Skip to content
البَقَرَة /

Ẹsẹ 237

2 : 237

Ẹsẹ 237 of البَقَرَة (2 : 237). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

البَقَرَة Àwọn Ẹsẹ 286
2 : 237

وَإِن طَلَّقۡتُمُوهُنَّ مِن قَبۡلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ وَقَدۡ فَرَضۡتُمۡ لَهُنَّ فَرِيضَةٗ فَنِصۡفُ مَا فَرَضۡتُمۡ إِلَّآ أَن يَعۡفُونَ أَوۡ يَعۡفُوَاْ ٱلَّذِي بِيَدِهِۦ عُقۡدَةُ ٱلنِّكَاحِۚ وَأَن تَعۡفُوٓاْ أَقۡرَبُ لِلتَّقۡوَىٰۚ وَلَا تَنسَوُاْ ٱلۡفَضۡلَ بَيۡنَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ

Tí ẹ bá sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó súnmọ́ wọn, tí ẹ sì ti sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn, ìlàjì ohun tí ẹ ti ṣòdíwọ̀n rẹ̀ ní sọ̀daàkí (ni kí ẹ fún wọn), àfi tí àwọn obìnrin náà bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀) tàbí tí ẹni tí ìtakókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀). Kí ẹ ṣàmójú kúrò ló súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Ẹ má ṣe gbàgbé oore àjùlọ ààrin yín. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹni tí ìtakókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rȩ̣̀ nínú āyah yìí lè jẹ́ ọkọ tàbí aláṣẹ obìnrin torí ààrin wọn ni ìtakókó yìgì ti ń wáyé. Níwọ̀n ìgbà tí a sì ti rí “àfi tí àwọn obìnrin náà bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀)”, igun ọkọ ni ọ̀rọ̀ kàn. Wa-llāhu ’a‘lam.