Bawo ni ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ṣe maa ki rakah meji gbigbe urumi? Njẹ o ni ẹtọ fun obinrin ti o n ṣe nnkan oṣu lati paara èyíkéyìí aaya Kuraani ni jẹ́jẹ́, àbí ko ni ẹtọ?
السؤال
Ibeere akọkọ:
Bawo ni ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ṣe maa ki rakah meji gbigbe urumi? Njẹ o ni ẹtọ fun obinrin ti o n ṣe nnkan oṣu lati paara èyíkéyìí aaya Kuraani ni jẹ́jẹ́, àbí ko ni ẹtọ?
س47: كيف تصلّي الحائض ركعتي الإحرام؟ وهل يجوز للمرأة الحائض ترديد آي الذّكر الحكيم في سرّها، أو لا؟
الجواب
Idahun akọkọ:
Akọkọ: O tọ ki a mọ pe gbigbe urumi ko ni irun kankan ti o n bẹ fun un; dajudaju ko wa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe o ṣe irun kan ni ofin fun ìjọ rẹ fun gbigbe urumi, boya pẹlu ọrọ rẹ ni tabi pẹlu iṣe rẹ tabi pẹlu ifirinlẹ rẹ
Ikeji: Dajudaju obinrin yii ti o ri nnkan oṣu ṣiwaju ki o to gbe urumi, ọ rọrun fun un lati gbe urumi ti o si n ṣe nnkan oṣu ;
Nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pa Asmau ọmọ Umays, iyawo Abu Bakr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- laṣẹ nigba ti ẹjẹ ìbímọ n da lara rẹ ni Zhul Hulayfah, o pa a laṣẹ lati wẹ ki o si de aṣọ kan mọ oju ara rẹ, ki o si gbe urumi, gẹgẹ bẹẹ naa ni ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu naa, yoo wa lori urumi rẹ titi yoo fi mọ, lẹyin naa yoo rọkirika ile Oluwa, yoo si sa sàfá ati máríwà.
Ṣugbọn ibeere ti o béèrè pé: Njẹ o ni ẹtọ fun un lati ka Kuraani? Bẹẹni, ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ni ẹtọ lati ka Kuraani nigba bukaata tabi anfaani, ṣugbọn laini bukaata tabi anfaani, bi ko ṣe pe o fẹ ka a ni ti ijọsin ati isunmọ Ọlọhun, eyi ti o daa julọ ni ki o ma ka a
ﺟ47: أولًا: ينبغي أن نعلم أن الإحرام ليس له صلاةٌ؛ فإنه لم يرد عن النبيّ ﷺ أنه شرع لأمته صلاةً للإحرام لا بقوله، ولا بفعله، ولا بإقراره.
ثانيًا: إن هذه المرأة الحائض الّتي حاضت قبل أن تحرم يمكنها أن تحرم وهي حائضٌ؛ لأن النبي ﷺ أمر أسماء بنت عميسٍ امرأة أبي بكرٍ رضي الله عنهما حين نفست في ذي الحليفة، أمرها أن تغتسل وتستثفر بثوبٍ، وتحرم [1]، وهكذا الحائض أيضًا، وتبقى على إحرامها حتى تطهر، ثمّ تطوف بالبيت، وتسعى.
[18] رواه مسلم، كتاب الحج، باب حج النبي ﷺ (2137).
وأما قوله في السّؤال: هل لها أن تقرأ القرآن؟ فنعم، الحائض لها الحقّ أن تقرأ القرآن عند الحاجة أو المصلحة، أمّا بدون حاجةٍ ولا مصلحةٍ، إنما تريد أن تقرأه تعبّدًا وتقرّبًا إلى الله، فالأحسن ألا تقرأه.