Skip to content

«Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ».

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

«Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ».

«إذا قُلْتَ لِصَاحِبِكَ: أَنْصِتْ، يومَ الجمعةِ، والْإِمامُ يَخْطُبُ، فَقَدْ لَغَوْتَ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju ninu awọn ẹkọ ti o jẹ dandan fun ẹni ti o ba wa gbọ khutuba jimọ ni: Didakẹ jẹjẹ fun ẹni ti n ṣe khutuba; lati le ba maa ronu si awọn iṣiti yẹn, ati pe dajudaju ẹni ti o ba sọrọ - koda ko jẹ ọrọ diẹ - ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, ti o wa sọ fun ẹni ti o yatọ si i pe: "Dakẹ" ki o si tun "tẹti", ọla irun jimọ ti bọ fun un.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

أَنْصِتْ: اسكت عن الكلام.

لَغَوْتَ: لغا أتى بقول ساقط، ليس فيه فائدة.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ṣiṣe ọrọ sisọ ni eewọ ni asiko ti a ba n gbọ khutuba, koda ki o jẹ pẹlu kikọ kuro nibi ibajẹ tabi didahun salamọ ati ṣíṣe adua fún ẹni ti o ba sin.

Wọn ṣe ayaafi nibi eleyii ẹni ti o ba n ba imaamu sọrọ tabi ẹni ti imaamu ba n ba sọrọ.

Lilẹtọọ ọrọ sisọ laarin khutuba mejeeji ti a ba bukaata si i.

Ti wọn ba darukọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, dajudaju waa tọrọ ikẹ ati ọla fun un ni jẹ́jẹ́, bakannaa ni ṣiṣe aamiin si adua.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (2/ 13) (934).

Tira Sọhiihu ti Muslim (2/ 583) (851).

Àlékún (10)

تيسير العلام شرح عمدة الأحكام.

للبسام (ص244).

تنبيه الأفهام.

للعثيمين (2/ 307).

الإلمام بشرح عمدة الأحكام.

لإسماعيل الأنصاري (1/ 195).

فتح الباري.

لابن حجر (2/ 409).

تاج العروس من جواهر القاموس.

لمحمّد الحسيني الزَّبيدي (39/ 463).