المختصر المفيد للمسلم الجديد

المختصر المفيد للمسلم الجديد

الكتاب يعرض مبادئ الدين الإسلامي بشكل مختصر وواضح، يتناول أساسيات العقيدة الإسلامية، وأركان الإسلام والإيمان، والعبادات المفروضة والمنفولة كالصلاة والصيام والزكاة والحج. مع التأكيد على أهمية القرآن الكريم كمصدر إرشادي أساسي، ويوضح دور النبي محمد ﷺ كرسول الرحمة والهداية للعالمين.

Language: lang_yo
Prepared by:
Version: 1.0
Translations 31
Amharic Bosnian Dhivehi English +27
Attachments 7
PDF
Audio
Video
+3

Ọrọ ṣókí ti yoo ṣe anfaani fún Musulumi titun

Ìgbéjáde

Muhammad Ash-Shihriy

1441 - 2020

Pẹlu orukọ Ọlọhun Ajọkẹ ayé Àṣàkẹ́ ọ̀run

Ọrọ itisiwaju

Dajudaju gbogbo ẹyin tí Ọlọhun ni, a n yin In, a tun n wa iranwọ Rẹ, a sì tún n wa aforijin Rẹ, a sì tún n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi aburu ẹ̀mí wa ati kuro nibi awọn aburu àwọn iṣẹ wa, Ẹni tí Ọlọhun ba fi m'ọna ko si ẹnití o le sọ ọ nù, ẹnití O ba sì sọnu, ko si ẹni ti o le fi mọna. Mo wa jẹrii wipe dajudaju ko si olujọsin fun miran ayafi Allooh ni Oun nikan ṣoṣo, ko si orogun fun Un, mo si tun jẹrii wipe dajudaju Anabi Muhammad ẹru Rẹ ni ojiṣẹ Rẹ si ni pẹlu.

Lẹyin naa:

Ọlọhun ti ọla Rẹ ga gbe apọnle fún ọmọ Anabi Ādam, O si tun gbe ọla fún wọn lori ọpọ nínú àwọn ẹdá Rẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam. Suuratul Isrāi: 70. O tun wa ṣe alekun apọnle fún ìjọ yìí pẹ̀lú pe O ran sí wọn ẹnití o ni ọla julọ ninu awọn Anabi Rẹ, oun náà ni Muhammad- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a -, O si tun sọkalẹ fún wọn eyiti o lóore julọ ninu awọn tira Rẹ, oun náà ni Al-Qur'ān alapọn-ọnle, O si tun yọnu sí fún wọn eyiti o tobi julọ ninu ẹsin ti o ṣe l'ofin, oun náà ni Islām, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ jẹ́ ìjọ t’ó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́. Aal-Imraan 110. Ati pe ninu titobi idẹra Ọlọhun ti ọla Rẹ ga lori ọmọnìyàn ni wipe O ṣe idẹkun le wọn lori pẹlu ṣiṣe amọna wọn lọ sí inu Islām, ati fífi ẹsẹ wọn rinlẹ ni ori rẹ, ati ṣíṣe iṣẹ tọ àwọn idajọ rẹ ati awọn òfin rẹ, ati pe ninu iwe yii ti o kere ni iwọn, ti nkan ti o ko sinu si tobi, ti olumọna titun a máa kọ níbẹ̀ nkán ti ko gbọdọ ma mọ ni ibẹrẹ Islām rẹ ni ọna ṣókí ti yíò máa ṣàlàyé fún un àwọn nkan àmì ẹsin ti o tobi yii. Ti o ba ti wa gbọ ọ ye ti o sì ṣe àmúlò nkan ti o n pepe si, yoo gbera lati lọ wa ìmọ̀ ati alekun rẹ kí imọ rẹ nípa Oluwa rẹ ti ọla Rẹ ga ati Anabi rẹ Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a-, ati ẹsin rẹ tii ṣe Islām le baa lekun síi; nitori naa yíò máa sin Ọlọhun ti ọla Rẹ ga lori amọdaju ati ìmọ̀, ti ọkan rẹ o si tun balẹ, ti ìgbàgbọ́ rẹ o si tun lekun pẹlu isunmọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu ìjọsìn, ati titẹle ilana Anabi Rẹ Muhammad (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a).

Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni mo n béèrè lọ́wọ́ Rẹ ki O fi alubarika sí gbogbo gbólóhùn inu iwe yii, kí O sí jẹ kí o ṣe Islām ati awọn Musulumi ni anfaani, ki O si tun ṣe e ni nkan ti a fi n wa ojú rere Ọlọhun, kí O sí tun ṣe ẹsan rẹ fún gbogbo Musulumi alààyè inú wọn ati òkú.

Ikẹ ati ọla Ọlọhun kí o maa ba Anabi wa Muhammad ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ lapapọ.

Muhammad ọmọ Ash-shaybah Ash-shihriy

2/11/1441 A.H

Allāhu ni Oluwa mi

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: «Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná) » Suratul Baqara: 21

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Sūratul Hashri: 22

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran. Suuratu Shuuroh: 11.

Allāhu Oun ni Oluwa wa ati Oluwa gbogbo nkan, Olukapa, Adẹdaa, Olupese jíjẹ mímú, Olùdarí gbogbo nnkan.

Ati pe Oun nikan ni O lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn, ko si oluwa kankan yatọ sí I, ko sì sí olùjọsìn fún miran yatọ sí I.

TiRẹ ni awọn orukọ ti o dara julọ ati awọn iroyin ti o ga jùlọ tí O fi rinlẹ fún ara Rẹ ti Anabi Rẹ náà sì fi rinlẹ fún Un- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a-, eyi ti o de ogongo nibi pipe ati didara, ko sí nnkan kan ti o jọ Ọ, Oun ni Olugbọ Oluriran.

Ninu awọn orukọ Rẹ ti o dara julọ ni:

Olupese jíjẹ mímu, Ọba Ajọkẹ ayé, Ọba Alágbára, Ọba Olukapa, Ọba Olugbọ, Ọba Alaafia, Ọba Oluri, Ọba Alamojuto, Ọba Adẹdaa, Ọba Alaanu, Ọba Olutofunni, Ọba Alaforijin.

Ar-Razzāq: Oun ni Ẹni tí O se agbatẹru jíjẹ mímu awọn ẹda eyi ti o ṣe wipe pẹlu rẹ ni diduro tọ àwọn ọkàn àti ara wọn wa.

Ar-Rahmān: Ẹni tí O ni ikẹ ti o gbaaye ti o si tobi ti o Kari gbogbo nnkan.

Al-Qodīr: Ẹni tí O ni agbara ti o pe ti ikagara tabi ikọlẹ o lee de ba a.

Al-Malik: Oun ni Ẹni tí wọn n royin pẹlu awọn iroyin titobi ati bibori àti ṣiṣeto, Olukapa gbogbo nkan Oludari àlámọ̀rí rẹ.

As-Samī‘: Ẹni tí O ni òye gbogbo ohun afetigbọ èyí tí o pamọ ninu rẹ ati èyí tí o han.

As-Salām: Ẹni tí O mọ kuro nibi gbogbo adinku ati abuku ati aleebu.

Al-Basēr: Ẹnití irina Rẹ kari gbogbo nkan kódà kí o wẹ́ ki o tun kere, Ẹnití O ni amọdaju nípa gbogbo nkan Olufunni ni iro nipa rẹ, Olumọ nipa awọn kọkọ rẹ.

Al-Wakīl: Alakoso awọn jíjẹ-mímu ẹda Rẹ, Alamojuto wọn pẹ̀lú awọn anfaani wọn, Ẹnití O ṣe Alatilẹyin fun awọn ààyò Rẹ; nitori naa O ṣe e ni irọrun fún wọn, O si tun to wọn nibi àlámọ̀rí wọn.

Al-Khāliq: Olumu awọn nkan bẹ ati Olusẹda wọn láìsí afijọ kan ti o ṣaaju.

Al-Latēf: Ẹnití O maa n pọn awọn ẹru Rẹ le, ti O si tun máa n kẹ wọn, ti O si tun máa n fún wọn ní ìbéèrè wọn.

Al-Kāfii: Ẹnití máa n to awọn ẹru Rẹ nibi gbogbo nkan ti wọn ba bukaata sí, Ẹnití wọn máa n gba tito pẹlu ikunlọwọ Rẹ kuro l'ọdọ ẹnití o yatọ sí I, ti wọn sì tún máa n rọrọ pẹlu Rẹ kuro l'ọdọ ẹnití o yatọ sí I.

