Skip to content
البَقَرَة /

Ẹsẹ 116

2 : 116

Ẹsẹ 116 of البَقَرَة (2 : 116). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

البَقَرَة Àwọn Ẹsẹ 286
2 : 116

وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۖ بَل لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ كُلّٞ لَّهُۥ قَٰنِتُونَ

Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un! Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, (àmọ́) tiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.

Explanation & meanings · 1
  1. Àṣẹ Allāhu lórí ẹ̀dá pín sí ọ̀nà méjì gbòòrò. Ìkíní: ’amr ṣẹr‘iy “àṣẹ tẹ̀sìn” àti ’amr kaoniy “àṣẹ tayé”. Àwọn mọlāika àti àwọn mùsùlùmí nìkan ló ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ méjèèjì. Àmọ́ àṣẹ tayé nìkan ṣoṣo ni àwọn aláìgbàgbọ́ ń tẹ̀lé. Ìyẹn sì ni àṣẹ tí kádàrá bá mú wá. Ìyẹn ni pé, ohun tí Allāhu bá fẹ́ fi ẹ̀dá Rẹ̀ rọ ló máa fi rọ, jíjẹ́ aláìgbàgbọ́ ẹ̀dá náà kò lè dí I lọ́wọ́.