọ nínú Tawaaf rẹ̀, bí ó bá sì ka nkankan nínú Al-kuraani níbẹ̀ ó dára; kò sì sí ìrántí pàtó kan, tàbí adura pàtó kan, tí ó jẹ́ ọranyan nínu Tawaaf( irọkirika ) yíì, tàbí òmíràn nínú àwọn Tawaaf, tàbí nínú Sa'yi.
Ní ti ohun tí àwọn ènìyàn kan dá sílẹ̀ nípa pípinnu ìrántí Ọlọhun kan pàtó tàbí adua kan pàtó fún ìròǹká kọ̀ọ̀kan nínú Tawaaf tàbí Sa'yi ( ipọsẹsẹ ) èyí kò ní ìpìlẹ̀, ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá rọrùn nínú idarukọ Ọlọhun àti adua o ti to. sugbọn nígbà tí ó bá dé ìdojúkọ origun Al-yamaani, yóò fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kàn án, yóò sì wí pé: "Bismillahi wallahu akbar", kò sì ní fi ẹnu kò ó. Tí ó bá sì ṣòro fún un láti fi ọwọ́ kàn án, yóò fi sílẹ̀, yóò sì máa bá Tawaaf rẹ̀ lọ. Kò ní tọ́ka sí i, kò sì ní ṣe takbīr nígbà tí ó bá dé ìdojúkọ rẹ̀; nítorí pé ìyẹn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a - gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀, Ó sì jẹ́ ohun tí a fẹ́ràn fún un kí ó máa sọ láàárín origun Al-yamaani àti Hajar al-aswad pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.” [Suratul Baqara: 201]. Gbogbo ìgbà tí ó bá kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkúta dúdú, yóò fi ọwọ́ kàn án, yóò sì fi ẹnu kòó, yóò sì sọ pé: "Allahu Akbar". Tí kò bá rọrùn láti fi ọwọ́ kàn án àti fi ẹnu kòó, yóò tọ́ka sí i nígbàkúgbà tí ó bá kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì sọ pé: "Allahu Akbar".
Kò sí ewu nínú rirọkirika lẹ́yìn Zamzam àti Makaamọ, pàápàá jùlọ nígbà tí àwọn ènìyàn bá pọ̀. Mọ́ṣáláṣí náà pátápátá jẹ́ ibi rirọkirika, tí ó bá tilẹ̀ rọkirika ní àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ Mọ́ṣáláṣí náà, ìyẹn tó fún un. Ṣùgbọ́n kí ó rọkirika ní ìtòsí Ka'ba lóore jù, tí ó bá rọrùn.
Tí o bá parí irọkirika ile Ọlọhun tan, yóò kirun raka méjì lẹyìn ààyè ibuduro Anọbi Ibrahim tí o bá rọrun fún un bẹẹ, tí kò bá sì rọrun fún un nítorí pípọ̀ ènìyàn àti bẹẹbẹẹ lọ, yóò kí raka méjèèjì ní èyíkeyi ààyè nínú Mọsalasi, ó sì jẹ́ sunna pé kí ó ka nínú wọn lẹ́yìn Fatiha Sọ pé: “Ẹ̀yin aláìgbàgbọ́, [suratul-kaafirun:1] Níbi raka akọkọ àti Sọ pé: “Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo. [Al-ikhlas: 1] Ní raka kejì, èyí ni o dára jù, tí o bá sì ka suurah miran yàtọ̀ sí àwọn méjèèjì náà, kò sí ìyọnu, lẹ́yìn náà yóò lọ sí ibi òkúta dúdú yóò sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kan án tí o bá rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀; ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Ànábì - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a - nínú ìyẹn.
Lẹyin naa yóò jáde lọ sí oke Safa láti ẹnu ọ̀nà rẹ̀, yóò gùn ún tàbí kí ó dúró níbẹ̀, gígùn Safa sì dára jù tí ó bá rọrùn, yóò si ka ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àkọ́kọ́ gbolohun Ọlọhun pe: « Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu. ( Ọlọhun .» [Al-baqarah: 158].
Wọ́n si fẹ kí o da oju kọ Kiblah ( ibudajukọ ) lórí òkè Safa, yio wa yin Ọlọhun, yio si gbe é tobi, yio si sọ pé: "Kòsí ẹni kankan tí o yẹ kí a fi ìjọsìn fún àyàfi Allah, Allah sì ni Ẹni Tí ó Tóbi Jùlọ, kòsí ẹni kankan tí o yẹ kí a fi ìjọsìn fún àyàfi Allah nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un, Òun l'ó ni ìkápá àti ìyìn, Ó ń sọni di ààyè, Ó sì ń pa ni, Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan, kòsí ẹni kankan tí o yẹ kí a fi ìjọsìn fún àyàfi Allah nìkan ṣoṣo, Ó pé àdéhùn Rẹ̀, Ó sì ran ẹrú Rẹ̀ lọ́wọ́, Ó sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun ní Òun nìkan ṣoṣo»," Lẹ́yìn náà yóò ṣe àdúà pẹ̀lú èyí tó bá rọrùn fún un, yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè, yóò sì tún ìrántí àti àdúà yìí sọ (nígbà mẹ́ta). Lẹ́yìn náà yóò sọkalẹ̀, yóò sì máa rìn lọ sí Marwah títí yóò fi dé ibi àmi àkọ́kọ́, ọkùnrin yóò sì yara rìn títí yóò fi dé ibi àmi ẹlẹẹkeji. Ṣugbọn obìnrin, a kò pa á láṣẹ fún un láti yàrá láàrin àwọn àmì méjèèjì; nítorí pé hoho ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, rírìn ni a pa láṣẹ fún un níbi gbogbo ipọsẹsẹ náà. Lẹ́yìn náà yóò rìn, yóò sì gun oke Marwah tàbí kí o dúró ní ẹgbẹ́ rẹ̀, Gigun un si loore ju ti o ba rọrun fun un lati ṣe bẹẹ, yoo sọ, yoo si ṣe lori oke Marwah gẹgẹ bi o ti sọ, ti o si ṣe lori oke Safa, ayafi kika ayah naa, eyi si ni gbolohun Ọlọhun pe: «Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu...» [Al-baqarah: 158], eleyii jẹ ìlànà ofin ẹsin nígbàtí a bá n gùn òkè Sọfa nínu ipaara àkọ́kọ́ nìkan; láti fi ṣe àfarawé Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a, lẹ́yìn náà yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì rìn ní ààyè ìrìn rẹ̀, yóò sì yára ní ààyè ìyára títí yóò fi dé orí òkè sofa, yóò ṣe ìyẹn ní ẹẹmeeje, lílọ rẹ̀ jẹ́ ipaara kan, bẹ́ẹ̀ ni ìpadà rẹ̀ náà jẹ́ ipaara kan; nítorí pé Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a - ṣe ohun tí a mẹ́nu bà, ó sì sọ pé: ""Ẹ kẹkọ awọn iṣẹ Hajj yin lati ọdọ mi"" Ó jẹ́ ohun tí ó dára láti pọ̀ ní ṣíṣe ìrántí Ọlọ́hun àti àdúà nínú sisa safa ati mariwa rẹ̀ pẹ̀lú ohun tí ó bá rọrùn fún un, àti pé kí ó wà ní ìmọ́ra kúrò níbi ẹgbin ńlá àti kékeré. Tí ó bá tilẹ̀ sa safa ati mariwa láìsí ìmọ́ra, yóò tó fún un, bẹẹ gẹgẹ ti obinrin ba ri nnkan oṣu tabi ti o n se ẹjẹ ibimọ lẹyin irọkirika ile Oluwa; yoo sa safa ati mariwa, iyẹn yoo si to fun un; nitori pe imọra kii ṣe majẹmu fun sisa safa ati mariwa, ṣugbọn o jẹ ohun ti o dara lati ṣe gẹgẹ bi o ti ṣiwaju. [51] Ìtọ́kasí imujade rẹ̀ ti ṣíwájú.
Nigbati o ba ti pari irin Sa'y (ipọsẹsẹ) rẹ tan, yoo fa irun ori rẹ tabi ki o ge e. Fifa irun ori si ni o lọla ju fun ọkunrin, Ṣugbọn ti o ba ge e, ti o si fi fifa irun silẹ fun Hajj, o dara. Ti dide rẹ si Makkah ba wa sunmọ àsìkò Hajj, gige irun ni o lọla ju fun un ki o le fa iyoku irun ori rẹ ni asiko Hajj; nitoripe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigbati oun ati awọn Saabe rẹ de Makkah ni ọjọ kẹrin oṣu Dhul-Hijjah, o paṣẹ fun ẹnikẹni ti kò mú ẹran Hadiyya dani pe ki o bọra kuro ninu harami ki o si ge irun rẹ, kò si paṣẹ fun wọn pe ki wọn fa a. Ó jẹ dandan nibi gige irun pe ki o kárí gbogbo orí, gige apá kan rẹ kò si to, gẹgẹbi fifa apá kan rẹ kò ṣe to. Obinrin, ko si ohun ti a pa ni aṣẹ fun un ayafi gige irun, ohun ti o jẹ aṣẹ fun un si ni pe ki o mu ninu ọkọọkan irun idi rẹ ni iwọn ipari ika tabi ki o dinku ju bẹẹ lọ. Al-Anmulah si ni: ipari ika, obinrin kò si gbọdọ mu ju ìyẹn lọ.
Tí ẹniti o gbe harami bá ti ṣe ohun tí a ti mẹ́nukàn yii, ó ti parí Umrah rẹ̀ niyẹn, ó sì ti di ẹtọ fún un gbogbo ohun tí ó jẹ́ eewọ̀ fún un látarí harami, àyàfi tí ó bá jẹ́ pé ó mú ẹran ìtọrẹ dání, dájúdájú yóò wà nínú harami rẹ̀ títí yóò fi parí Hajj àti Umrah papọ̀.
Ṣùgbọ́n fún ẹni tí ó bá gbé harami fún Hajj nìkan ṣoṣo, tàbí fún Hajj àti Umrah papọ̀, ìlànà anọbi ni fún un kí ó fagi lé harami rẹ̀ sí Umrah, kí ó sì ṣe ohun tí ẹni tí ó ń ṣe Tamattu' ń ṣe, ayafi tí ó bá jẹ́ pé ó ti mú ẹran ìtọrẹ dání; nítorí pé Anabi -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pa àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún àwọn saabe rẹ̀, ó sì sọ pé: «Bí kì í bá ṣe pé èmi ti da ẹran ìtọrẹ wá, dájúdájú èmi ìbá túra sí lẹ níbi Arami mi pẹ̀lú yín» [52]. [52] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1568).
Ti obinrin ba ṣe nnkan oṣù tàbí ó ní ẹjẹ ibimọ lẹ́yìn tí ó ti gbé harami fún Umrah, kò níí ṣe tawaafu ile Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni kò níí pọ ṣẹṣẹ láàárín Safa àti Marwa títí yóò fi mọra padà . Tí o bá ti mọra, yóò ṣe tawaafu, yóò pọ ṣẹṣẹ láàrin Sọfa ati Marwah yóò sì gé díẹ̀ kúrò nínú irun orí rẹ̀, Umrah rẹ̀ sì ti parí pẹ̀lú ìyẹn. Ṣùgbọ́n tí kò bá mọra ṣíwájú ọjọ́ Tarwiyah ( ọjọ náà ni ọjọ kẹjọ nínú osun Dhilihijjah ) , yóò gbé harami fún Hajj láti ibi tí ó ngbe, yóò sì bá àwọn ènìyàn jáde lọ sí Mina, yóò sì di ẹni tí ó ń ṣe Kirọọnu. Yóò ṣe gbogbo ohun tí àwọn alalaaji ń ṣe bíi dídúró ní Arafat, àti ní Masha'ar (Muzfalifah), bíi jíjú òkúta Jamarat, sísùn ní Muzdalifah àti Mina, dídú ẹran, àti gígé irun kúrú. Tí ó bá wá mọra, yóò ṣe tawaafu ile Oluwa, yóò sì se ipọsẹsẹ láàárín Safa àti Marwa, tawaafu ẹ̀ẹ̀kan àti ipọ sẹsẹ ẹ̀ẹ̀kan, ìyẹn sì ti tó fún un fún Hajj rẹ̀ àti Umrah rẹ̀ pátápátá; nítorí hadith 'Ā'ishah pé òun náà ṣe nnkan oṣù lẹ́yìn tí ó gbé harami fún Umrah, ni Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá sọ fún un pé: “Ṣe nkan ti alalaaji n ṣe yatọ si pe ọ ko gbọdọ rọkirika ile Olúwa titi ti o fi mọ” [53] Wọn fi ẹnu ko le e lori. [53] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (305), àti Muslim, pẹlu onka (1211).
Tí obinrin tó wà nínú nnkan oṣù tàbí obinrin tó nṣe ẹjẹ ibimọ bá ju oko ní ọjọ ọdún ìléyá, tí ó sì gé irun rẹ̀ kúrú, gbogbo nnkan tí ó jẹ́ èèwọ̀ fún un látàrí harami ti di ẹtọ̀ fún un láti ṣe, gẹ́gẹ́ bíi lílo lọ́fíńdà àti àwọn nǹkan bíi bẹ́ẹ̀, àfi Ibalopọ tọkọ-taya nikan títí tí yóò fi parí iṣẹ́ Hajj rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin yòókù tí wọ́n mọ́. Tí ó bá wá ṣe tawaafu, tí ó sì sá safa àti marwa lẹ́yìn tó bá ti mọ́, ọkọ rẹ̀ á wá di ẹtọ̀ fún un.
Ori-iwe àkòrí ọrọ
Nípa Ìdájọ́ gbígbé arami fún Hajj ní ọjọ́ kẹjọ nínú oṣù Dhul-Hijjah àti jíjáde lọ sí Mina.
Tí ó bá di ọjọ Tarwiyah, èyí tí í ṣe ọjọ kẹjọ oṣù Dhul-Hijjah, ó jẹ́ ohun tí ó yẹ fún àwọn tí kò sí nínu ipò arami ní Makkah àti àwọn ará ìlú tí wọ́n fẹ́ ṣe Hajj, pé kí wọ́n gbé arami fún Hajj láti ibùgbé wọn; nítorí pé àwọn ọ̀rẹ́ Ànábì – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tẹ̀ ibudó sí Abutah, wọ́n sì gbé arami fún Hajj láti ibẹ̀ ní ọjọ́ Tarwiyah lórí àṣẹ rẹ̀ – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –. Ànábì – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kò sì pa wọ́n láṣẹ pé kí wọ́n lọ sí Ilé Ọlọ́hun kí wọ́n gbé arami níbẹ̀ tàbí níbi Mīzāb. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kò pa wọ́n láṣẹ láti ṣe pípoòyí ìdágbére nígbàtí wọ́n ń jáde lọ sí Mina. Tí ó bá jẹ́ pé ìyẹn jẹ́ ìlànà ẹ̀sìn, ìbá kọ́ wọn nípa rẹ̀. Gbogbo òore pátá sì wà nínú títẹ̀lé Ànábì – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – àti àwọn saabe rẹ̀, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí wọn.
Wọ́n fẹ fún un kí o wẹ̀, kí o sì ṣe ìmọ́tótó, kí o sì lo lọfinda nígbà tí o bá fẹ́ wọ ihram fún Hajj, gẹ́gẹ́ bí o ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí o bá fẹ́ wọ ihram láti meeqat (ni aaye ti a ti má nbẹrẹ ìjọsìn Umrah tabi Hajj). Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé arami fún Hajj, o wà nínú ìlànà anọbi fún wọn láti gba Mìná lọ ṣíwájú kí oòrùn tó yẹ àtàrí tàbí lẹ́yìn rẹ̀ ní ọjọ́ atẹ́rùn (Tarwiyah), wọ́n ó sì máa pọ̀ ní pípè Talbiyah títí tí wọ́n yóò fi ju òkò Jamratul-Ákọ́bà. Wọ́n máa kí Irun ọsán (Zhuri) àti Irun irọlẹ (Asr) àti Irun aṣalẹ (Magrib) àti Irun Akisun (Ishai) àti irun ìdaji (Fajr) ní Mìná, ìlànà anọbi sì ni pé kí wọ́n máa kí irun kọ̀ọ̀kan ní àsìkò rẹ̀ ní ẹdinku láì papọ̀, àfi irun aṣalẹ (Magrib) àti irun ìdaji (Fajr), àwọn wọ̀nyí a kì í ṣe wọ́n ní ẹdinku.
Kò sí ìyàtọ̀ láàrin àwọn ará Mẹ́kà àti àwọn mìíràn; nítorí pé Anabi -kí ìkẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- bá àwọn ènìyàn tó jẹ́ ará Mẹ́kà àti àwọn mìíràn kirun àdínkù ní Mína, 'Arafah, àti Muzdalifah, kò sì pàṣẹ fún àwọn ará Mẹ́kà láti pé irun wọn, tí ó bá sì jẹ́ pé ó jẹ́ dandan fún wọn ni, ìbá ṣe àlàyé rẹ̀ fún wọn.
Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti yọ ní ọjọ́ Àràfá, ẹni tí ó ń ṣe hajj yóò mórílé Àràfá láti Mìná, ó sì jẹ́ ìlànà anọbi pé kí wọ́n sọkalẹ sí Namirọ títí tí oòrùn yóò fi yẹ̀ kúrò ní àtàrí, tí ìyẹn bá rọrùn; nítorí iṣẹ́ Anabi -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a-.
Tí oòrùn bati yẹ kúrò, o jẹ sunna fun Imaamu tabi arole rẹ lati ṣe khutubah fun awọn eeyan, khutubah ti o ba akoko naa mu, ti yio maa ṣe alaye ninu rẹ ohun ti o jẹ ofin fun alalaaji ni ọjọ yii ati lẹyin rẹ, o si maa npaṣẹ fun wọn pẹlu iberu Ọlọhun ati mimọ Ọ ni ọkan ṣoṣo ati ṣiṣe ifọkansin fun Un ni gbogbo awọn iṣẹ, yoo si maa kìlọ fun wọn kuro nibi awọn nnkan eewọ Rẹ, o si maa ngba wọn niyanju ninu rẹ pẹlu didi Tira Ọlọhun mu ati sunna Anọbi Rẹ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a -, ati ṣiṣe idajọ pẹlu awọn mejeeji, ati wiwa idajọ lọdọ awọn mejeeji ni gbogbo ọrọ; nitori itẹle Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - nibi gbogbo eyi. Lẹyin igba naa ni wọn o wa ki Irun ọsan (Zhuri) àti Irun irọlẹ (Asr) ní méjì méjì, ti wọn yio si kí méjèjì pọ ni àsìko irun alakọkọ pẹlu Adhan ( piperun ) lẹẹkan ati Iqamah lẹẹmeji; nitori iṣe Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a -. Muslim lo gba a wa lati inu hadiithi Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i -.
Lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn yíò dúró ní Àràfá, gbogbo rẹ̀ sì ni ibùdúró àyàfi inú àfonífojì Urana, ó sì jẹ́ ohun tí o dára láti dojú kọ Kibla àti Òkè Àánú (Jabal Rahmah) bí o bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí kò bá sì rọrùn láti dojú kọ àwọn méjèèjì, yíò dojú kọ Kibla bí kò tilẹ̀ dojú kọ òkè náà, ó sì jẹ́ ohun tí o dára fún ẹni tí ó n ṣé haji ní ibùdúró yí láti sa ipá rẹ̀ ní ìrántí Ọlọ́hun tí ó jẹ́ mimọ́ àti ṣíṣe adua sí i, àti idirebe sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè nígbà tí ó n gbàdúrà, bí ó bá sì pe Talbiyyah tàbí kí ó ka díẹ̀ nínú Kuraani, ó dára, Sunnah ni kí ó pọ̀ ní sísọ pé: "LĀ ILĀHA ILLALLĀHU WAḤDAHU LĀ SHARĪKA LAH(U), LAHUL-MULKU WA LAHUL-ḤAMDU, YUḤYĪ WA YUMĪTU WA HUWA ʿALĀ KULLI SHAYʾIN QADĪR"; nítorí ohun tí a gbà wá láti ọ̀dọ̀ Ànábi kí ikẹ Ọlọhun àti Ọlá Rẹ maa ba pé ó sọ pé: Adua ti o loore ju ni adua ọjọ Arafa, atipe eyi ti o lọla ju ti emi pẹlu awọn anabi to saaju mi ma nṣe ni: "laa ilaaha illal laahu wahdahu laa shariika lahi, lahul mulku wa lahul amdu, yuhyii wa yumiitu, wa huwa ala kulli shaihin qodiir". Tí ọ túmọ sí pé « Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun l'O n so ni di alaaye, Oun si l'O n pa ni, Oun sini oba ti o ni ikapa lori gbogbo nkan. O sí tún ni àlàáfíà lati ọdọ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wipe o sọ pe: “Ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹrin ni: SUBHAANALLAH, ati ALHAMDULILLAAH, ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati ALLAHU AKBAR” tí o túmọ sí pé : Mimọ fún Ọlọhun, àti ìyìn fún Ọlọhun , àti pé kòsí ẹnikọ̀ọ̀kan tí o lẹtọ láti jọsin fún ayaafi Ọlọhun àti pé Ọlọhun nìkan lotobi jùlọ.[55]. [54] At-tirmidhi lo gba wa, pẹlu onka (3585). [55] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (2137).
Ó yẹ kí a máa ṣe ìrántí yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, kí a sì máa tún un sọ pẹ̀lú ìtẹríba pẹlu itaji ọkàn, ó sì yẹ pẹ̀lú kí a máa ṣe àwọn ìrántí àti àwọn àdúrà tí ó wá láti inú òfin Ọlọ́hun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní gbogbo ìgbà, pàápàá jùlọ ní ipò yìí ní ọjọ́ ńlá yìí, kí a sì yan àwọn ìrántí àti àdúrà tó gbopọn, nínú rẹ̀ ni:
«Afọmọ ni fun Ọlọhun, ati ọpe niti Ọlọhun, Afọmọ ni fun Ọlọhun ti O tobi». «Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi wà nínú àwọn alábòsí.» [Suuratul Anbiyaah: 87].
«Ko si ẹniti ijọsin tọsi ayafi Allah, atipe awa ko nii sin ẹlomii yatọ si I, Ti Ẹ ni ikẹ nse, ti Ẹ ni ọlá nse atipe ti Ẹ ni ẹyin to rẹwa nse, ko si ẹniti ijosin tọsi àyàfi Allaah ni ẹniti a nse afọmọ ẹṣin fun Un, koda bi kò tilẹ dùn mọn awọn keferi rara ».
« kò sí ète kankan, kò sì sí agbára kankan àfi pẹ̀lú Ọlọ́hun» [56] Muslim lo gba wa láti ọwọ́ Ibn Zubayr, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (594).
« Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná». [Suratul Baqara: 201].
«Ọlọhun, ba mi tun ẹsin mi ṣe, èyí tí ó jẹ́ ìdábo bo fún àlámọrí mi, àti ba mi tun ayé mi ṣe, èyí tí iṣẹmi mi wà nínú rẹ̀, àti ba mi tun ọrun mi ṣe, èyí tí ó jẹ́ ibùpadàsí mi, kí O sì ṣe ìgbésí ayé ní àlékún fún mi nínú gbogbo òòrè, àti ikú ní ìsinmi fún mi kúrò nínú gbogbo aburú. [57] Muslim lo gba wa lati ọdọ Abu Hurayrah, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (2720).
« Mo sàdì Ọlọ́hun kúrò níbi ìpọ́njú àdánwò, àti ìbápadé òṣì, àti àbúrú kàdárà, àti inúdídùn àwọn ọ̀tá »[58]. [58] Al-Bukhari lo gba wa lati ọdọ Abu Hurayrah, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i, pẹlu onka (6347).
«;Irẹ Ọlọ́hun, mo wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kúrò níbi ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́, mo wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kúrò níbi ikagara àti òròjú, mo wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kúrò níbi ọjọ àti ahun, àti níbi ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹrù gbèsè, mo sì wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kúrò níbi kí gbèsè ó borí mi àti ìjẹgàba àwọn ènìyàn lórí mi» [59] Pẹlu gbólóhùn yii ni Baba Daud gba wa lati ọdọ baba Umamah Al-Ansari, láìsí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (Wa minal-ma'thami wal-maghram) pẹlu onka (1554).
“Iwọ Ọlọhun mo fi Ọ wa iṣọ kuro nibi àbàwọ́n ara, àti wèrè, àti ẹ̀tẹ̀, àti kuro nibi aburú àwọn àìsàn” [60]. [60] Bàbá Daud l'o gba wa, lati ọdọ Anas, ki Ọlọhun yọnu si i, pẹlu onka (1554).
« Iwọ Ọlọhun, emi ntọrọ amojukuro Rẹ ati ini Alafia ara ni aye ati ọrun ».
Irẹ Ọlọhun, dajudaju mo n tọrọ àmójúkúrò ati alaafia lọwọ Rẹ ninu ẹsin mi, ayé mi, ará ilé mi, ati dukia mi.
« Ọlọhun ba mi gbe aleebu mi pamọ ki O si fi aya mi balẹ nibi gbogbo ohun ti npami laya, Ọlọhun fi isọ Rẹ sọ mi ni iwaju mi, ati ni ẹyin mi, ati ọtun mi, ati osi mi, ati ni oke mi, mo si fi Ọ wa isọra nibi ki a yọ mi pa lati isalẹ mi. [61] Bàbá Daud lo gba wa láti ọ̀dọ̀ Ibn Umar (kí Allāhu yọ́nú sí i), pẹlu onka (5074).
« Irẹ Oluwa fi ori jin mi isẹ gidi mi ati awada mi, ati asise mi ati mọọmọ mi, ati pe gbogbo eyi wa lọdọ mi, ati ohun ti mo ti se siwaju ati si ẹyìn, ati ohun ti mo se ni kọkọ ati ni gbangba, ati ohun ti O mọ nipa Rẹ ju emi lọ. Irẹ ni O maa nti nkan siwaju, Irẹ ni O si maa nti nkan si ẹyìn, ati pe O lagbara lori ohun gbogbo. [62] Abala kan ni ninu hadith tí Muslim gba wa láti ọwọ́ bàbá Mūsā Al-Aṣ'arī, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (2719).
* Irẹ Ọlọhun, mo n tọrọ lọwọ Rẹ idurosinsin lori aṣẹ Rẹ ati ini-ipinnu lori itọsọna, mo si n tọrọ ọpẹ́ fún ìkẹ́ Rẹ àti ìjọ́sìn rere, mo si n tọrọ ọkàn mímọ́ àti ahọ́n olóòótọ́, mo si n bẹ Ọ́ nínú oore tí Irẹ Ọlọhun mọ̀, mo sì ń fi Ọ́ sàbò kúrò nínú aburú tí Iwọ Ọlọhun mọ̀, mo sì ń tọrọ àforíjìn Rẹ fún ohun tí O mọ̀, dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ gbogbo kọkọ [63]. [63] At-tirmidhi l'o gba wa láti ọwọ́ Shaddad ọmọ Aus (kí Allāhu yọ́nú sí i), pẹlu onka (3407).
« Mope Irẹ Ọlọhun, Oluwa Anabi Muhammad, kí ọlá Ọlọ́hun àti ìkẹ́ Rẹ̀ máa bá a, forí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí, kí O sí mú ìbínú ọkàn mi kúrò, kí O sí gbà mí lọ́wọ́ àwọn àdánwò tó ń ṣini lọ́nà níwọ̀n ìgbà tí O bá fi wá sípò ààyè [64]. [64] Ahmad lo gba wa lati inu hadith Iya Salamah, ki Ọlọhun yọnu si i (6/301).
* Mo pe Iwọ Ọlọhun Oluwa sanmo mejeeje, Oluwa ile mejeeje, Oluwa to ni aga al-arashi to tobi, Ọlọhun wa, Oba gbogbo nkan, Olumu eso ati koro hu jade, Olusọ taorah ati injiil ati al-fur'qooni ti nse Al kuraani kalẹ, mo fi Ọ wa isọra kuro nibi aburu gbogbo nkan to jẹ pe aaso ori re nbe lọwọ Re, mo pe Iwọ Ọlọhun Iwọ ni Ọba akọkọ ti nkankan ko gbawaju Rẹ, Iwọ ni Ọba igbẹyin ti nkankan ko si lẹyìn Rẹ, Iwọ ni Ọba ti O han, ko si nkankan ni oke Rẹ, Iwọ ni Ọba ti o pamo, ti ko si nkankan ti o pamo ju Ọ lọ, ba wa san gbese ọrun wa ki O si la wa kuro ninu osi [65]. [65] Muslim lo gba wa lati inu hadith Abu Hurairah (Ki Ọlọhun yọnu si i), pẹlu onka (2713).
« Ọlọhun, fún ẹ̀mí mi ní ìbẹ̀rù Rẹ, kí o sì sọ ọ́ di mímọ́, Ìwọ l'Oóre jùlọ láti sọ ọ́ di mímọ́, Ìwọ ni Aláàbò rẹ àti Olùrànlọ́wọ́ rẹ. Olohun, mo fi O wá ìsora kúrò níbi ìkàgàrà àti ìkóròjú, àti pé mo fi Ọ wá ìsora kúrò níbi ojo ṣíṣe àti ogbó àti ahun, àti pé mo fi Ọ wá ìsora kúrò níbi ìyà sàárè [66]. [66] Muslim lo gba wa lati ọdọ Zaid ọmọ Arqam, ki Ọlọhun yọnu si i, pẹlu onka (2722).
« Ìwọ Ọlọ́hun, Ìwọ ni mo juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, Ìwọ nìkan náà ni mo sì gbàgbọ́, Ìwọ náà sì ni mo gbára lé, ọ̀dọ̀ Rẹ náà sì ni mo tuba lọ, pẹ̀lú Rẹ sì ni mo fi gbógunti. Mo fi iyì Rẹ wá ìṣọ́ kúrò níbi kí O jẹ́ kí n sọnù; kò sí ẹlòmíràn tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ, Ìwọ ni Alààyè tí kì í kú, àwọn àlùjọ̀nnú àti àwọn ènìyàn a sì máa kú [67]. [67] Muslim lo gba wa láti inú hadith ọmọ Abbas, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí awọn mejeeji, pẹlu onka (2717).
*Irẹ Ọlọ́hun, mo wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kuro nibi imọ̀ tí kò ní anfaani, mo sì wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kuro nibi ọkàn tí kò ní ìpayà, mo sì wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kuro nibi ẹ̀mí tí kìí yó, mo sì wá ìṣọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ kuro nibi àdúà tí a kì í gbà. [68] Èyí jẹ́ apá kan nínú hadith Zaid ọmọ Arqam, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i, èyí tí ìtọ́kasí rẹ̀ ti ṣáájú pẹlu ounka (2722).
« Irẹ Ọlọhun, so mí jìnnà sí ìwà búburú, àti iṣẹ́ búburú, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àti àrùn búburú [69]. [69] At-Tirmidhi lo gba wa lati ọdọ Ziyad ọmọ 'Alaqah, lati ọdọ arakunrin baba rẹ, pẹlu onka (3591).
* Ọlọhun, fi ìmọ̀nà mi mọ̀ mí, kí o sì sọ mí kúrò níbi aburú araa mi [70]. [70] At-tirmidhi lo gba wa láti ọdọ̀ Imran ọmọ Husain, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (3483).
* Olohun fi halaali ( ẹtọ ) Rẹ tomi kuro nibi nkan haram Eewọ ) Rẹ, ki Ọ si fi ọlá Rẹ sọmi di ọlọrọ kuro nibi ohun ti o ba yato si O.[71] [71] At-tirmidhi lo gba wa nínu hadith Ali (kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i), pẹlu onka (3563).
*«Irẹ Ọlọhun, mo n tọrọ lọ́wọ́ Rẹ, imọna, àti ìpayà, àti ikora ẹni ni ijanu, àti irọrọ» [72]. [72] Muslim lo gba wa lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i, pẹlu onka (2721).
* Irẹ Ọlọhun, emi n tọrọ lọ́wọ́ Rẹ imọna àti ìdúródéédé [73]. [73] Muslim lo gba wa láti ọ̀dọ̀ Ali, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (2725).
Ọlọhun, dajudaju emi nbeere gbogbo oore lọwọ Rẹ, ti isinsinyi ati ti ọjọ iwaju, eyi ti mo mọ ninu re ati eyi ti nko mo, mo si nfi O wa isora kuro nibi gbogbo aburu, ti isinsinyi ati ti ojo iwaju, eyi ti mo mo ninu re ati eyi ti nko mo. Mo si nbeere oore ti erusin Re ati Anabi Re Muhammad (ki ike ati ola Olohun ki o maa baa) toro lọwọ Re, mo si nfi O wa isora kuro nibi aburu ti erusin Re ati Anabi Re Muhammad (ki ike ati ola Olohun ki o maa baa) ti wa isora kuro nibi re. Olohun, dajudaju emi nbeere Alujanna lọwọ Rẹ̀ ati ohun ti o le mu ni sunmọ on ninu ọrọ tabi ise, mo si nfi Ọ wa isọra kuro nibi Ina ati ohun ti o le mu ni sunmọ on ninu ọrọ tabi iṣẹ. Mo si nbeere lọwọ Rẹ wipe ki O se gbogbo kadara ti Ọ kadara rẹ fun mi ni oore. [74] Omọ Majah l'o gba a wa láti ọ̀dọ̀ Aishah, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i, pẹlu onka (3846).
*Ko si ẹnití ijosin to si ayafi Allah nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ola nse, ti E ni eyin nse, Oun ni njini Oun ni si npani, owo Re ni gbogbo daada wa, Oun ni alagbara lori gbogbo nkan, mimo fun Allaah, eyin ti Allaah ni, ko si si eniti ijosin tosi ayafi Allaah, atipe Allaah ni O tobi ju, atipe ko si ogbon ko si agbara ayafi pelu Allaah Oba ti O ga ju ti O si tobi[75]. [75] Al-Bukhari lo gba wa látọ̀dọ̀ Ubadah ọmọ As-Samit, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (1154).
« Ọlọhun se ikẹ fún Anọbi Muhammad, àti fún àwọn ará ilé Anọbi Muhammad, gẹ́gẹ́ bí O ti se ikẹ fún Anọbi Ibrahim, àti fún àwọn ará ilé Anọbi Ibrahim; dájúdájú Ìwọ ni Ọba Ẹlẹ́yìn, Ọba tí Ó gbọ̀ngbọ̀n. Kí O sì se ìbùkún fún Anọbi Muhammad, àti fún àwọn ará ilé Anọbi Muhammad, gẹ́gẹ́ bí O ti se ìbùkún fún Anọbi Ibrahim, àti fún àwọn ará ilé Anọbi Ibrahim; dájúdájú Ìwọ ni Ọba Ẹlẹ́yìn, Ọba tí Ó gbọ̀ngbọ̀n [76]. [76] Al-Bukhari lo gba wa láti ọ̀dọ̀ Ka'b ọmọ 'Ujrah, kí Allaah yọ́nú sí i, pẹlu onka (3370).
Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná. [Suratul Baqara: 201].
‹ Ó sì jẹ́ fífẹ́ ní ibùdúró ńlá yìí kí ẹni tí nṣe ìjọsìn Hajj máa tún àwọn ìrántí Ọlọhun àti àwọn adua tí ó ti ṣíwájú sọ, àti ohun tí ó bá jọọ́ ní ìtumọ̀ nínú ìrántí Ọlọhun àti adua àti ìtọrẹ ìkẹ́ fún Ànábì (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a), kí ó sì wo mọ́ adua ṣíṣe, kí ó sì béèrè rere ayé àti ti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ànábì (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a), tí ó bá ṣe adua, ó máa ń tún un sọ ní ẹẹmẹta, nítorínáà ó yẹ kí á fi ṣe àwòkọ́ṣe nínú ìyẹn, kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a.
