Skip to content
الأعرَاف /

Ẹsẹ 142

7 : 142
الأعرَاف Àwọn Ẹsẹ 206
Súrà · الأعرَاف
Yorùbá · Mikail
7 : 142

۞ وَوَٰعَدۡنَا مُوسَىٰ ثَلَٰثِينَ لَيۡلَةٗ وَأَتۡمَمۡنَٰهَا بِعَشۡرٖ فَتَمَّ مِيقَٰتُ رَبِّهِۦٓ أَرۡبَعِينَ لَيۡلَةٗۚ وَقَالَ مُوسَىٰ لِأَخِيهِ هَٰرُونَ ٱخۡلُفۡنِي فِي قَوۡمِي وَأَصۡلِحۡ وَلَا تَتَّبِعۡ سَبِيلَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ

Àti pé A yan ọgbọ̀n òru fún (Ànábì) Mūsā. A tún fi mẹ́wàá kún un. Nítorí náà, àkókò (tí) Olúwa Rẹ̀(dá fún un fún ìbánisọ̀rọ̀) pé ní òru ogójì. (Ànábì) Mūsā sọ fún arákùnrin rẹ̀ Hārūn, pé: “Rólé dè mí láààrin àwọn ènìyàn mi. Kí o máa ṣe àtúnṣe. Má sì ṣe tẹ̀lé ọ̀nà àwọn òbìlẹ̀jẹ́.”

Explanation & meanings · 1
  1. Àwọn onitafsīr sọ pé, Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - gba ààwẹ̀ fún ogójì ọjọ́ láti gbaradì fún ìbànisọ̀rọ̀ náà. Ogójì ọjọ́ náà ni ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Thul-ƙọ'dah àti ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú oṣù Thul-Hijjah.