Skip to content

“Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pé o maa kú si ilẹ̀ kan, O maa jẹ ki o ni bukaata si i.”

Láti ọ̀dọ̀ Matọr ọmọ Ukaamis- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

“Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pé o maa kú si ilẹ̀ kan, O maa jẹ ki o ni bukaata si i.”

«إِذَا قَضَى اللَّهُ لِعَبْدٍ أَنْ يَمُوتَ بِأَرْضٍ جَعَلَ لَهُ إِلَيْهَا حَاجَةً».

Tirmisiy ni o gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pe ki o kú sí ilẹ̀ kan ti ko si si nibẹ; O maa jẹ ki o ni bukaata si i, yoo waa wa si ibẹ, wọn si maa gba ẹ̀mí rẹ nibẹ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Hadiisi naa n jẹrii si òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ti O sọ pe: {Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí}.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sunanu ti Tirmidhiy (4/ 23) (2146).

Àlékún (1)

تحفة الأحوذي (6/ 299).