Skip to content

“Maa wa nibi adágún naa ki n le ri ẹni tí o maa wa si ọdọ mi ninu yin, wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ mi, mo maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara ìjọ mi ni wọn

Lati ọdọ Asma ọmọ Abubakr, ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji, o sọ pe: Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé:

“Maa wa nibi adágún naa ki n le ri ẹni tí o maa wa si ọdọ mi ninu yin, wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ mi, mo maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara ìjọ mi ni wọn, wọn maa wa sọ pé: Ǹjẹ́ o mọ nǹkan ti wọn ṣe lẹ́yìn rẹ, mo fi Ọlọhun bura, wọn kò yẹ̀ wọn kò gbò ti wọn n kúrò nínú Isilaamu”.

«إِنِّي عَلَى الحَوْضِ حَتَّى أَنْظُرَ مَنْ يَرِدُ عَلَيَّ مِنْكُمْ، وَسَيُؤْخَذُ نَاسٌ دُونِي، فَأَقُولُ: يَا رَبِّ مِنِّي وَمِنْ أُمَّتِي، فَيُقَالُ: هَلْ شَعَرْتَ مَا عَمِلُوا بَعْدَكَ، وَاللَّهِ مَا بَرِحُوا يَرْجِعُونَ عَلَى أَعْقَابِهِمْ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe oun yoo wa nibi odò adágún rẹ ni ọjọ igbende láti ri awọn ti wọn maa wa síbẹ̀ nínú ìjọ rẹ, Wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ rẹ, ki ikẹ ati ọla maa ba a, o maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara mi ni wọn, ara ìjọ mi si ni wọn, Wọn maa sọ pé: Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọn ṣe lẹ́yìn ti ẹ ti jọ pínyà, mo fi Ọlọhun bura, wọ́n kò yẹ̀ wọn kò gbò ti wọn n kúrò nínú ẹsin wọn, wọn kì í ṣe ara rẹ, wọn o si ki i ṣe ara ìjọ rẹ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Aanu Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, si awọn ijọ rẹ ati itaraṣaṣa rẹ si wọn.

Ewu ìyapa ohun ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lórí rẹ.

Igbaniyanju lati di sunna Anabi mu, ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (8/ 121) (6593).

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 1793) (2292).

Àlékún (2)

عمدة القاري (23/144).

البحر المحيط الثجاج (37/322).