2 : 1
الٓمٓ
’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)
Explanation & meanings · 1
- Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ ’Islām máa ń sọ pé irúfẹ́ àwọn lẹ́tà (háràfí) wọ̀nyí dúró fún àwọn ọ̀rọ̀ kan, ohun tí àwọn onímọ̀ ’Islām faramọ́ jùlọ ni pé, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nìkan ṣoṣo l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn harafi náà.