Skip to content
الأعرَاف /

Ẹsẹ 43

7 : 43

Ẹsẹ 43 of الأعرَاف (7 : 43). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

الأعرَاف Àwọn Ẹsẹ 206
Súrà · الأعرَاف
Yorùbá · Mikail
7 : 43

وَنَزَعۡنَا مَا فِي صُدُورِهِم مِّنۡ غِلّٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهِمُ ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي هَدَىٰنَا لِهَٰذَا وَمَا كُنَّا لِنَهۡتَدِيَ لَوۡلَآ أَنۡ هَدَىٰنَا ٱللَّهُۖ لَقَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُ رَبِّنَا بِٱلۡحَقِّۖ وَنُودُوٓاْ أَن تِلۡكُمُ ٱلۡجَنَّةُ أُورِثۡتُمُوهَا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

A ó sì mú inúnibíni kúrò nínú ọkàn wọn. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn yóò sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fi wá mọ̀nà yìí. Àwa ìbá tí mọ̀nà, tí kì í bá ṣe pé Allāhu tọ́ wa sí ọ̀nà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá.” Wọ́n sì máa pè wọ́n pé: “Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fún yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

Explanation & meanings · 1
  1. Àànú Allāhu la fi máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọgbà Ìdẹ̀ra.