“Gbogbo dáadáa sàárà ni”.
Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Gbogbo dáadáa sàárà ni”.
«كُلُّ مَعْرُوفٍ صَدَقَةٌ».
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo dáadáa ati àǹfààní fun ẹlòmíràn, bóyá ọrọ ni tabi iṣẹ, o maa jẹ sàárà, ẹ̀san si n bẹ nibẹ.
معروف : المعروف اسم جامع لكل ما فيه نفع للآخرين من قول أو فعل.
Sàárà kò mọ lori nǹkan ti èèyàn n yọ jáde ninu dúkìá, bi ko ṣe pe o ko gbogbo oore ti ọmọniyan n ṣe tàbí sọ sínú, ti o si maa de ọdọ ẹlòmíràn.
O n bẹ nibẹ isẹnilojukokoro lati maa ṣe dáadáa ati gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun ẹlòmíràn.
Ki èèyàn ma fi ojú kere dáadáa kankan, kódà ki o kéré.
Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (8/ 11) (6021).
Tira Sọhiihu ti Muslim (2/ 697) (1005).
Àlékún (4)
منحة العلام في شرح بلوغ المرام.
لعبد الله الفوزان (10/ 117).
توضيح الأحكام من بلوغ المرام.
للبسام (7/ 341).