Musulumi yóò wà ní ipò yìí ní ẹni tó ń tẹríba fún Olúwa rẹ̀ -Mímọ́ ni Fún Un-, tó jẹ́ onírẹlẹ sí I, tó sì ro ara rẹ̀ pìtì níwájú Rẹ̀, ó ń retí ìkẹ́ Rẹ̀ àti àforíjìn Rẹ̀, ó sì ń bẹ̀rù ìyà Rẹ̀ àti ìbínú Rẹ̀, ó ń se ìsirò ara rẹ̀, ó sì ń sọ ìrònúpìwàdà òdodo di ọtun; nítorípé ọjọ́ ńlá ni èyí àti àpéjọ ńlá, Ọlọhun a máa se ọ̀pọ̀ oore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nínú rẹ̀, a sì máa fi wọ́n ṣefefe sí àwọn mọlaika Rẹ̀, ìtúsílẹ̀ kúrò nínú iná sì máa pọ̀ nínú rẹ̀. A kò rí Èṣù rí ní ọjọ́ kan tí ó jẹ́ ẹni-ìlékúrò, ẹni-àìkàsí, àti ẹni-ìtẹ́mọ́lẹ̀ ju ọjọ́ Arafa lọ, àfi ohun tí a rí ní ọjọ́ Badar; èyí jẹ́ nítorí ohun tí ó ń rí nínú oore Ọlọhun sí àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ àti iṣẹ́-rere Rẹ̀ sí wọn àti bí ìtúsílẹ̀ àti àforíjìn Rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.
O wa ninu Sohiihu Muslim, lati ọdọ A'isha kí Ọlọhun yọnu sí, dájúdájú Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ máa ba a - sọ pé: «Kò sí ọjọ́ kan tí Ọlọ́hun ti máa ń sọ ẹrú di omnira kúrò nínú iná tó pọ̀ ju ọjọ́ Arafa lọ, dájúdájú Ó máa ń súnmọ́ wọn, lẹ́yìn náà, Ó sì máa fi wọ́n yangàn sí àwọn malaika, yóò sì wá sọ pé: ‘Kí ni àwọn wọ̀nyí fẹ́?’» [77]. [77] Muslim lo gba wa lati ọdọ Aisha, kí Allāhu yọ́nú síi, pẹlu onka (1348).
Ó yẹ kí àwọn Mùsùlùmí fi rere han Ọlọ́hun nínú ara wọn, kí wọ́n sì yẹpẹrẹ ọ̀tá wọn tii se èṣù, kí wọ́n sì ba inú rẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú púpọ̀ nínú ìrántí Ọlọ́hun, àdúà, àti rírọ̀mọ́ ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe. Àwọn alálààájì kò sì ní yéé jẹ́ ẹni tó ń ṣe ìrántí Ọlọ́hun, àdúà, àti ìdẹ́bẹ̀ síwájú Rẹ̀ ní ibi ìdúró yíì títí tí oòrùn yíò fi wọ̀, tí oòrùn bá ti wọ̀, wọ́n á lọ sí Musidalifa pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn àti ọlá, kí wọ́n sì máa pe Talbiyah púpọ̀, kí wọ́n sì yára ní àwọn ààyè tó gbòòrò; nítorí iṣe Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a - Kò sì lẹtọọ láti kúrò ṣíwájú kí oòrùn tó wọ̀; nítorí pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a - dúró títí tí oòrùn fi wọ̀, ó sì sọ pé: ""Ẹ gba ẹkọ awọn iṣẹ Hajj yin lati ọdọ mi"" [78] [78] Ìtọ́kasí rẹ̀ ti ṣíwájú.
Tí wọ́n bá dé Muzdalifat, wọ́n yóò kí irun Magrib níbẹ̀ ní rakah mẹ́ta àti irun Ishai ní rakah méjì ní apapọ̀, pẹ̀lú pipe irun àti Iqamah méjì ní kété tí wọ́n bá dé ibẹ̀; nítorí iṣẹ́ Anọbi – kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a –, yálà wọ́n dé Muzdalifat ní àkókò irun Magrib tàbí lẹ́yìn tí àkókò irun Ishai bá ti wọlé.
Ohun tí àwọn kan nínú àwọn ènìyàn máa ń ṣe nípa sísa òkúta tí a fi ń ju oko ní kété tí wọ́n bá dé Musidalifa ṣíwájú kí wọ́n tó kírun, àti gbígbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn pé èyí bá òfin mu, àsìṣe ni, kò sì ní ìpìlẹ̀. Anabi -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- kò pa á láṣẹ pé kí wọ́n sa òkúta fún òun àfi lẹ́yìn ìgbà tí ó ti kúrò ní Maṣ'ar lọ sí Mìná. Ibikíbi tí ènìyàn bá sì ti sa òkúta náà, ó ti tó fún un, kò pọn dandan pé kí á sa á ní Musidalifa, ṣùgbọ́n ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sa á ní Mìná. Sunna ni pé kí á sa méje ní ọjọ́ yìí, tí a ó fi ju Jamratul Akọba; láti fi ṣe àfarawé Anabi -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a-. Ní ti àwọn ọjọ́ mẹ́ta yòókù, a ó máa sa òkúta mọ́kànlélógún ní Mìná lójoojúmọ́ láti fi ju àwọn Jamarat mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
Kò yẹ láti wẹ òkúta, kàkà bẹ́ẹ̀, a máa fi ju ú láì wẹ̀ ẹ́; nitoripe a kò rí i gbà wá látọ̀dọ̀ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - àti àwọn sàábà rẹ̀, a o si ni ju pẹlu okuta ti a ti lò.
Alalaaji yóò sun ní Muzdalifah ní alẹ́ yìí, ó sì lẹ́tọ̀ fún àwọn aláìlágbára nínú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé àti àwọn míìrán tó dà bíi wọn láti lọ sí Mina ní ìparí òru; nítorí hadith ‘Ā’ishah àti ìyá Salamah àti àwọn mìíràn. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn yòókù nínú àwọn alálàájì, a tẹnumọ́ ọn fún wọn pé kí wọ́n wà níbẹ̀ títí tí wọ́n yóò fi kirun aarọ, lẹ́yìn náà kí wọ́n dúró ní ìdí Al-Mash'ar Al-Haram ( èyí wa Ni Muzfalifah) , kí wọ́n sì da ojú kọ Qiblah, kí wọ́n sì pọ nínú iranti Ọlọhun àti igbe Ọlọhun tobi àti ṣíṣe adua títí tí ojú ọjọ́ yóò fi là dáadáa. Ati pe a fẹ gbigbe ọwọ mejeeji soke nibi ni akoko ṣiṣe adura, ati ibikibi ti wọn ba duro si ni Muzdalifah iyẹn ti to fun wọn, ko si jẹ ọranyan lori wọn lati sunmọ Mash'ar tabi ki wọn gun un; nitori ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -: «mo duro ní ààyè yí níbi - ìyẹn ni pé ní Al-Mash'ar Al-Haram - àtipe àkójọ papọ gbogbo rẹ ni ààyè ìdúró» [79] Muslim lo gba a wa ninu sohiihu (tira) rẹ, "Jam'u" ni Muzdalifah. [79] Muslim lo gba a wa lati ọdọ Jabir, ki Ọlọhun yọnu si i, pẹlu onka (1218).
Tí ilẹ̀ bá ti mọ́ dáadáa, wọn yóò darí sí Mina kí oòrùn tó yọ, kí wọ́n sì má ṣe labbayka (gbólóhùn ijẹpe) lọpọlọpọ nínú ìrìn wọn. Tí wọ́n bá dé Muhassar, a fẹ́ kí wọ́n yara rìn díẹ̀.
Tí wọ́n bá dé Mìná, wọn yóò dá Talbiyah dúró níbi Jamratul Aqaba, lẹ́yìn náà, wọn yóò jù ú nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé pẹ̀lú òkúta méje tí wọ́n yóò jù tẹ̀le ara wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, yóò máa gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè nígbà tí ó bá ń ju òkúta kọ̀ọ̀kan, yóò sì máa gbé Ọlọ́hun tóbi. Ó sì jẹ́ ohun tí ó yẹ kí ó jù ú láti inú àfonífojì, kí ó fi Kaaba sí apá òsì rẹ̀, kí Mìná sì wà ní apá ọ̀tún rẹ̀; nítorí iṣe Anabi - kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a -. Tí ó bá sì jù ú láti àwọn apá yòókù, ó tó fún un tí òkúta náà bá bọ́ sínú ibi ìjùkò náà. Kò sì pọndandan kí òkúta náà kù sínú ibi ìjùkò, ṣùgbọ́n ohun tí ó jẹ́ dandan ni pé kí ó bọ́ sínú rẹ̀. Tí òkúta náà bá bọ́ sínú ibi ìjùkò, lẹ́yìn náà tí ó jáde kúrò níbẹ̀, ó gbà fún un ní ìhàn gbangba ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀. Lára àwọn tí ó sì ṣe àlàyé rẹ̀ kedere ni: An-Nawawī - kí Ọlọ́hun bawa kẹ ẹ - nínú ìwé Sharhu al-Muhadhab. Òkúta Jamarat yóò sì jẹ́ bíi òkúta ìta-kòkò, ó sì tóbi díẹ̀ ju ẹwa lọ.
Lẹyin naa, lẹyin sísọ oko, ni yóò dunbu ẹran adaaya rẹ, o sì jẹ ohun tí a fẹran ki o sọ nigba ti o ba fẹ gun un tabi ti o fẹ dunbu rẹ pe: "BISMILLAHI WALLAHU AKBAR, ALLAHUMMA HADHA MINKA WA LAKA", èyí tí o túmọ sí pé : « Pẹlu orúkọ Ọlọhun, Ọlọhun ní ọ to bí jùlọ, Irẹ Ọlọhun , ọdọ Rẹ ni eleyii tí wà tí yóò sí padà sí ) yóò si kọjú rẹ si Qiblah. Sunna ni ki a gun rakunmi looro ti a ó fi okun di ẹsẹ osi rẹ to nbẹ niwaju soke, ati ki a dunbu maalu ati ẹran lori ẹgbẹ osi rẹ. Tí o ba si dunbu rẹ si ibomiiran yatọ si Qiblah, o ti fi sunna silẹ, ṣugbọn ohun ti o pa yẹn ti tó fun un; nitori pe kikoju nkan si Qiblah nigba didunbu, sunna ni, kii ṣe ọranyan. Wọ́n tun fẹran ki o jẹ ninu ẹran adaaya rẹ, ki o fi ṣe ẹbùn, ki o si fi ṣe saara; nitori ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: « ... Ẹ jẹ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi bọ́ aláìlera, tálíkà. [Suratul Hajj: 28], Àsìkò didu ẹran naa si silẹ títí dé ìwọ̀ oòrùn ọjọ́ kẹta nínú àwọn ọjọ́ Tashreeq (Iguran), lórí ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀ tí ó tọ́ jùlọ, nítorí náà, àkókò tí a fi n du ẹran jẹ́ ọjọ́ Yawmun-Nahri (igunran àti ipá ẹran) àti ọjọ́ mẹta lẹ́yìn rẹ̀.
Lẹ́yìn bẹ , lẹ́yìn pípa ẹran Hadaya (ẹran ìjọsìn) tan, yóò fa irun orí rẹ̀ tàbí kí o gẹ ẹ́, fifa irun ni ó lọlá jù; nítorí pé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tọrọ ìkẹ àti àforíjìn fún àwọn olufari (lẹẹmẹta), ó sì tọrọ rẹ fún àwọn olùgérun-kuru lẹẹkan. Gígẹ apá kan nínú irun orí kò tó, ṣùgbọ́n ó pọn dandan pé kí gígẹ náà kárí gbogbo orí gẹ́gẹ́ bíi fifa. Ní ti obìnrin, yóò gẹ nínú ìdírun rẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n orí ika kan tàbí kí ó dínkù síbẹ̀.
Lẹ́yìn jíju òkúta ní 'Aqabah àti fífa irun orí tàbí gígé e kúrú, gbogbo nǹkan tí ó jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó gbé harami nípasẹ̀ harami rẹ̀ yóò di ètọ fún un, àyàfi àwọn obìnrin. Wọ́n sì máa ń pe ìtúsílẹ̀ yìí ní: Ìtúsílẹ̀ àkọ́kọ́. Ó jẹ́ ìlànà Anọbi fún un lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ yìí láti lo òórùn dídùn, kí ó sì forí lé Makkah, láti lọ ṣe Tọwafu Ifadọh; nítorí hadith A'ishah, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i, tó sọ pé: « Emi a maa fi lọfinda si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lara fun ihram ṣiwaju ki o to gbe harami, ati fun ipari harami rẹ siwaju ki o to tawaf kaaba ( rọkirika ) » [80] Bukhaari lo gbe e jade àti Muslim. [80] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1539), àti Muslim pẹlu onka (1189).
A si n pe irọkirika yii ni: Tawaaful Ifaadọ, ati Tawaafu Ziyaarah, o si jẹ origun kan ninu awọn origun Hajj, Hajj ko si le pe lai si i, oun si ni erongba ninu ọrọ Rẹ Ọlọlá wipe: « Lẹ́yìn náà, kí wọ́n yanjú ìdọ̀tí ara wọn fún ìparí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé náà.» [Al-Hajj 29].
Lẹyìn náà, lẹyìn irọkirika ile Ọlọhun àti kíkirun raka méjì lẹyìn ààyè ìdúró Anọbi Ibrahim, yóò se ipọsẹsẹ láàrin Sọfa àti Marwah tí o bá jẹ́ pé ó jẹ́ ẹni tí nṣe Hajj ibọ Arami silẹ lẹyìn Umrah (Tamattu'). Ipọsẹsẹ yìí jẹ́ fún ìjọsìn Hajj rẹ̀, ipọsẹsẹ àkọ́kọ́ sì jẹ́ fún Umrah rẹ̀.
Safa àti Mariwa kan kò tó nínu ọ̀rọ̀ àwọn onímímọ̀ tó tọ̀nà jùlọ; nítorí hadith Aishah -ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: «A jade pẹlu ojiṣe Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-» o wa sọ hadith naa, o si wa ninu rẹ pe o sọ pe: «Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ẹran adáyà dání, kí ó ṣe àrámi Hajj pẹ̀lú 'Umrah, lẹ́yìn náà kò sì ní tú arámi títí yóò fi parí àwọn méjèèjì papọ̀»... titi de ibi tí o tí sọ pé: « Ni awọn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ‘Umrah ba rọ̀kirika Ilé náà, wọ́n sì pọ ṣẹṣẹ láàrin Sọfā àti Mọrwah, lẹ́yìn náà wọ́n tú. Wọ́n sì tún ṣe ìrọ̀kirika mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n ti padà láti Mina fún Hajj wọn.» [81] Bukhari ati Muslim ni won gba a wa. [81] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1556), àti Muslim pẹlu onka (1211).
Ati gbolohun rẹ - kí Ọlọ́hun yọnu si i - nípa àwọn tí wọ́n dá Umurah lé: “Lẹ́yìn náà, wọ́n tún ṣe tawaafu mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n padà dé láti Mina fún hajj wọn”, ohun tí ó fi túmọ̀ sí ni: ipọsẹsẹ láàárín Safa àti Mariwa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó péye jùlọ nínú ìtumọ̀ hadisi yìí. Ṣùgbọ́n ní ti èrò ẹni tí ó sọ pé irọkirika ile Oluwa ti Ifaadọ ni ó ní lọ́kàn pẹ̀lú èyí, kò tọ̀nà; nítorí pé irọkirika ile Oluwa ti Ifaadọ jẹ́ origun fún gbogbo ènìyàn, wọ́n sì ti ṣe é. Ṣùgbọ́n ohun tí a fẹ́ sọ níbẹ̀ ni pé ohun tó kan ẹni tó ń ṣe hajj Tamattu, èyí tí í ṣe ipọsẹsẹ láàárín Safa àti Mariwa ní ìgbà kejì lẹ́yìn tí a bá ti padà dé láti Mina láti fi parí hajj rẹ̀. Èyí sì hàn kedere, ọpẹ́ ni fún Ọlọ́hun, òun sì ni èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímímọ̀.
ohun ti o n fi ododo eleyii han pẹlu ni ohun ti Bukhaari gbe jade nínú Sọhiihu rẹ ni muhallaq ti wọn fi rinlẹ, láti ọ̀dọ̀ ọmọ Abbaas - ki Ọlọhun ba wa yọnu si awọn mejeeji -, pe wọn bi i leere nipa Hajj Tamattuhi, o wa sọ bayi pe: «Àwọn Muhajirun ( awọn Musulumi ti wọn wa láti ìlú Makkah) Ansaar ( Awọn musulumi tí wọn jẹ àrà Modinah ) àti àwọn ìyàwó Anabi - ki ikẹ ati igẹ Ọlọhun maa ba a-, gbé aniyan nínu hajji ìdágbére, àwa náà sì gbé aniyan. Nígbà tí a dé Makkah, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati igẹ Ọlọhun maa ba a- sọ pé: ‘Ẹ sọ aniyan Hajj yín di umrah, àyàfi ẹni tí ó bá mú ẹran ijọsin dání.’ A sì rọkirika Ilé Ọlọhun àti Safa àti Mariwat, a súnmọ́ àwọn obinrin, a sì wọ aṣọ wa. O sì sọ pé: ‘Ẹni tí ó bá mú ẹran ijọsin dání, kò ní le bọ́ra sílẹ̀ títí di ìgbà tí ẹran náà yóò fi dé ibi pípa rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún wa ní àṣálẹ́ ọjọ́ Tarwiyah pé kí a tún gbé aniyan Hajj. Nígbà tí a bá sì parí àwọn iṣẹ́ Hajj náà tán, a padà wá, a sì rọkirika Ilé Ọlọhun àti Safa àti Mariwat» [82]. Oun ti a fẹ ninu rẹ lo pari sibi, o si jẹ́ ohun tó hàn gbangba nípa ṣíṣe Sa'i lẹ́ẹ̀mejì fún al-mutamatti', Ọlọhun lo sì mọ ju. [82] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1572).
Ní ti èyí tí Muslim gba wa láti ọdọ Jaabir -ki Ọlọhun yọnu si i-: ««Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - àti àwọn saabe rẹ kò ṣe tawaafu láàrin Sọfa àti Marwah àfi irọkirika kan ṣoṣo» [83], Tawaafu wọn àkọ́kọ́, ni wan fi sọri àwọn tí wọ́n fa ẹran ìjọsìn lọ́wọ́ nínú àwọn Saabe; nítorí pé wọ́n wà lórí harami wọn pẹ̀lú Ànábì - ki ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - títí wọ́n fi bọ́ra sílẹ̀ kúrò nínú hajji àti umrah méjèèjì papọ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ànábì - ki ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - ti gbé harami fún hajji àti umrah, ó sì pa àwọn tí wọ́n fa ẹran ìjọsìn lọ́wọ́ láṣẹ pé kí wọ́n gbé harami fún hajji pẹ̀lú umrah, àti pé kí wọ́n má ṣe bọ́ra sílẹ̀ títí wọ́n yóò fi bọ́ra sílẹ̀ kúrò nínú méjèèjì papọ̀; Al-Qaarin, ẹni tí ó pa Hajj àti Umrah pọ̀, kò sí Sa'i ( ipọsẹsẹ ) kankan lórí rẹ̀ àfi ẹyọ kan ṣoṣo, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Hadith Jaabir tí a mẹ́nu bà àti àwọn Hadith ododo mìíràn. [83] Muslim lo gba wa pẹlu onka (1215).
