Ni Orukọ Ọlọhun, Ọba Ajọkẹ-aye, Aṣakẹ ọrun Njẹ o ti ẹ bi ararẹ leere: pé taani o da awọn sanma ati ilẹ ati gbogbo awọn ẹda n lanla ti o wà ninu mejeeji? Tani eni to ṣe eto tí ó muna doko tí ó sì duro daada yii sinu rẹ?
pé taani o da awọn sanma ati ilẹ ati gbogbo awọn ẹda n lanla
ti o wà ninu mejeeji? Tani eni to ṣe eto tí ó muna doko tí ó sì duro daada yii sinu rẹ?
Bawo ni agbaye nla yii ṣe tò ti o si tun fidi mulẹ pẹlu awọn òfin ti o n dari re pelu idari ti okunan daada ti osi péye lati odún gbọọrọ (bi ọdun ṣe n gori ọdun)?
Ṣe agbaye yìí ṣẹda ara rẹ ni bi? Tàbí ó wá lati ibi asán ni bi ? àbí a kàn déédé Waye bee ni bi?
Tani ó da ọ?
Tani ó ṣe awọn ètò tó muna doko yii sinu awọn irinse ati eronja ara rẹ ati ara awọn ẹda alaaye miiran?
Kosi ẹnikẹni ti yoo gbagbọ pe ki wọn sọ fun un pe ile yii ( ti o nwo yi ) kàn wa ni láìsí ẹnikankan ti ó kọ ọ! Tabi ki wọn sọ fun un pe aisi ni ó kọ́ ile yii! báwo waa ni awọn kan ṣe lè gbagbọ lododo si ẹni ti nsọ pé agbaye nla yìí kàn wa ni láìsí ẹnikankan tó da? báwo ni onilaakaye (olopolo ) èniyàn ṣe lè gba lododo kí wọ́n waa sọ fún un pé ètò agbaye tó muna doko yìí ṣà déédé wa ni fun rara re?
dajudaju Ọlọhun kan nbẹ tó tobi, Oluṣẹda ati Oludari gbogbo agbaye yii ati gbogbo ohun tí ó wa ninu rẹ, Oun naa ni Ọlọhun Allah mimọ ni fun Ọba ti ọla Rẹ ga ju lo.
Bee ni Ọlọhun - mimọ ni fun Un - ti rán awọn ojiṣẹ kan si wa, O si sọ awọn tira ti see Oro Olohun (imisi) kalẹ fun wọn, eyi ti ó sokalẹ gbẹyin ni Al-Qur’aani Alapọnle ti Ọlọhun sọ ọ kalẹ fun Muhammad, ẹni ti o kẹhin de ninu awọn ojiṣẹ Ọlọhun, ati pe lataara awọn tira Ọlọhun ati awọn ojiṣẹ Rẹ:
⦁ Ni Ọlọhun ti fi ara Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn ẹtọ Rẹ lori wa mọ wa, O si ṣalaye awọn ẹtọ wa lori Rẹ.
⦁ O si tọ wa sọnan pe Oun ni Oluwa tí O da gbogbo ẹda, ati pe Ohun ni Alaayè ti ko nii ku, ati pe gbogbo ẹda wa ni ikawo Rẹ ati labẹ Ileke Rẹ Lori gbogbo I
nkan ati ise bose wu ni iidari Rẹ.
O si fun un wa ni ro pé ninu awọn iroyin Oun ni ìmọ̀, bee si ni Oun si ti rọkirikaa ( Mon ) gbogbo nkan la kotan , ati pe Oun ni Olugbọoro ati Oluriran, ko si nkankan tó pamọ si Oun ninu gbogbo nkan tó wà lori ilẹ aye ati ninu sanmọ. ( Ati Larin )
⦁ O si tun fun wa
Niro pe pé dajudaju Oun ni Oluwa naa , Eni tí awọn iroyin pípé nbẹ lara Rẹ, O Pese Opolo ( laakaye ) fun wa ati awọn iye-ara to wa fun mi mon n kan ti nlo layika tí a o fi mọ àwọn iyanu ant eehmon isẹda Rẹ̀ ati agbara Rẹ̀, ninu awọn nkan tí ó ń tọ́kaa wa sí títóbi Rẹ̀ ati agbára Rẹ̀ àti pípé awọn iroyin Rẹ̀, Ó dá adamọ kan siwa lara eyi tó n tọka si ìjẹ́pípé Rẹ̀ ati pé kò rọrun ki a royin Rẹ̀ pẹlu abuku ( idinkun tabi aaye)
⦁ O fi mọ wa pé dajudaju Ọlọhun naa nbẹ lókè awọn sanmọ Rẹ̀, ati pe Ọlọhun naa kò sí ninu agbaye, bẹ́ẹ̀ ni agbaye naa kò ni ise si pelu Rẹ̀.
