Skip to content

“Ayé ìgbádùn ni, eyi ti o loore ju ninu ìgbádùn ayé ni obìnrin rere”

Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

“Ayé ìgbádùn ni, eyi ti o loore ju ninu ìgbádùn ayé ni obìnrin rere”

«الدُّنْيَا مَتَاعٌ، وَخَيْرُ مَتَاعِ الدُّنْيَا الْمَرْأَةُ الصَّالِحَةُ».

Muslim ni ọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ayé pẹ̀lú nǹkan ti n bẹ ninu ẹ jẹ nǹkan ti eeyan maa n gbádùn fun ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn naa ni o maa kúrò, ati pe ìgbádùn rẹ ti o ni ọlá jù ni obìnrin rere, eyi ti o ṣe pe ti o ba wo o yoo dun un ninu, ti o ba pa a láṣẹ yoo tẹle e, ti ko ba si ni tòsí o maa ṣọ́ ọ ninu ẹ̀mí ara rẹ ati dúkìá rẹ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ìní ẹtọ ìgbádùn àwọn nǹkan ti o dáa ni ayé, eyi ti Ọlọhun ṣe ni ẹtọ fun awọn ẹru Rẹ láìsí ìná-àpà tabi ìgbéraga.

Ṣiṣenilojukokoro lori yíyan ìyàwó rere; tori pe iranlọwọ ni in fun ọkọ lati tẹle àṣẹ Olúwa rẹ.

Eyi ti o loore julọ ninu ìgbádùn ayé ni eyi ti o ba wa fun itẹle àṣẹ Ọlọhun, tabi ti o ṣe iranlọwọ lati tẹle àṣẹ Ọlọhun.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (2/ 1090) (1467).

Àlékún (6)

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (1/ 365).

كشف المشكل من حديث الصحيحين.

لابن الجوزي (4/ 129).

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

لمصطفى الخن وغيره (1/ 286).