Skip to content

Njẹ nnkan ti o n san ti o n jade lára obìnrin- funfun ni o jẹ ni tabi pupa- jẹ nnkan ti o mọ àbí nnkan ẹgbin ni bí? Njẹ aluwala jẹ dandan nibẹ, pẹlu nini imọ pe o n jade lai dúró? Ki ni idajo ti o ba n ṣe ṣegeṣege, pataki julọ ọpọlọpọ awọn obinrin- paapaa julọ awọn akẹ́kọ̀ọ́ lobinrin- wọn maa n ka iyẹn si ìtutù abẹ́ ti adamọ, ti aluwala ko jẹ dandan latara rẹ?

السؤال

Ibeere akọkọ:

Njẹ nnkan ti o n san ti o n jade lára obìnrin- funfun ni o jẹ ni tabi pupa- jẹ nnkan ti o mọ àbí nnkan ẹgbin ni bí? Njẹ aluwala jẹ dandan nibẹ, pẹlu nini imọ pe o n jade lai dúró? Ki ni idajo ti o ba n ṣe ṣegeṣege, pataki julọ ọpọlọpọ awọn obinrin- paapaa julọ awọn akẹ́kọ̀ọ́ lobinrin- wọn maa n ka iyẹn si ìtutù abẹ́ ti adamọ, ti aluwala ko jẹ dandan latara rẹ?

س35: هل السائل الّذي ينزل من المرأة -أبيض كان أم أصفر- طاهرٌ أو نجسٌ؟ وهل يجب فيه الوضوء، مع العلم بأنه ينزل مستمرًّا؟ وما الحكم إذا كان متقطّعًا، خاصةً أن غالب النّساء -لا سيما المتعلّمات- يعتبرن ذلك رطوبةً طبيعيةً، لا يلزم منه الوضوء؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Eyi ti o han si mi lẹyin iwadii ni pe: Nǹkan ti o n san ti o n jade lára obinrin ti ko ba jade lati inú àpò ìtọ̀, bi ko ṣe pe o n jade láti apo ibi, nnkan ti o mọ ni, ṣugbọn yoo ba aluwala jẹ tòun ti bi o ṣe jẹ nnkan ti o mọ; nitori pe wọn ko ṣe ni majẹmu fun nnkan ti o n ba aluwala jẹ lati jẹ nnkan ẹgbin, gẹ́gẹ́ bíi iso ti o n jade lati idi, ko ni ara, tòun ti bẹẹ naa o n ba aluwala jẹ.

Lori eyi, ti o ba jade lara obìnrin ti o si ni aluwala, yoo ba aluwala jẹ, o si di dandan fún un ki o tun un ṣe.

Ti ko ba dúró, ko nii ba aluwala jẹ, ṣugbọn yoo maa ṣe aluwala fun irun ti akoko rẹ ba wọle, ti yoo si kirun ọran-anyan ati naafila ni akoko ti o ṣe aluwala nibẹ yii, yoo ka Kuraani, yoo si ṣe nnkan ti o fẹ ninu nnkan ti wọn ṣe ni ẹtọ fun un

Gẹgẹ bi awọn onimimọ ṣe sọ nipa eyi nibi ẹni ti n tọ̀ sára, eleyii ni idajọ nnkan ti o n sàn ni abala imọra, nnkan ti o mọ ni, ni abala biba aluwala jẹ, o jẹ nnkan ti o n ba aluwala jẹ ayafi ti ko ba dúró, ti ko ba duro ko nii ba aluwala jẹ, ṣugbọn o jẹ dandan fun obinrin naa lati má ṣe aluwala fun irun afi lẹyin ti akoko rẹ ba wọle, ki o si wé nǹkan mọ ọn.

