Ti obinrin ba ri ẹjẹ kan ni asiko nnkan oṣu rẹ ni ọjọ kan, ti ko wa ri ẹjẹ ni ọjọ ti o tẹle e ni gbogbo ọsan, ki ni o jẹ dandan fun un lati ṣe?
السؤال
Ibeere akọkọ:
Ti obinrin ba ri ẹjẹ kan ni asiko nnkan oṣu rẹ ni ọjọ kan, ti ko wa ri ẹjẹ ni ọjọ ti o tẹle e ni gbogbo ọsan, ki ni o jẹ dandan fun un lati ṣe?
س15: إذا رأت المرأة في زمن عادتها يومًا دمًا، والذي يليه لا ترى الدم طيلة النهار، فماذا عليها أن تفعل؟
الجواب
Idahun akọkọ:
Eyi ti o han ni pe mimọ yii tabi gbígbẹ ti o ṣẹlẹ si i ni awọn ọjọ nnkan oṣu rẹ maa tẹle nnkan oṣu ni, a ko nii ka a si mimọ, lori eyi yoo wa ni ẹni tí yoo jáwọ́ kúrò nibi gbogbo nǹkan ti ẹni tí ń ṣe nǹkan oṣù kò gbọ́dọ̀ ṣe.
Awọn apakan ninu awọn onimimọ sọ pe: Ẹni ti o ba ri ẹjẹ ni ọjọ kan, ti o ri mimọ ni ọjọ miiran, ẹjẹ náà maa jẹ ẹjẹ nnkan oṣu, mimọ naa si maa jẹ imọra titi yoo fi pe ọjọ marundinlogun,
Ti o ba ti pe ọjọ marudinlogun, nnkan ti o ba wa lẹyin rẹ ti di ẹjẹ awaada, eleyii ni nnkan ti o gbajugbaja ninu oju ọna Imam Ahmad ọmọ Hanbal- ki Ọlọhun kẹ ẹ-
ﺟ15: الظاهر أن هذا الطّهر أو اليبوسة التي حصلت لها في أيام حيضها تابعٌ للحيض، فلا يعتبر طهرًا، وعلى هذا فتبقى ممتنعةً ممّا تمتنع منه الحائض.
وقال بعض أهل العلم: من كانت ترى يومًا دمًا، ويومًا نقاءً، فالدم حيضٌ، والنقاء طهرٌ حتى يصل إلى خمسة عشر يومًا،
فإذا وصل إلى خمسة عشر يومًا صار ما بعده دم استحاضةٍ. وهذا هو المشهور من مذهب الإمام أحمد بن حنبلٍ رحمه الله.