2 : 15
ٱللَّهُ يَسۡتَهۡزِئُ بِهِمۡ وَيَمُدُّهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ
Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.
Explanation & meanings · 1
- Kì í ṣe gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ ni ó máa di orúkọ Rẹ̀ àfi èyí tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - sọllallāhu alaehi wa sallam - bá pè ní orúkọ Rẹ̀ àti ìròyìn Rẹ̀.