Skip to content

Olubeere kan n sọ pe: Dajudaju lati igba ti awẹ ti jẹ dandan fun un ti o n gba awẹ Ramadan, ṣugbọn kii san awẹ awọn ọjọ ti o ja awẹ nibẹ tori nǹkan oṣù, torí aimọ onka awọn ọjọ ti o ja awẹ nibẹ ni o fi n beere itọsọna rẹ lọ si nnkan ti ṣíṣe rẹ jẹ dandan fun un nsinyii.

السؤال

Ibeere akọkọ:

Olubeere kan n sọ pe: Dajudaju lati igba ti awẹ ti jẹ dandan fun un ti o n gba awẹ Ramadan, ṣugbọn kii san awẹ awọn ọjọ ti o ja awẹ nibẹ tori nǹkan oṣù, torí aimọ onka awọn ọjọ ti o ja awẹ nibẹ ni o fi n beere itọsọna rẹ lọ si nnkan ti ṣíṣe rẹ jẹ dandan fun un nsinyii.

س30: سائلةٌ تقول: إنها منذ وجب عليها الصّيام وهي تصوم رمضان، ولكنها لا تقضي صيام الأيام التي تفطرها بسبب الدورة الشهرية، ولجهلها بعدد الأيام التي أفطرتها، فهي تطلب إرشادها إلى ما يجب عليها فعله الآن.

الجواب

Idahun akọkọ:

O ṣe wa laanu ki eyi maa ṣẹlẹ laaarin awọn obinrin olugbagbọ, dajudaju gigbe ju silẹ yii- ohun ti mo gba lero ni: Gbigbe sisan nnkan ti o jẹ dandan fun un ninu awẹ ju silẹ- ninu ki o jẹ ni ti aimọkan, tabi ki o jẹ ni ti àìní àkàkún, àdánwò ni mejeeji jẹ; nitori pe aimọkan, iwosan rẹ ni imọ ati ibeere

Ṣugbọn àìní àkàkún, iwosan rẹ ni ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ati ṣíṣe amujuto rẹ, ati ipaya iya Rẹ, ati titete lọ si ibi nnkan ti iyọnu rẹ n bẹ nibẹ

O jẹ dandan fun obinrin yii lati ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun latara nnkan ti o ṣe, ki o si wa aforijin, ki o si ṣe ìwádìí àwọn ọjọ ti o gbe wọn ju silẹ bi o ba ṣe lágbára mọ, yoo si san wọn pada, pẹlu eyi ni ọrùn rẹ yóò fi mọ́, ki Ọlọhun gba ìrònúpìwàdà rẹ.

ﺟ30: يؤسفنا أن يقع مثل هذا بين نساء المؤمنين، فإن هذا الترك -أعني: ترك قضاء ما يجب عليها من الصّيام- إما أن يكون جهلًا، وإما أن يكون تهاونًا، وكلاهما مصيبةٌ؛ لأن الجهل دواؤه العلم والسّؤال،

وأما التهاون فإن دواءه تقوى الله عز وجل، ومراقبته، والخوف من عقابه، والمبادرة إلى ما فيه رضاه.

فعلى هذه المرأة أن تتوب إلى الله مما صنعت، وأن تستغفر، وأن تتحرى الأيام التي تركتها بقدر استطاعتها فتقضيها، وبهذا تبرأ ذمتها، ونرجو أن يقبل الله توبتها.