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹni tí ó ṣe Hajj Ifrad (tí ọ da ìjọsìn Hajj se Lai pa a pọ mọn Umrah) tí ó sì wà pẹ̀lú harami rẹ̀ títí di ọjọ́ ọdún, kò sí fún un ju ipọsẹsẹ kan ṣoṣo lọ. Tí ẹni tí ó nṣe Qiran àti Ifrad bá sì ṣe ipọsẹsẹ lẹ́yìn Tawaf al-Qudum, èyí yẹn yóò tó fún un kúrò nínú ṣíṣe ipọsẹsẹ lẹ́yìn Tawaf al-Ifadah. Èyí sì ni ìṣọ̀kan láàrin hadisi méjì ti Aisha àti ọmọ Abbas pẹ̀lú hadisi Jabir tí a mẹ́nubà, pẹ̀lú èyí ni àìbáramu yóò fi kúrò, tí a óò sì lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn hadisi náà pátápátá.
Lára nǹkan tí ó fi ìdí ìpanupọ̀ yí múlẹ̀ ni pé hadiisi méjèèjì ti Aisha àti ọmọ Abbaas jẹ́ hadiisi méjì tó ní àlàáfíà, wọ́n sì ti fi ipọsẹsẹ ẹlẹ́ẹ̀kejì rinlẹ fún ẹni tó ń ṣe Hajj Mùtámóti'u, nígbàtí ohun tó hàn nínú hadiisi Jaabir kọ èyí. A sì máa ń gbé ìfirinlẹ̀ ṣáájú ìsẹ́ni, gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹsẹ̀ rinlẹ nínú ìmọ̀ méjèèjì ti Usūl àti Mustalah al-Hadiith. ( Òun ni ipilẹ imọ Frua ati imọ hadith) Ọlọhun sì ni Aṣekọ́ngẹ́ sí ohun tó tọ̀nà, kò sì sí agbára tàbí okun àyàfi pẹ̀lú Ọlọhun.
Abala Àkòrí ọrọ
Alaye ohun tí ọ lọla ju lọ tí Alaalaji ni láti ṣe ní ọjọ́ iduran.
Ohun tí ó lọlá jù fún ẹni tó ń ṣe haji ni kí ó to àwọn nǹkan mẹ́rin wọ̀nyí ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé ní ọjọ́ ọdún gẹ́gẹ́ bí a se sọ ọ: kí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú jiju Jamratul Aqabah, lẹ́yìn náà kí ó du ẹran, lẹ́yìn náà kí ó fári tàbí kí ó din irun rẹ̀ kù, lẹ́yìn náà kí ó ṣe Tawaafu ilé Ọlọhun àti ipọsẹsẹ lẹ́yìn rẹ̀ fún ẹni tí ó ṣe tamattu', bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ẹni tí ó ṣe ifrọọdu àti kirọọnu tí wọn kò bá ti sa pẹ̀lú tawaaful-kuduum. Tí ó bá sì gbé àwọn kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣáájú àwọn kan, ìyẹn lẹtọọ fún un; nítorí pé ìyọ̀ǹda ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a – nípa ìyẹn. Síṣíwájú ipọsẹsẹ lé Tawaafu lórí náà wà nínú ìyẹn; nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí a ń ṣe ní ọjọ́ ọdún, ó sì ti wọ abẹ́ ọ̀rọ̀ Sọhábì pé: “Wọn kò bi í ní ọjọ́ yẹn nípa nǹkan kan tí a ṣe ṣáájú tàbí tí a fà sẹ́yìn bí kò ṣe pé ó sọ pé:” «Ṣe é, kò sì sí wàhálà» [84], Àti pé nítorí pé ó jẹ́ lára àwọn nǹkan tí ìgbagbe àti àìmọ̀ ti máa ń ṣẹlẹ̀, ó sì pọn dandan pé kí ó wọ inú gbogbogbòò yìí; nítorí ìrọ̀rùn àti ìdẹ̀ra tí ó wà nínú rẹ̀. [84] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (83), àti Muslim pẹlu onka (1306).
Ati pe o ti fẹsẹmulẹ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe wọn bi i leere nipa ẹni ti o sa safa ati mariwa ṣiwaju ki o to rọkirika ile Oluwa, o si sọ pe: "Kò sí ẹ̀ṣẹ̀" [85] Bàbá Daud ni o gbe e jade, lati inu hadith Usamah ọmọ Sharik pẹlu ẹgbawa ti o ni alaafia, eyi si mu ki o han gbangba pe o wa ninu akopọ gbogbogboo lai si iyemeji, Ọlọhun si ni Olu fini se deede . [85]Bàbá Daud lo gba a wa, pẹlu onka (2015).
Àwọn nǹkan tí alalaaji fi máa ń bọ aṣọ harami sílẹ̀ pátápátá jẹ́ mẹ́ta, àwọn ni: jíju òkúta níbi Jamratul Akọba, fífa orí tàbí gígé irun kúrú, àti ṣíṣe Tọwafu Ifadọh pẹ̀lú ipọsẹsẹ lẹ́yìn rẹ̀. Tí ó bá ti ṣe àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí tan, gbogbo nǹkan tí ó jẹ́ èèwọ̀ fún un nítorí ìwọṣọ harami yóò di ẹ̀tọ́ fún un gẹgẹbii sisunmọ obìnrin, lilo lọfinda àti àwọn mìíràn. Ẹni tí ó bá sì ṣe méjì nínú wọn, gbogbo nǹkan tí ó jẹ́ èèwọ̀ fún un nítorí ìwọṣọ harami yóò di ẹ̀tọ́ fún un, àfi isunmọ obìnrin, a sì ń pe èyí ní: Ìbọra-sílẹ̀ Àkọ́kọ́.
Ó sì jẹ́ fífẹ́ fún aláàájì mímu nínú omi samsam àti mímu rẹ̀ ní àmuyó, àti ṣíṣe adura pẹ̀lú èyí tí ó bá rọrùn fún un nínú adura tí ó sanfaani, "Omi zamzam wa fun ohunkohun ti a ba tori rẹ mu u ni." [86] Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu sọhiihu Muslim lati ọdọ Abu Dharr: pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ nipa omi zamzam pe: ""Dájúdaju titọwo rẹ jẹ ounjẹ to dun " [87]." Bàbá Dawood ṣafikun pe: “iwosan ni fun aisan” [88]. [86] Ọmọ Maajah lo gba wa lati ọdọ Jaabir ọmọ Abdullah- ki Ọlọhun yọnu si i-, pẹlu onka (3062). [87] Muslim lo gba a wa, pẹlu onka (2473). [88] Ó túmọ̀ sí: Abu Daa'ud At-Tọyālisi, òun sì ni ó gbé e jáde nínú hadith ìtàn gbigba I'slām Abu Dharr (kí Allāhu yọ́nú sí i). Wo Musnad Bàbá Daa'ud At-Tọyālisi pẹlu oúnka (459).
Lẹ́yìn Tawaafu Ifadah, àti Sa'y fún ẹni tí ó bá wà fún, àwọn alalaaji yóò padà sí Mina, wọn yóò sì dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta pẹ̀lú àwọn òru rẹ̀. Wọn yóò máa ju àwọn Jamarat mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ mẹ́ta náà lẹ́yìn tí oòrùn bá ti yẹ àtàrí, ó sì jẹ́ dandan kí wọ́n tẹ̀lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ní jíjù rẹ̀.
Yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Jamrah àkọ́kọ́: òhun ni èyí tí ó tẹ̀lé mosalasi Al-Khaif, yóò sì jù ú pẹ̀lú òkúta méje tẹ̀le ara wọn, yóò máa gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè pẹ̀lú òkúta kọ̀ọ̀kan. Nínú ìlànà anọbi ni kí ó sún sẹ́yìn kúrò níbẹ̀, kí ó fi sí apá òsì rẹ̀, kí ó kọjú sí Qiblah, kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè, kí ó sì pọ̀ nínú àdúà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.
Lẹyìn náà ni yóò jù oko eleekeji gẹgẹ bii alakọkọ, bẹẹ ní o jẹ́ sunnah pé kí ò sún síwájú díẹ̀ lẹ́yìn jùjú rẹ̀, yóò sì fi sí apá ọ̀tún rẹ̀, yóò sì da ojú kọ Qiblah, yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè, yóò sì se àdúà púpọ̀.
Lẹ́yìn náà yóò ju òkúta ẹlẹẹkẹta náà, kò sì ní dúró níbẹ̀.
Lẹyìn náà ni yóò ju awọn òkúta ní ọjọ́ keji nínú àwọn ọjọ́ (Tashriq) lẹ́yìn irun osan , gẹ́gẹ́ bí ó ti jù wọ́n ní ọjọ́ kinni, yóò sì ṣe bẹ níbi (jamrat) kinni àti ikeji gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní ọjọ́ kinni; láti fi ṣe àfarawé Anabi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ ko máa ba .
Jijú òkúta ní àwọn ọjọ méjì àkọ́kọ́ nínú àwọn ọjọ Tashreeq jẹ́ ọranyan nínú àwọn ọranyan Hajj, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni sísùn sí Mina ní alẹ́ àkọ́kọ́ àti ìkejì jẹ́ ọranyan, ayàfi fún àwọn onipèsè-omi àti àwọn darandaran àti àwọn tó jọ wọ́n, kò jẹ́ ọranyan.
Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn sísọ oko ní ọjọ méjèèjì náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kanjú kúrò ní Mínà, wọn yọ̀ǹda fún un, yóò sì jáde kúrò kí oòrùn tó wọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì lọra, tí ó sì sùn ní òru kẹta, tí ó sì sọ àwọn oko ní ọjọ kẹta, èyí ni ó lọ́lá jùlọ, tí ó sì ní ẹ̀san ńlá jùlọ, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun Atóbilọ́lá ṣe wí pé: « Ẹ ṣèrántí Allāhu láààrin àwọn ọjọ́ tó ní òǹkà. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá bẹ̀rù...» [Al-Baqorah: 203], Ati nitoripe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - yọnda fún àwọn ènìyàn láti kanju, ṣùgbọ́n oun fúnrarẹ̀ kò kanjú; kàkà bẹ́ẹ̀, ó dúró sí Mina títí ó fi ju awọn Jamarat ní ọjọ́ kẹtàlá lẹ́yìn tí òrun ti yẹ̀ kúrò ní àtàrí, lẹ́yìn náà ni ó kúrò ṣáájú kí ó tó kirun Suhr.
O si lẹtọ fun alábojútó ọmọkùnrin kekere ti kò lagbara lati sọ oko funra rẹ pé kí ó ba a sọ oko Jamarat al-Aqaba ati gbogbo awọn Jamarat yoku lẹyin igba ti o ba ti sọ oko ti ara rẹ, bakannaa ni ọmọbinrin kekere ti kò lagbara lati sọ oko, alábojútó rẹ yoo ba a sọ oko fun un; nitori hadith Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i -, to sọ pe: «A ṣe Hajj pẹ̀lú ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, àwọn obinrin àti àwọn ọmọdé sì wà pẹ̀lú wa, a wa pe Talbiyah fún àwọn ọmọdé, a sì sọkò fún wọn» [89] Ọmọ Mājah ni o gbe e jáde. [89] At-Tirmidhi lo gba wa, pẹlu onka (927).
O si lẹtọ fun ẹni tí kò lagbara lati sọ oko nitori aare tàbí ọjọ́ ori tàbí oyun lati wá ẹnikan ti yoo ba a sọ oko; nitori ọrọ Ọlọhun ọba tó ga: « Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ ». [At-Tagoobun: 16], Àwọn wọ̀nyí kò ní agbára láti bá àwọn ènìyàn dí pọ̀ ní bí Jamarat, àsìkò ìjùko yóò sì kọjá, kò sì sí àṣẹ nínú ẹ̀sìn pé kí wọ́n san án padà, fún ìdí èyí, ó yọ̀ǹda fún wọn láti yan aṣojú, èyí yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ Hajj yòókù. Kò yẹ kí ẹni tí ó gbé harami yan aṣojú tí yóò bá a ṣe é, kódà bí ó jẹ́ pé Hajj àfisùn ni ó ń ṣe; nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé harami fún Hajj tàbí Umrah, kódà bí méjèèjì jẹ́ iṣẹ́ àfisùn, ó di dandan fún un láti parí méjèèjì; nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun - tó ga - pé: « Ẹ ṣe àṣepé iṣẹ́ Hajj àti ‘Umrah fún Allāhu...» [Súràtu Al-Baqarah: 196] Àsìkò rirokirika ile Ọlọhun àti As-Sa'y kì í kọjá, yàtọ̀ sí àsìkò oko sísọ.
Ṣùgbọ́n ní ti diduro ní Arafah, àti sísun ní Muzdalifah àti Mina, láìṣé àní-àní pé àsìkò wọn a máa kọjá lọ, ṣùgbọ́n wíwà aláìnílágbára ní àwọn ibi wọ̀nyí ṣeéṣe bí ó tilẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú wàhálà, tó yàtọ̀ sí jiju òkúta fúnra rẹ̀; àti nítorípé yíyan aṣojú nínú jiju òkúta ti wáyé látọ̀dọ̀ àwọn asiwaju rere fún ẹni tí ó ní àwíjàre, láìdàbí ti àwọn iṣẹ́ yòókù.
Àti pé ìjọsìn jẹ ikoraduro lórí bo ba tí se wa lọdọ aṣòfin, kò lẹtọ fun ẹnikẹ́ni láti dá nkankan gbé kalẹ̀ nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà ẹṣin àyàfi pẹ̀lú ẹ̀rí, o si lẹtọ fun abanijuko lati sọ oko fun ara rẹ, lẹyin naa fun ẹni tí ó n ba jùkó fún, níbi jamarat kọọkan nínú àwọn jamarat mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nígbà tí ó wà ní ibùdó kan náà, kò si jẹ dandan lórí rẹ̀ lati parí sisọ àwọn jamarat mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún ara rẹ tán, kí ó tó padà wá sọ ọ́ fún ẹni tí ó n ba jùkó fún, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀ tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà jùlọ; nítorí àìsí ẹ̀rí tó fi dandan, àti nítorí ìṣòro àti wàhálà tí ó wà nínú rẹ̀, Ọlọhun Alápọ́nmọ́le sì wí pé: «...kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn...» [Al-Hajj: 78]. « Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa bá a- sọ pe» : “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn” [90]. Nítorí pé ìyẹn kò jẹ́ ohun tí a gbà ròyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn saabe ojiṣẹ́ Ọlọhun – ki ikẹ àti ọlá Ọlọhun máa bá a – nígbà tí wọ́n ju òkò dipo àwọn ọmọdé wẹ́wẹ́ wọn àti àwọn aláìlágbára nínú wọn. Tí wọ́n bá sì ti ṣe ìyẹn, wọ́n ìbá gbà á ròyìn; nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn n̄ǹkan tí ọkàn àwọn ènìyàn máa ń fà sí láti ròyìn. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ. [90] Al-Bukhari lo gba a wa nínú hadith Anas, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (69).
Ori- Ọrọ
Nípa ọranyan itanran lórí ẹni tó ń ṣe hajji Tamattu'i àti ti Kirọọnu.
Ọranyan ni fun alaalaji tí ó bá ń ṣe Hajj Tamattu' tàbí Qiran - tí kò bá sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùgbé ilẹ̀ Haram - kí ó pa ẹran kan. Èyíun ni: ẹran kan, tàbí ìdá meje ràkúnmí, tàbí ìdá meje mààlúù. Ó sì jẹ́ ọranyan kí èyí jẹ́ láti inú owó halaali tí ó mọ́; nítorípé Ọlọ́hun ti Ọlá Rẹ gaju lọ, Mímọ́ ni, kò sì ní gba nkankan àfi èyí tó bá mọ́.
O yẹ fun Musulumi lati jina si bibi awọn eniyan leere fun ẹbun tabi nnkan miran, yala wọn jẹ ọba ni tabi ẹlomiran, ti Ọlọhun ba ti ṣe ohun rọrun fun un ninu dukia rẹ ti yio fi jẹ ki o rọrọ kuro nibi ohun ti nbẹ lọwọ awọn eniyan; nitori ohun ti o wa ninu awọn Hadith pupọ lati ọdọ Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - nipa bibu ibeere ati alebu rẹ, ati yiyin ẹniti o ba gbe e ju silẹ.
Tí oni-Tamattu' àti oni-Qiran kò bá lágbára ẹran ìtọrẹ, ó jẹ́ ọranyan fún un láti gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta lásìkò Hajj àti méje tí ó bá padà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀, ó sì ní àṣàyàn nípa gbígba ààwẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, tí ó bá fẹ́, ó lè gbà á ṣáájú ọjọ́ Nahri, tí ó ba sì fẹ́, ó lè gbà á ní àwọn ọjọ́ Taṣriiq mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Allahu Ta'ala sọ pe: «...Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ‘Umrah àti Hajj nínú oṣù iṣẹ́ Hajj, ó máa fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹni tí kò bá rí (ẹran ọrẹ), kí ó gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú (iṣẹ́) hajj, méje nígbà tí ẹ bá darí wálé. Ìyẹn ni (ààwẹ̀) mẹ́wàá tó pé. Ìyẹn wà fún ẹni tí kò sí ẹbí rẹ̀ ní Mọ́sálásí Haram...» [Al-Baqarah: 196] Aayah.
