“Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”.
Láti ọ̀dọ̀ Uqbah ọmọ Aamir Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”.
«الجاهِرُ بالقرآن كالجاهِرِ بالصَّدَقَةِ، والمُسِرُّ بالقرآن كالمُسِرِّ بالصَّدَقَة».
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ẹni ti ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni tí n kéde sàárà ṣíṣe, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni tí n fi sàárà pamọ.
...:
Kika Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ ni o ni ọlá jù, gẹgẹ bi fifi sàárà pamọ naa ṣe ní ọlá jù; tori imọkanga ti o wa nibẹ, ati ijinna si ṣekarimi ati motomoto, àyàfi tí bukaata tabi anfaani ba pepe lọ sibi ki a ka a sókè, gẹgẹ bii kikọ èèyàn ni Kuraani.
Tira Sunanu ti baba Daud (2/ 494) (1333).
Tira Sunanu ti Tirmidhiy (5/ 40) (2919).
Tira Sunanu ti An-Nasaaiy (5/ 80) (2561).
Àlékún (4)
الكاشف عن حقائق السُّنن (5/1688).
شرح أبي داود للعيني (5/238).
تحفة الأحوذي (8/ 191).
التنوير في شرح الجامع الصغير (5/286).