Skip to content

Mo wa lati Yanbuh fun Umrah emi ati ìyàwó mi, ṣugbọn nigba ti mo de Jeddah, iyawo mi ri nnkan oṣu, ṣugbọn mo pari Umrah ni emi nikan yatọ si iyawo mi, ki ni idajọ nipa ti iyawo mi?

السؤال

Ibeere akọkọ:

Mo wa lati Yanbuh fun Umrah emi ati ìyàwó mi, ṣugbọn nigba ti mo de Jeddah, iyawo mi ri nnkan oṣu, ṣugbọn mo pari Umrah ni emi nikan yatọ si iyawo mi, ki ni idajọ nipa ti iyawo mi?

س55: لقد قدمت من ينبع للعمرة أنا وأهلي، ولكن حين وصولي إلى جدة أصبحت زوجتي حائضًا، ولكنّي أكملت العمرة بمفردي دون زوجتي، فما الحكم بالنّسبة لزوجتي؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Idajọ nipa iyawo rẹ ni pe: Yoo ṣe suuru titi ti yóò fi mọ, lẹyin yoo ṣe Umrah rẹ;

Nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti Sofiyyah- ki Ọlọhun yọnu si i- ri nǹkan oṣù, o sọ pe: “Ṣe oun ni o maa da wa duro ni? Wọn sọ pe: O ti ṣe tawaaful ifaadọ. O sọ pe: “Ti o ba ri bẹ́ẹ̀, ki o maa lọ”

Ọrọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: “Ṣe oun ni o maa da wa duro ni? Jẹ ẹri lori pe o jẹ dandan fun obinrin lati duro- ti o ba ri nnkan oṣu ṣiwaju tawaaful ifaadọ- titi ti yoo fi mọ, lẹyin naa yoo rọkirika ile Oluwa

Gẹgẹ bẹẹ naa ni irọkirika ile Oluwa ti Umrah, oun naa da gẹgẹ bii irọkirika ile Oluwa ti ifaadọ; nitori pe o jẹ origun kan ninu Umrah, ti ẹni ti o n ṣe Umrah ba ri nnkan oṣu ṣiwaju irọkirika ile Oluwa, yoo ṣe suuru titi ti yoo fi mọ, lẹyin naa yoo rọkirika ile Oluwa

ﺟ55: الحكم بالنّسبة لزوجتك: أن تبقى حتى تطهر، ثم تقضي عمرتها؛ لأن النبي ﷺ لـما حاضت صفية رضي الله عنها قال:

«أَحَابِسَتُنَا هِيَ؟» قَالُوا: إِنَّهَا قَدْ أَفَاضَتْ. قَالَ: «فَلْتَنْفِرْ إِذًا» [1]،

فقوله ﷺ: «أحابستنا هي؟» دليلٌ على أنه يجب على المرأة أن تبقى -إذا حاضت قبل طواف الإفاضة- حتى تطهر، ثمّ تطوف.

[27] تقدم تخريجه.

وكذلك طواف العمرة مثل طواف الإفاضة؛ لأنه ركنٌ من العمرة، فإذا حاضت المعتمرة قبل الطواف انتظرت حتى تطهر، ثم تطوف.