Skip to content
البَقَرَة /

Ẹsẹ 84

2 : 84

Ẹsẹ 84 of البَقَرَة (2 : 84). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

البَقَرَة Àwọn Ẹsẹ 286
2 : 84

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ لَا تَسۡفِكُونَ دِمَآءَكُمۡ وَلَا تُخۡرِجُونَ أَنفُسَكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ ثُمَّ أَقۡرَرۡتُمۡ وَأَنتُمۡ تَشۡهَدُونَ

(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ léra yín jáde kúrò nínú ilé yín. Lẹ́yìn náà, ẹ fi rinlẹ̀, ẹ sì ń jẹ́rìí sí i.

Explanation & meanings · 1
  1. Àdéhùn yìí wáyé láààrin Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn yẹhudi ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí āyah 85 ṣe fi rinlẹ̀, àwọn yẹhudi gbàbọ̀dè, wọ́n sì lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn Ƙuraeṣi tí wọ́n wá gbé ogun ti àwọn mùsùlùmí ní ìlú Mọdīnah.