⦁ O tun sọ fun wa pe tulasi ( dandan ) ni fun was lati juwọ-jusẹ silẹ ( gbaa ) fun Oun - mimọ ni fun Un -, Oun ni Ẹlẹdaa wa ati Ẹlẹdaa agbaye
be si ni Oun ni Oludari rẹ̀.
Ọlọhun Ẹlẹda ní awọn iroyin titobi, ko si rọrun laelae ki O gba iroyin pẹlu aini tabi abuku, Ọlọhun kò kí ńgbagbe nkan, kò sì kíí sùn, bẹẹ ni kò kí ńjẹ ounjẹ, kò sì ṣeeṣe kó ní iyawo tabi ọmọ; ati pe gbogbo awọn ọrọ atọrunwa tí ó bá ti yapa si titobi Ọlọhun Ẹlẹdaa ko kii ṣẹ ọrọ tó lalaafia eyi ti awọn ojiṣẹ Ọlọhun mu wa - ki alaafia Ọlọhun maa ba wọn -.
Ti o bá ní igbagbọ si Ọlọhun Ẹlẹda... njẹ o ti ẹ beere ni ọjọ kan pé kini idi ti Ọlọhun fi da ọ? ki ni Ọlọhun Allah fẹ lọdọ wa, ki ni erongba
( Afojusun ) bibe layer wa ?
Inje ó ṣeeṣe ki o jẹ pe Ọlọhun kan dá wa sile lasan ? Se oseese ki o ja si pe Olohun kan dá gbogbo awọn ẹda wọnyi laisi erongba ( afojusun ) kan tabi idi kan pato?
Bi Oro se ri gele ni pe dajudaju Ọlọhun Ẹlẹda ti O tobi “Allahu” sọ fun wa nipa idi ti O fi ṣẹda wa, idi naa ni jijọsin fun Ọlọhun Allahu nikanṣoṣo, ati pe ki ni ohun ti O fẹ lati ọdọ wa! O sọ fun wa pe Oun nikanṣoṣo ni O lẹtọ si ijọsin, O sì ṣe alaye fun wa nipasẹ awọn ojiṣẹ Rẹ̀ - ki alaafia Ọlọhun maa ba wọn - bawo ni a o ṣe maa jọsin fun Un
? bawo si ni a ṣe lè sún mọ́ ọn
pelu ijosin latara titẹle awọn aṣẹ Rẹ̀ ati gbigbe awọn mi o fe Rẹ̀ ju silẹ? bawo ni a ṣe le rí iyọnu Rẹ̀? ti a si sọra fun ìyà Rẹ̀, O sọ fun wa nipa ibugbe ( Aaye to a o pada si ) wa lẹhin iku?
O sọ fun wa pe daju daju iṣẹmi ile aye yii adanwo lásán ni, ati pe iṣẹmi otitọ gangan tí ó peé oun ni yoo waye ni ọjọ ikẹyin lẹyin iku.
O tun sọ fun wa pe ẹni ti o ba jọsin fun Ọlọhun gẹgẹ bi O ṣe pa a laṣẹ, tí ó sì yàgò kuro nibi ohun tí Ó kọ̀ fun, onitọhun yoo maa gbe igbesi aye daada ni ile aye, yoo si ni idẹra gbere ni ọjọ ikẹyin, ṣugbọn ẹnikẹni tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ( ti o tapa si àṣẹ Olohun ) ti o tun ṣe aigbagbọ si i, Oriibu ni yoo je tie ni ile aye, yoo sì jẹ iya gbere ni ọjọ ikẹyin.
Nitoripe a timon kò rọrun ki a maa ba ile ayé yii lọ láìjẹ́ pé gbogbo eniyan kokan ninu wa maa gba ẹsan ohun ti ó bá ṣe ni iṣẹ yálà daada ni tabi aburu, ati pe kò rọrun kó ma si ijiya fun awọn alabosi tabi ẹsan daada fun awọn oluṣe rere?
