بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
- Sūratun Mọkkiyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú Hijrah. Bákan náà, sūratun Mọdaniyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn Hijrah.
الفَاتِحة is chapter 1 of the Quran and has 7 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá (àgbáńlá ayé àti ọ̀run),
ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run,
مَٰلِكِ يَوۡمِ ٱلدِّينِ
Ọba Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san.
إِيَّاكَ نَعۡبُدُ وَإِيَّاكَ نَسۡتَعِينُ
Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá ìrànlọ́wọ́ sí.
ٱهۡدِنَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ
Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (ẹ̀sìn ’Islām),
صِرَٰطَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِمۡ غَيۡرِ ٱلۡمَغۡضُوبِ عَلَيۡهِمۡ وَلَا ٱلضَّآلِّينَ
ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún, yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasọ̄rọ̄).