Al-Gafūr: Ẹnití máa n sọ awọn ẹru Rẹ kuro nibi aburu àwọn ẹṣẹ wọn, ti ko sì tún nii fi iya jẹ wọn lori rẹ.

Mùsùlùmí yíò máa ronú nípa èèmọ dídá ẹda Ọlọhun m ṣíṣe e ni irọrun rẹ, ninu ìyẹn náà ni akolekan awọn ẹda pẹlu kekere wọn nibi ṣiṣe ojúkòkòrò lori fifun wọn ni oúnjẹ àti nini akolekan pẹlu wọn titi ti wọn yíò fi daduro fun'ra wọn; nitori naa mimọ ni fún Ọba ti O da a ti O si tun ni aanu rẹ, ati pe ninu aanu Rẹ ni wipe O ṣe ni irọrun fún un nkan ti yíò máa ran an lọwọ ti yíò sì máa tún ìṣesí rẹ ṣe tòun ti bi ko ṣe ni agbara kankan.

Anabi mi ni Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a-

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó ìnira ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore ọ̀run) fun yín; aláàánú àti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo. Sūratut Taobah: 128.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá. Suuratul Anbiyaah: 107.

Muhammad- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- oun ni ikẹ ti a fi tọrẹ fún àwọn ẹ̀dá.

Oun ni Muhammad ọmọ Abdullah- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- igbẹyin awọn Anabi ati awọn Òjíṣẹ́, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ran an n'iṣẹ pẹlu ẹsin Islām sí gbogbo èèyàn pátápátá, kí o le baa juwe wọn lọ sí ibi dáadáa tí èyí tí o tobi julọ ninu rẹ jẹ mímú Ọlọhun ni ọkan, kí o si tun máa kọ fún wọn kuro nibi aburu ti èyí tí o tobi julọ ninu rẹ jẹ mímú orogun pẹlu Ọlọhun.

Titẹle e jẹ dandan nibi nkan ti o ba pàṣẹ rẹ, ati gbigba a l'ododo nibi nkan ti o ba funni ni iro nipa rẹ, ati jijina sí nkan ti o ba kọ funni kuro níbẹ̀ ti o si tun leni jina sí i, kí wọn sì tún má jọsin fún Ọlọhun ayaafi pẹlu nkan ti o ba ṣe l'ofin.

Iṣẹ rẹ ati iṣẹ awọn Anabi to ṣáájú rẹ ni ipepe lọ si ibi ìjọsìn fún Ọlọhun ni Oun nìkan ṣoṣo ti ko si orogun fún Un.

Ninu awọn iroyin rẹ- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ni:

Otitọ, Ikẹ, Atẹmọra, Sùúrù, Akin, Ọrẹ títa, Iwa dáadáa, Déédéé, Itẹriba, Amojukuro.

Al-Qur'ān Alapọn-ọnle ọrọ Oluwa mi ni.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ t’ó yanjú kalẹ̀ fun yín. An-Nisaa: 174

Al-Qur'ān Alapọn-ọnle ni ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti O sọkalẹ fún Anabi Rẹ Muhammad- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- lati fi mu awọn eeyan jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn lọ sí inu imọlẹ, ati lati ṣe amọna wọn lọ sí ojú ọna ti o tọ.

Ẹnití o ba ka a yíò ri ẹsan ti o tobi, ẹnití o ba sí ṣiṣẹ tọ imọna rẹ o ti rin ojú ọna ti o tọ.

Maa mọ nipa awọn orígun Islām.

Ọ sọ- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- pe: Wọn mọ Islām pa lori nkan márùn-ún: Jijẹrii wipe ko si ẹni tí ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allōhu, ati pe Muhammad òjíṣẹ́ Rẹ ni, ati gbigbe Irun dúró, ati yiyọ Zakah, ati gbigba aawẹ Ramadan, ati ṣiṣe Hajj.

Awọn orígun Islām ìjọsìn kan ni wọn ti o jẹ dandan lori gbogbo Musulumi, Islām ọmọnìyàn o si le ni alaafia ayaafi pẹlu nini adisọkan jíjẹ́ dandan rẹ ati mímú gbogbo rẹ wá sí ìmúṣẹ; nitori pe wọn ti mọ Islām pa le e lori, nitori naa ni wọn fi sọ ọ ni orígun Islām.

Ati pe awọn orígun náà niyi:

Orígun akọkọ: Jijẹrii wipe ko si ẹni tí ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allōhu, ati pe dajudaju Muhammad òjíṣẹ́ Rẹ ni.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu. Sūratu Muhammad: 19.

Oba ti ọla Rẹ ga tun sọ pe: Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó ìnira ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore ọ̀run) fun yín; aláàánú àti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo. Sūratut Taobah: 128.

Ìtumọ Shahādatu an lā ilāha illallāh ni pe: Ko si olùjọsìn fún kankan ni ododo àyàfi Allāhu.

Ìtumọ Shahādatu anna Muhammadan rọsūlullāh ni: Titẹle e nibi nkan ti o ba pàṣẹ rẹ, ati gbigba a l'ododo nibi nkan ti o ba funni ni iro nipa rẹ, ati jijina sí nkan ti o ba kọ funni kuro níbẹ̀ ti o si tun leni jina sí i, kí wọn sì tún má jọsin fún Ọlọhun ayaafi pẹlu nkan ti o ba ṣe l'ofin.

Orígun Kejì: Gbígbé Irun dúró.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ kírun. Sūratul Baqorah: 110.

Gbigbe Irun dúró yíò máa jẹ pẹlu pípé e lori ojupọna tí Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe l'ofin ti Òjíṣẹ́ Rẹ Muhammad- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- si fi mọ wa.

Orígun Kẹta: Yiyọ saka

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ yọ Zakāh. Sūratul Baqorah: 110.

Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe Zakah ni ọranyan lati fi ṣe idanwo fun ijẹ ododo ìgbàgbọ́ Musulumi, ati lati fi dupe fún Oluwa rẹ lori nkan ti O ṣe fún un ninu idẹra dukia, ati lati jẹ iranlọwọ fún àwọn aláìní ati awọn ti wọn bukaata sí i.

Ati yiyọ Zakah yíò máa bẹ pẹlu fifi i fún àwọn tí wọn ní ẹtọ sí i.

Oun naa ni ẹtọ kan ti o jẹ dandan ninu dukia tí o ba ti to odiwọn kan pàtó, ti wọn yíò máa fi i fún àwọn ìran mẹjọ ti Ọlọhun darukọ wọn nínú Al-Qur'ān Alapọn-ọnle, ninu wọn ni olosi ati aláìní.

O n bẹ nibi yiyọ Zakah ìní iroyin ikẹ ati aanu lára, ati ṣíṣe afọmọ fún àwọn iwa Musulumi ati àwọn dukia rẹ, ati didun awọn olosi ati aláìní nínú, ati fífún asopọ ìfẹ́ àti jíjẹ́ ọmọ-iya laarin ẹnikọọkan ni àwùjọ Musulumi ni agbara. Fún ìdí ìyẹn, Musulumi dáadáa yíò máa yọ ọ (Zakah) ni ti inu didun pẹlu yiyọ rẹ, latari ohun tí n bẹ níbẹ̀ bii kiko idunnu ba ẹnití o yatọ sí i ninu awọn ọmọnìyàn.

Odiwọn Zakah owo jẹ 2.5% ninu owo ti a fi pamọ bii Góòlù ati Silifa ati awọn owo oni pepa ati ọjà ti o jẹ ti òwò ti a pèsè fún katakara lati le jèrè; ti iye rẹ ba ti to odiwọn kan pàtó ti ọdún kan si ti rekọja lori rẹ.

Gẹgẹbi Zakah ṣe jẹ dandan fún ẹnití o ba ni onka kan pàtó ninu awọn ẹran-ọ̀sìn (awọn ni Ràkúnmí ati Maalu ati Aguntan pẹlu Ewúrẹ), ti o ba n jẹ ninu awọn koríko ilẹ fún eyiti o pọ jù nínú ọdún tí kii ṣe wipe olówó rẹ lo n wa ounjẹ fún un.

Bákan náà Zakah jẹ dandan nibi nkan ti o n jade nínú ilẹ bii awọn kóró ati awọn eso ati awọn alumoni ati awọn ìṣúra ti o ba ti to odiwọn kan pàtó."

