Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

15 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè} [Aal Imraan: 7]. O sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ti o ba ti ri awọn ti n tẹle ohun ti o ruju ninu ẹ, àwọn ti Ọlọhun sọ nìyẹn, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pé: Mo pin irun laaarin Mi ati ẹru Mi si meji ọgbọọgba, ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere o maa jẹ tirẹ, ti ẹru Mi ba sọ pe: (Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi dupẹ fun mi, ti o ba sọ pe: (Ar-Rahmaanir-Raheem), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi yin Mi, ti o ba sọ pe: (Maaliki Yawmid-Deen), O maa sọ pé: Ẹru Mi gbe Mi tobi, -O tun maa sọ nígbà miran pe: Ẹru mi fi ọrọ rẹ le Mi lọwọ-, ti o ba sọ pe: (Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een), O maa sọ pe: Eleyii wa laaarin Mi ati ẹrú Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ, ti o ba wa sọ pe: (Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem, Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen), O maa sọ pe: Eleyii jẹ ti ẹru Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ".
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ.
O ni alaafia Baba Daud ni o gba a wa
“Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Dajudaju awọn eeyan kan ninu awọn ẹlẹbọ (awọn ti wọn mu orogun mọ Ọlọhun), ti wọn si pa ọpọlọpọ eeyan, ti wọn tun ti ṣe ọpọlọpọ agbere, ni wọn wa ba Muhammad – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni wọn wa sọ fun un pe: Dajudaju nkan ti o n sọ ti o si n pepe si, nkan ti o daa ni, ti o ba fun wa niroo pe aforijin n bẹ fun nkan ti a ṣe, nigba naa ni o sọkalẹ pe {(Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā}[Al-Furqān: 68], o tun sọkalẹ pe: {Sọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu}[Az-Zumar: 53].
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ, ìyẹn ni igba ti: (ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà)) Al-An’am, Ayah 158. Alukiyaamọ maa tó, ti ọkùnrin meji si ti tẹ aṣọ silẹ láàrin ara wọn, wọn ko si nii lee ta ọjà fun ara wọn bẹẹ ni wo ko si nii lee ka a padà, alukiyaamọ maa tó, ti èèyàn si ti bu wàrà ràkúnmí rẹ lọ ti ko si nii le mu u, alukiyaamọ maa tó, ti ó sì ti tún àmù omi rẹ ṣe, ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ mu nínú ẹ, alukiyaamọ maa tó, ti ẹnìkan nínú yin si ti gbe oúnjẹ rẹ sí ẹnu, ko si nii lee jẹ ẹ”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ. O sọ pe: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
“Wọn maa mu ikú wá ni ìrísí àgbò ti o ni dúdú ati funfun lára, olupepe kan maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, wọn maa garùn wọn si maa wò, yoo wa sọ pé: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, lẹyin naa o maa pe pe: Ẹyin ọmọ iná, wọ́n maa garùn wọ́n sì maa wò, o maa waa sọ pe: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, wọn maa du u, lẹyin naa o maa sọ pé: Ẹyin ọmọ alujanna, gbére, ko si ikú mọ, ẹyin ọmọ iná, gbére, ko si ikú mọ, lẹyin naa ni o ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná} [Maryam: 39], àwọn wọ̀nyí wa ninu igbagbera ni àwọn ará ayé, {wọn kò sì gbàgbọ́} [Maryam: 30]”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni