Ki ni idajọ kí obinrin wà ni mọsalasi ọwọ ti o si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu; fun titẹti si awọn hadisi ati awọn khutubah?
السؤال
Ibeere akọkọ:
Ki ni idajọ kí obinrin wà ni mọsalasi ọwọ ti o si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu; fun titẹti si awọn hadisi ati awọn khutubah?
س34: ما حكم وجود المرأة في المسجد الحرام وهي حائضٌ؛ لاستماع الأحاديث والخطب؟
الجواب
Idahun akọkọ:
Ko lẹtọọ fun obinrin ti o n ṣe nnkan oṣu lati wa ninu mọsalasi eewọ tabi mọsalasi mìíràn , ṣugbọn o lẹtọọ fun un lati kọja ninu mọsalasi lati mu nnkan ti o ni bukaata si nibẹ ati nnkan ti o jọ iyẹn
Gẹgẹ bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe sọ fun Aisha nigba ti o pa a laṣẹ mu khumroh wa[1], o sọ pe: O wa ninu mọsalasi, mo si n ṣe nnkan oṣu. O sọ pe: “Dajudaju nnkan oṣu rẹ ko si ni ọwọ rẹ”.
Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ba kọja ninu mọsalasi, ti ọkàn rẹ si balẹ̀ pe ẹ̀jẹ̀ ko nii kan sínú mọsalasi, ko si ẹṣẹ fun un.
[1] Al-Khumroh: Oun ni itẹ ti olukirun maa n fi ori kanlẹ lori rẹ, wọn sọ ọ ni khumroh; nitori pe o maa n khammaroh oju, itumọ rẹ ni pe: O maa n bo o
Ṣugbọn ti o ba fẹ wọle ki o jokoo, eleyii ko lẹtọọ
Ẹri lori iyẹn ni pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pa awọn obinrin laṣẹ nibi irun yidi lati jade lọ si aaye ti wọn ti n ki irun yidi (àwọn ọdọbinrin ti wọn ṣẹṣẹ bàlágà, ati awọn obìnrin ti wọn maa n wà nínú ilé lẹ́yìn gàgá, ati awọn ti n ri ẹjẹ nkan oṣù), ṣùgbọ́n wọn pa àṣẹ fun awọn ti n ṣe nnkan oṣu lati jìnnà si ààyè ìkírun.
Ìyẹn n tọka si pe ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ko lẹtọọ fun un lati wa nínú mọsalasi lati tẹti si khutuba, tabi ẹkọ ati awọn hadisi
ﺟ34: لا يجوز للمرأة الحائض أن تمكث في المسجد الحرام ولا غيره من المساجد، ولكن يجوز لها أن تمر بالمسجد، وتأخذ الحاجة منه وما أشبه ذلك؛ كما قال النبيّ ﷺ لعائشة حين أمرها أن تأتي بالخمرة[1]، فقالت: إنها في الـمسجد، وإنّي حائضٌ، فقال:
«إِنَّ حَيْضَتَكِ لَيْسَتْ فِي يَدِكِ» [2]،
فإذا مرت الحائض في المسجد، وهي آمنةٌ من أن ينزل دمٌ على المسجد، فلا حرج عليها.
[14] الخمرة: هي السجادة يسجد عليها المصلي، وسميت خمرة؛ لأنها تخمر الوجه، أي: تغطيه.
[15] مسلم، كتاب الحيض، باب جواز غسل الحائض رأس زوجها وترجيله (11) (298).
أما إن كانت تريد أن تدخل وتجلس فهذا لا يجوز.
والدليل على ذلك: أن النبي ﷺ أمر النّساء في صلاة العيد أن يخرجن إلى مصلى العيد -العواتق، وذوات الخدور، والحيض- إلا أنه أمر أن يعتزل الحيض المصلى [3]،
فدل ذلك على أنّ الحائض لا يجوز لها أن تمكث في المسجد لاستماع الخطبة، أو استماع الدرس والأحاديث.
[16] البخاري، كتاب العيدين، باب خروج النساء والحيض (974)، ومسلم، كتاب العيدين، باب ذكر إباحة خروج النساء في العيدين إلى المصلى (10) (890).
من أحكام الطهارة في الصلاة