Ṣugbọn ti o ba maa n dá, ti o si wa ninu iṣesi rẹ lati maa dá ni awọn akoko irun, yoo lọ irun lara di asiko ti o maa n dá nibẹ, niwọn igba ti ko ba paya ki akoko irun lọ, ti o ba paya rẹ yoo ṣe aluwala, yoo si wé aṣọ mọ ọn, yoo si kirun

Ko wa si iyatọ laaarin eyi ti o kere ati eyi ti o pọ; nitori pe oju ara ni gbogbo ẹ ti n jáde, kekere rẹ ati pupọ rẹ maa jẹ nnkan ti o n ba aluwala jẹ, yatọ si eyi ti o n jade lati ẹ̀yà ara ti o ṣẹku gẹgẹ bii ẹjẹ ati eebi, ko nii ba aluwala jẹ, ati kekere rẹ ni o tabi pupọ rẹ

Ṣugbọn ini adisọkan awọn obinrin kan pe ko lee ba aluwala jẹ, eleyii mi ko mọ ẹri kankan fun un, afi ọrọ kan ti Ibn Hazmi- ki Ọlọhun kẹ ẹ- sọ pe: Dajudaju eyi ko lee ba aluwala jẹ. Ṣugbọn ko sọ ẹri kankan fun eyi, ti o ba ni ẹri kan ninu iwe Ọlọhun ati ọrọ Ojiṣẹ Ọlọhun tabi awọn ọrọ awọn sọhaba ni, ko ba jẹ awijare

O jẹ dandan fun obinrin lati bẹru Ọlọhun, ki o si ko akolekan imọra rẹ; nitori pe irun, wọn ko lee tẹwọ gba a laisi imọra ko da ki o kirun ni ìgbà ọgọrun-un, bi ko ṣe pe apakan awọn onimimọ sọ pe: Dajudaju ẹni ti o n kirun laini imọra maa di keferi; nitori pe eyi wa ninu abala iṣe yẹyẹ pẹlu awọn aayah Ọlọhun- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga-

ﺟ35: الظاهر لي بعد البحث: أن السائل الخارج من المرأة إذا كان لا يخرج من المثانة، وإنما يخرج من الرحم، أنّه طاهرٌ، ولكنه ينقض الوضوء وإن كان طاهرًا؛ لأنه لا يشترط للناقض للوضوء أن يكون نجسًا، فها هي الرّيح تخرج من الدّبر، وليس لها جرمٌ، ومع ذلك تنقض الوضوء.

وعلى هذا، إذا خرج من المرأة وهي على وضوءٍ فإنه ينقض الوضوء، وعليها تجديده.

فإن كان مستمرًّا فإنه لا ينقض الوضوء، ولكن تتوضأ للصلاة إذا دخل وقتها، وتصلّي في هذا الوقت الّذي تتوضأ فيه فروضًا ونوافل، وتقرأ القرآن، وتفعل ما شاءت ممّا يباح لها،

كما قال أهل العلم نحو هذا فيمن به سلس البول، هذا هو حكم السائل من جهة الطهارة، فهو طاهرٌ، ومن جهة نقضه للوضوء، فهو ناقضٌ للوضوء إلا أن يكون مستمرًّا عليها، فإن كان مستمرًّا فإنه لا ينقض الوضوء، لكن على المرأة ألا تتوضأ للصلاة إلا بعد دخول الوقت، وأن تتحفظ.

أما إن كان منقطعًا، وكان من عادته أن ينقطع في أوقات الصلاة، فإنها تؤخّر الصلاة إلى الوقت الّذي ينقطع فيه، ما لم تخش خروج الوقت، فإن خشيت خروج الوقت فإنها تتوضأ، وتتلجم -تتحفظ- وتصلّي.

ولا فرق بين القليل والكثير؛ لأنه كله خارجٌ من السبيل، فيكون ناقضًا قليله وكثيره، بخلاف الذي يخرج من بقية البدن كالدم والقيء، فإنه لا ينقض الوضوء، لا قليله ولا كثيره.

وأما اعتقاد بعض النّساء أنه لا ينقض الوضوء فهذا لا أعلم له أصلًا، إلا قولًا لابن حزمٍ رحمه الله، فإنه يقول: إن هذا لا ينقض الوضوء، ولكنه لم يذكر لهذا دليلًا، ولو كان له دليلٌ من الكتاب والسّنة أو أقوال الصحابة لكان حجةً.

وعلى المرأة أن تتقي الله، وتحرص على طهارتها؛ فإن الصلاة لا تقبل بغير طهارةٍ ولو صلت مئة مرةٍ، بل إن بعض العلماء يقول: إن الذي يصلّي بلا طهارةٍ يكفر؛ لأن هذا من باب الاستهزاء بآيات الله سبحانه وتعالى.