O wa ninu iwe Saheeh Al-Bukhari, lati ọdọ Aisha ati ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si wọn - wọn sọ pé: «A ò yọ̀ǹda gbígba aawẹ ní àwọn ọjọ́ Tashrīq, àfi fún ẹni tí kò bá rí Hady (Ẹran ìtọrẹ) » [91], Èyí sì wà ní ipò ọ̀rọ̀ tí a gbé taara lọ sí ọ̀dọ̀ Anabi -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, ohun tó dára jù ni pé kí ó gbé aawẹ àwọn ọjọ mẹ́ta náà síwájú ọjọ Arafah, kí ó lè jẹ́ ẹni tí kò gbààwẹ̀ ní ọjọ Arafah; nítorípé dajudaju Anabi -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- dúró ní ọjọ Arafah ní ẹni tí kò gbààwẹ̀, ó sì kọ̀ nípa gbígbà aawẹ ọjọ Arafah ní Arafah, àti pé nítorípé àìgbààwẹ̀ ní ọjọ́ yí máa fún un ní okun púpọ̀ síi lórí ìrántí (Ọlọhun) àti ṣíṣe àdúà. Ó yọ̀ǹda láti gba aawẹ àwọn ọjọ mẹ́ta tí a mẹ́nu bà yẹn ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé tàbí ní aitẹle ra wọn , gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni aawẹ ọjọ méje, kò jẹ́ ọ̀ranyàn lórí rẹ̀ láti gbà á ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé, ṣùgbọ́n ó yọ̀ǹda láti gbà á ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé tàbí ní pípín-ká; nítorípé dajudaju Ọlọhun -Mímọ́ ni Fún Un- kò fi gbígbà á ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé ṣe májẹ̀mú, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni Òjíṣẹ́ Rẹ̀ -kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọhun máa bá a-. Ohun tó dára jù ni pé kí ó sún aawẹ ọjọ méje náà sẹ́yìn títí yóò fi padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀; nítorí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ -Ọlá ni fún Un- pé: «...méje nígbà tí ẹ bá darí wálé...» [Suuratul Baqara: 196]. [91] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (1998).
Aawẹ gbigba fun aláìníkapá Hadyi lọla ju bibeere lọwọ awọn ọba ati awọn yooku fun Hadyi ti yoo pa fun ara rẹ. Ẹniti wọn ba fun ni Hady tabi nnkan miiran lai beere fun un, tabi lai jẹ pe ọkan rẹ n wu u si, ko si aburu ninu eyi. Koda bi o ba n ṣe Hajj fun ẹlomiiran, iyẹn ni pe: ti awọn ti o ran an niṣẹ Hajj naa ko ba da a le lori pe ki o ra Hady pẹlu owo ti wọn fun un. Ṣugbọn niti ohun ti awọn eniyan kan n ṣe nipa bibeere lọwọ ijọba tabi awọn yooku fun diẹ ninu Hady pẹlu orukọ awọn eniyan kan ti o darukọ, ti o si jẹ pe opurọ ni, ko si iyemeji ninu eewọ rẹ; nitori pe o jẹ́ apákan ninu fífi irọ́ jẹun, Ki Ọlọhun gba awa ati awọn Musulumi la kuro nibi iyẹn.
Ori- Àkòrí ọrọ
Lórí ṣíṣe ìpani lasẹ fún àwọn oníṣẹ́ Hajj àti àwọn mìíràn láti ṣe daada.
Ati pe ninu eyi ti o tobi julọ ninu ohun ti o jẹ dandan fun awọn alarinrin-ajo Hajj ati awọn miiran ni pipaṣẹ rere ati kikọ aburu, ati sisọ awọn irun maraarun-un ni janmọọn, gẹgẹ bi Ọlọhun ṣe paṣẹ bẹẹ ninu Tira Rẹ, ati lori ahọn Ojiṣẹ Rẹ - ki ikẹ Ọlọhun àti Ọlá Rẹ máa ba.
Amọ niti ohun ti ọpọlọpọ awọn eniyan n ṣe ninu awọn olugbe Makkah ati awọn ilu miiran, nipa kiki irun ni ile ati fifi awọn mọsalasi pa sofo, dajudaju aṣiṣe ni o, o si tako ofin ẹsin. Nitori naa, o jẹ dandan ki a kọ kuro nibẹ, ki a si paṣẹ fun awọn eniyan lati maa mojuto irun kiki ni mọsalasi; nitori ohun ti o ti fẹsẹ rinlẹ lati ọdọ rẹ -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- pe o sọ fun ọmọ ìyà Maktum -ki Ọlọhun yọnu si i- nigba ti o gba iyọnda lọdọ rẹ lati kirun ni ile rẹ; nitori pe o jẹ afọju, ti ile rẹ si jinna si mọsalasi: «Ṣé o n gbọ́ ìpe ìrun? Ó ní: Bẹ́ẹ̀ni, ó ní: Jẹ́pẹ́» [92]، Nínú ẹgbawa miran: «Èmi kò rí ìyọ̀ǹda idẹkùn fún ọ» [93]، Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: «Mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ọkunrin kan laṣẹ ki o ṣiwaju awọn eeyan, lẹyin naa ki n wa gbera lọ si ọdọ awọn ọkunrin kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori» [94]، O si wa ninu Sunan ọmọ Maajah ati awọn miiran pẹlu ọna itan to dara, lati ọdọ ọmọ Abbas kí Ọlọhun yonu sí awọn méjèjì, pe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹnikẹni tí ó gbọ́ ìpè, tí kò sì wá, kò sí irun fún un àfi pẹ̀lú ìdí»[95]، O wa ninu Saheeh Muslim, lati ọdọ ọmọ Mas'ud (ki Ọlọhun yọnu si i) o sọ pe: «Ẹnikẹ́ni ti inu rẹ ba dun lati pade Ọlọhun lọ́la gẹ́gẹ́ bi Musulumi, ki o maa pa àwọn irun wọnyi mọ́ nibi ti a ti n pe wọn, dájúdájú Ọlọhun gbe àwọn ọna ìmọna kalẹ̀ fun Anabi yín, dájúdájú wọn si jẹ ara àwọn ọna ìmọna, ti o ba si jẹ pe ẹyin n kirun nile yin, gẹgẹ bi asẹyin yii ti n kirun nile rẹ ni ẹ ba ti pa Sunna Anabi yin ti, ti ẹ ba si pa Sunna Anabi yin ti ni ẹ ba ti sọnù, kò si sí ọkunrin kan ti o maa ṣe imọra ti yio si ṣe e daadaa, lẹ́yìn naa ti yio si gbéra lọ sí mọ́sálásí kan ninu àwọn mọ́sálásí wọnyi, àfi ki Ọlọhun kọ oore kan sílẹ̀ fún un pẹ̀lú gbogbo ìgbésẹ̀ ẹsẹ̀ ti o ba gbé, O si fi gbe e ni ipò kan, O si fi pa asiṣe kan rẹ́ kúrò lara rẹ, dájúdájú a ti ri ara wa pe kò si sí ẹni ti o yóò máa fa sẹyin kúrò ninu wọn àyàfi oni seyi sòún ti a mọ seyin sòún rẹ , dájúdájú a si maa n gbe ọkunrin kan wa sí mọsalasi ti a n fí sí aarin ọkunrin meji titi ti a o fi gbe e duro ninu saafu ( tito dúró lórí ìrun ) » [96]." [92] Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (2420), àti Muslim pẹlu onka (651). [93] Muslim lo gba wa láti ọdọ̀ Abu Hurairah, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (653). [94] Bàbá Daud lo gba wa lati ọdọ Abdullah ọmọ iya Maktum, pẹlu onka (552). [95] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (654). [96] Baba Daud lo gba wa látọ̀dọ̀ ọmọ Abbas, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì, pẹlu onka (551).
O jẹ ọranyan lori awọn alalaaji ati awọn yooku lati jinna si awọn eewọ Ọlọhun - Ọba giga -, ati lati ṣọra kuro nibi ṣíṣe awọn iwa ẹsẹ ; gẹgẹ bii: ṣina (Agbere), ati iṣe Lūti ( Ibalopọ láàrin ọkunrin ati ọkùnrin) , ati ole jija, ati jijẹ owo èlé, ati jijẹ dukia ọmọ orukan, ati itanjẹ ninu awọn iṣowo, ati ìwùwà ọdàlẹ ni bí ohun igbẹkẹle, ati mimu awọn nkan ti maa n muni hunrira ( bi mímú ọtí àti nkán míràn), ati siga mimu, ati fifa aṣọ la ilẹ, ati igberaga, ati ilara, ati ṣiṣe karimi, ati ọrọ ẹyin, ati ofofo, ati fifi awọn Musulumi ṣe yẹyẹ, ati lilo awọn ohun elo ere idaraya; gẹgẹ bii awọn awo-orin, ati 'ūd, ati robāb, ati awọn fèrè, ati iru wọn, ati gbigbọ awọn orin, ati awọn ohun elo orin lati inu redio ati bẹẹbẹẹ lọ, ati ṣiṣere ayò onídáìsì, ati ṣaasi, ati ṣiṣe iṣowo pẹlu Mọisir - oun naa ni: tẹtẹ tita - ati yiya aworan awọn nnkan to ni ẹmi ninu awọn ọmọ eniyan ati awọn miiran, ati yiyọnu si iyẹn. Dajudaju, gbogbo iwọnyi jẹ ninu awọn iṣẹ ibi ti Ọlọhun ṣe leewọ fun awọn ẹru Rẹ ni gbogbo asiko ati ni gbogbo aye, nitori naa o jẹ ọranyan ki awọn alalaaji ati awọn olugbe Ile Ọlọhun ti o jẹ ile ọwọ ṣọra fun un ju awọn yooku lọ; nitori pe awọn iṣẹ-ẹṣẹ ni ilu ifọkanbalẹ yii, ẹṣẹ rẹ le koko ju, iya rẹ si tobi ju.
Dájúdájú Ọlọhun ti ọla Rẹ ga si ti sọ pe: « Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní èrò láti ṣe ìyípadà kan ( gẹgẹ bí itako bibẹ Ọlọhun ) níbẹ̀ pẹ̀lú àbòsí, A máa mú un tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò». [Suratul Hajj: 25], Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọhun ti ṣèlérí ìyà fún ẹni tí ó kàn ní èrò láti ṣe àìtọ́ pẹ̀lú àbòsí nínú ọgba eewọ, báwo ni ifiyajẹni ẹni tí ó ṣe é gan-an yóò ṣe rí?! Kò sí iyèméjì pé yoo tóbi ju, yoo sì le koko ju; nítorí náà, ó yẹ láti ṣọ́ra kúrò níbẹ̀ àti kúrò nínú gbogbo àwọn ẹṣẹ̀ yòókù.
Àwọn Aláájì kò níí rí gbígba Hájì àti ìforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ gbà, bí kò ṣe nípa ṣíṣọ́ra kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn nínú ohun tí Ọlọ́hun ṣe ní èèwọ̀ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wá nínú hadíìsì láti ọ̀dọ̀ Ànábì (ki ikẹ ati ọla ọlọhun máa bá a) pé ó sọ pé: «Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i saye ni » [97]. [97] Al-Bukhari lo gba wa lati ọdọ Baba Hurairah, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i pẹlu onka (1521), àti Muslim pẹlu onka (1350).
Ohun tí ó lagbara ju nínú àwọn Munkari ( ibajẹ àti àìdá ) wọ̀nyí, tí ó sì tún tóbi jù wọ́n lọ ni: kikepe awọn oku, ati wiwa iranlọwọ pẹlu wọn, ati ṣíṣe ileri fun wọn, ati didunbu fun wọn; pẹ̀lú ìrètí pé kí wọ́n ṣìpẹ̀ fún ẹni tí ó ń pè wọ́n ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, tàbí kí wọ́n wo aláìsàn rẹ̀ sàn, tàbí kí wọ́n dá ẹni rẹ̀ tí ó sọnù padà, ati nnkan ti o jọ ìyẹn.
Eleyii wa ninu ẹbọ ńlá tí Ọlọhun ṣe ní èèwọ̀, òun ni ẹ̀sìn àwọn oṣẹbọ ìgbà aimọkan, èyí tí Ọlọhun rán àwọn Òjíṣẹ́, tí O sì sọ àwọn iwe kalẹ̀ fún ṣíṣe àtakò sí i àti kíkọ̀ rẹ̀.
Ó wáá jẹ́ dandan fún gbogbo ẹni kọ̀ọ̀kan nínú àwọn oníṣẹ́ ìjọsìn Hajj àti àwọn mìíràn láti ṣọ́ra níbi rẹ̀, kí ó sì ṣe atúbà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun nípa ohun tí ó ti kọjá, tí ó bá jẹ́ pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbẹ̀, kí ó sì bẹ̀rẹ̀ Hajj tuntun lẹ́yìn atúbà kúrò nínú rẹ̀; nítorípé ẹbọ ńlá a máa ba gbogbo iṣẹ́ jẹ́ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun tí ọlá Rẹ ga ti sọ pé: « Tí wọ́n bá fi lè ṣẹbọ ni, dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) ìbá bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.» [Suratul An'aam: 88].
Lara awọn iru ẹbọ kekere ni: Ibura pẹlu nnkan miran yatọ si Ọlọhun; gẹgẹ bii ibura pẹlu Anabi - ki Ọlọhun ṣe ikẹ ati igẹ Rẹ fun un -, Kaaba, ati nkan gbà fi pamọ, ati nkan to jọ bẹẹ.
Ninu rẹ ni: ìfihàn àti gbọ́-kan-mi, àti sísọ pé, “Ohun ti Ọlọhun fẹ ati ohun ti ìwọ naa ba fẹ,” àti “Bí kìí bá ṣe Ọlọhun àti ìwọ,” àti “Èyí láti ọ̀dọ̀ Ọlọhun wá àti láti ọ̀dọ̀ rẹ,” àti nnkan ti o jọ ìyẹn.
Nitori naa, ọranyan ni kí a ṣọra kuro nibi àwọn ohun ìríra ti ẹlẹbọ wọnyi, kí á sì máa gba awọn eniyan ní ìyànjú láti fi wọ́n sílẹ̀; nitori ohun ti o ti fidi rẹ mulẹ lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pé ó sọ pé: «Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ» [98]. Ahmad ati Bàbá Daud ati Tirmidhi gba a wa pẹlu ẹgbawa ti o ni alaafia. [98] Baba Daud lo gba wa pẹlu onka (3251).
O wa ninu Saheeh lati ọdọ Umar - ki Alloohu ba wa yonu si i- o so pe: ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- sọ pe: «Ẹnikẹni ti o ba máa bura, kí o fi Ọlọhun bura tàbí kí o dakẹ» [99]. Anọbi tun sọ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa bá a - bakanna pe: «ẹníkẹni tí o búra pẹlu nkan gbà fi pamo kò sí nínú wa» [100]. Abu Daa'ud ni o gbe e jade. [99] Baba Daud lo gba wa pẹlu onka (3253). [100] Al-Bukhari lo gba wa lati ọdọ Abdullah pẹlu onka (2679), àti Muslim pẹlu onka (1646).
Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - tun sọ bakanna pe: "Ohun ti mo nbẹru ju fun yin ni: ẹbọ kekerẹ, wọn wa bi i leerẹ nipa rẹ, o wa sọ pe: ṣekarimi" [101]. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ" [102] Ati pe An-Nasā'ī gba a wa, lati ọdọ ọmọ Abbaas - ki Ọlọhun bawa yọnu si awọn mejeeji -, wipe arakunrin kan sọ pe: Ìwọ òjíṣẹ́ Ọlọhun, ohun ti Ọlọhun ba fẹ ati ohun ti ìwọ náà bá fẹ́, nígbà náà ni o sọ pé: «Njẹ o fẹ maa ṣe mi ni olubakẹgbẹ fun Ọlọhun, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun ti Ọlọhun Allah ba fẹ nikan ni» [103]. [101] Ahmad lo gba wa, pẹlu onka (5/428). [102] Bàbá Daud lo gba wa pẹlu onka (4980). [103] Ọmọ Mājah lo gba wa, pẹlu onka (2117).
Àwọn hadiith wọnyi si n tọka si idabobo Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – fun ọla imọ Ọlọhun lọkan, ati iṣe ikilọ rẹ fun awọn ijọ rẹ kuro nibi ẹbọ nla ati ẹbọ kekere, ati ṣiṣe ojukokoro rẹ lori aabo igbagbọ wọn ati igbala wọn kuro nibi iya Ọlọhun ati awọn okunfa ibinu Rẹ, ki Ọlọhun san an ni ẹsan ti o dara ju lori iyẹn, dajudaju o ti jẹ iṣẹ o si ti ṣe ikilọ, o si ṣe imọran ododo fun Ọlọhun ati fun awọn ẹru Rẹ, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ti o jẹ titi lai maa ba a titi di ọjọ igbende.
Ọranyan sì ni lórí àwọn onímímọ̀ nínú àwọn aláàájì àti àwọn olùgbé ní ìlú Ọlọhun tí ó fàyàbalẹ̀ àti ìlú Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Alápònnle -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé kí wọ́n kọ́ àwọn ènìyàn ní ohun tí Ọlọhun fi ṣe òfin fún wọn, kí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tí Ọlọhun ṣe ní èèwọ̀ fún wọn nínú àwọn oríṣiríṣi ṣíṣe ìbọ̀ àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀, àti pé kí wọ́n ṣàlàyé ìyẹn fófó pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí rẹ̀, kí wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀ ní àlàyé tó kúnná; kí wọ́n le baà fi ìyẹn mú àwọn ènìyàn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn lọ sínú imọ́lẹ̀, kí wọ́n sì le baà fi ìyẹn ṣe ohun tí Ọlọhun ṣe ní ọranyan lórí wọn nínú iṣẹ́ ìkéde àti àlàyé, Ọlọhun Ẹni-Mímọ́ sọ pé: « (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn àwọn tí A fún ní tírà pé ẹ gbọ́dọ̀ ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn, ẹ ò sì gbọdọ̀ fi pamọ́...» [Āli ‘Imrān: 187]
Àfojúsùn inú èyí ni: ìkìlọ̀ fún àwọn onímọ̀ ìjọ yíì kuro níbi títẹ ipasẹ̀ àwọn aláìṣòdodo nínú àwọn tí a fún ní tírà, nípa fífi òdodo pamọ́; nítorí pé wọ́n yan ayé láàyò ju ọ̀run lọ, Ọlọ́hun tí Ó ga jùlọ sì ti wí pé: « Dájúdájú àwọn tó ń daṣọ bo ohun tí A sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rí tó yanjú àti ìmọ̀nà, lẹ́yìn tí A ti ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn sínú Tírà, àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ń ṣẹ́bi lé. Àwọn olùṣẹ́bi sì ń ṣẹ́bi lé wọn ». « Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n sì ṣàfi hàn òdodo, nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn ni Mo máa gba ìronúpìwàdà wọn. Èmi sì ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run ». [Suuratul Baqorah: 159-160]. Àwọn ẹsẹ Al-Qur'ān àti àwọn Hadith Anọbi ti fi hàn pé ipepe sí ọ̀dọ̀ Ọlọhun (mímọ́ ni fún Un) àti ìtọ́sọ́nà àwọn ẹrúsìn sí ohun tí A fi dá wọn fún wà nínú àwọn iṣẹ́ ìsúnmọ́ tó dára jùlọ àti àwọn ojúṣe tó ṣe pàtàkì jùlọ, àti pé òun ni ọ̀nà àwọn ojiṣẹ àti àwọn olùtẹ̀lé wọn títí di ọjọ́ Àjíǹde, gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun (mímọ́ ni fún Un) ti sọ pé: « Níbi ọ̀rọ̀ sísọ, ta ni ó dára ju ẹni tí ó pèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ṣe iṣẹ́ rere, tí ó sì sọ pé: “Dájúdájú èmí wà nínú àwọn mùsùlùmí?” [Fussilat: 33], Ọlọhun tí O gbọngbọn tí O tóbi jù sọ pé: « Sọ pé: “Èyí ni ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) mi, èmi àti àwọn tó tẹ̀lé mi sì ń pèpè sí (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Mímọ́ ni fún Allāhu. Èmi kò sì sí lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.” [Suuratu Yuusuf: 108].
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa bá a- sọ pe: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ́ka ẹnikan sí oore kan, tirẹ̀ ni irú ẹ̀san olùṣe rere náà .” [104] « Tí Ọlọhun ba fi ẹnikan ṣoṣo mọ̀nà nípasẹ̀ rẹ, o dara fun ọ ju awọn rakunmi pupa lọ» [105] Awọn Aayah àti Awọn Hadiisi rẹpẹtẹ lo wa nipa itumọ yii. [104] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1893). [105] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (3009), àti Muslim pẹlu onka (2406).
O tọ́ si àwọn onimọ̀ ati onigbagbọ ododo ki wọn pọn ìsapá wọn lé nínú ipepe sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun Mímọ́, àti títọ́nisọ́nà àwọn ẹrúsìn sí àwọn ọ̀nà ìgbàlà, àti ṣíṣe ìkìlọ̀ fún wọn kúrò nínú àwọn ọ̀nà ìparun, pàápàá jùlọ ní àsìkò ti a wa yii níbi tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti borí, tí àwọn ìlànà ìparun àti àwọn ọ̀rọ̀-ìpolongo ìṣìnà sì ti tàn kálẹ̀, tí àwọn olupepe sí ìmọ̀nà ti din ku tí àwọn olupepe sí àìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́hun àti ìṣekúṣe sì ti pọ̀ síi, Ọlọ́hun ni a bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, kò sì sí agbára tàbí ọgbọn kan àfi pẹ̀lú Ọlọ́hun, Ọba ti o ga , tí o tobi jùlọ.
Ori-Akori Ọrọ
F'ifẹ ki a ni ìpèsè itẹle aṣẹ Ọlọhun.
A fẹ́ fún àwọn tí wọ́n nṣe hajj kí wọ́n dúró ti ríranti Ọlọ́hun àti ṣíṣe ìgbọràn sí I àti ṣíṣe iṣẹ́ rere ní àsìkò gbígbé wọn ní Makkah, kí wọ́n sì pọ̀ ní ìrun kíkí àti pípooyi Ilé náà; nítorí pé àwọn iṣẹ́ rere ní inú Haram adípèlé ni ẹsan rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ níbẹ̀ sì tóbi ó sì le púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí a ṣe fẹ́ fún wọn láti pọ̀ ní kíkí ìkẹ àti ọlá fún Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.
Nígbàtí àwọn alálàájì bá fẹ́ jáde kúrò ní Makkah, ó jẹ́ ọranyàn fún wọn láti ṣe irọkirika Ilé Olúwa fún ìdágbére; kí ó jẹ́ pé Ilé Olúwa ni wọn wá kẹ́yìn. Ayafi obinrin tí nṣe nkan oṣù àti èyí tó wà nínú ẹjẹ ìbímọ, kò sí idagbere lórí àwọn méjèèjì; nítorí hadith ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu sí wọn - ti o sọ pé: "Wọn pa awọn eeyan laṣẹ pẹlu wipe ki ohun ti wọn ṣe kẹhin ki wọn to kuro ni Makkah ni pipooyi ile Ọlọhun, yatọ si wipe wọn se e ni fifuyẹ fun obinrin ti nse nkan osu."[106] [106] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1755), àti Muslim, pẹlu onka (1328).
Tí ó bá ti parí ìdágbére fún ilé Ọlọ́hun, tí ó sì fẹ́ jáde kúrò nínú mọsalasi, yóò tẹ̀síwájú ní bí ìrìn rẹ̀ títí yóò fi jáde, kò sì yẹ fún un pé kí ó máa rìn sẹ́yìn; nítorí pé èyí kò jẹ́ nǹkan tí a gbà wá láti ọ̀dọ̀ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, tàbí láti ọ̀dọ̀ àwọn Saabe rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ lára àwọn àdàsílẹ̀ nínú ẹ̀sìn, Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sì ti sọ pé: «Ẹnití o ba ṣe iṣẹ kan ti ko sì àṣẹ wa nibẹ, yíò jẹ adapada fún » [107]. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: « O di ọwọ yin, ki ẹ jina si adadaalẹ ti ko ki nṣe ara ẹsin; tori pe gbogbo idasilẹ pata adadaalẹ ni (bid'ah) ati pe gbogbo adadaalẹ pata ọna anu ni» [108]. [107] Ìtọ́kasí rẹ̀ ti ṣáájú. [108] Muslim lo gba wa lati ọdọ Jābir ọmọ Abdullāh, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (867).
A n beere ifẹsẹmulẹ lọwọ Ọlọhun ninu ẹsin Rẹ, ati ààbò kuro nibi ohun to lodi si i, Oun ni Ọba Ọlọrẹ Onikẹ.
Ori-Akori Ọrọ
Nipa àwọn ìdájọ abẹwo àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ.
Ó jẹ́ ìlànà Anọbi láti ṣe àbẹ̀wò sí Masalasi Anọbi -kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- ṣáájú Hajj tàbí lẹ́yìn rẹ̀; nítorí ohun tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìwé Saḥiḥ méjèèjì láti ọ̀dọ̀ Bàbá Hurayrah -kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- ó sọ pé: Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun -kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- sọ pé: “Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ (ni Makkah) ”[109]. Ati lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ” [110] Muslim ni o gba a wa. Ati lati ọdọ Abdullahi ọmọ Zubair- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun ti a ki ni ibi ti o yatọ si i lọ, afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ, àti pé irun kan ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ loore ju ọgọ́rùn-ún irun lọ ti a ki ni mọsalasi mi yii” [111] Ahmad ni o gbe e jade, ati ọmọ Khuzaymah, ati ọmọ Hibbaan. [109] Al- Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (1190), àti Muslim, pẹlu onka (1394). [110] Muslim lo gba wa, pẹlu onka (1395). [111] Ahmad lo gba wa pẹlu onka (4/5).
Láti ọdọ Jaabir - kí Ọlọ́hun yọnu sí i -, pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - sọ pé: “Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun ti a ki ni ibi ti o yatọ si i lọ, afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ, àti irun kan ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ loore ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún irun ti a ki ni ibi ti o yatọ si i lọ” [112] Ahmad ni o gbe e jade, ati ọmọ Maajah. Àwọn Hadith lórí ìtumọ̀ yìí sì pọ̀. [112] ọmọ Mājah ni o gba a wa pẹlu ounka (1406).
Tí olùṣe abẹwò bá dé mọsalasi, won fẹ kí ó wọlé pẹ̀lú ẹsẹ ọ̀tún rẹ, kí ó sì sọ pé: "Pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́hun, ìkẹ́ àti ọlà kí ó máa bá Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, mo fi Ọlọ́hun Atóbilọ́lá, àti Ojú Rẹ̀ Alápọ̀n-ọ́lá, àti agbára Rẹ̀ ayérayé wá ààbò kúrò lọ́wọ́ Èṣù ẹni-ẹ̀kọ, Irẹ Ọlọ́hun, ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ìkẹ́ Rẹ fún mi",
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe n sọ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ó bá wọ àwọn masalaasi yooku, kò sì sí ìrántí pàtó kan fún wíwọ masalaasi Rẹ̀ -kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a-. Lẹ́yìn náà, yio kirun rakaah meji, yio sì gbàdúrà sí Ọlọ́hun nínú àwọn méjèèjì pẹ̀lú ohun tí ó bá fẹ́ nínú oore ayé àti ti ọ̀run. Tí ó bá sì kirun àwọn méjèèjì ní ààyè Araodọh Alaponle, òun ni ó dára jùlọ; nítorí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ -kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a- pé: «láàrin ile mí sí pepele ìdúró sọrọ mí abata kan ni nínú awọn abata ọgbà idẹra» [113]. Lẹ́yìn náà lẹ́yìn irun, yóò ṣe abẹwo sí saare Anabi (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a), àti saare àwọn ọrẹ rẹ méjèèjì: Abubakar àti Umar (kí Ọlọhun yọnu si wọn), yóò wá dúró ní ìkọjú sí saare Anabi (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) pẹlu ẹ̀kọ́ àti rírẹ ohun silẹ, lẹ́yìn náà yóò salamọ sí i (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) ní ẹni tí yóò sọ pé: "Àlàáfíà kí o máa bá ọ, ìwọ ojisẹ Ọlọhun, àti ìkẹ́ Ọlọhun àti ìbùkún Rẹ̀"; nítorí ohun tí ó wà nínú tira Sunan Bàbá Dāwūd pẹ̀lú ìtọ́kasí tó dára, láti ọdọ Baba Hurayrah (kí Ọlọhun yọ́nú sí i) tó sọ pé: ojisẹ Ọlọhun (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) sọ pé: «Ko si ẹnikankan ti yio salaamọ simi ayaafi ki Ọlọhun da ẹmi pada simi lara titi maa fi da a loun salamọ rẹ» [114]. Tí olùṣe-abẹwo bá sì sọ nínú kíki rẹ̀ pé: "Àlàáfíà kí o máa bá ọ, ìwọ Ànábì Ọlọhun, Àlàáfíà kí o máa bá ọ, ìwọ àṣàyàn Ọlọhun nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, Àlàáfíà kí o máa bá ọ, ìwọ olórí àwọn òjíṣẹ́ àti aṣíwájú àwọn olùbẹ̀rù-Ọlọhun, mo jẹri pé o ti jisẹ náà dé òpin, o sì ti ṣe asepe ìgbà fipamọ, o si se ìkìlọ mimọ fún àwọn ìjọ rẹ, o sì ti jagun sí ojú ònà Ọlọhun ní tòótọ" kò sí aburú níbẹ̀; nítorí pé gbogbo èyí jẹ́ apá kan nínú àwọn àpèjúwe rẹ̀ (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a), yóò sì ṣe ìkẹ́ sí i (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) yóò sì gbàdúrà fún un; nítorí ohun tí ó ti fẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú òfin pé kí á pa ìkẹ́ àti ọlá pọ̀ lórí rẹ̀, ní ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba-tó-ga-jùlọ: « Dájúdájú Allāhu àti àwọn mọlāika Rẹ̀ ń kẹ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tọrọ ìkẹ́ fún un, kí ẹ sì kí i ní kíkí àlàáfíà. [Suratul Ahzab: 56]. Lẹyìn náà yóò kí Àbí Bakir àti Umar, kí Ọlọhun yonu sí wọn, yóò sì gbàdúrà fún wọn, yóò sì tọrọ ìyọ́nú fún wọn. [113] Al-Bukhari lo gba wa láti ọdọ Abdullah ọmọ Zayd Al-Māziniy, pẹlu ounka (1195), àti Muslim, pẹlu ounka (1390). [114] Bàbá Daud lo gba wa pẹlu onka (2041).
Ọmọ Umar - kí Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - tí o bá kí òjíṣẹ - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa bá a - àti awàn ọrẹ rẹ méjèjì, kò máa ń ṣe àlékún ní ọ̀pọ̀ ìgbà ju ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ: «Àlàáfíà kí ó máa bá ọ, ìwọ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, Àlàáfíà kí ó máa bá ọ, ìwọ Abū Bakr, Àlàáfíà kí ó máa bá ọ, ìwọ bàbá mi» Lẹ́yìn náà yóò pẹyìndà.
Dájúdájú àbẹwò yìí jẹ́ ohun tí ó l'ẹtọọ fún àwọn ọkùnrin nìkan, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin, bíbẹ saare kankan wò kò sí fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹsẹ̀ rìnlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pé «O ṣẹbi le awọn olùṣe abẹwo saare lóbìnrin, ati awọn ti wọn n sọ di Mọsalasi, ti wọn si n tan atupa si i» [115]. [115] Bàbá Daud lo gba a wa pẹlu onka (3236).
Ṣugbọn nípa gbígbèrò láti lọ sí Madinah láti lọ kirun ní Mọsalasi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, àti láti ṣe àdúrà níbẹ̀, àti irú èyí nínú ohun tó lẹ́tọ̀ọ́ ní òfin nínú àwọn mọsalasi yòókù, ó jẹ́ ohun tí a ṣe ní òfin fún gbogbo ènìyàn lápapọ̀; nítorí àwọn hadith tí ó ti ṣíwájú lórí èyí.
Ìlànà Anabi lọ jẹ́ fún ẹni tí ó ṣe àbẹ̀wò kí ó kí àwọn irun márààrún ní Mọsalasi Anabi (kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà a), kí ó sì pọ̀ níbẹ̀ ní ṣíṣe ìrántí Ọlọhun, àdúà, àti kíki irun àfìkún; láti jẹ ànfàní ẹsan ńlá tí ó wà nínú rẹ̀.
Ó sì jẹ́ fífẹ́ kí ó máa ṣe ìrun àfìkún ní ọpọlọpọ ní Araodọh Alapọnle; nítorí ohun tí ó ti ṣáájú nínú hadíìsì Sahihi nípa ọlá rẹ̀, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ànábì -kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a- pé: «láàrin ile mí sí pepele ìdúró sọrọ mí abata kàn nínú awọn abata ọgbà idẹra wa níbẹ » [116]. [116] Ìtọ́kasí rẹ̀ ti ṣíwájú.
Ṣùgbọ́n ní ti irun ọ̀ranyàn, ó yẹ fún olùbẹ̀wò àti ẹlòmíràn yàtọ̀ sí i láti yára lọ síbẹ̀, kí ó sì ya sọ ila tito alakọkọ bí ó bá ti ṣeé ṣe fún un tó, pàápàá jùlọ tí ó bá jẹ́ ní apá àfikún iwájú; nítorí ohun tí ó wá nínú àwọn hadith ododo láti ọ̀dọ̀ Ànọ́bì -kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- nípa ìṣenilójúkòkòrò àti ìfanimọ́ra sínú ila tito alakọkọ, fún àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀ -kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- pé: «Tó ba se pé awọn ènìyàn mọ òòrè tí o wa níbi piperun àti tito sí iwájú, lẹ́yìn náà tí wan kò rí ọ̀nà kan àfi kí wan se ifigagbaga lé e lórí, wan baa se bẹ» [117] Imam Bukhari ati Muslim panupọ lórí lilalaafia rẹ, Àti bíi ọrọ Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a- tí o sọ fún àwọn sàábà Rẹ pé: «Ẹ tẹ̀ síwájú kí ẹ sì máa tẹ̀lé mi, kí àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn yín sì máa tẹ̀lé yín, ọmọniyan kan kò níí yéé máa fà sẹ́yìn kúrò níbi Irun títí tí Ọlọ́hun yóò fi fà á sẹ́yìn» [118] Muslim lo gba a wa [117] Muslim lo gba wa lati ọdọ Bàbá Sa‘īd al-Khudriyy, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i, pẹlu onka (438). [118] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (615), àti Muslim pẹlu onka (437).
Bàbá Daud sì gbà á wá, láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- pẹ̀lú ìtẹ̀lé-ìtàn tó dára, pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ọmọniyan kò níí yéé máa fà sẹ́yìn kúrò ní saafu iwájú títí tí Ọlọ́hun yóò fi fà á sẹ́yìn sínú Ina» [119]. O tun rinlẹ lati ọdọ rẹ - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a - wípé ó sọ fún àwọn sàábà Rẹ pé: «Ṣé ẹ ò níí tò bí àwọn Mọlaika ṣe ń tò ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn?» Wọ́n sọ pé: “Ìwọ ojíṣẹ́ Ọlọhun, báwo ni àwọn Mọlaika ṣe ń tò ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn?” Ó sọ pé: “Wọn a máa pé àwọn sọ́ọ̀fù àkọ́kọ́, wọ́n sì ń fúnra pọ̀ nínú sọ́ọ̀fù.» [120] Muslim ni o gba a wa. [119] Muslim lo gba wa lati ọdọ Jābir ọmọ Samurah, pẹlu onka (430). [120] Baba Daud lo gba wa pẹlu onka (679), ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ni: "àwọn ènìyàn kan kò níí yéé máa fà sẹ́yìn kúrò ní bí sàfúù (ila tito fun ìrun) àkọ́kọ́ títí tí Ọlọ́hun yóò fi fà wọ́n sẹ́yìn sínú Iná."
Àwọn Hadith lórí ìtumọ̀ yí pọ̀, ó sì kan mọ́sálásí rẹ̀ -kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- àti àwọn mìíràn yàtọ̀ sí i, ṣáájú àfikún àti lẹ́yìn rẹ̀, o sì ti fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Anabi -kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- pé dájúdájú ó máa ń rọ àwọn saabe rẹ̀ sí apá ọ̀tún àwọn saafu, a sì mọ̀ dájú pé apá ọ̀tún saafu nínú mọ́sálásí rẹ̀ àkọ́kọ́ wà ní ìta Rawdah, a fi mọ̀ pẹ̀lú èyí pé ṣíṣe àbójútó àwọn saafu àkọ́kọ́ àti apá ọ̀tún wọn ní àṣáájú lórí ṣíṣe àbójútó Rawdah ọlọ́lá náà, àti pé pípa méjèèjì mọ́ ló sàn jù pípa kíkirun nínú Rawdah mọ́, èyí sì hàn gbangba fún ẹni tí ó bá ṣe àṣàrò lórí àwọn hadith tí ó wá nípa orí yí, Ọlọ́hun ni Olùrànlọ́wọ́.
