«Ẹnikẹni ninu yin o gbọdọ fi ọwọ ọtun rẹ mu nkan ọmọkunrin rẹ nigba ti o ba n tọ, ko si gbọdọ fi ọwọ rẹ ọtun ṣe imọra nibi igbọnsẹ, ko si gbọdọ fẹ atẹgun si inu ife imumi».
Lati ọdọ Abu Qatāda- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ẹnikẹni ninu yin o gbọdọ fi ọwọ ọtun rẹ mu nkan ọmọkunrin rẹ nigba ti o ba n tọ, ko si gbọdọ fi ọwọ rẹ ọtun ṣe imọra nibi igbọnsẹ, ko si gbọdọ fẹ atẹgun si inu ife imumi».
«لَا يُمْسِكَنَّ أَحَدُكُمْ ذَكَرَهُ بِيَمِينِهِ وَهُوَ يَبُولُ، وَلَا يَتَمَسَّحْ مِنَ الْخَلَاءِ بِيَمِينِهِ، وَلَا يَتَنَفَّسْ فِي الْإِنَاءِ».
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn ẹkọ kan; nigba ti o kọ ki ọkunrin fi ọwọ ọtun rẹ gba oko re mu nigba ti o ba n tọ, ati lati mu ẹgbin kuro niwaju tabi ẹyin pẹlu ọwọ rẹ ọtun; nitori pe ọwọ ọtun wọn pese rẹ fun awọn iṣẹ rere ni, Gẹgẹ bi o ṣe kọ fun ọmọniyan lati mi sinu igba ti o fẹ mu nibẹ.
Alaye gbigba iwaju Isilaamu ninu awọn ẹkọ ati imọtoto.
Jijina si awọn nnkan ìdọ̀tí, ti ko ba wa si ibuyẹ afi ki o ṣe e, ki o yaa jẹ pẹlu ọwọ osi.
Alaye iyi ti o n bẹ fun ọwọ ọtun ati ọla ti o n bẹ fun un lori ọwọ osi.
Pipe Sharia Isilaamu ati kikun awọn ẹkọ rẹ.
Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 42) (154).
Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 225) (267).
Àlékún (4)
تيسير العلام شرح عمدة الأحكام.
للبسام (ص41).
تنبيه الأفهام شرح عمدة الأحكام.
لابن عثيمين (1/ 45).