Orígun kẹrin: Aawẹ oṣù Ramadan.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu). Sūratul Baqorah: 110.

Ramadan ni: Oṣù kẹsàn-án ninu ọdún nínú kàlẹ́ndà hijirah, òun sì ni oṣù ti wọn máa n gbe tobi l'ọdọ awọn Musulumi, ipo ẹsa sí n bẹ fún un tayọ awọn oṣù ọdún tí o ṣẹku, ati pé gbigba aawẹ rẹ ni pipe jẹ ọkan ninu awọn orígun Islām márùn-ún.

Aawẹ Ramadan ni: Jijọsin fún Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu kiko ara ro kuro nibi jíjẹ ati mímu àti ibalopọ lọkọ-laya ati gbogbo nkan ti o le ba aawẹ jẹ, láti igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun o fi wọ ni gbogbo ọjọ oṣù Ramadan alalubarika.

Orígun Karùn-ún: Ṣíṣe haji ile Ọlọhun abeewọ.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, t’ó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Aal-Imraan 97

Hajj yíò máa bẹ fún ẹni ti o ba ni ikapa ọ̀nà tí o le gba dé ibẹ, ni ẹẹkan pere ninu ọjọ-ori, oun na ni: Gbigbero ile abeewọ ati awọn ààyè àmì ti o jẹ mímọ́ ni ilu Makkah Alapọn-ọnle lati pe awọn ìjọsìn kan pàtó ni igba kan pàtó, ati pe Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ti ṣe Hajj ti awọn ti wọn yatọ sí i ninu awọn Anabi to ṣáájú rẹ náà sì ṣe Hajj, Ọlọhun sí tún pa Anabi Ibrōhēm- ki ọla máa bá a- laṣẹ ki o pe awọn eeyan fún iṣẹ Hajj, gẹgẹbi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe fún wa ni iro ninu Al-Qur'ān Alapọn-ọnle, O wa sọ pé: Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀. Wọn yó sì máa gun àwọn ràkúnmí wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn Al-Hajj 27

Maa mọ awọn orígun igbagbọ:

Wọn bí Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- leere nipa igbagbọ, o wa sọ pe: Kí o ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn Tira Rẹ, ati awọn Òjíṣẹ́ Rẹ, ati Ọjọ Ìkẹhìn, ati Kadara dáadáa rẹ ni tabi aburu rẹ.

Awọn orígun igbagbọ ni awọn ìjọsìn ti wọn jẹ ti ọkan ti o jẹ dandan fún gbogbo Musulumi, Islām ọmọnìyàn o si le ni alaafia ayaafi pẹlu nini adisọkan pẹlu rẹ; tori ìyẹn ni wọn fi sọ ọ ni awọn orígun igbagbọ Ati pe iyatọ to wa láàrin rẹ ati origun Islām ni pé: Awọn orígun Islām jẹ awọn iṣẹ ti o hàn ti ọmọnìyàn o maa ṣe e pẹlu oríkèé ara rẹ, gẹgẹ bii sísọ gbólóhùn ijẹrii mejeeji, ati Irun ati Zakah, ti awọn orígun igbagbọ sì jẹ́ awọn iṣẹ ti ọkan ti ọmọnìyàn a máa ṣe e pẹlu ọkàn rẹ gẹgẹ bii: Nini ìgbàgbọ́ pẹlu Ọlọhun ati awọn tira Rẹ ati awọn òjíṣẹ́ Rẹ.

Agbọye ìgbàgbọ́ àti ìtumọ̀ rẹ: Oun ni igbalododo ọkan ti o daju pẹlu Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn Tira Rẹ, ati awọn Òjíṣẹ́ Rẹ, ati Ọjọ Ìkẹhìn, àti Kadara dáadáa rẹ ati aburú rẹ, ati titẹle gbogbo nkan ti òjíṣẹ́- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mu wa, àti ṣíṣe amulo rẹ ni sísọ pẹlu ahọn, gẹgẹ bii gbólóhùn "lā ilāha illallāh", ati kika Al-Qur'ān, ati ṣiṣe àfọ̀mọ́ ati gbólóhùn lā ilāha illallāh, ati yíyin Ọlọhun.

Ati ṣíṣe iṣẹ pẹlu oríkèé ara ti o han: Gẹ́gẹ́ bíi Irun, ati Hajj, ati Aawẹ.... ati awọn oríkèé ara ti o pamọ tí o so papọ mọ ọkàn gẹ́gẹ́ bíi ini ìfẹ́ Ọlọhun ati pipaya Rẹ, ati gbigbe ara le E àti ṣíṣe imọkanga fún Un.

Awọn onímọ̀ nipa TAOHEED máa n salaye rẹ ni ṣókí wipe oun ni: Dídì si ọkàn, ati sísọ pẹlu ahọn, ati ṣíṣe pẹlu awọn oríkèé ara, ti yíò máa lekun pẹlu titẹle, yíò sì máa dinku pẹlu ẹṣẹ.

Orígun Akọkọ: Nini ìgbàgbọ́ pẹlu Ọlọhun.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àwọn onígbàgbọ́ ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Sūratun Nūr: 62

Nini ìgbàgbọ́ nínú Ọlọhun n tọ́ka sí mimu un lọkan nibi jíjẹ́ Oluwa Rẹ, ati ninu lilẹtọọ sí ìjọsìn Rẹ, ati nibi awọn orukọ ati awọn iroyin Rẹ, o si tun ko awọn nkan ti o n bọ yìí sinu:

Nini ìgbàgbọ́ nínú bíbẹ Rẹ, mimọ Rẹ Ọba ti ọla Rẹ ga.

Nini ìgbàgbọ́ nínú jíjẹ́ Olúwa Rẹ- mimọ Rẹ- ati pe Oun ni Olukapa gbogbo nkan ati Aṣẹ̀dá rẹ ati Olupese jíjẹ mímu rẹ ati Oludari àlámọ̀rí rẹ.

Nini ìgbàgbọ́ nínú níní ẹtọ sí ìjọsìn Rẹ, ati pe Oun ni Ẹni tí O lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn ni Oun nikan ṣoṣo, kò si orogun fún Un nibi nkankan ninu rẹ: Gẹ́gẹ́ bíi Irun, ati adua, ati jíjẹ́jẹ̀ẹ́, ati didu nkan, ati wiwa iranlọwọ, ati wiwa iṣọra, ati gbogbo awọn ìjọsìn miran.

Nini ìgbàgbọ́ nínú àwọn orúkọ Rẹ ti o rẹwa julọ àti àwọn iroyin Rẹ tí o ga jùlọ tí O fi rinlẹ fúnra Rẹ, tabi èyí tí Anabi Rẹ- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - fi rinlẹ fún Un, ati ihanna nkan tí O ba hanna kuro fúnra Rẹ, tabi èyí tí Anabi- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ba hanna kuro fún Un ninu awọn orukọ ati awọn iroyin, ati pe dajudaju awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ dé ogongo nibi pipe àti didara, ati pe ko si nkankan ti o jọ ọ, Oun sì ni Olùgbọ́ Oluri.

Orígun keji: Nini ìgbàgbọ́ nínú àwọn Mọlaika

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Sūratu Fātir: 1.

A maa ni igbagbọ wípé dájúdájú àwọn Malaika agbaye kan ni wọ́n ti o pamọ́, ati pe ẹrú Ọlọhun ni wọn ti O da wọn latara imọlẹ, Ó sì tún ṣe wọn ní olutẹle E àti olurẹ ara wọn nilẹ fún Un.

Ati pe ẹ̀dá ńlá ni wọn, kò sì sí ẹni tí ó mọ agbára wọn àti onka wọn leyin Ọlọhun, àti pe ó ń bẹ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn àwọn ìròyìn àti orúkọ àti iṣẹ tí Ọlọhun ti ọlá Rẹ ga ṣẹsa wọn pẹlu rẹ.

Origun kẹta: Níní ìgbàgbọ́ nínú àwọn tira.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un.” Suratul Baqorah: 136.

Igba lododo tó dájú wípé dájúdájú gbogbo àwọn tira tí ó wà láti sanmọ ọ̀rọ̀ Ọlọhun ni wọn.

Ati pe dájúdájú wọn sọ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọhun ti O biyi tí Ó tún gbọnngbọn fún àwọn ojisẹ Rẹ si awọn ẹru Rẹ pẹlu òdodo tí ó fi ojú hàn.

