Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

البَقَرَة

البَقَرَة is chapter 2 of the Quran and has 286 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

286 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 2
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓمٓ

’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ ’Islām máa ń sọ pé irúfẹ́ àwọn lẹ́tà (háràfí) wọ̀nyí dúró fún àwọn ọ̀rọ̀ kan, ohun tí àwọn onímọ̀ ’Islām faramọ́ jùlọ ni pé, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nìkan ṣoṣo l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn harafi náà.

ذَٰلِكَ ٱلۡكِتَٰبُ لَا رَيۡبَۛ فِيهِۛ هُدٗى لِّلۡمُتَّقِينَ

Tírà yìí, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìmọ̀nà ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡغَيۡبِ وَيُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ

(Àwọn olùbẹ̀rù Allāhu ni:) àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìkọ̀kọ̀ àti àwọn tó ń kírun àti àwọn tó ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn,

Explanation & meanings · 1
  1. Ìkọ̀kọ̀ ni ohun tí ẹ̀dá kò lè fi ọ̀nà kan kan nímọ̀ nípa rẹ̀ nínú ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - sọllallāhu alaehi wa sallam - sọ nípa rẹ̀.

وَٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبۡلِكَ وَبِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ يُوقِنُونَ

àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ àti àwọn tó ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Explanation & meanings · 1
  1. Ní àkọ́kọ́ ná, Allāhu kò dárúkọ bíbélì nínú al-Ƙur’ān. Orúkọ àwọn tírà mímọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ nípa wọn nínú al-Ƙur’ān ni Zabūr, Suhuf, Taorāt àti ’Injīl. Lẹ́yìn náà, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi rinlẹ̀ nínú al-Ƙur’ān pé kò sí ojúlówó àwọn tírà náà mọ́ níta, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:75 & 79, sūrah an-Nisā’; 4:46 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13. Nítorí náà, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé ni tírà ìkẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún gbogbo ẹ̀dá. Kò sí òmíràn mọ́.

أُوْلَٰٓئِكَ عَلَىٰ هُدٗى مِّن رَّبِّهِمۡۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.