2 : 269
يُؤۡتِي ٱلۡحِكۡمَةَ مَن يَشَآءُۚ وَمَن يُؤۡتَ ٱلۡحِكۡمَةَ فَقَدۡ أُوتِيَ خَيۡرٗا كَثِيرٗاۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّآ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní òye ìjìnlẹ̀. Ẹni tí A bá sì fún ní òye ìjìnlẹ̀, A kúkú ti fún un ní oore púpọ̀. Ẹnì kan kò níí lo ìrántí àfi àwọn onílàákàyè.
Explanation & meanings · 1
- Mímọ̀ọ́ṣe àti mímọ̀ọ́sọ ni gbogbo ìtúmọ̀ “hikmah” ń dálé.