Ati pe Ọlọhun- ti mímọ ń bẹ fún Un- pẹ̀lú rírán tí Ó rán Anabi Rẹ Muhammad - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si gbogbo èèyàn pátápátá, Ó ti fi òfin rẹ pa gbogbo òfin tí ó ṣáájú rẹ rẹ, O wa ṣe Al-Qur’an Alapọn-ọnle ní nkan ti o n ṣẹri lórí gbogbo àwọn tira sanmọ yòókù tí ó sì tún pá wọn rẹ, ati pe Ọlọhun ti jẹ́ ẹjẹ láti sọ́ Al-Qur’an Alapọn-ọnle kúrò níbi eyikeyi yíyípadà tàbí yiyipo; nítorí náà Ọba ti ọlá Rẹ ga sọ pé: Dájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀. Suratul Hijir: 9. Nítorí pé dájúdájú Al-Qur’an ni igbẹyin àwọn tira Ọlọhun si awọn èèyàn, ati pe Anabi Rẹ Muhammad - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni igbẹyin àwọn ojiṣẹ, ati pe ẹsin Isilaamu ni ẹsin ti Ọlọhun yọnu si fún àwọn èèyàn titi di ọjọ́ ìgbédìde, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pé: Dájúdájú ẹ̀sìn t’ó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Aal-Imraan 19

Ati pe àwọn tira sanmọ tí Ọlọhun ti ọlá Rẹ ga sọ nínú tira Rẹ ni:

Al-Qur’an Alapọn-ọnle: Ọlọhun sọ ọ́ kalẹ̀ fún Anabi Rẹ Muhammad - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-.

At-Taorāh: Ọlọhun sọ ọ́ kalẹ̀ fún Anabi Rẹ Musa- kí ọla Ọlọhun maa ba a-.

Al-Injiil: Ọlọhun sọ ọ́ kalẹ̀ fún Anabi Rẹ Ēsa- kí ọla Ọlọhun maa ba a-.

Az-Zabuur: Ọlọhun sọ ọ́ kalẹ̀ fún Anabi Rẹ Dāud- kí ọla Ọlọhun maa ba a.

Suhuf Ibrahim: Ọlọhun sọ ọ́ kalẹ̀ fún Anabi Rẹ Ibrahim- kí ọla Ọlọhun maa ba a.

Origun kẹrin: Níní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ojiṣẹ.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Suratul Nahl: 36

Igbalododo ti o daju wipe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga gbedide ninu gbogbo ijọ Kookan òjíṣẹ́ kan ti o n pe wọn lọ síbi jijọsin fún Olohun nikan ṣoṣo tí kò sí orogun fún Un, ati ṣíṣe aigbagbọ sí nkan ti wọn ba n jọsin fún yàtọ̀ sí I.

Ati pe dajudaju gbogbo wọn patapata abara ọkunrin ni wọn ti wọn sì jẹ ẹrú fún Ọlọhun, ati pe olododo ti a máa n gba ọrọ wọn l'ododo ni wọn, olupaya Ọlọhun olufọkantan ni wọn, atọnisọna tí wọn mọ̀nà ni wọn, Ọlọhun sí tún kun wọn lọwọ pẹlu awọn iṣẹ ìyanu tí n tọka sí òdodo wọn, ati pe dajudaju wọn mu gbogbo nkan ti Ọlọhun fi ran wọn dé etigbọọ àwọn èèyàn, ati pe dajudaju gbogbo wọn patapata wa lori ododo ti o han, ati imọna ti o yanjú.

Ipepe wọn papọ̀ lati ori alakọkọọ wọn titi dori igbẹyin wọn nibi ipilẹ ẹsin, oun náà ni mímú Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo Ọba ti O biyi ti O gbọnngbọn nibi ìjọsìn ati ki èèyàn ma mu orogun mọ Ọn.

Orígun karùn-ún: Nini ìgbàgbọ́ nínú ọjọ ìkẹhìn.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu lọ? Sūratun Nisā’: 87.

Gbigba gbogbo nkan ti o rọ̀ mọ́ ọjọ́ ìkẹyìn lododo ti o dájú nínú nkan ti Ọlọhun ti O biyi tí Ó gbọnngbọn fún wa ni iro nípa rẹ nínú Al-Qur’an Alapọn-ọnle, tàbí tí Anabi wa sọ fún wa - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, gẹ́gẹ́ bíi ikú ọmọniyan, àti ìgbédìde, àti iṣipẹ, àti òṣùwọ̀n, àti ìṣirò, àti alijanna àti iná, àti nkan ti o yatọ si ìyẹn nínú nkan ti o sopọ mọ ọjọ́ ìkẹyìn.

Origun Kẹfà: Níní ìgbàgbọ́ nínú kadara dáadáa rẹ àti aburu rẹ.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá. Suratul Qomar: 49.

Nini adisọkan wípé dájúdájú gbogbo nkan ti o ba ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹ̀dá nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ni ile ayé yìí, o n ṣẹlẹ̀ pẹlu imọ Ọlọhun ati agbara Rẹ, àti ìdarí Rẹ ni ní Oun nìkan tí kò sí orogun fún Un, ati pe dájúdájú àwọn kadara yìí nkan ti wọn ti kọ silẹ síwájú dídá ọmọniyan ni, ati pe dájúdájú erongba àti fífẹ́ ń bẹ fún ọmọniyan, ati pe dájúdájú òun ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀ l'ododo; ṣùgbọ́n gbogbo iyẹn pátápátá kò kúrò lábẹ́ imọ Ọlọhun ati erongba Rẹ ati fífẹ́ Rẹ̀.

Níní ìgbàgbọ́ nínú kadara yìí dúró lórí ipele mẹrin, òun náà ni:

Alakọkọọ: Níní igbagbọ pẹ̀lú imọ Ọlọhun ti o kún tí ó sì kari.

Ẹlẹẹkeji: Níní ìgbàgbọ́ pẹ̀lú kíkọ àkọsílẹ̀ Ọlọhun fún gbogbo nkan ti ń bẹ títí di ọjọ́ ìgbédìde.

Ìkẹta: Níní ìgbàgbọ́ pẹ̀lú fífẹ́ Ọlọhun ti máa ń ṣẹ àti agbára Rẹ ti o pe, nítorí náà nkan ti O ba fẹ́ ni yio ṣẹ, nkan ti ko ba si fẹ́ ko nii ṣẹ.

Ikerin: Níní ìgbàgbọ́ pe Olohun ni O da gbogbo nnkan, ko ni orogun nibi eda Re.

Maa kọ aluwala.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùronú-pìwàdà. Ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùmọ́ra. (Al-Bakorah 22)

O sọ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - pe: O sọ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - pe: “Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yìí, lẹyin naa ti o wa ki rakah meji ti ko ba ara rẹ sọ̀rọ̀ nibi mejeeji, Ọlọhun maa ṣe aforiji nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ fun un"

Ninu títóbi ipò irun ni wípé Ọlọhun ṣe imọra ni òfin síwájú rẹ, O si tun ṣe é ní majẹmu fún ìní àlàáfíà rẹ, òun sì ni kọkọrọ irun, ati pe mímọ ọlá tí ń bẹ fún un lára máa ń jẹ ki ọkàn ó fà mọ pípé irun. Ọ sọ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - pe: (Imọra ìdajì ìgbàgbọ́ ni.. ati pe irun imọlẹ ni).

Ó sọ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- pe: (Ẹniti o ba ṣe aluwala tí ó sì ṣe é dáadáa, àwọn àṣìṣe rẹ ó jáde kúrò nínú ara rẹ).

Nítorí náà ẹrú máa lọ bá Olúwa rẹ ni ẹniti o mọ́ra ni imọra tí a fi ojú rí pẹlu aluwala, àti èyí tí a o fi ojú rí pẹlu pípé ìjọsìn yìí, ní ẹniti o mọ ọn kanga fún Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ní eniti ń tẹle ìlànà Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -.

Nnkan ti aluwala jẹ dandan fun:

1- Gbogbo Ìrun pátápátá, bóyá ó jẹ ọranyan ni tàbí aṣegbọrẹ.

2- Rirọkirika kaaba.

3- Gbigba Al-Qur’an mú.

Maa ṣe aluwala máa sì tún wẹ pẹlu omi tí ó mọ́.

Omi tí ó mọ́, òun ni: Gbogbo omi tí ó sọ̀kalẹ̀ láti sanmọ tàbí ó yọ láti inú ilẹ̀ tí ó sì wá lórí ipilẹ ìṣẹ̀dá rẹ, tí ọkan ninu awọn ìròyìn rẹ mẹtẹẹta ó sì yípadà, òun náà ni: Awọ àti itọwo àti òórùn, pẹ̀lú nkankan nínú àwọn nkan ti o le gba mímọ́ omi kúrò.

