Skip to content

Njẹ aaye ti a ti n sa safa ati mariwa wa lara Haram? Njẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu maa sunmọ ọn? Njẹ o jẹ dandan fun ẹni ti o ba wọ Haram lati aaye ti a ti n sa safa ati mariwa lati yan nafila Tahiyyatul Masjid?

السؤال

Ibeere akọkọ:

Njẹ aaye ti a ti n sa safa ati mariwa wa lara Haram? Njẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu maa sunmọ ọn? Njẹ o jẹ dandan fun ẹni ti o ba wọ Haram lati aaye ti a ti n sa safa ati mariwa lati yan nafila Tahiyyatul Masjid?

س56: هل المسعى من الحرم؟ وهل تقربه الحائض؟ وهل يجب على من دخل الحرم من المسعى أن يصلّي تحية المسجد؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Eyi ti o han ni pe aaye ti a ti n sa safa ati mariwa ko si ninu mọsalasi; nitori idi eyi ni wọn fi mọ ogiri kan ti o ṣe opinya laaarin mejeeji, ṣugbọn ogiri kekere ni, ko si iyemeji pe oore ni fun awọn eniyan; nitori pe ti wọn ba mu u wọ inu mọsalasi ti wọn fi si ara rẹ, ì bá jẹ eewọ fun obinrin ti o ba ri nnkan oṣu laaarin irọkirika ile Oluwa ati sisa safa ati mariwa lati sa safa ati mariwa.

Ìdájọ́ ti maa ṣe ni pe: Ti o ba ri nnkan oṣu lẹyin irọkirika ile Oluwa ati ṣiwaju sisa safa ati mariwa, yoo sa safa ati mariwa; torí pé aaye ti a ti n sa safa ati mariwa kii ṣe ara mọsalasi.

Ṣugbọn nafila tahiyyatul masjid, a le sọ pe: Dajudaju ti ọmọniyan ba sa safa ati mariwa lẹyin irọkirika ile Oluwa, ti o wa pada si mọsalasi lẹ́yìn náà, yoo ki i, ti o ba si gbe nafila tahiyyatul masjid ju silẹ, ko si ẹṣẹ kankan fun un

Eyi ti o daa julọ ni ki o ṣe amulo anfaani naa, ki o si ki rakah meji; nitori ọla ti o n bẹ fun irun ni aaye yii.

ﺟ56: الّذي يظهر أن المسعى ليس من المسجد، ولذلك جعلوا جدارًا فاصلًا بينهما، لكنه جدارٌ قصيرٌ، ولا شك أن هذا خيرٌ للناس؛ لأنه لو أدخل في المسجد وجعل منه، لكانت المرأة إذا حاضت بين الطواف والسعي امتنع عليها أن تسعى.

والّذي أفتي به: أنها إذا حاضت بعد الطواف وقبل السعي فإنها تسعى؛ لأن المسعى لا يعتبر من المسجد.

وأما تحية المسجد فقد يقال: إن الإنسان إذا سعى بعد الطواف، ثم عاد إلى المسجد، فإنه يصلّيها، ولو ترك تحية المسجد فلا شيء عليه،

والأفضل أن ينتهز الفرصة، ويصلّي ركعتين؛ لـما في الصلاة في هذا المكان من الفضل.