Skip to content

Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ba mọra, ti o wẹ lẹyin irun alufajari, ti o ki run, ti o pari awẹ ọjọ rẹ, njẹ idapada rẹ jẹ dandan fun un?

السؤال

Ibeere akọkọ:

Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ba mọra, ti o wẹ lẹyin irun alufajari, ti o ki run, ti o pari awẹ ọjọ rẹ, njẹ idapada rẹ jẹ dandan fun un?

س2: إذا طهرت الحائض، واغتسلت بعد صلاة الفجر، وصلت، وكملت صوم يومها، فهل يجب عليها قضاؤه؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Ti ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ba mọra ṣiwaju yiyọ alufajari koda ko ṣe pe pẹlu iṣẹju kan, ṣugbọn o ni amọdaju nipa imọra, ti o ba jẹ inu Ramadan, dandan ni fun un ki o gba awẹ, awẹ rẹ ni ọjọ yẹn yoo ni alaafia, ti idapada rẹ ko nii jẹ dandan fun un; nitori pe o gba awẹ nigba ti o wa ni mimọ, koda ki o ma wẹ afi lẹyin yiyọ alufajari, ko si ẹṣẹ nibẹ

Gẹgẹ bi o ṣe jẹ pe ti ọkùnrin ba jẹ oni janaba lara latara ibalopọ tabi ala, ti o wa jẹ saari, ti ko wẹ afi lẹyin yiyọ alufajari, awẹ rẹ ni alaafia

Pẹlu ibamu yii, mo fẹ lati pe yin si akiyesi si alamọri mìíràn kan lọdọ awọn obìnrin ti ẹjẹ nnkan oṣu ba yọ si i ti o si ti gba awẹ ọjọ yẹn, apakan ninu awọn obinrin maa n lérò pe ti ẹjẹ nnkan oṣu ba yọ si i lẹyin ti o ba ṣinu ṣiwaju ki o to ki irun Ishai pe awẹ rẹ ọjọ yẹn ti bajẹ

Èyí ko si ẹri fun un, bi ko ṣe pe ẹjẹ nnkan oṣu ti o ba yọ si i lẹyin wiwọ oòrùn, koda ko ṣe pe pẹlu iṣẹju aaya, dajudaju awẹ rẹ pe o si ni alaafia

ﺟ2: إذا طهرت الحائض قبل طلوع الفجر ولو بدقيقةٍ واحدةٍ، ولكن تيقنت الطّهر، فإنه إذا كان في رمضان فإنه يلزمها الصوم، ويكون صومها ذلك اليوم صحيحًا، ولا يلزمها قضاؤه؛ لأنها صامت وهي طاهرٌ، وإن لم تغتسل إلا بعد طلوع الفجر فلا حرج،

كما أن الرجل لو كان جنبًا من جماعٍ أو احتلامٍ، وتسحر، ولم يغتسل إلا بعد طلوع الفجر، كان صومه صحيحًا.

وبهذه المناسبة أودّ أن أنبّه إلى أمرٍ آخر عند النّساء إذا أتاها الحيض وهي قد صامت ذلك اليوم، فإن بعض النّساء تظنّ أن الحيض إذا أتاها بعد فطرها قبل أن تصلّي العشاء فسد صوم ذلك اليوم،

وهذا لا أصل له، بل إن الحيض إذا أتاها بعد الغروب ولو بلحظةٍ فإن صومها تامٌّ وصحيحٌ.