Skip to content
البَقَرَة /

Ẹsẹ 232

2 : 232

Ẹsẹ 232 of البَقَرَة (2 : 232). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

البَقَرَة Àwọn Ẹsẹ 286
2 : 232

وَإِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَبَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا تَعۡضُلُوهُنَّ أَن يَنكِحۡنَ أَزۡوَٰجَهُنَّ إِذَا تَرَٰضَوۡاْ بَيۡنَهُم بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ ذَٰلِكَ يُوعَظُ بِهِۦ مَن كَانَ مِنكُمۡ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۗ ذَٰلِكُمۡ أَزۡكَىٰ لَكُمۡ وَأَطۡهَرُۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ

Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn (padà), nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.

Explanation & meanings · 1
  1. Kókó āyah yìí ni pé, ó ń pàrọwà fún aláṣẹ obìnrin láti fọwọ́ wọ́nú lórí ìkọ̀sílẹ̀ ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ìkọ̀sílẹ̀ ẹ̀ẹ̀ kejì, pé kí ó tún yọ̀ǹda obìnrin tí ó jẹ́ alásẹ fún láti padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ bá ti wọ̀ padà láààrin ọkùnrin àti obìnrin náà.