Skip to content

(Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem)

Lati ọdọ Az-Zubair ọmọ Al-Awwaam, o sọ pe:

Nigba ti (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) sọkalẹ (At-Takathur: 8), Az-Zubair sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ, dajudaju mejeeji ni dudu meji, eso dabinu ati omi? O sọ pe: “Oun naa ni o maa jẹ”.

لَمَّا نَزَلَتْ: {ثُمَّ لَتُسْأَلُنَّ يَوْمَئِذٍ عَنِ النَّعِيمِ} [التكاثر: 8]، قَالَ الزُّبَيْرُ: يَا رَسُولَ اللهِ، وَأَيُّ النَّعِيمِ نُسْأَلُ عَنْهُ، وَإِنَّمَا هُمَا الْأَسْوَدَانِ التَّمْرُ وَالْمَاءُ؟ قَالَ: «أَمَا إِنَّهُ سَيَكُونُ».

Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ni ọ gba a wa
O daa
Àlàyé

Nigba ti ayah sọkalẹ: (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) o n túmọ̀ si pe: Wọn maa pada beere lọwọ wọn nipa idupẹ lori nnkan ti Ọlọhun ṣe ni idẹra le wọn lori ninu awọn idẹra, Az-Zubair ọmọ Al-‘Awwam- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ? Dajudaju idẹra mejeeji ko kii ṣe nnkan ti wọn le bukaata si ibeere ati pe mejeeji ni eso dabinu ati omi! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: Dajudaju wọn maa bi yin leere nipa idẹra pẹlu isẹsi yii ti ẹ wa nibẹ yìí, nitori pe mejeeji jẹ idẹra nla meji ninu awọn idẹra Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ikanpamọ idupẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn idẹra.

Idẹra, ninu nǹkan ti wọn maa bèèrè nipa rẹ lọ́wọ́ ẹrú ni Ọjọ́ Àjíǹde ni, o kéré ni tabi o pọ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sunanu ti Tirmidhiy (5/ 375) (3356).

Tira Sunanu ti Ọmọ Maajah (5/ 262) (4158).

Àlékún (3)

شرح سنن ابن ماجه للسيوطي (ص: 307).

تحفة الأحوذي (9/203).

مرشد ذوي الحجا والحاجة إلى سنن ابن ماجه والقول المكتفى على سنن المصطفى (25/ 251).