Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الأعرَاف

الأعرَاف is chapter 7 of the Quran and has 206 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

206 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 7
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓمٓصٓ

’Alif lām mīm sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

كِتَٰبٌ أُنزِلَ إِلَيۡكَ فَلَا يَكُن فِي صَدۡرِكَ حَرَجٞ مِّنۡهُ لِتُنذِرَ بِهِۦ وَذِكۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ

Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (nìyí). Nítorí náà, wàhálà (iyèméjì) kan kò gbọ́dọ̀ sí nínú ọkàn rẹ lórí rẹ̀ láti fi ṣe ìkìlọ̀ àti ìrántí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

ٱتَّبِعُواْ مَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُمۡ وَلَا تَتَّبِعُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَۗ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ

Ẹ tẹ̀lé ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn wòlíì (ṣaetọ̄n àti òrìṣà) lẹ́yìn Rẹ̀. Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.

Explanation & meanings · 1
  1. Wòlíì túmọ̀ sí alásùn-únmọ́, aláfẹ̀yìntì, ọ̀rẹ́ àti aláàbò.

وَكَم مِّن قَرۡيَةٍ أَهۡلَكۡنَٰهَا فَجَآءَهَا بَأۡسُنَا بَيَٰتًا أَوۡ هُمۡ قَآئِلُونَ

Mélòó mélòó nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́! Ìyà Wa dé bá wọn ní òru tàbí nígbà tí wọ́n ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.

فَمَا كَانَ دَعۡوَىٰهُمۡ إِذۡ جَآءَهُم بَأۡسُنَآ إِلَّآ أَن قَالُوٓاْ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ

Igbe ẹnu wọn kò jẹ́ kiní kan nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn ju pé wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”