Maa kọ aluwala.

Igbesẹ kinni: Àníyàn tí ààyè rẹ sì jẹ ọkan, ati pe ìtumọ̀ àníyàn ni: ìpinnu ọkàn lórí ṣíṣe ìjọsìn lati sunmọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.

Igbesẹ keji: Fifọ ọwọ méjèèjì.

Igbesẹ kẹta: Yíyọ ẹnu.

AL-MAD'MADỌ ni: Fífi omi si ẹnu àti gbígbo ó ṣùkùṣùkù, lẹyin naa títú ú jáde.

Igbesẹ kẹrin: Fífín omi sí imú.

Al-Istinshaaq ni: Fifa omi pẹlu èémí sí ipẹ̀kun imú.

Lẹyin naa ni Al-Istinthaar: Oun náà ni mímú nkan ti o wa ninu imú bíi ikunmu àti nkan ti o yatọ si i jáde pẹ̀lú èémí.

Ìgbésẹ̀ karùn-ún: Fifọ oju

Ààlà oju:

Oju ni: Nkan ti idaju-kọni ṣe máa n ṣẹlẹ.

Ààlà rẹ ní ìbú: Lati eti sí eti.

Ààlà rẹ ni òòró: Nkan ti n bẹ láàrin ibùyọ irun orí ti a ti ba sáábà titi dé ìparí agbọ̀n.

Fífọ ojú ko gbogbo nkan ti n bẹ nibẹ bii irun ti o fẹlẹ sinu, bakannaa o ko Al-Bayād ati Al-‘idhāru sinu.

Al-Bayād ni: Nkan ti n bẹ láàrin Al-‘idhāru ati ibi isalẹ eti (jọbọjọbọ eti).

Al-‘idhāru ni: Irun ti o wa lori eegun ti o ta sita ti o ṣe déédéé ihò eti eleyi ti o lọ sí inú ori ati eyiti o san walẹ ninu rẹ lọ sí ibi èèkàn etí.

Bákan náà fifọ ojú kó gbogbo nkan ti o han nibi irugbọn ti o pọ pẹlú eyiti o san walẹ ninu rẹ sinu.

Ìgbésẹ̀ kẹfà: Fifọ ọwọ mejeeji lati ori awọn ọmọ-ìka ọwọ mejeeji titi dé igunpa mejeeji.

Igunpa mejeeji wọ inú fifọ ọwọ mejeeji ti o jẹ ọran-anyan

Ìgbésẹ̀ keje: Pipa gbogbo ori mọ eti méjèèjì pẹlu atẹlẹwọ mejeeji ni ẹẹkan ṣoṣo.

Yíò bẹrẹ lati iwájú ori l'ẹniti yíò máa mú mejeeji lọ sí ipakọ rẹ, lẹyin naa yíò da mejeeji pada.

Yóò sì tún ti ika ifabẹla rẹ mejeeji bọ inu eti rẹ mejeeji.

Yíò wá fi àtànpàkò rẹ mejeeji sí ẹyin eti rẹ mejeeji, ti yíò sì fi iyen pa ẹyin eti rẹ ati inú eti re.

Ìgbésẹ̀ kẹjọ: Fifọ ẹsẹ mejeeji lati ibi awọn ọmọ ika ẹsẹ titi dé kokosẹ mejeeji, ti kokosẹ méjèèjì náà sì wọ inú fifọ ẹsẹ ti o jẹ ọran-anyan.

Al-ka‘bān: Ni eegun meji ti wọn ta sita ni isalẹ ojúgun.

Aluwala o máa bajẹ pẹlu awọn àlámọ̀rí ti o n bọ yii:

1. Nnkan ti o n jade láti ojú ọna mejeeji bíi itọ, ati igbẹ, ati iso, àti atọ ti máa n di ọmọ, ati àtọ̀ ìrèké.

2. Yíyẹ̀ làákàyè pẹlu oorun ti ó pẹ́, tabi didaku, tabi ihunrira, tabi yiya weere.

3. Gbogbo nkan ti o maa n sọ iwẹ di dandan gẹ́gẹ́ bíi janaba, ati ẹjẹ nkan oṣù, ati ẹjẹ ìbímọ.

Ti ọmọnìyàn ba ti biya bukaata rẹ tán, o jẹ dandan fún un kí o mu ẹgbin kúrò pẹlu omi ti o mọ, ìyẹn ni o lọla julọ, tabi pẹlu nkan ti o yatọ sí omi ti o mọ ninu nkan ti ẹ̀gbin le kuro pẹlu rẹ, gẹ́gẹ́ bíi okuta, ati ewé, ati aṣọ, ati nnkan ti o jọ ìyẹn, pẹlu májẹ̀mú fífi nù ú ni ẹẹmẹta ti yíò mọ ọn tàbí jù bẹẹ lọ, ati pẹlu nnkan ti o ba mọ ti o si lẹtọọ.

Pípa ìbọ̀sẹ̀ aláwọ mejeeji ati ìbọ̀sẹ̀ olówùú.

Ti èèyàn bá wọ ìbọ̀sẹ̀ aláwọ mejeeji ati ìbọ̀sẹ̀ olówùú, ó le pa mejeeji laibukaata sí fifọ ẹsẹ mejeeji pẹlu awọn majẹmu yii:

1. Kí wíwọ mejeeji o jẹ lẹyin imọra ti o pe kúrò nibi ẹgbin kekere ati ẹgbin nla, ti wọn sì fọ ẹsẹ mejeeji ninu rẹ (imọra).

2. Kí mejeeji o jẹ nnkan ti o mọ ti ko ni ẹgbin.

3. Kí pípa maa wáyé ni àsìkò ti wọn ti la kalẹ fún un.

4. Kí mejeeji o jẹ nkan ẹtọ, mejeeji o si gbọdọ jẹ nkan ti wọn ji tabi nkan ti wọn gbà ní tipá àti àbòsí.

Al-khuffān ni: Nǹkan ti wọn n wọ̀ sí ẹsẹ ti wọn ṣe latara awọ ti o fẹlẹ ati nkan ti o jọ ọ, iru rẹ náà ni awọn bàtà tí o maa n bo ẹsẹ.

Al-Jaorọbān ni: Nnkan ti ọmọnìyàn maa n wọ̀ sí ẹsẹ rẹ mejeeji tí wọ́n ṣe latara aṣọ ati nkan ti o jọ ọ, oun náà ni nkan ti wọn mọ sí (Ash-Sharrōb).

Ọgbọn tí n bẹ nibi ṣiṣe pipa ibọsẹ alawọ ni òfin:

Ọgbọn tí n bẹ nibi pipa ibọsẹ alawọ ni ṣiṣe irọrun ati ṣíṣe nǹkan ni fifuyẹ fún àwọn Musulumi, awọn ti bibọ ibọsẹ alawọ tàbí ibọsẹ olowuu ati fífọ ẹsẹ mejeeji máa n ni lara, àgàgà jùlọ ní àwọn àsìkò ọyẹ́ ati òtútù ti o le, ati ni irin-ajo.

Àsìkò pípa.

Ẹnití o wa ni ile: Ọjọ kan ati oru rẹ (24 wakati).

Oni irin-ajo: Ọjọ mẹta ati oru rẹ (72 wakati).

Iṣiro àsìkò pipa yíò máa bẹrẹ lati ìbẹ̀rẹ̀ pipa ibọsẹ alawọ tàbí ibọsẹ olowuu lẹyin ẹgbin.

Ìròyìn pipa ibọsẹ alawọ tabi ibọsẹ olowuu:

1- A maa bu omi rin ọwọ mejeeji.

A maa mu ọwọ kọja lori òkè ẹsẹ (lati awọn ori ọmọ-ika ẹsẹ titi dé ibẹrẹ ojúgun).

Wọn o pa ẹsẹ ọtun pẹlu ọwọ ọtun ati ẹsẹ òsì pẹlu ọwọ òsi.

Awọn nnkan ti o maa n ba pípa jẹ:

1- Nǹkan ti o maa n sọ iwẹ di dandan.

2- Pipari àsìkò pípa.

