Skip to content
البَقَرَة /

Ẹsẹ 112

2 : 112
البَقَرَة Àwọn Ẹsẹ 286
2 : 112

بَلَىٰۚ مَنۡ أَسۡلَمَ وَجۡهَهُۥ لِلَّهِ وَهُوَ مُحۡسِنٞ فَلَهُۥٓ أَجۡرُهُۥ عِندَ رَبِّهِۦ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ

Bẹ́ẹ̀ kọ́ (wọn kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi) ẹni tí ó bá ju ara rẹ̀ sílẹ̀ (sínú ’Islām) fún Allāhu, tí ó sì jẹ́ olùṣe rere. Nítorí náà, ẹ̀san (rere) rẹ̀ ń bẹ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

Explanation & meanings · 3
  1. Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá ṣe ’Islām pẹ̀lú àfọ̀mọ́-ọkàn.
  2. Ìyẹn ni pé, kò níí sí ìbẹ̀rù fún àwọn mùsùlùmí nípa ohun tí wọ́n ń lọ bá pàdé ní Ọjọ́ Àjíǹde.
  3. Ìyẹn ni pé, kò níí sí ìbànújẹ́ fún àwọn mùsùlùmí nípa ohun tí ọwọ́ wọn kò bà nínú oore ayé nítorí pé, Allāhu máa dí i fún wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde.