Skip to content
البَقَرَة /

Ẹsẹ 212

2 : 212

Ẹsẹ 212 of البَقَرَة (2 : 212). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

البَقَرَة Àwọn Ẹsẹ 286
2 : 212

زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَيَسۡخَرُونَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۘ وَٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ وَٱللَّهُ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٖ

Wọ́n ṣe ìṣẹ̀mí ayé ní ọ̀ṣọ́ (ẹ̀tàn) fún àwọn aláìgbàgbọ́. (Tí ayé bá sì yẹ wọ́n tán,) wọn yó máa fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn tó sì bẹ̀rù Allāhu máa wà l’ókè wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Àti pé Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ni pé, oore ayé dúró sórí bí Allāhu ṣe fẹ́ kí ó pọ̀ tó fún ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ ẹ fún. Bí a bá sì gbé e ka orí oore tọ̀run, ó máa túmọ̀ sí pé, ẹ̀san rere àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọ̀run máa pọ̀ jaburata débi pé, àwọn gan-an kò níí mọ ìsírò rẹ̀, bí wọ́n bá gbìyànjú láti ṣe ìṣírò rẹ̀.