Iwẹ

Ti ibalopọ lọ́kọ-láya ba wáyé lati ọdọ ọkùnrin tabi obinrin, tabi ti atọ ba jade lara awọn mejeeji pẹlu adùn ni àsìkò tí kò sùn tabi àsìkò oorun; iwẹ jẹ dandan fún awọn mejeeji ki àwọn méjèèjì le baa ni anfaani lati ki ìrun tabi ṣe nnkan ti imọra jẹ dandan fún, ati pe ti ọmọbinrin ba mọra kuro nibi ẹjẹ nnkan oṣù ati ẹjẹ ìbímọ, iwẹ jẹ dandan fún un ṣíwájú ki o to ni anfaani lati ki irun tabi ṣe nnkan ti imọra ba jẹ dandan fún.

Alaye iwẹ lọ bayi pe:

Kí Musulumi o fi omi kárí gbogbo ara rẹ ní ọ̀nà yòówù kí ó rí kí ó gbà ṣe é, ninu rẹ naa ni fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi sí imu. Ti o ba ti fi omi kárí gbogbo ara rẹ, ẹgbin nla ti kuro fún un, imọra rẹ si ti pé.

O jẹ eewọ fún ẹnití o ni janaba lara láti ṣe awọn nkan ti o n bọ yii titi ti yíò fi wẹ̀:

01- Irun kiki.

02- Rirọkirika Ka‘bah.

03- Wíwà ní inú Mọsalasi, ṣùgbọ́n o ni ẹtọ fún un kí ó kọjá níbẹ̀ nikan láìní dúró.

04- Gbigba Al-Qur'ān mu.

05- Kika Al-Qur'ān.

Aluwala elérùpẹ̀

Ti Musulumi o ba ri omi ti yíò fi ṣe imọra tabi ti ko ba ni ikapa lilo omi latari àìsàn ati nkan ti o jọ ọ ti o si n paya ki asiko ìrun o ma bọ mọ oun lọwọ, nigba naa yíò ṣe aluwala pẹlu erupẹ.

Iroyin ìyẹn ni ki o fi atẹlẹwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan pere, lẹyin naa yóò wàá fi mejeeji pa oju rẹ ati ọrùn ọwọ rẹ mejeeji nikan. Wọn ṣe e ni majẹmu ki erupẹ yẹn ó mọ́.

Aluwala elerupẹ máa n bajẹ pẹlu awọn nkan ti o n bọ yìí:

1- Aluwala elerupẹ o maa bajẹ pẹlu nkan ti o maa n ba aluwala jẹ.

2- Ti wọn ba ri omi ṣíwájú bibẹrẹ ìjọsìn ti wọn ti ṣe aluwala elerupẹ fun.

Maa kọ ìrun.

Ọlọhun ṣe ìrun márùn-ún ni ọranyan lori Musulumi ni ojoojumọ, àwọn naa ni: Al-fajari ati Zuuri ati Asri ati Magrib ati ‘Ishā’.

Maa gbaradi fún ìrun.

Ti àsìkò ìrun ba ti wọlé, Musulumi o maa mọra kuro nibi ẹgbin kekere ati ẹgbin nla, ti o ba jẹ ẹnití o ni ẹgbin nla ni ara.

Ẹgbin nla ni: Nnkan ti o maa n sọ iwẹ di dandan fún Musulumi.

Ẹgbin kekere ni: Nnkan ti yíò máa sọ aluwala di dandan fún Musulumi.

Musulumi o máa kirun pẹlu awọn aṣọ tí o mọ ni ààyè ti o mọ kuro nibi ẹgbin ni ẹni tí yoo bo ihoho rẹ.

Musulumi o máa ṣe ọṣọ pẹlu awọn aṣọ tí ó yẹ ni àsìkò ìrun ti yíò si bo ara rẹ pẹlu rẹ, ko sì lẹtọọ fún ọkunrin kí o fi nnkan ti o wa laarin idodo ati orokun hàn nínú irun.

O jẹ dandan fún obìnrin ki o bo gbogbo ara rẹ ninu ìrun ayaafi oju ati ọrùn ọwọ rẹ mejeeji.

Musulumi o gbọdọ máa sọ̀rọ̀ lori irun pẹlu awọn ọrọ ti o yatọ si eyiti o jẹ ẹsa fún irun, yíò sì tún dakẹ fún imāmu rẹ, ko sì tún nii máa wo kaakiri lori irun rẹ, ati pe ti o ba kagara lati ha awọn ọrọ ti o jẹ ẹsa fún irun nigba naa ni yíò máa rántí Ọlọhun yíò sì máa ṣe afọmọ fún Un titi ti yíò fi pari irun, o si jẹ dandan fún un kí o yara lati lọ kọ irun ati awọn ọrọ rẹ.

Maa kọ irun.

Ìgbésẹ̀ kinni: Aniyan fún ọranyan ti mo gbero lati kí, ọkan si ni ààyè rẹ.

Lẹyin ti mo ti ṣe aluwala, máa da ojú kọ kíbúlà, maa si kirun lẹniti yíò duro ti mo ba jẹ ẹnití o ni ikapa láti dúró.

Ìgbésẹ̀ keji: Maa gbé ọwọ mi mejeeji soke ti yíò ṣe deede ejika mi mejeeji, máa wáá sọ pe: (Allāhu akbar) l'ẹniti n gbero wíwọ inú irun.

Ìgbésẹ̀ kẹta: Maa ka adua ìṣírun pẹlu nkan ti o wa lati ọdọ Anabi, ninu ìyẹn náà ni gbolohun: (Subhānaka llāhummọ wa bi hamdika wa tabārọka Ismuka wa ta‘āla jadduka wa lā ilāha gayruka). (Subhānaka llāhummọ wa bi hamdika wa tabārọka Ismuka wa ta‘āla jadduka wa lā ilāha gayruka).

Ìgbésẹ̀ kẹrin: Maa wá iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ satani ẹni ẹkọ, màá wá sọ pe: (’A‘ūdhu billāhi minash Shaytānir rajīm)

Ìgbésẹ̀ karùn-ún: Maa ka Sūratul fātiha ni gbogbo raka, oun náà sì ni: Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (3) Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san. Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí. Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (’Islām), ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún,yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasara).

Lẹyin Fātiha maa ka èyí tí o ba rọrun ninu Al-Qur'ān ni rákà akọkọ ati ìkejì nikan ninu gbogbo ìrun, ati pe eléyìí kii ṣe dandan, ṣugbọn ẹsan ti o tobi wa nibi ṣiṣe e.

Ìgbésẹ̀ kẹfà: Maa sọ pe: (Allāhu akbar) lẹyin naa maa rùkúù titi ti ẹyin mi o fi nà tọ̀ọ̀, ti ọwọ mi mejeeji o sì wa lórí orunkun mi méjèèjì, ti awọn ọmọ-ika o sì wà ní yíyà ti ko nii lẹ̀pọ̀, lẹyin naa maa wá sọ ni rukuu pe: (Subhāna robbiyal ‘adhīm).

Ìgbésẹ̀ keje: Maa gbé ori sókè ni rukuu ni ẹni tí yíò máa sọ pe: (Sami‘a llāhu liman hamidah) ni ẹni tí n gbe ọwọ mi mejeeji sí déédéé ejika mejeeji, ti ara mi ba ti wá nà tọ̀ọ̀ ní ẹni tí o duro maa sọ pe: (Robbanā wa lakal hamdu).

Ìgbésẹ̀ kẹjọ: Maa sọ pe: (Allāhu akbar) maa wá fi ọwọ mejeeji kan ilẹ̀, ati orunkun méjèèjì, ati ẹsẹ mejeeji, ati iwájú ori pẹlu imu, maa wá sọ ni iforikanlẹ mi pé: (Subhāna robbiyal ’a‘lā).

Ìgbésẹ̀ kẹsàn-án: Maa sọ pe: (Allāhu akbar), maa sì gbe ori kuro ni iforikanlẹ titi ti ẹyin mi o fi na dáadáa ni ẹni tí yíò jókòó lori ẹsẹ òsì ti yíò sì na ẹsẹ ọtun sókè, maa wá tun sọ pe: (Robbi igfir li).

Ìgbésẹ̀ kẹwàá: Maa sọ pé: (Allāhu akbar), maa sì tún fi ori kanlẹ ni ẹẹkan síi gẹ́gẹ́ bíi iforikanlẹ

Ìgbésẹ̀ kọkànlá: Maa gbé ori kuro ni iforikanlẹ ni ẹni tí yíò máa sọ pe: (Allāhu Akbar) titi ti máa fi duro tọ, màá sì tún ṣe nibi alakọkọọ. gbogbo rakaa irun to sẹku gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe nibi rakaa alakọkọọ.

