Skip to content

“Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”.

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:

“Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”.

«تَعَاهَدُوا هَذَا الْقُرْآنَ، فَوَالَّذِي نَفْسُ مُحَمَّدٍ بِيَدِهِ لَهُوَ أَشَدُّ تَفَلُّتًا مِنَ الْإِبِلِ فِي عُقُلِهَا».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ ki a maa ka Kuraani nígbà gbogbo, ki a si maa tẹra mọ́ kika a ki èèyàn ma baa gbagbe rẹ lẹyin híhá a, o wa tẹnu mọ́ ọn pẹ̀lú ìbúra pe Kuraani yára kuro ninu àyà ju rakunmi ti a so lọ, oun naa ni eyi ti a fi okùn dè ni aarin ẹsẹ, ti eeyan ba n ka a nígbà gbogbo, o maa di i mu, ti o ba si tu u sílẹ̀, o maa lọ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ti ẹni tí ó ha Kuraani ba tẹra mọ kika rẹ léraléra o maa wa ni hiha ninu ọkan rẹ, bi bẹẹ kọ yoo lọ ti yoo si gbagbe rẹ.

Lara anfaani kika Kuraani nígbà gbogbo ni: Ẹ̀san, ati igbega ni ipò ni Ọjọ́ Àjíǹde.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 545) (791).

Àlékún (7)

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

تأليف سليم الهلالي (2/ 231).

رياض الصالحين من كلام سيد المرسلين (ص299) (1002).

شرح رياض الصالحين.

للشيخ محمد بن صالح العثيمين (4/ 657).

كنوز رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (13/ 5).