2 : 41
وَءَامِنُواْ بِمَآ أَنزَلۡتُ مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَكُمۡ وَلَا تَكُونُوٓاْ أَوَّلَ كَافِرِۭ بِهِۦۖ وَلَا تَشۡتَرُواْ بِـَٔايَٰتِي ثَمَنٗا قَلِيلٗا وَإِيَّٰيَ فَٱتَّقُونِ
Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó pọ́ọ́kú. Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù.
Explanation & meanings · 1
- Títa āyah Taorāt àti ’Injīl ní owó pọ́ọ́kú ni títi ọwọ́ bọ̀ ọ́ lójú nítorí kí wọ́n lè jáde kúrò lábẹ́ òfin Allāhu fún ìgbádùn ayé.