Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu tabi ti ẹjẹ ìbímọ n da lara rẹ ba mọ ni asiko Asr, njẹ irun Zuhr pẹlu Asr jẹ dandan fun un, tabi nnkankan ko jẹ dandan fun un yatọ si irun Asr nikan?
السؤال
Ibeere akọkọ:
Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu tabi ti ẹjẹ ìbímọ n da lara rẹ ba mọ ni asiko Asr, njẹ irun Zuhr pẹlu Asr jẹ dandan fun un, tabi nnkankan ko jẹ dandan fun un yatọ si irun Asr nikan?
س12: إذا طهرت الحائض أو النّفساء وقت العصر، فهل تلزمها صلاة الظّهر مع العصر، أو لا يلزمها سوى العصر فقط؟
الجواب
Idahun akọkọ:
Eyi ti o tẹsuwọn julọ nibi ọ̀rọ̀ yii ni pe: Nǹkan kan ko jẹ dandan fun un yatọ si irun Asr nikan; nitori pe ko si ẹri kankan lori jijẹ dandan irun Zuhr, ati pe ipilẹ ni ki ọrùn ó mọ́, lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Ẹnikẹni ti o ba ba rakaa kan ninu Asr ṣiwaju ki oòrùn to wọ, o ti ba Asr”.
Ko sọ pe o ba Zuhr, ti o ba ṣe pe Zuhr jẹ dandan ni, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko ba ṣe alaye rẹ, ati pe nitori pe obinrin ti o ba ṣe nnkan oṣu lẹyin wiwọle asiko Zuhr, nnkankan ko jẹ dandan fun un afi sisan irun Zuhr yatọ si irun Asr, bi o ti lẹ jẹ pe wọn maa n da Zuhr pọ mọ Asr, ko si si iyatọ laaarin rẹ ati laaarin aworan ti ibeere waye lori rẹ
Lori eyi, ọrọ ti o tẹsuwọn julọ maa jẹ pe irun Asr nikan ni o maa jẹ dandan fun un; fun itọka ọrọ Ọlọhun ati ìfiwéra, gẹgẹ bẹẹ ni ọrọ naa ṣe ri ti o ba mọra ṣiwaju wiwọle asiko 'Ishai, ko si nnkankan ti o jẹ dandan fun un afi 'Ishai, ti irun Magrib ko si jẹ dandan fun un
ﺟ12: القول الراجح في هذه المسألة: أنه لا يلزمها إلا العصر فقط؛ لأنه لا دليل على وجوب صلاة الظّهر، والأصل براءة الذّمة، ثم إن النبي ﷺ قال:
«مَنْ أَدْرَكَ رَكْعَةً مِنَ الْعَصْرِ قَبْلَ أَنْ تَغْرُبَ الشَّمْسُ فَقَدْ أَدْرَكَ الْعَصْرَ» [1]،
ولم يذكر أنه أدرك الظّهر، ولو كان الظّهر واجبًا لبينه النبيّ ﷺ، ولأن المرأة لو حاضت بعد دخول وقت الظّهر لم يلزمها إلا قضاء صلاة الظّهر دون صلاة العصر، مع أن الظّهر تجمع إلى العصر، ولا فرق بينها وبين الصّورة التي وقع السّؤال عنها.
[2] البخاري، كتاب الصوم، باب الحائض تترك الصوم والصلاة (1951).
وعلى هذا يكون القول الراجح أنه لا يلزمها إلا صلاة العصر فقط؛ لدلالة النصّ والقياس عليها، وكذلك الشأن فيما لو طهرت قبل خروج وقت العشاء، فإنه لا يلزمها إلا صلاة العشاء، ولا تلزمها صلاة المغرب.