Daju daju Ọlọhun wa ti sọ fun wa pe jijere iyọnu Oun ati lílà kuro nibi iya Oun ko le waye ayaafi pẹlu kikọ wọnú ẹsin Islaamu, eleyii ti o tu mo ṣi pe oun ni ijuwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun Ọba ati jijọsin fun Un ni Oun nikanṣoṣo láì fí orogun fun Un, ati gbigbafa lati tẹle aṣẹ Rẹ, ati mimu ofin Rẹ lo pẹlu iyọnu ati itẹwọgba, Ọlọhun si ti sọ fun wa pe Oun kò nii gba ẹsin kankan lọwọ awọn eniyan ayaafi ẹsin Islaamu, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe báyi pe :{Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Iruenibe yóò sì máa wá nínú àwọn ẹni ofo ni ojo ikeyin )Surah Âl-Imrân: 85.
ẹnikẹni tí ó bá woye si ohun ti ọpọlọpọ awọn eniyan n jọsin fun lode oni ; yoo ri pe awọn kan n jọsin fun eniyan, awọn miiran n jọsin fun oriṣa,( eere ) awọn miiran n jọsin fun irawọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, kò sì lẹtọ fun onilaakaye eniyan lati jọsin fun nkankan
miran yatosi Ọlọhun Oluwa gbogbo agbaye, Ẹniti O pe nibi awọn iroyin Rẹ, bawo ni yoo ṣe maa jọsin fun ẹda ( eniyan) bii rẹ̀ tabi eyi tí ó kere si i! nitori naa nkan ti a fẹ maa jọsin fun kò gbọdọ jẹ eniyan
kan , tabi oriṣa tabi kan , igi tabi ẹranko kan !
gbogbo ẹsin ti awọn eniyan n ṣe loni - yatọ si ẹsin Islaamu - Ọlọhun kò nii tẹwọgbaa lọwọ wọn nitori pe yala ki o je ẹsin ti awọn eniyan kan daa kalẹ ni tabi ki o jẹ ẹsin lati ọdọ Ọlọhun ti awọn eniyan ti fi ọwọ ibajẹ yi i pada, ṣugbọn ẹsin Islaamu, oun ni ẹsin Ọlọhun gbogbo agbaye, ko yii pada, ko si nii yii pada, ati pe tira ẹsin yii ni Al-Qur’an Alapọnle, oun ni tira ti wọn daa bo bo ( ti a fi iso so ) ti osi wa gẹgẹ bi Ọlọhun ti ṣe sọ ọ kalẹ, o wa lonọwọ awọn Musulumi titi di oni pẹlu ede ti wọn fi sọ ọ kalẹ si ojiṣẹ igbẹyin.
Ninu awọn ipilẹ Islaamu ni ìní ki ọ ni gbagbọ si gbogbo awọn ojiṣẹ ti Ọlọhun rán niṣẹ, gbogbo wọn ni eniyan ti Ọlọhun fi awọn aami ati awọn iṣẹ iyanu ṣe atilẹyin ( Ikun lowo ) fun wọn, O si rán wọn niṣẹ lati pèpè lọ sibi jijọsin fun Oun nikanṣoṣo lai wa orogun fun Un,Ẹni ti o kẹyin ninu awọn ojiṣẹ ni Anabi Muhammad, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun ko maa ba a, Ọlọhun ti ranise pẹlu iilanan ofin sharia to je ti Rẹ, eyi ti o jẹ igbẹyin ( opin ) awọn ofin, ti o sì pa ofin awọn ojiṣẹ tí ó ṣiwaju rẹ̀ rẹ́, O kun un lọwọ pẹlu awọn aami nlanla, eyi ti o tobi julọ ninu awọn àmi náà ni Al-Qur’an Alapọnle, ọrọ Oluwa gbogbo agbaye, tira ti o tobi julọ ninu awọn tira ti awọn ẹda eniyan timọ̀, iyanu ni aparapo nkan tó wà nínú rẹ ati gbolohun rẹ̀ ati agbekalẹ ọrọ rẹ̀ ati awọn idajọ rẹ̀, imọna si ọna ododo wà nínú rẹ , eyi tí yoo muni dé ibi orire aye ati ọrun, pàápàá jùlọ tira naa sọkalẹ pẹlu ede Larubawa.
Ọpọlọpọ awon ẹri to ba laakaye mu ati imọ-ijinlẹ eyi ti o nṣe afirinle laisi iyemeji nibẹ pé Al-Qur’aani yii ọrọ Ọlọhun Ọba Ẹlẹda ni - mimọ ni fun Ọba ti ọla Rẹ ga - ati pe kò rọrùn kí ó jẹ pe iṣẹ ọwọ eniyan ni.
Ninu awọn ipilẹ Islaamu ni ini igbagbọ ninu awọn Malaika ( iransẹ Olohun ) ati ini igbagbọ si ọjọ ikẹyin, nigba ti Ọlọhun yoo gbe awọn eniyan dide lati inu saare wọn ni ọjọ ajinde ( igbende) lati ṣe iṣiro wọn lori awọn iṣẹ wọn, ẹnikẹni ti ó bá ṣe iṣẹ rere ti ó si jẹ onigbagbọ ododo, idẹra ayeraye yoo maa bẹ fun un ninu alujannah, ẹnikẹni ti ó bá sì ṣaigbagbọ ti ó tun ṣe iṣẹ aburu, ìyà to tobi nbẹ fun un ninu ina, ninu awọn ipilẹ islaamu bakanaa ni ini igbagbọ si kadara ( Eto Ọlọhun lori gbogbo eda , rere ni tabi aburu.
Ẹsin Islaamu ni ilanọ tí ó kó iṣẹmi aye ni akotan sinu , osi wa ni ibamu pẹlu adamọ eniyan ati ilaakaye, (opolo ) awọn ẹmi ati ọkan tí ó wà ní adamon wan
a tẹwọgba a, Ọlọhun Ọba Ẹlẹda ti O tobi ni O ṣe e lofin fun awọn ẹda Rẹ, oun ni ẹsin orire ati idunnu fun gbogbo eniyan ni aye ati ọrun, kò kii n dá iran kan yatọ si omiran bẹẹni kii n da ẹya alawọ kan yatọ si ẹya alawọ miiran, bakan naa ni gbogbo eniyan se je lọdọ rẹ, ko si enikan ti ó dá yatọ si ẹlomiiran ninu islaamu ayaafi pẹlu bi odiwọn iṣẹ rere rẹ̀ ba ṣe tó.
Ninu awọn nkan ti Ọlọhun n fi idi rẹ mulẹ ninu Al-Qur'an Alapọnle ni pe ini igbagbọ sì Allahu gẹgẹ bi Oluwa ati Ọlọhun, ati ini igbagbọ sì Islaamu gẹgẹ bi ẹsin, ati ini igbagbọ si Muhammad gẹgẹ bi ojiṣẹ, ati wiwọ inu esin Islaamu, gbogbo awọn nkan wọnyii dandan lo jẹ fun eniyan, ko sii aaye fun un lati ṣẹṣa, ti o bá wa di ọjọ Ajinde iṣiro iṣẹ ati ẹsan nbẹ; ẹnikẹni tí ó bá jẹ́ onigbagbọ ododo erenjẹ tí ó tobi nbẹ fun un, ẹnikẹni tí ó bá sì jẹ aláìgbagbọ òfò ti o hàn ponbele nbẹ fun un.
Ẹnikẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú ẹ̀sìn Islaamu ( gbaa Islam ) Oni lati sọ pé: (Ash'hadu an laa ilaaha illa Allah wa ash'hadu anna muhammdan rasuulu Llah). Eyi ti otumon sì pe : (Mogba pe kosi enikankan ti o to lati máa fí ìjọsìn fún àyàfi Olohun Allah , ati pe anọbi Muhammed ni Ojisẹ Re. ) ní ẹniti yoo mọ itumọ rẹ̀, ti yoo sì ní igbagbọ ninu rẹ̀, bayii ni yóò ṣe di mùsùlùmí; Lẹyin naa yoo maa kọ́ awọn iyoku ninu awọn ofin Islaamu diẹdiẹ; lati lè ṣe ohun tí Ọlọhun ṣe ni ọranyan fun un.
Islaamu ni ijuwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun, Oluṣẹda ati Oludari gbogbo agbaye, ati itẹriba fun Un ni ti ifẹ ati gbigbetobi, ipilẹ Islaamu ni níní igbagbọ si Ọlọhun, ati pe Oun ni Ọba Asẹ́dàá, bẹẹ si ni ẹda ni gbogbo ohun tó yatọ Sii, ati pé Òun nikan ṣoṣo ni o tọ láti jọsin fún, ko si orogun fun Un, bẹ ni ko si ẹnikan ti a gbọdọ jọsin fun lododo ayafi Oun nikan, ti Rẹ̀ ni awọn orukọ tó rẹwa julọ ati awọn iroyin tó ga julọ, Oun ni O ni pipe laisi abuku, kò bimọ, ẹnikan ò si bi, bẹẹni ko si iru tabi alafijọ fun Un, ko si ki n ko si ara nkankan ninu awọn ẹda Rẹ̀. Ati pé Islaamu ni ẹsin Ọlọhun Ọba…