Skip to content

"Dajudaju ẹ ma maa tẹle oju ọna awọn ti wọn ṣáájú yin, ni odiwọn ìbú atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

"Dajudaju ẹ ma maa tẹle oju ọna awọn ti wọn ṣáájú yin, ni odiwọn ìbú atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa, koda ki wọn wọnu isa agilinti ẹ maa tẹle wọn" a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, awọn Juu ati Nasara àbí? O sọ pe: "Taa waa tún ni?".

«لَتَتَّبِعُنَّ سَنَنَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ، شِبْرًا بِشِبْرٍ، وَذِرَاعًا بِذِرَاعٍ، حَتَّى لَوْ دَخَلُوا فِي جُحْرِ ضَبٍّ لَاتَّبَعْتُمُوهُمْ» قُلْنَا: يَا رَسُولَ اللهِ آلْيَهُودَ وَالنَّصَارَى؟ قَالَ: «فَمَنْ؟».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n fun wa ni iro nipa nnkan ti isesi awọn kan ninu ìjọ rẹ maa wa lori rẹ lẹyin ti o ba lọ tan, oun ni itẹle oju ọna Juu ati Nasara nibi awọn adisọkan wọn ati awọn iṣe wọn ati awọn àṣà wọn ni itẹle kan ti o péye ti o lágbára ni odiwọn ibu atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa, koda ki wọn wọnu isa agilinti awọn wọnyii maa wọle lẹyin wọn.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

قال فمن؟: استفهامٌ إنكاريٌّ أي: فمن هم غيرُ أولئك.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ami kan ninu awọn ami ijẹ anabi rẹ nigba ti o sọ fun wa nipa ìyẹn ṣíwájú ki o to ṣẹlẹ̀ ti o si ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi o ṣe sọ.

Kikọ kuro nibi ki Mùsùlùmí máa fara wé awọn alaigbagbọ, boya nibi awọn adisọkan wọn ni tabi ìjọsìn wọn, tabi awọn ọdun wọn tabi awọn aṣọ wọn ti a mọ̀ mọ̀ wọn.

Alaye awọn nnkan ti a ko le ni imọlara rẹ pẹlu awọn apejuwe ti a le ni imọlara rẹ wa ninu awọn ọna ikọnilẹkọọ ninu Isilaamu.

Agilinti ni: Ẹranko kan ti isa rẹ ṣókùnkùn gan-an ti oorun rẹ buru jàì, o wa nínú awọn ẹranko afayafa, o pọ ni awọn aṣálẹ̀, ìdí ti wọn fi dárúkọ ihò agilinti ni: “Bí o ṣe há gan-an àti pé kò dára, síbẹ̀, nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé oripa wọn, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ọ̀nà wọn, bí wọ́n bá wọ irú ibi tó há gan-an tó sì jẹ́ ibi tí kò dára bẹ́ẹ̀, wọ́n á gbà pẹ̀lú wọn! Ọlọhun sì ni Ẹni tí a ń bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (9/ 103) (7320).

Tira Sọhiihu ti Muslim (4/ 2054) (2669).

Àlékún (4)

الجديد في شرح كتاب التوحيد.

لمحمد القرعاوي (ص213).

الملخص في شرح كتاب التوحيد.

لصالح الفوزان (ص193).