Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الكَهف

الكَهف is chapter 18 of the Quran and has 110 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

110 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 18
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَىٰ عَبۡدِهِ ٱلۡكِتَٰبَ وَلَمۡ يَجۡعَل لَّهُۥ عِوَجَاۜ

Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀.

قَيِّمٗا لِّيُنذِرَ بَأۡسٗا شَدِيدٗا مِّن لَّدُنۡهُ وَيُبَشِّرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرًا حَسَنٗا

(Ó ṣe é ni tírà) tó dúró déédé nítorí kí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí ó lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra);

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé jẹ́ tírà tí kì í gbèfún ìbàjẹ́, irọ́, àbòsí àti ìsọkúsọ.

مَّٰكِثِينَ فِيهِ أَبَدٗا

Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé.

وَيُنذِرَ ٱلَّذِينَ قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗا

Àti nítorí kí ó lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.”

مَّا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٖ وَلَا لِأٓبَآئِهِمۡۚ كَبُرَتۡ كَلِمَةٗ تَخۡرُجُ مِنۡ أَفۡوَٰهِهِمۡۚ إِن يَقُولُونَ إِلَّا كَذِبٗا

Kò sí ìmọ̀ kan kan fún àwọn àti bàbá wọn nípa rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wọn tóbi. Dájúdájú wọn kò wí kiní kan bí kò ṣe irọ́.