Kò lẹ́tọ̀ fún ẹnìkankan kí ó fi ọwọ́ pa yàrá anọbi tàbí kí ó fi ẹnu kò ó tàbí kí ó rọ kiriká rẹ; nítorí pé wọn kò gba á wá láti ọdọ àwọn aṣíwájú rere, bí kò ṣe pé adadaalẹ burúkú ni.
Kò lẹ́tọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti béèrè fún ìbiya búkàátà, tàbí ìdásílẹ̀ kúrò nínú wàhálà, tàbí ìwòsàn aláìsàn, tàbí irú bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ Òjíṣẹ́ kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ̀ má ba a; nítorí pé gbogbo èyí pátá a kii beere rẹ lọdọ ẹnikẹni àyàfi Ọlọhun tí ọlá Rẹ̀ ga, bíbéèrè rẹ̀ lọ́dọ́ àwọn òkú jẹ́ ṣiriki sí Ọlọhun àti ìjọsìn fún ẹni tí ó yàtọ̀ sí I, ẹ̀sìn Islam sì dúró lórí ìpìlẹ̀ méjì:
Ọ̀kan nínú rẹ̀ ni: kí a má ṣe jọsin fun ẹnikankan àfi Ọlọhun nìkan ṣoṣo.
Èkejì: Kí a má ṣe ijọsin àfi pẹ̀lú nǹkan tí Ojisẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ní òfin.
Èyí sì ni itumọ ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si l'ododo ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni , kò lẹ́tọ̀ fún Ẹnikẹ́ni láti wá isipẹ̀ lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ̀ má bà; nítorí pé ẹ̀tọ́ Ọlọhun ni, a kii wa a àyàfi lọ́dọ̀ Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ti ọlá Rẹ̀ ga ṣe sọ pé: «Sọ pé: “Ti Allāhu ni gbogbo ìṣìpẹ̀ pátápátá...» [Az-Zumar: 44] O ó wa sọ pe: “Ire Ọlọhun, gba ìpẹ̀ anọbi Rẹ, Ire Ọlọhun, gba ìpẹ̀ awọn Malaika Rẹ, àti ti àwọn ẹrusin Rẹ onigbagbọ, Ire Ọlọhun, gba ìpẹ̀ àwọn ọmọ mi tí wọ́n ti ṣíwájú”, àti irúu rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn òkú, a kì í wá nnkankan lọ́dọ̀ wọn, kì í ṣe ìṣípẹ̀ tàbí ohun mìíràn, kódà kí wọ́n jẹ́ anọbi tàbí tí kì í ṣe anọbi; nítorípé wọn kò ṣe ìyẹn ní òfin, àti nítorípé iṣẹ́ òkú ti parí ayafi ohun tí Aṣòfin yọ kúrò.
O wa ninu Sohiihu Muslim, Lati ọdọ Baba Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ti ọmọniyan ba ku iṣẹ rẹ ti dawọ duro fun un afi nnkan mẹta: saara kan ti o n ṣan, tabi imọ kan ti wọn n ṣe anfaani latara rẹ, tabi ọmọ rere kan ti o n ṣe adura fun un» [121]. [121] Muslim lo gba wa lati ọdo Bàbá Hurayrah, kí Allāhu yọ́nú sí i, pẹlu onka (1631).
Dájúdájú ó lẹtọ láti wá ìṣipẹ lọ́dọ̀ Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - lásìkò ìgbésí ayé rẹ̀ àti ní ọjọ́ ìgbédìde nítorí pé ọ ni ìkápá lórí ìyẹn, nítorí pé ó le lọ síwájú kí ó sì beere lọ́wọ́ Olúwa rẹ̀ fún ẹni tí ó n beere náà. Ní ti ayé, èyí jẹ́ ohun tí a mọ̀, kò sì wá fún òun nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo gbòò ni fún òun àti àwọn mìíràn pẹ̀lú. Ó sì yọ̀ǹda fún Musulumi láti sọ fún ọmọ ìyá rẹ̀ pé: ṣìpẹ̀ fún mi lọ́dọ̀ Olúwa mi lórí báyìí báyìí, èyí tó túmọ̀ sí: gba adúà sí Ọlọ́hun fún mi, ó sì yọ̀ǹda fún ẹni tí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀ fún láti beere lọ́wọ́ Ọlọ́hun kí ó sì ṣìpẹ̀ fún ọmọ ìyá rẹ̀, tí ohun tí ó n wá yẹn bá jẹ́ nínú àwọn ohun tí Ọlọ́hun ṣe ni ẹtọ láti wá.
Àmọ́ ní ọjọ́ ìgbèdìde, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò lè ṣe ìṣìpẹ̀ àfi lẹ́yìn ìyọ̀ǹda Ọlọ́hun Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun tí ọlá Rẹ̀ ga ti sọ pé: « Kò sí ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? [Suuratul Baqorah: 255].
Àmọ́ ní pa tí isesi ikú, ọ jẹ isesi ti o yatọ, kò tọ́ kí a fi wé ipò ọmọ ènìyàn ṣáájú ikú, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ fi wé ipò rẹ̀ lẹ́yìn ìgbéndé àti dídá ẹmi padà sí lára, nítorí pé iṣẹ́ òkú ti dúró, ó sì ti di ohun tí a fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ dogo kalẹ fún, àfi ohun tí òfin ẹsin yọ sílẹ̀. Wíwá ìpẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn òkú kò sí nínú ohun tí òfin yọ sílẹ̀, nítorí náà, kò tọ́ láti fi kún un. Kò sí iyèméjì pé Anabi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) lẹ́yìn ikú rẹ̀, ó wà láààyè ní ìgbésí ayé sàré kan tí ó pé ju ìgbésí ayé àwọn tí wọ́n kú ikú ṣẹhidi ( wàn ku sí ojú ọ̀nà Allah) lọ, ṣùgbọ́n kì í ṣe irú ìgbésí ayé rẹ̀ ṣáájú ikú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe irú ìgbésí ayé rẹ̀ ní ọjọ́ àjíǹde, ṣùgbọ́n ìgbésí ayé kan ni tí ẹnikẹ́ni kò ní imọ òdodo nípa rẹ̀ àti bí ó ṣe rí àyàfi Ọlọ́hun tí Ó mọ́ kúrò níbi àbùkù. Nítorí èyí ni ó ṣe wá nínú ọ̀rọ̀ ọlọ́lá, ọ̀rọ̀ rẹ̀ (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) wípé: «Ko si ẹnikankan ti yio salaamọ ( ki mi ) simi ayaafi ki Ọlọ́hun da ẹmi pada simi lara titi maa fi da a loun salamọ rẹ» [122]
Èyí ni ẹ̀rí pe ó ti kú, àti wípé ẹ̀mí rẹ̀ ti pínyà kúrò lára rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí rẹ̀ a máa padà sára rẹ̀ nígbà tí a bá sálámọ̀ sí i. Àwọn ẹsẹ ẹ̀rí tó n tọ́ka sí ikú rẹ̀ (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a) láti inú al-Ƙur'ān àti Sunnah jẹ́ ohun tí a mọ̀ daju , ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn onímọ̀ wà lórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò dí ìgbésí ayé Barzakh (Afonufoju ayé àti orún ) rẹ̀ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí ikú àwọn tí wọn ku sí oju ọna Ọlọhun (Shahidi) náà kò ṣe dí ìgbésí ayé Barzakh wọn lọ́wọ́, èyí tí A mẹ́nu bà nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ọlá Rẹ̀ ga to sọ pé: « Ẹ má ṣe lérò pé òkú ni àwọn tí wọ́n pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, bí kò ṣe pé alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n. Wọ́n sì ń pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn » . [Āli ‘Imrān: 169]. [122] Bàbá Daud lo gba a wa pẹlu onka (2041).
Ase alaye lẹkunrẹrẹ lori alamọri yii ni, nitori bukata tí a ni sí latari ọpọ iruju ti nwa yé nípa rẹ latari pípọ̀ àwọn ti n da ojuuru sí i nipa ọ̀rọ̀ yii, ti wọn si n pe ni si ẹbọ ati ijọsin fun awọn oku yàtọ̀ sí Ọlọhun, nitori naa, a n bẹ Ọlọhun fún àwa àti gbogbo àwọn Musulumi kí o lawa kuro nibi gbogbo nnkan ti o tako ofin Rẹ, Ọlọhun si ni Onimọ julọ.
Ṣugbọn èyí tí awan apakan olubẹwo nṣe bí gbígbé ohun sókè níbi saare rẹ kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà, àti diduro pẹ níbẹ òun ni o yato si òun tí wan se ni ilanan ẹṣin; nítorípé Ọlọhun mímọ tí kọ fún ìjọ anabi nípa gbígbé ohun wan sókè ju òunh anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà, àti nípa sísọ̀rọ̀ síi ní òunh òkè gẹ́gẹ́ bí apákan nínú wan ṣe má n sọ sí apákan, ó sì gba wan níyànjú láti rẹ òunh wan sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí Ó ga jù lọ pé: « Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe gbé ohùn yín ga borí ohùn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Kí ẹ sì má ṣe fi ohùn ariwo bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan yín ṣe ń fi ohùn ariwo bá apá kan sọ̀rọ̀ nítorí kí àwọn iṣẹ́ yín má baà bàjẹ́, ẹ̀yin kò sì níí fura». «Dájúdájú àwọn tó ń rẹ ohùn wọn nílẹ̀ lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣàfọ̀mọ́ ọkàn wọn fún ìbẹ̀rù (Rẹ̀). Àforíjìn àti ẹ̀san ńlá wà fún wọn». [Al-Hujrat: 2-3]
Àti pé nítorípé pipẹ níbi saare rẹ kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà àti pipara itọrọ alaafia fún anọbi lọpọlọpọ yóò má mú idifunfun àti ọpọ ariwo àti gíga òhun níbi saare rẹ - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà -, eleyii un yatọ sí nkan tí Ọlọhun se ni òfin fún awọn Musilim ninu haya (ọrọ) tí wọn se lasepe daada yí, bẹni anọbi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má ba a - ni ẹni ọwọ láàyè àti òkú, kò tọ fún musulumi kí o se nkan tí o yatọ sí ẹkọ àgbè kalẹ òfin Ọlọhun níbi saare anọbi.
Bákan náà ni awọn apakan nnkan tí awọn olubẹwo ile Ọlọhun àti awọn ẹlòmíràn má nṣe bí kí wọn wo mọn sise awaka ádùrá ṣíṣe níbi saare rẹ tí won yóò kojú sí saare tí wan yóò gbé ọwọ méjèjì sókè, gbogbo eleyii ni o yapa si nkán tí awọn enisiwaju enire nínú awọn saabe òjíṣẹ Ọlọhun àti awọn tí wan tẹle wọn pẹlu daada nṣe, koda adadaalẹ tí wọn ṣẹṣẹ muwa lojẹ, Anabi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà - sì sọ pé: «Sunnah mi àti sunnah àwọn arole ẹni imọna tí a ti fi wọn mọna lẹ́yìn mi dọwọ yín, ẹ dì í mú, kí ẹ sì fi eyin ọ̀gán gbà á mú, ẹ sì ṣọ́ra fún àwọn adadaalẹ̀, nítorí pé dájúdájú gbogbo ohun àdásílẹ̀ ni titun ni adadaalẹ̀, gbogbo adadaalẹ̀ sì ni ànù»[123]. [123]Baba Daud lo gba wa láti ọwọ́ Al-irbad ọmọ Sariyah, pẹlu onka (4607).
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: «Ẹniti o ba da adadaalẹ sinu alamọri wa yii ti ko si ninu rẹ, yoo jẹ adapada »[124] «Ẹnití o ba ṣe iṣẹ kan ti ko si àṣẹ wa lori rẹ, yio di adapada»[125]. [124] Ìgbéjáde rẹ̀ ti ṣíwájú. [125] Àtọ́kasí rẹ̀ ti ṣíwájú.
Aliy ọmọ Husein Zainul ‘Ābidīn- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- ri ọkunrin kan t'on gbadura lẹbaa saare Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o si kọ fun un nipa iyẹn, o si sọ pe: Ṣe ki n sọ hadith kan fun ọ ti mo gbọ lati ọdọ baba mi, lati ọdọ baba nla mi, lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe o sọ pe: «Ẹ má ṣe sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ sì má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ maa ṣe asalatu fún mi, dájúdájú sàlámọ̀ yín yóò máa dé ọ̀dọ̀ mi níbikíbi tí ẹ bá wà»[126]. [126] ẹgbawa láti ọ̀dọ̀ Zain al-'Aabidiin tí Sheikh tọ́ka rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ al-Hafidh al-Maqdisi, ẹni tí ó gba hadith náà jáde láìsí ìtàn rẹ̀; Ahmad sì tún gbà á wá nínú Musnad (2/367).
Bayi ni apakan awan olùṣe àbẹwò má nṣe nígbà tí wọ́n bá n salamọ sí i -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà- nípa gbígbé ọwọ́ ọ̀tún lé òsì lórí igbáàyà tàbí ní abẹ́ rẹ̀ bí irisi ẹni tí nkirun. Irú irisi yí kò tọ́ nígbà tí a bá nfi salamọ sí i -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà-, bẹ́ẹ̀ ni kò tọ́ nígbà tí a bá ń kí àwọn ẹlòmíràn yàtọ̀ sí i nínú àwọn ọba, àwọn aṣíwájú àti àwọn mìíràn; nítorí pé ó jẹ́ irisi iyẹpere, ìtẹríba àti ìjọsìn tí kò yẹ fún ẹnikẹ́ni àfi fún Ọlọhun, gẹgẹ bí Al-Hafiz ọmọ Hajar -kí Ọlọhun kẹ́ ẹ- ṣe rò ó nínu ìwé rẹ̀ Al-Fath láti ọ̀dọ̀ àwọn òní mimọ. Ọ̀rọ̀ náà sì ṣe kedere, ó sì hàn gbangba fún ẹni tí ó bá ro ipò ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀, tí èròǹgbà rẹ̀ sì jẹ́ láti tẹle ìtọ́sọ́nà àwọn ẹnisiwaju ẹnire.
Ní ti ẹni tí ìforítì, ìfẹ́-inú, itẹle afọju, àti èròkerò sí àwọn olùpèpè sí ojú-ọ̀nà àwọn àṣíwájú rere ti gba ọkàn rẹ̀, nígbà náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọ́hun. A sì n beere lọ́dọ̀ Ọlọ́hun fún àwa àti òun ní ìmọ̀nà àti ìrànwọ́ láti gb'ọla fún ododo lórí ohun yówù tí ó yàtọ̀ sí i. Dájúdájú Oun ni Ẹni tí ó dára jùlọ tí a ń tọrọ lọ́dọ̀ Rẹ̀.
Bákan náà ni ohun tí àwọn kan nínú àwọn ènìyàn máa ń ṣe nínú kíkọjú sí saare alápọnle náà láti ibi jíjìn àti jijẹnu wuyẹ wọn pẹ̀lú kíki ( salamọ) tàbí ṣíṣe ádúrà, gbogbo èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn adadaalẹ tí ó ti ṣáájú. Kò sì tọ́ fún Musulumi láti ṣe adadaalẹ nínú ẹ̀sìn rẹ̀ ohun tí Ọlọ́hun kò yọ̀ǹda. Pẹ̀lú iṣẹ́ yìí, ó súnmọ́ ìjáfara ju bí ó ṣe súnmọ́ ìfẹ́ àti ìṣàfọ̀mọ́ lọ. Dájúdájú Imam Malik - kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ - ti kọ iṣẹ́ yìí àti àwọn tó jọ ọ́, ó sì sọ pé: ""Kò sí ohun tí yóò tún ìgbẹ̀yìn ìjọ yíì ṣe bí kò ṣe ohun tí ó tún ti àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ̀ ṣe" [127]." [127] Igaathatul-Lahfaan fii Mọṣọọ'idish-Shaytọọn (1/ 363).
A sì mọ̀ pé ohun tí ó tún àwọn ẹni àkọ́kọ́ ìjọ yíì ṣe ni rírin lórí ọ̀nà ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, àti ti àwọn arole rẹ̀ ẹni imọna, àti àwọn saabe rẹ̀ tí Ọlọhun yọ́nú sí, àti àwọn olùtẹ̀lé wọn pẹ̀lú iṣẹ́ rere, kò sì níí sí ohun tí yóò tún ìgbẹ̀yìn ìjọ yíì ṣe bí kò ṣe dídìí mú wọn nínú ìyẹn, àti rírin wọn lórí rẹ̀.
Ki Ọlọhun fi àwọn Musulumi se dedee sọ́nà ohun tí ó ní ìgbàlà, ìdùnnú, àti ọlá nínú fún wọn láyé àti lọ́run; dajudaju Oun ni Ọlọrẹ Alapọn-ọnle.
Akiyesi
Ìdájọ́ abẹwo sí saare Anabi (kí ikẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a).
Ṣíṣe àbẹwò sí saare Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - kìí ṣe dandan tàbí ààlà kan nínú Hajj gẹ́gẹ́ bí àwọn kan nínú àwọn ọpọ ènìyàn àti irú wọn ṣe lérò, bí kò ṣe pé nnkan tí a fẹ́ ni fún ẹni tí ó bá ṣe àbẹwò sí mọsalasi Òjíṣẹ́ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - tàbí tí ó wà nítòsí rẹ̀.
Ní ti ẹni tí ó jìnà sí ìlú Mòdínà, kò yẹ fún un láti ṣe ìrìn-àjò pẹ̀lú èrò láti lọ ṣe àbẹwò sí saare, ṣùgbọ́n ó jẹ́ Sunnah fún un láti ṣe ìrìn-àjò pẹ̀lú èrò láti lọ bẹ Mọ́sálásí abiyi wò, tí o bá dé bẹ̀ yóò bẹ saare abiyi wò àti saare àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjèèjì, bẹ́ẹ̀ ni àbẹwò sí saare rẹ, kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a, àti sí saare àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjèèjì wá di ìtẹ̀lé fún àbẹwò sí mọ́sálásí rẹ̀, kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a, èyí sì jẹ́ nítorí ohun tí ó fìdí múlẹ̀ nínú àwọn ìwé Sọhihu méjèèjì, pé Anabi, kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a, sọ pé: «A kò gbọdọ̀ rin irin-àjò àyàfi lọ sí àwọn mọ́sálásí mẹ́ta: Mọ́sálásí Harami, Mọ́sálásí mi yìí, àti Mọ́sálásí Al-Aqsa»[128]. [128] Al-Bukhari lo gba a wa lati ọdọ Baba Hurayrah, pẹlu onka (1189), àti Muslim, pẹlu onka (1397).
