Skip to content

«Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ».

Lati ọdọ Abu Sa‘ēd Al-khudriyy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

«Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ».

«إِذَا سَمِعْتُمُ النِّدَاءَ، فَقُولُوا مِثْلَ مَا يَقُولُ المُؤَذِّنُ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣeni lojukokoro lori jijẹ ipe oluperun nigba ti a ba n gbọ ọ, ati pe ìyẹn ni ki a maa sọ nkan ti o n sọ, ni gbolohun gbolohun. Nigba ti o ba wa sọ gbolohun Allāh Akbar àwa naa o wi i lẹyin rẹ, ati pe nigba ti o ba mu gbolohun ijẹrii mejeeji wa, awa naa o mu un wa lẹ́yìn rẹ, Ati pe wọn ṣe ayaafi gbolohun: (Hayya ‘alas sọlāt, Hayya ‘alal falāh) wọn maa sọ lẹyin awọn mejeeji pe: lā haola walā quwwata illā biLlāh.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Yio maa tẹle oluperun keji lẹyin ti alakọkọọ ba pari, koda ki awọn oluperun o pọ! Latari kikari hadīth yii.

Yio maa jẹ ipe oluperun (yio maa sọ nkan ti o ba n sọ) ni gbogbo iṣesi rẹ, ti ko ba ti si ni ile ẹgbin tabi lori bukaata rẹ (itọ tabi igbẹ).

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 126) (611).

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 288) (383).

Àlékún (4)

تيسير العلام شرح عمدة الأحكام.

للبسام (ص120).

الإلمام بشرح عمدة الأحكام.

لإسماعيل الأنصاري (1/ 98).