Lẹyin rakaa keji nibi irun Aila ati Alaasari ati Magribi ati ‘Ishai, màá jókòó fún kíka ataaya alakọkọọ, oun náà ni: "At-Tahiyyātu lillāh was-sọlawātu wat-tọyyibātu, as salāmu ‘alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmọtullāh wa barakaatuhu, as salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis sọọlihīna, ’ashadu ’an lā ilāha illallāh, wa ’ashadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu". "Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo Irun ati gbogbo dáadáa tí Ọlọhun ni, ọla Ọlọhun ki o maa ba ọ iwọ Anabi ati ikẹ Rẹ ati awọn oore Rẹ, ọla Ọlọhun ki o maa ba awa naa ati gbogbo awọn ẹrusin Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni ire, mo jẹrii wipe ko si ẹnití ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allōhu, mo sì tun jẹrii wipe Muhammad ẹru Rẹ ni òjíṣẹ Rẹ sì ni pẹlu". Lẹyin naa maa dide fún rakaa kẹta lẹyin ìyẹn.

Lẹyin rakaa igbẹyin ninu gbogbo irun maa jókòó fún kíka ataaya igbẹyin, oun náà ni: "At-Tahiyyātu lillāh was-sọlawātu wat-tọyyibātu, as salāmu ‘alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmọtullāh wa barakaatuhu, as salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis sọọlihīna, ’ashadu ’an lā ilāha illallāh, wa ’ashadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu". Allāhummo sọlli ‘alā Muhammadin wa ‘ala ’āli Muhammadin, kamā sollayta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘ala ’āli ’Ibrāhīm, ’innaka hamīdun majīd. Allāhummo bārik ‘alā Muhammadin wa ‘ala ’āli Muhammadin, kamā bārakta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘ala ’āli ’Ibrāhīm, ’innaka hamīdun majīd". "Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo Irun ati gbogbo dáadáa tí Ọlọhun ni, ọla Ọlọhun ki o maa ba ọ iwọ Anabi ati ikẹ Rẹ ati awọn oore Rẹ, ọla Ọlọhun ki o maa ba awa naa ati gbogbo awọn ẹrusin Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni ire, mo jẹrii wipe ko si ẹnití ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allōhu, mo sì tun jẹrii wipe Muhammad ẹru Rẹ ni òjíṣẹ Rẹ sì ni pẹlu, Iwọ Oluwa wa ṣe ikẹ fún Anabi Muhammad, ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe ikẹ fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm, dajudaju Irẹ ni Ọba Ẹlẹyin Ọba ti O tobi, Oluwa wa, ṣe ìbùkún fún Anabi Muhammad ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe ìbùkún fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm, dajudaju Irẹ ni Ọba Ẹlẹyin Ọba ti O tobi"

Ìgbésẹ̀ Kejìlá: Lẹyin ìyẹn maa salamọ sí ọtun mi máa wá sọ pe: (As-Salāmu ‘alaykum wa rahmatullāhi wa barakātuhu), màá sì tun salamọ sí òsì mi, màá wá sọ pe: (As-Salāmu ‘alaykum wa rahmatullāhi wa barakātuhu) ní ẹni tí n daniyan jijade kuro ninu irun, ati pe lẹyin naa maa jẹ ẹnití o ti pe irun.

Ibori ọmọbinrin Musulumi.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ìwọ Ànábì sọ fún àwọn ìyàwó rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ àti àwọn obìnrin onígbàgbọ́ òdodo pé kí wọ́n máa gbé àwọn aṣọ jilbāb wọn wọ̀ sí ara wọn bámúbámú. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti fi mọ̀ wọ́n (ní olùbẹ̀rù Allāhu). Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò níí fi ìnira kàn wọ́n. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. {Al-Ah’zaab: 59}

Ọlọhun ṣe hijab ni ọranyan fun ọmọbìnrin Musulumi, ati bibo ihoho rẹ àti gbogbo ara rẹ fun àwọn ọkùnrin tí wọn kii ṣe eléèwọ̀ rẹ pẹ̀lú aṣọ tí wọ́n bá sáábà ní ìlú rẹ̀. Kò ní ẹ̀tọ́ fun un ki o bọ hijab rẹ silẹ ayaafi ni iwájú ọkọ rẹ tàbí àwọn eleewọ rẹ, àwọn naa ni àwọn ti o ṣe wipe kò ni ẹtọ fún ọmọbìnrin Mùsùlùmí láti fẹ́ wọn lailai, àwọn naa ni: (Baba kódà ki o ga, àti ọmọ kódà kí ó wálẹ̀, ati ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò bàbá lọkunrin, àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ìyá lọkunrin, àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni lọkunrin, àti ọmọkùnrin ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni lọkunrin, àti ọmọkùnrin ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni lóbìnrin, àti ọkọ ìyá ẹni, àti bàbá ọkọ ẹni kódà ki o ga, àti ọmọkùnrin ọkọ ẹni kódà kí ó wálẹ̀, àti arákùnrin tí èèyàn jọ mu ọyàn papọ, àti ọkọ ẹni tí ó fún ni lọ́yàn, nǹkan ti o ba jẹ eewọ latara ẹbí, yóò jẹ eewọ latara ọyàn naa).

Ọmọbìnrin Mùsùlùmí maa ṣe àkíyèsí àwọn ìlànà ti ó pọ̀ níbi aṣọ rẹ:

Àkọ́kọ́: Bibo gbogbo ara

Ẹẹkeji: Ki o ma jẹ nínú nǹkan ti obìnrin maa n wọ láti fi ṣe ọsọ.

Ẹẹkẹta: Kí ó má jẹ nǹkan ti o maa ṣe àfihàn ara rẹ̀.

Ẹẹkẹrin: Kí ó jẹ́ aṣọ tí ó fẹ̀ tí kò nii fún ti yoo waa maa ṣe ìròyìn bí nǹkan kan nínú ara rẹ ṣe rí.

Ẹẹkarun-un: Kí ó má jẹ nǹkan ti a fi lọfinda si

Ẹẹkẹfa: Kí ó má jọ aṣọ ọkùnrin.

Ẹẹkeje: Kí ó má jọ aṣọ àwọn ti kii ṣe Mùsùlùmí lóbìnrin níbi ìjọsìn wọn àti ọdún wọn.

Nínú àwọn ìròyìn Mumini

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé. [Al-Anfaal:2]

Olódodo ni yoo jẹ níbi ọ̀rọ̀ rẹ, ko nii máa pa irọ́.

Yóò máa ṣíkà àdéhùn

Kò nii máa dá ẹ̀ṣẹ̀ níbi ìjà "

Yoo máa dá àgbàfipamọ́ padà

Yoo fẹ fún ọmọ ìyá rẹ ti ó jẹ́ Mùsùlùmí nǹkan tí ó bá fẹ́ fún ara rẹ

Yóò jẹ́ alapọn-ọnle

Yoo máa ṣe dáadáa sí àwọn èèyàn

Yóò máa da ẹbí pọ̀

Yóò máa yọ́nú sí kádàrá Ọlọhun, yóò sì máa dúpẹ́ fún Un ni ìgbà ìdẹ̀kùn, yóò sì máa ṣe sùúrù ní ìgbà ìnira.

Yoo jẹ onitiju

Yoo maa ṣàánú àwọn ẹ̀dá.

Ọkàn rẹ maa mọ kúrò níbi ìkórìíra, àwọn oríkèé rẹ

Yóò máa ṣe amojukuro fún àwọn ènìyàn

Ko nii máa jẹ rìbá, ko si nii maa ba àwọn èèyàn lò pẹ̀lú rẹ.

Ko nii maa ṣe àgbèrè

Ko nii maa mu ọtí.

Yoo maa ṣe dáadáa si awọn aládùúgbò rẹ.

Ko nii maa ṣe àbòsí, ko si nii máa jàǹbá

Ko nii máa jalè, ko si nii máa dá ète.

Yoo maa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ méjèèjì kódà ki wọn má jẹ Mùsùlùmí, yóò máa tẹle àṣẹ wọn níbi dáadáa.

Yóò máa re àwọn ọmọ rẹ lórí ìwà dáadáa, yóò máa pa wọn láṣẹ láti máa ṣe àwọn nǹkan tí ó jẹ ọranyan ti òfin ẹsin, yóò máa kọ fún wọn kúrò níbi ìwà burúkú àti àwọn nǹkan eewọ.