Ká ní ó jẹ́ pé ṣíṣe ìrìn-àjò pẹ̀lú èrò láti ṣabẹwo saare rẹ̀ - kí ìkẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - tàbí saare ẹlòmíràn bá òfin ẹ̀sìn mu ni, ìbá tọ́ka ìjọ rẹ̀ sí i, ìbá sì tọ́ wọn síbi àjẹmónú rẹ̀; nítorí pé òun ni olùgbani nímọ̀ran jùlọ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́hun jùlọ, tí ó sì bẹ̀rù Rẹ̀ jùlọ. Dájúdájú ó ti jíṣẹ́ pípẹ́ tó yanjú, ó sì ti tọ́ ìjọ rẹ̀ síbi gbogbo ohun rere, ó sì kìlọ̀ fún wọn nípa gbogbo ohun búburú. Báwo ni, nígbàtí ó tiẹ̀ ti kìlọ̀ nípa ṣíṣe ìrìn-àjò sí ibòmíràn yàtọ̀ sí àwọn Mọ́sálásí mẹ́ta náà, tí ó sì sọ pé: «Ẹ má ṣe sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ sì má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dájúdájú asalatu yín yóò máa dé ọ̀dọ̀ mi níbikíbi tí ẹ bá wà»[129] [129] Àtọ́kasí rẹ̀ ti ṣáájú.
Sísọ pé ó jẹ́ ìlànà ẹ̀sìn láti ṣe ìrìn-àjò láti lọ bẹ saare rẹ̀ wò - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - a máa yọrí sí sísọ ọ́ di ọdún, àti bibọ sínú ohun tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - bẹ̀rù; èyíun ni àṣejù àti ìyìnsí àpọ̀jù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe bọ́ sínú ìyẹn nítorí ìgbàgbọ́ wọn pé ó jẹ́ ìlànà ẹ̀sìn láti ṣe ìrìn-àjò láti lọ bẹ saare rẹ̀ wò - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -.
Ṣùgbọ́n nípa ohun tí wọ́n gbà wá nípa akọle yìí nínú àwọn ọ̀rọ̀ anọbi, èyí tí àwọn tó sọ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìrìn-àjò lọ síbi saare rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi ń ṣe ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ anọbi wọ̀nyẹn lẹ ní ti ọnà ìgbàwá, kódà, àdáparọ ni wọ́n, gẹ́gẹ́ bí àwọn Al-Hafis ṣe sọ lilẹ awọn hadith naa di mímọ̀; bíi Ad-Daraqutni, Al-Bayhaqi, àti Al-Hafis ọmọ Hajar àti àwọn mìíràn. Nítorí náà, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi wọ́n tako àwọn ọ̀rọ̀ anọbi tó ní àláàfíà, èyí tó ń tọ́ka sí èèwọ̀ ṣíṣe ìrìn-àjò sí ibòmíràn yàtọ̀ sí àwọn Mọ́ṣáláṣí Mẹ́ta.
Irẹ oluka iwe yí gba nínú awọn agbelẹrọ ọrọ anọbi nípa akọle ọrọ yí kí ọ le mọn kí ọ le ṣọra níbi igbatanjẹ pẹlu rẹ:
Alakọkọ: (ẹnikẹni tí o bà se isẹ hajj tí kò wa se abẹwo simi irú ẹni bẹ tí wuwa agọ sí mi)
Ẹ́ekeji: (ẹnikẹni tí o bà se àbẹwò simi lẹyìn tí mo ba tí kutan gẹgẹ bí ẹni pé o se àbẹwò simi nígbàtí mowa láyè ni).
Ẹlẹẹkẹta: «ẹni k'ẹni tí o bà se àbẹwò sí mí, tí o sí ṣe àbẹwò sí bàbá mí Ibrahim ní ọdún kan náà mọ fi ọwọ́ sọya fún níwájú Ọlọhun pé yóò wọ ọgbà idẹra».
Êlẹkerin: (ẹni k'ẹni tí o bà se àbẹwò sí saare mí isipẹ mí tí di dandan fún).
Awon ọrọ anọbi wọnyíi àti irú rẹ kò sí nkán kan nínú rẹ tí o tí ọdọ anọbi wà - kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a -.
Al-Hafis ọmọ Ajar nínú tira rẹ "Attalikhs" sọ pé: - lẹyìn tí o tí mẹnuba ọpọ awọn ẹgbawa - gbogbo awọn ọna ọrọ anọbi yii ni o lẹ.
Al-Hafis Al-'Uqayliy sọ pé: kò sí kàn nínú ọrọ anọbi tí wọn mu wa nípa akọle yí to ọ ni alaafia.
Aafa agba ẹsin Isilaamu, ọmọ Taymiyyah - ki Ọlọhun ṣe ikẹ Rẹ fun un - la ọrọ mọlẹ pé, àwọn àgbélẹ̀rọ ni gbogbo àwọn Hadiisi wọ̀nyí. Ó sì tó fún ọ́ ní ẹ̀rí pẹ̀lú ìmọ̀, àkisórí, àti ìwádìí rẹ̀.
Bí ó bá jẹ́ pé nkankan nínú rẹ̀ fìdí múlẹ̀, àwọn saabe - kí Ọlọ́hun yọ́nú sí wọn - ni ìbá yára jùlọ nínú àwọn ènìyàn láti fi ṣiṣẹ́, àti láti ṣe àlàyé rẹ̀ fún ìjọ àti láti pè wọ́n sí i; nítorí pé àwọn ni ó loore jùlọ nínú àwọn ènìyàn lẹ́yìn àwọn Anọbi, tí wọ́n sì ní ìmọ̀ jùlọ nípa àwọn ààlà Ọlọ́hun àti ohun tí Ó pa láṣẹ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ aláìlẹ́tàn jùlọ sí Ọlọ́hun àti sí àwọn ẹda Rẹ̀. Nígbà tí a kò sì ròyìn nkankan nínú èyí látọ̀dọ̀ wọn, èyí fi hàn pé kì í ṣe ohun tí a pa láṣẹ.
Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ohun kan nínú rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀, ìbá jẹ́ dandan láti mú un túmọ̀ sí àbẹwò tó bá òfin mu, èyí tí kò sí rírìn ìrìn-àjò nínú rẹ̀ fún ìpinnu saare nìkan ṣoṣo; láti ṣe ìparapọ̀ láàrin àwọn hadith, Ọlọ́hun - Atóbilọ́lá - sì ni Onímọ̀ Jùlọ.
Ori-Akori Ọrọ
Nípa ninifẹ sí ṣíṣe àbẹ̀wò sí Mọsalasi Quba àti Al-Baqi’.
Wọn fẹ fún ẹni tí o bà se àbẹwò sí Madina kí o se àbẹwò sí mọsalasi Quba kí o si kirun nibẹ; nítorí ohun tí ó wà nínú ìwé Sahih méjèèjì láti inú hadith ọmọ Umar, kí Ọlọhun yọnu sí wọn, o sọ pé: «Anọbi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - a máa ṣe àbẹwò sí mọsalasi Qubah ní ẹni tí ó gun nǹkan tàbí tí ó fi ẹsẹ̀ rìn, ó sì kí irun rakah méjì níbẹ̀»[130]. [130] Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1193), àti Muslim pẹlu onka (1399).
Ati lati ọdọ Sahl ọmọ Hunaif - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: òjíṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - sọ pé: «ẹni tí o bà se imọra láti Ile rẹ lẹyìn náà ní o wa wa sí mọsalasi Qubah, o wa kí Irun kan nibẹ yóò máa ni ẹsan bí ẹ ni tí o se Umrah» [131]. [131] ọmọ Mājah lo gba a wa, pẹlu onka (1412) .
Ìlànà anọbi lọ jẹ fún un láti ṣe abẹwo sí awọn saare Al-Baqiih, àti awọn saare awọn tí wọn ku sí ojú ònà Ọlọhun, àti saare Amzah kí Ọlọhun yonu sí; nitori anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa bá , a máa se àbẹwò sí wọn, a si máa se àdura fun wọn àti nítorí ọrọ rẹ kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a tí o sọ pé: «Ẹ maa ṣe abẹwo saare, tori pe dajudaju yio maa ran yin leti ọjọ ikẹhin» [132]. Muslim lo gba a wa [132] Muslim lo gba a wa, pẹlu onka (976).
ati pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o maa n kọ awọn saabe rẹ nigbati wọn ba bẹ saare wo pe ki wọn maa sọ pe: "As salaamu alaykum ahlad- diyaar minal mu'miniina wal muslimiin, wa innaa insha Allahu bikum laahiquun, nas'alu llaha lanaa wa lakumu al aafiyah" itumọ rẹ ni pe: Alaafia Ọlọhun ki o maa ba yin ẹyin ara itẹ ninu ẹyin olugbagbọ ododo ati musulumi, ati pe awa naa nbọ wa dára pọ mọn yin pẹlu ogo Ọlọhun, awa tọrọ alaafia lati ọdọ Ọlọhun fun yin ati fun awa naa [133]. Muslim ni o mu jáde láti inú hadith Sulaiman ọmọ Bureda láti ọdọ bàbá rẹ. [133] Muslim lo gba a wa, pẹlu onka (975).
Tirmidhi mu jade, lati ọdọ ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi àwọn saare Mọdina, o wa kọ oju rẹ si wọn, ni o wa sọ pe: Alaafia Ọlọhun ki o maa ba yin, ẹyin ara itẹ, ki Ọlọhun o ṣàforíjìn fún wa àti fún yín, ẹyin ni asiwaju wa, awa naa si nbọ lẹyin [134]. [134] At-Tirmidhi lo gba wa, pẹlu onka (1035).
Àti pé nínú àwọn hadisi wọ̀nyí ni a ti mọ̀ pé dájúdájú àbẹwò sí saare tí ó bá òfin mu ni ohun tí a gbá lérò níbẹ̀ ni riranti ọrùn, àti iṣẹ rere sí àwọn òkú, àti ṣíṣe àdúà fún wọn àti títọrọ ìkẹ fún wọn.
Ṣugbọn ṣíṣe àbẹwò wọn ní erongba sise adura níbi saare wọn, tàbí ìdádúró níbẹ̀, tàbí bibere ibiya bukaata ni ọdọ wọn, tàbí ibere ìwòsàn alaarẹ, tàbí ifi orukọ wọn bẹ Ọlọhun, tàbí fífi ìyí àti ọlá wọn tọrọ àti bẹẹbẹẹ lọ, eleyii ni isabẹwo tí o kun fún adadaalẹ tí kò da, Ọlọhun kò gbé Kalẹ ní ìlànà òfin, bẹ ni òjíṣẹ rẹ kò filelẹ ni ìlànà ẹṣin, bẹẹ ni awọn ẹnisiwaju ti wọn jẹ ẹnire ko se e, kí Ọlọhun yọnu si wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ lára ìyapa tí Òjíṣẹ́ Ọlọhun kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bàa kọ̀, níbi tí ó ti sọ pé: «Ẹ maa ṣe abẹwo saare, ẹ ko si gbọdọ sọ ọ̀rọ̀ odi» [135]. [135] Muslim lo gba wa, lati ọdọ ọmọ Buraydah, lati ọdọ baba rẹ, pẹlu onka (977).
Àwọn ọ̀rọ̀ tí a dárúkọ yíì papọ̀ nínú jíjẹ́ adadaalẹ, ṣùgbọ́n wọ́n yàtọ̀ sí ara wọn ní ipò; apá kan nínú rẹ̀ jẹ́ adadaalẹ kì í sì í ṣe ẹbọ; gẹ́gẹ́ bíi síṣe àdúà sí Ọlọ́hun níbi àwọn sàréè, àti fífi ẹ̀tọ́ òkú àti ọlá rẹ̀ bẹ Ọlọhun, àti bẹ̃bẹ̃ lọ, tí apá kan nínú rẹ̀ sì jẹ́ nínú ẹbọ ńlá, gẹ́gẹ́ bíi kikepe àwọn òkú fún ìrànlọ́wọ́ àti wíwá ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú wọn, àti bẹ̃bẹ̃ lọ.
Àlàyé èyí ti gbawaju ni ẹkunrẹrẹ lọ́nà fífẹ̀ nínú ohun tó ti ṣíwájú, nítorínáà kíyè sára kí o sì ṣọ́ra, kí o sì beere kongẹ àti ìtọ́sọ́nà síbi ododo lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, dájúdájú Òun ni Olùfúni ni kọ́ngẹ́ àti Olùtọ́nisọ́nà, kò sí ọlọ́hun mìíràn yàtọ̀ sí I, bẹ́ẹ̀ ni kò sí olúwa kan yàtọ̀ sí I.
Eyi ni igbẹyin ohun ti a fẹ kọ silẹ, ọpẹ ni fun Ọlọhun ni akọkọ ati ni igbẹyin, ikẹ Ọlọhun ki o maa ba ẹru Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ ati ayanfẹ Rẹ ninu awọn ẹda Rẹ, Muhammad, ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ, ati ẹniti o ba tẹle wọn pẹlu daadaa titi di ọjọ ẹsan.
Related books
All books
Ọrọ ní ṣókí (aboode ọrọ) nípa bí aṣele ṣe iṣẹ Umrah àti awọn ìdájọ rẹ59 èdèỌrọ ní ṣókí (aboode ọrọ) nípa bí aṣele ṣe iṣẹ Umrah àti awọn ìdájọ rẹ
Ọpẹ ni fun Ọlọhun Olúwa gbogbo àgbáyé, kí ikẹ àti ọla Ọlọhun máa ba Anọbi wa Muhammad àti awọn ara ilé rẹ àti awọn saabe rẹ lapapọ. Ọpẹ ni fun Ọlọhun Olúwa gbogbo àgbáyé, kí ikẹ àti igẹ Ọlọhun máa ba anọbi wa Muhammad ati awọn ara ilé rẹ àti awọn ọmọ lẹyìn rẹ lapapọ. Lẹyin naa: Eleyi ni idani lẹkọ ni ṣoki nipa bí aṣele ṣe ìjọsìn Umrah àti awọn idajọ àti ẹkọ rẹ, a gbiyanju láti ṣe àlàyé ọpọ nkán tí ẹni ti o nṣẹ Umrah ni bukaata sí nínú rẹ. À ń bẹ Ọlọhun pé kí O ṣe ni ohun tí a fi wa ojuure Rẹ Alapọnle, kí O si jẹ kí o wúlò fún gbogbo apapọ awọn musulumi.
Awọn ipilẹ mẹta ati awọn ẹri rẹ65 èdèAwọn ipilẹ mẹta ati awọn ẹri rẹ
Iwe yii ṣe alaye awọn nnkan ipilẹ ti kíkọ́ wọn jẹ dandan fun musulumi: mímọ Ọlọhun, mímọ ẹsin Isilaamu, ati mímọ Anabi Muhammad (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a), o si ṣe alaye pataki awọn ìpìlẹ wọnyi nibi gbigbe ìgbàgbọ́ ro ati ṣíṣe iṣẹ rere pẹlu gbigbarale awọn ẹri lati inu Alikuraani ati Hadiisi.
Awọn ẹkọ ti o ṣe pataki fun gbogbo ali'ummah ( ìjọ musulumi)40 èdèAwọn ẹkọ ti o ṣe pataki fun gbogbo ali'ummah ( ìjọ musulumi)
Tira 'Ad-duruusul Muhimmah li 'aammatil Ummah' ( Awàn ẹkọ tí o pàtàkì fún apapọ ìjọ musulumi) ti alufaa agba Sheik Abdul Azeez ọmọ Bāz - ki Ọlọhun kẹ ẹ - jẹ́ ìwé tí o wa nisoki ṣùgbọ́n tí anfaani rẹ̀ pọ̀ yanturu, tí Imaamu ( asíwájú ẹṣin,) naa ṣe àkójọ rẹ láti jẹ́ ipese ìmọ̀ fún gbogbo Musulumi. Ó ṣe àlàyé àwọn ìpìlẹ̀ ẹsìn àti àwọn òpó rẹ̀ nínú rẹ , bẹ̀rẹ̀ láti orí ọrọ imọn Ọlọhun nikanṣoṣo Tawhiidi, Imaani, ìgbàgbọ àti Isilaamu, títí dé orí àwọn òfin imọra àti irun kíkí, àwọn ẹkọ rere ti Isilaamu kọ wa , àti àlàyé lórí ewu Ṣirik ( iṣẹ ẹbọ pẹlu Ọlọhun,) àti àwọn ìyapa Ọlọhun, pẹ̀lú ọ̀nà…
Eleyii ni akọsilẹ soki kan nipa ẹsin Isilaamu gẹgẹ bi o ṣe wa ninu Alikuraani alapọnle pẹlu Sunnah Anọbi71 èdèEleyii ni akọsilẹ soki kan nipa ẹsin Isilaamu gẹgẹ bi o ṣe wa ninu Alikuraani alapọnle pẹlu Sunnah Anọbi
Ẹsin Isilaamu Tira pataki to ko alaye nipa ẹsin Isilaamu sinu, to nṣalaye eyi ti o pataki ju ninu awọn ìpìlẹ, ẹkọ ati awọn ẹwa rẹ lati inu awọn iwe-ẹri ipile; eyi tii ṣẹ Alikuraani alapọnle ati Sunnah Anọbi. Tira yii eyi ti a fi nba gbogbo ẹniti o ti balaga sọrọ, yala o jẹ musulumi tabi kii tiẹṣe musulumi, to si wa ni ede onikaluku wọn, ko le baa wulo ni gbogbo asiko, aaye ati oniruuru iṣesi tabi ipo ti wọn ba wa. Ẹda kan niyi ti o ko awọn ẹri lati inu Alikurani ati Sunnah Anọbi sinu 1. Ẹsin Isilaamu ni iṣẹ naa ti Allah fi ranṣẹ si gbogbo eniyan. Paapaajulọ Oun ni iṣẹ ayeraye ti o sijẹ opin…