Skip to content

Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu tabi ti ẹjẹ ìbímọ n da lara rẹ ba mọ ṣiwaju alufajari, ti ko ba wẹ afi lẹyin alufajari, njẹ awẹ rẹ ni alaafia tabi ko ni?

السؤال

Ibeere akọkọ:

Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu tabi ti ẹjẹ ìbímọ n da lara rẹ ba mọ ṣiwaju alufajari, ti ko ba wẹ afi lẹyin alufajari, njẹ awẹ rẹ ni alaafia tabi ko ni?

س7: إذا طهرت الحائض أو النّفساء قبل الفجر، ولم تغتسل إلا بعد الفجر، فهل يصحّ صومها، أو لا؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Bẹẹni, awẹ obinrin ti o n ṣe nnkan oṣu ni alaafia ti o ba mọ ṣiwaju alufajari, ti ko wẹ afi lẹyin yiyọ alufajari, gẹgẹ bẹẹ naa ni ẹni ti ẹjẹ ìbímọ n da lara rẹ; nitori pe nígbà naa o wa ninu awọn alaawẹ, o jọ ẹni ti janaba wa ni ara rẹ, ti alufajari ba yọ ti o si jẹ oni janaba lara, dajudaju awẹ rẹ ni alaafia;

Fun ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe: {Ní báyìí, ẹ súnmọ́ wọn, kí ẹ sì wá ohun tí Allāhu kọ mọ yín (ní ọmọ). Ẹ jẹ, ẹ mu títí ẹ ó fi rí ìyàtọ̀ láààrin òwú funfun (ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀) àti òwú dúdú (ìyẹn, òkùnkùn òru) ní àfẹ̀mọ́júmọ́}[Surah Al-Baqarah: 187]

Nigba ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe iyọnda ibalopọ titi ti alufajari o fi han, o jẹ dandan nibi ìyẹn ki iwẹ ma waye afi lẹyin yiyọ alufajari, fun hadisi 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- pé Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ji ni oni janaba lara latara ibalopọ awọn ara ile rẹ ti o si n gba awẹ

Ìtumọ̀ rẹ ni pé: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko nii wẹ latara janaba afi lẹyin yiyọ owurọ.

ﺟ7: نعم، يصحّ صوم المرأة الحائض إذا طهرت قبل الفجر، ولم تغتسل إلا بعد طلوع الفجر، وكذلك النّفساء؛ لأنها حينئذٍ من أهل الصوم، وهي شبيهةٌ بمن عليه جنابةٌ، إذا طلع الفجر وهو جنبٌ فإن صومه يصحّ؛ لقوله تعالى:

﴿...فَٱلۡـَٰٔنَ بَٰشِرُوهُنَّ وَٱبۡتَغُواْ مَا كَتَبَ ٱللَّهُ لَكُمۡۚ وَكُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكُمُ ٱلۡخَيۡطُ ٱلۡأَبۡيَضُ مِنَ ٱلۡخَيۡطِ ٱلۡأَسۡوَدِ مِنَ ٱلۡفَجۡرِ...﴾

[البقرة:187]،

وإذا أذن الله تعالى بالجماع إلى أن يتبين الفجر لزم من ذلك ألّا يكون الاغتسال إلا بعد طلوع الفجر، ولحديث عائشة رضي الله عنها

«أَنَّ النَّبِيَّ ﷺ كَانَ يُصْبِحُ جُنُبًا مِنْ جِمَاعِ أَهْلِهِ وَهُوَ صَائِمٌ» [1].

أي: أنه عليه الصلاة والسلام لا يغتسل عن الجنابة إلا بعد طلوع الصّبح.

[1] البخاري، كتاب الصوم، باب اغتسال الصائم (1931)، ومسلم، كتاب الصوم، باب صحة صوم من طلع عليه الفجر وهو جنب (75) (1109).