Skip to content
البَقَرَة /

Ẹsẹ 194

2 : 194

Ẹsẹ 194 of البَقَرَة (2 : 194). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

البَقَرَة Àwọn Ẹsẹ 286
2 : 194

ٱلشَّهۡرُ ٱلۡحَرَامُ بِٱلشَّهۡرِ ٱلۡحَرَامِ وَٱلۡحُرُمَٰتُ قِصَاصٞۚ فَمَنِ ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَٱعۡتَدُواْ عَلَيۡهِ بِمِثۡلِ مَا ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ

Oṣù ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àwọn n̄ǹkan ọ̀wọ̀ sì ní (òfin) ìgbẹ̀san. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà si yín, ẹ gb’ẹ̀san ìtayọ ẹnu-ààlà lára rẹ̀ pẹ̀lú irú ohun tí ó fi tayọ ẹnu-ààlà si yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ni pé, ìpìlẹ̀ lọ́dọ̀ àwa mùsùlùmí ni bíbu ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àmọ́ tí àwọn kèfèrí bá dá ogun sílẹ̀ nínú oṣù ọ̀wọ̀, ẹ má ṣe káwọ́ gbera, ẹ ja àwọn náà lógun.