Ko nii máa kọ́ṣe àwọn tí kii ṣe Mùsùlùmí níbi àwọn ìròyìn ẹsin wọn ti wọn fi dá yàtọ̀, tàbí níbi àwọn àṣà wọn ti o ti di àmì idanimọ fún wọn.

Ìdùnnú mi n bẹ nínú ẹsin mi tii ṣe Islam

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t’ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn. Suuratun Nahl: 97.

Nínú nǹkan tí ó tóbi jù tí ó le mú ìdùnnú wọ ọkàn Mùsùlùmí náà ni asopọ rẹ tààrà mọ́ Olúwa rẹ̀ láìsí alàgàta kankan nínú àwọn alààyè ni tàbí àwọn òkú tàbí àwọn òrìṣà. Nígbà tí àwọn ẹrúsìn Mi bá bi ọ léèrè nípa Mi, dájúdájú Èmi ni Olùsúnmọ́. Èmi yóò jẹ́pè àdúà aládùúà nígbà tí ó bá pè Mí. Kí wọ́n jẹ́’pè Mi (nípa ìtẹ̀lé àṣẹ Mi). Kí wọ́n sì gbà Mí gbọ́ nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà (gbígbà àdúà). [Al-Baqara:186] O pa wa láṣẹ ki a maa pe Òun, O wa ṣe àṣẹ yìí nínú àwọn ìjọsìn tí ó tóbi jù tí Mùsùlùmí maa fi sunmọ Olúwa rẹ, Ọba ti O lágbára ti O gbọnngbọn sọ pé: Olúwa yín sọ pé: "Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Gaafir:60 Mùsùlùmí rere maa ni bukaata si Olúwa rẹ ni gbogbo ìgbà, yóò sì maa ṣe adua ni iwájú Rẹ ni gbogbo ìgbà, yóò si tun máa sunmọ Ọn pẹ̀lú àwọn ìjọsìn dáadáa.

Ọlọhun da wa si ayé yii fun ọgbọ́n ńlá kan ni, ko da wa fún eré, òun naa ni jijọsin fun Un ni Òun nìkan ti ko ni orogun. O waa ṣe ni òfin fun wa ẹsin kan ti o wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa ti o ko nǹkan ti o pọ sínú ti o n ṣètò gbogbo àlámọ̀rí isẹmi wa eyi ti o jẹ ti ẹni kọọkan ati ti gbogboogbo. O wa fi òfin oni déédéé yii dá ààbò bo àwọn nǹkan koseemani isẹmi, àwọn naa ni ẹsin wa, ati ẹmi wa, ati ọmọlúwàbí wa, ati làákàyè wa, ati dúkìá wa. Ẹni ti o ba ṣẹmi lẹniti n tẹle àwọn àṣẹ òfin ẹsin náà, ti o n jìnà sí àwọn eewọ, o ti dá ààbò bo àwọn koseemani náà, yóò si maa ṣẹmi lẹniti yóò máa dunnu ti ọkàn rẹ yóò balẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ láìsí iyèméjì rárá.

Asopọ Mùsùlùmí pẹ̀lú Olúwa rẹ nǹkan ti o jin ni, ti o si maa n ṣe okunfa ifarabalẹ ati ifọkanbalẹ ati ààbò àti ìdùnnú, àti imọlara pe Olúwa n bẹ pẹ̀lú ẹni ti O si ni akolekan ẹrú Rẹ, tí O si n ran ẹrú Rẹ ti o jẹ Mumini lọ́wọ́, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Allāhu ni Alárànṣe àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ Al-Baqara: 257

Ajọṣepọ nla yii naa ni imọlara kan ti o maa n ṣe okùnfà gbigbadun jijọsin fun Ọlọhun Ọba Ajọkẹ-ayé, ati jijẹran pipade Rẹ, yoo sọ ọkàn rẹ di ọkàn ìdùnnú pẹ̀lú imọlara adùn ìgbàgbọ́,

ìyẹn ni adùn ti ko si ẹni ti o lè ròyìn rẹ àyàfi ẹni tí ó bá tọ́ ọ wò pẹ̀lú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ olóore àti jíjìnnà si awọn iṣẹ aburú. Fun ìdí yẹn ni Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ṣe n sọ pé: "O ti tọ ìgbàgbọ́ wo, ẹni tí ó bá yọ́nú sí Ọlọhun ni Olúwa, ti o yọ́nú si Islam ni ẹsin, ti o yọnu si Muhammad ni ojiṣẹ".

Bẹẹni, ti ẹrú ba ni imọlara pe oun n bẹ ni gbogbo ìgbà ni iwájú Ẹni tí O dá a, ti o sì mọ̀ ọ́n pẹ̀lú àwọn orúkọ Rẹ àti àwọn ìròyìn Rẹ ti o dára jù ti o si jọ́sìn fun Un bi ìgbà tí o n ri I, ti o si ni imọkangan nibi jijọsin fun Un, ti ko si gbero nǹkan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun pẹlu ẹ, yoo maa ṣẹmi ìdùnnú ti o dáa ni ayé àti àtúbọ̀tán rere ni ọjọ́ ìkẹyìn.

Titi ti o fi dórí àwọn musiiba ti n ṣẹlẹ̀ si Mumini ni ayé, dájúdájú gbígbóná rẹ maa kúrò pẹlu títutù amọdaju, ati yiyọnu si kádàrá Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ati didupẹ fun Un lori gbogbo àwọn kádàrá Rẹ, èyí tí ó dáa níbẹ̀ ni àti èyí tí ó burú, ati yiyọnu pátápátá si i.

Nínú nǹkan ti o tọ́ ki Musulumi ṣe ojúkòkòrò rẹ ki oriire rẹ àti ifọkanbalẹ rẹ le baa lekun naa ni ìrántí Ọlọhun ti ọla Rẹ ga lọpọlọpọ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ pẹ̀lú ìrántí Allāhu; ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀. [Ar-Ra'd:28] Gbogbo ìgbà tí Mùsùlùmí ba n lekun nínú ìrántí Ọlọhun ati kika Kuraani naa ni asopọ rẹ pẹ̀lú Ọlọhun maa lekun, ti ẹmi rẹ yóò sì mọ́, ti ìgbàgbọ́ rẹ yóò sì lágbára.

Bẹẹ naa ni o ṣe tọ́ fún Mùsùlùmí kí ó maa ṣe ojúkòkòrò láti kọ́ nípa àlámọ̀rí ẹsin rẹ láti inú àwọn orísun ti o ni àlàáfíà, titi ti yóò fi máa sin Ọlọhun pẹlu imọ amọdaju, Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé: (Wíwá ìmọ̀ ọranyan ni fún gbogbo Mùsùlùmí), Ki o juwọ-jusẹ silẹ fún àwọn àṣẹ Ọlọhun ti O da a, bóyá ó mọ ọgbọ́n ti o wa nibẹ ni abi ko mọ̀ ọ́n, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nínú tira alapọn-ọnle rẹ pe: Kò tọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, nígbà tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ bá ti parí ọ̀rọ̀ kan, láti ní ẹ̀ṣà (ọ̀rọ̀ mìíràn) fún ọ̀rọ̀ ara wọn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé. [Al-Ahzaab:36]

Ki Ọlọhun ṣe ikẹ ati ọla fún Anọbi wa Muhammad, àti àwọn araale rẹ àwọn saabe rẹ lapapọ.

"O ti parí"

Atọ́ka àwọn àkòrí

"Nọmba"

"Àkòrí

Ojú-ìwé

Pípadà sí èèpo ẹ̀yìn ìwé

Bọ́ sí atọ́ka àwọn àkòrí

Sọ àwọn ìrírí rẹ pẹ̀lú tira náà fún wa

Ṣe abẹwo sí ìkànnì náà

Ìwé ti oni ibara-ẹni-ṣepọ fún fóònù alagbeeka

Tẹ̀ láti bọ́ sí àkòrí náà

Tẹ àwòrán náà láti padà sí eepo ẹyin ìwé

Pa báákoòdù náà rẹ́

Ìfihàn ti idanilẹkọọ (powerpoint)

Àbájáde iṣẹ́ àkànṣe naa

Tira tí a tẹ̀ jáde

Tira fóònù alagbeeka

Ìkànnì

Ìfihàn PowerPoint

Ẹ̀dà tí o jẹ ti fóònù ìgbàlódé nìkan