Obinrin kan ṣe irin ajo lọ si Hajj, ni o wa ri nǹkan oṣù rẹ lati ọjọ karùn-ún ti o ti bẹ̀rẹ̀ irin ajo rẹ, lẹyin dide rẹ si awọn aaye ti wọn ti maa n gbe áràmí, o wẹ, o si gbe arami, ti ko si tii mọra nibi nǹkan oṣù re, igba ti o de Mẹka Alapọn-ọnle, o wa ni ita Haram, ko si ṣe nnkankan ninu awọn iṣẹ Hajj tabi Umrah, o wa ni Mina fun ọjọ meji, lẹyin naa o mọra, o si wẹ, o si pe gbogbo iṣẹ Umrah ti o si jẹ ẹni ti o mọ, lẹyin naa ẹjẹ naa pada nigba ti o n ṣe Tawaaful Ifaadah, ṣùgbọ́n ojú n tì í, o si pari awọn iṣẹ Hajj, ti ko sọ fun alaṣẹ rẹ afi lẹyin dide rẹ pada si ilu rẹ, ki ni idajọ iyẹn?
السؤال
Ibeere akọkọ:

س48: سافرت امرأةٌ إلى الحجّ، وجاءتها العادة الشهريّة منذ خمسة أيامٍ من تاريخ سفرها، وبعد وصولها إلى الميقات اغتسلت وعقدت الإحرام، وهي لم تطهر من العادة، وحين وصولها إلى مكة المكرمة ظلت خارج الحرم، ولم تفعل شيئًا من شعائر الحجّ أو العمرة، ومكثت يومين في منًى، ثم طهرت، واغتسلت، وأدت جميع مناسك العمرة وهي طاهرٌ، ثمّ عاد الدم إليها وهي في طواف الإفاضة للحجّ، إلا أنها استحت، وأكملت مناسك الحجّ، ولم تخبر وليها إلا بعد وصولها إلى بلدها، فما حكم ذلك؟
الجواب
Idahun akọkọ:
Idajọ nibi eyi ni pe: Dajudaju ẹjẹ ti o ṣẹlẹ si i nibi Tawaaful Ifaadoh, ti o ba jẹ pe ẹjẹ nnkan oṣu ni, eyi ti o da a mọ pẹlu adamọ rẹ tabi awọn irora, dajudaju Tawaaful Ifaadoh naa ko ni alaafia, o si jẹ dandan fun un lati pada si Makkah; lati ṣe Tawaaful Ifaadoh, ti yoo si gbe arami Umrah lati awọn aaye ti wọn ti maa n gbe e, yoo si ṣe Umrah pẹlu irọkirika ile Oluwa ati sisa safa ati mariwa, yoo si ge irun rẹ, lẹyin naa yoo ṣe Tawaaful Ifaadoh.
Ṣugbọn ti ẹjẹ naa ko ba kii ṣe ẹjẹ nnkan oṣu, ẹjẹ ti adamọ ti a mọ, bi ko ṣe pe o jade latara àpọ̀jù àwọn èèyàn tabi ibẹru, tabi nnkan ti o jọ iyẹn, dajudaju irọkirika rẹ ni alaafia lọdọ ẹni ti ko fi imọra ṣe majẹmu fun irọkirika ile Oluwa
Ti pípadà ko ba rọrun fun un nibi ọ̀rọ̀ akọkọ, bóyá o wa ni ilu ti o jinna, Hajj rẹ ni alaafia; nitori pe ko ni ikapa ju nnkan ti o ṣe lọ
ﺟ48: الحكم في هذا: أنّ الدم الّذي أصابها في طواف الإفاضة إذا كان هو دم الحيض الّذي تعرفه بطبيعته وأوجاعه فإن طواف الإفاضة لم يصح، ويلزمها أن تعود إلى مكة؛ لتطوف طواف الإفاضة، فتحرم بعمرةٍ من الميقات، وتؤدّي العمرة بطوافٍ وسعيٍ، وتقصّر، ثم تطوف طواف الإفاضة.
أما إذا كان هذا الدم ليس دم الحيض، الدم الطبيعيّ المعروف، وإنما نشأ من شدّة الزّحام أو الروعة أو ما شابه ذلك، فإن طوافها يصحّ عند من لا يشترط الطهارة للطواف.
فإن لم يمكنها الرّجوع في المسألة الأولى، بحيث تكون في بلادٍ بعيدةٍ، فحجّها صحيحٌ؛ لأنها لا تستطيع أكثر ممّا صنعت.