Skip to content

Mo ṣe Hajj, ni mo wa ri nǹkan oṣù, ojú wa n ti mi lati sọ fun èèyàn, mo wa wọ inu Haram, mo si kirun, mo si rọkirika ile Oluwa, mo tun sa safa ati mariwa, ki ni o jẹ dandan fun mi lati ṣe ti o si jẹ pe ẹyin ẹjẹ ìbímọ ni o wa

السؤال

Ibeere akọkọ:

Mo ṣe Hajj, ni mo wa ri nǹkan oṣù, ojú wa n ti mi lati sọ fun èèyàn, mo wa wọ inu Haram, mo si kirun, mo si rọkirika ile Oluwa, mo tun sa safa ati mariwa, ki ni o jẹ dandan fun mi lati ṣe ti o si jẹ pe ẹyin ẹjẹ ìbímọ ni o wa

س57: حججت، وجاءتني الدورة الشهرية، فاستحييت أن أخبر أحدًا، ودخلت الحرم، فصليت، وطفت، وسعيت، فماذا علي، علمًا بأنها جاءت بعد النّفاس؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Ko lẹtọọ fun obinrin ti o ba n ṣe nnkan oṣu tabi ti ẹjẹ ibimọ ba n da lara rẹ lati kirun, boya ni Makkah ni tabi ni ilu rẹ tabi ni ibikíbi.

Fun ọrọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ nipa obinrin pe: “Ṣe kii ṣe pe ti o ba ṣe nnkan oṣu ko nii kirun, ko si nii gba awẹ ni?”.

Àwọn Musulumi ti fi ẹnu ko lori pe ko lẹtọọ fun ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu lati gba awẹ, ko si lẹtọọ fun un lati kirun

O jẹ dandan fun obinrin yii ti o ṣe iyẹn, lati ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun, ki o si wa aforijin nibi nnkan ti o waye lati ọwọ́ rẹ

Ṣugbọn irọkirika ile Oluwa rẹ ni asiko ti n ṣe nnkan oṣu ko ni alaafia, ṣugbọn sisa safa ati mariwa rẹ ni alaafia; nitori pe ọrọ ti o tẹsuwọn julọ ni pe a le sa safa ati mariwa ṣiwaju tawaafu ti hajj, lori eyi, o jẹ dandan fun un lati da irọkirika ile Oluwa pada; torí pe irọkirika ile Oluwa ti ifaadọ jẹ origun kan ninu origun Hajj, ti a ko le bọra sílẹ̀ ni ti ikeji àyàfi pẹ̀lú rẹ.

Ti o ba ri bẹẹ, obinrin yii, ọkọ rẹ ko nii sunmọ ọn- ti o ba jẹ ẹni ti o ni ọkọ- titi ti yoo fi rọkirika ile Oluwa, wọn ko si nii ta kókó ìgbéyàwó rẹ- ti ko ba tii ni ọkọ- titi ti yoo fi rọkirika ile Oluwa, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni O ni imọ ju lọ

ﺟ57: لا يحلّ للمرأة إذا كانت حائضًا أو نفساء أن تصلّي، سواء في مكة أو في بلدها أو في أيّ مكانٍ؛ لقول النبيّ ﷺ في المرأة:

«أَلَيْسَ إِذَا حَاضَتْ لَمْ تُصَلِّ، وَلَمْ تَصُمْ؟» [1]،

وقد أجمع المسلمون على أنه لا يحلّ لحائضٍ أن تصوم، ولا يحلّ لها أن تصلّي.

[28] تقدم تخريجه.

وعلى هذه المرأة التي فعلت ذلك، عليها أن تتوب إلى الله، وأن تستغفر ممّا وقع منها.

وأما طوافها حال الحيض فهو غير صحيحٍ، وأما سعيها فصحيحٌ؛ لأن القول الراجح جواز تقديم السعي على الطواف في الحجّ، وعلى هذا فيجب عليها أن تعيد الطواف؛ لأن طواف الإفاضة ركنٌ من أركان الحجّ، ولا يتمّ التحلّل الثاني إلا به.

وبناءً عليه فإن هذه المرأة لا يباشرها زوجها -إن كانت متزوّجةً- حتى تطوف، ولا يعقد عليها النّكاح -إن كانت غير متزوّجةٍ- حتى تطوف، والله تعالى أعلم.